Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 38

Saamu Dafidi. Ẹ̀bẹ̀.

38 Olúwa, Má ṣe bá mi wí nínú ìbínú rẹ,
    bẹ́ẹ̀ ni kí o má ṣe fi ìyà jẹ mí nínú ìrunú rẹ̀.
Nítorí tí ọfà rẹ kàn mọ́ mi ṣinṣin,
    ọwọ́ rẹ sì kì mí mọ́lẹ̀.
Kò sí ibi yíyè ní ara à mi, nítorí ìbínú rẹ;
    kò sí àlàáfíà nínú egungun mi nítorí i ẹ̀ṣẹ̀ mi.
Nítorí àìṣedéédéé mi ti borí mi mọ́lẹ̀;
    wọ́n tó ìwọ̀n bi àjàgà tí ó wúwo jù fún mi.

Ọgbẹ́ mi ń rùn ó sì díbàjẹ́
    nítorí òmùgọ̀ mi.
Èmi ń jòwèrè, orí mi tẹ̀ ba gidigidi
    èmi ń ṣọ̀fọ̀ rìn kiri ní gbogbo ọjọ́.
Nítorí ẹ̀gbẹ́ mi kún fún ìgbóná tí ń jóni
    kò sì ṣí ibi yíyè ní ara mi,
Ara mi hù, a sì wó mi jẹ́gẹjẹ̀gẹ;
    mo kérora nítorí ìrúkèrúdò àyà mi.

Olúwa, gbogbo ìfẹ́ mi ń bẹ níwájú rẹ;
    ìmí ẹ̀dùn mi kò sápamọ́ fún ọ.
10 Àyà mi ń mí hẹlẹ, agbára mi yẹ̀ mí sílẹ̀;
    bí ó ṣe ti ìmọ́lẹ̀ ojú mi ni, ó ti lọ kúrò lára mi.
11 Àwọn ọ̀rẹ́ mi àti àwọn ẹlẹgbẹ́ mi dúró lókèèrè réré kúrò níbi ìpọ́njú mi,
    àwọn alábágbé mi, dúró lókèèrè.
12 Àwọn tí n wá ẹ̀mí mi dẹ okùn sílẹ̀ fún mi;
    àti àwọn tí ó fẹ́ pa mí lára ń sọ̀rọ̀ nípa ìparun,
    wọ́n sì ń gbèrò ẹ̀tàn ní gbogbo ọjọ́.

13 Ṣùgbọ́n mo dàbí adití odi, èmi kò gbọ́ ọ̀rọ̀;
    àti bí odi, tí kò le sọ̀rọ̀.
14 Nítòótọ́, mo rí bí ọkùnrin tí kò gbọ́rọ̀,
    àti bí ẹnu ẹni tí kò sí ìjiyàn.
15 Ṣùgbọ́n sí ọ Olúwa, ìwọ ni mo dúró dè;
    ìwọ ni, Olúwa Ọlọ́run mi, ẹni tí yóò dáhùn.
16 Nítorí tí mo gbàdúrà, “Gbóhùn mi, kí wọn má ba à yọ̀ mí;
    nígbà tí ẹsẹ̀ mi bá yọ̀ wọn yóò máa gbé ara wọn ga sí mi.”

17 Nítorí tí mo ti ṣetán láti ṣubú,
    ìrora mi sì wà pẹ̀lú mi nígbà gbogbo.
18 Mo jẹ́wọ́ ìrékọjá mi;
    àánú sì ṣe mí fún ẹ̀ṣẹ̀ mi.
19 Àwọn tí ó jẹ́ ọ̀tá mi láìnídìí pàtàkì, wọ́n lágbára púpọ̀,
    ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn tí ó kórìíra mi lọ́nà òdì.
20 Àwọn tí wọn ń fi ibi san rere fún mi
    àwọn ni ọ̀tá mi
    nítorí pé mò ń tọ ìre lẹ́yìn.

21 Má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀, ìwọ Olúwa!
    Ọlọ́run mi, Má ṣe jìnnà sí mi.
22 Yára láti ràn mí lọ́wọ́,
    Olúwa, Olùgbàlà mi.

Saamu 119:25-48

Àdúrà láti ní òye ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

25 Ọkàn mí lẹ̀ mọ́ erùpẹ̀;
    ìwọ sọ mí di ààyè gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.
26 Èmi tún ọ̀nà mi ṣírò ìwọ sì dá mi lóhùn;
    kọ́ mi ní àṣẹ rẹ.
27 Jẹ́ kí n mọ ẹ̀kọ́ ìlànà rẹ:
    nígbà náà ni èmi yóò ṣe àṣàrò iṣẹ́ ìyanu rẹ.
28 Ọkàn mi ń ṣe àárẹ̀ pẹ̀lú ìbànújẹ́;
    fi agbára fún mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.
29 Pa mí mọ́ kúrò nínú ọ̀nà ẹ̀tàn
    fún mi ní oore-ọ̀fẹ́ nípa òfin rẹ.
30 Èmi ti yan ọ̀nà òtítọ́
    èmi ti gbé ọkàn mi lé òfin rẹ.
31 Èmi yára di òfin rẹ mú. Olúwa
    má ṣe jẹ́ kí ojú kí ó tì mí.
32 Èmi sáré ní ipa ọ̀nà àṣẹ rẹ,
    nítorí ìwọ, ti tú ọkàn mi sílẹ̀.

Ìlérí Ọlọ́run fún aláforítì

33 Kọ́ mi, Olúwa, láti tẹ̀lé àṣẹ rẹ;
    nígbà náà ni èmi yóò pa wọ́n mọ́ dé òpin.
34 Fún mi ní òye, èmi yóò sì pa òfin rẹ mọ́
    èmi yóò sì máa kíyèsi i pẹ̀lú ọkàn mi.
35 Fi ipa ọ̀nà àṣẹ rẹ hàn mí,
    nítorí nínú rẹ̀ ni èmi rí inú dídùn.
36 Yí ọkàn mi padà sí òfin rẹ
    kí ó má ṣe sí ojúkòkòrò mọ́.
37 Yí ojú mi padà kúrò láti máa wo ohun asán:
    pa ọ̀nà mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.
38 Mú ìlérí rẹ sẹ sí ìránṣẹ́ rẹ,
    nítorí òfin rẹ dára.
39 Yí ẹ̀gàn mi padà tí mo bẹ̀rù
    nítorí tí ìdájọ́ rẹ dára.
40 Kíyèsi i, ọkàn mi ti fà sí ẹ̀kọ́ rẹ!
    Pa ayé mi mọ́ nínú òdodo rẹ.

Ìgbàlà láti inú òfin Ọlọ́run

41 Jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ tí kì í kùnà wá bá mi, Olúwa,
    ìgbàlà rẹ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ;
42 Nígbà náà ni èmi yóò dá
    ẹni tí ń sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí mi lóhùn,
    nítorí èmi gbẹ́kẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ.
43 Má ṣe gba ọ̀rọ̀ òtítọ́ láti ẹnu mi
    nítorí èmi ti gbé ìrètí mi sínú àṣẹ rẹ
44 Èmi yóò máa gbọ́rọ̀ sí òfin rẹ nígbà gbogbo
    láé àti láéláé.
45 Èmi yóò máa rìn káàkiri ní òmìnira,
    nítorí èmi ti kígbe ẹ̀kọ́ rẹ jáde.
46 Èmi yóò sọ̀rọ̀ òfin rẹ níwájú àwọn ọba
    ojú kì yóò sì tì mí,
47 Nítorí èmi ní inú dídùn nínú àṣẹ rẹ
    nítorí èmi ní ìfẹ́ wọn.
48 Èmi gbé ọwọ́ mi sókè nítorí àṣẹ rẹ, èyí tí èmi fẹ́ràn,
    èmi sì ń ṣe àṣàrò òfin rẹ̀.

Amosi 8

Agbọ̀n èso pípọ́n

Èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè fihàn mi: agbọ̀n èso pípọ́n. Ó béèrè pé, “Amosi kí ni ìwọ rí.”

Mo sì dáhùn pé, “Agbọ̀n èso pípọ́n.”

Nígbà náà ni Olúwa wí fún mi pé, “Àsìkò náà pọ́n tó fún àwọn ènìyàn mi Israẹli; Èmi kì yóò dá wọn sí mọ́.”

Olúwa Olódùmarè wí pé, “Ní ọjọ́ náà, àwọn orin tẹmpili yóò yí padà sí ohùn réré ẹkún. Ọ̀pọ̀, àní ọ̀pọ̀ ara òkú ni yóò wà ni ibi gbogbo! Àní ni ìdákẹ́ jẹ́ẹ́!”

Ẹ gbọ́ èyí, ẹ̀yin tí ń tẹ aláìní lórí ba,
    tí ẹ sì ń sọ tálákà di ilẹ̀.

Tí ẹ ń wí pé,

“Nígbà wo ni oṣù tuntun yóò parí
    kí àwa bá à lè ta ọkà
kí ọjọ́ ìsinmi kí ó lè dópin
    kí àwa bá à le ta jéró?”
Kí a sì dín ìwọ̀n wa kù
    kí a gbéraga lórí iye tí a ó tà á
    kí a sì fi òṣùwọ̀n èké yàn wọ́n jẹ
Kí àwa lè fi fàdákà ra àwọn tálákà
    kí a sì fi bàtà ẹsẹ̀ méjèèjì ra aláìní
    kí a sì ta jéró tí a kó mọ́ ilẹ̀.

Olúwa ti fi ìgbéraga Jakọbu búra pé: “Èmi kì yóò gbàgbé ọ̀kan nínú ohun tí wọ́n ṣe.

“Ǹjẹ́ ilẹ̀ náà kì yóò ha wárìrì fún èyí?
    Àwọn tí ń gbé inú rẹ̀ kì yóò ha ṣọ̀fọ̀?
Gbogbo ilẹ̀ yóò ru sókè bí omi Naili,
    yóò sì ru ú sókè pátápátá bí ìkún omi
    a ó sì tì í jáde, a ó sì tẹ̀ ẹ́ rì gẹ́gẹ́ bí odò Ejibiti.

“Yóò sì ṣe ní ọjọ́ náà,” ni Olúwa Olódùmarè wí,

“Èmi yóò mú oòrùn wọ̀ ní ọ̀sán,
    Èmi yóò mú kí ayé ṣókùnkùn ní ọ̀sán gangan.
10 Èmí yóò yí àsè ẹ̀sìn yín padà sí ọ̀fọ̀,
    gbogbo orin yín ni èmi yóò sọ di ẹkún.
Èmi yóò mú kí gbogbo yín wọ aṣọ ọ̀fọ̀,
    kí a sì fá orí yín.
Èmi yóò mú kí ìgbà náà rí bí ìṣọ̀fọ̀ fún ọmọkùnrin
    kan ṣoṣo tí a bí àti òpin rẹ̀ bí ọjọ́ kíkorò.

11 “Ọjọ́ ń bọ̀,” ni Olúwa Olódùmarè wí,
    “nígbà tí èmi yóò rán ìyàn sí ilẹ̀ náà,
kì í ṣe ìyàn oúnjẹ tàbí òǹgbẹ fún omi.
    Ṣùgbọ́n ìyàn gbígbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa.
12 Àwọn ènìyàn yóò rìn kiri láti Òkun dé Òkun
    wọn yóò sì máa rìn ká láti gúúsù sí àríwá,
wọn yóò máa wá ọ̀rọ̀ Olúwa
    ṣùgbọ́n wọn kì yóò rí i.

13 “Ní ọjọ́ náà

“àwọn arẹwà wúńdíá àti àwọn alágbára ọ̀dọ́mọkùnrin
    yóò dákú fún òǹgbẹ omi.
14 Àwọn tí ó fi ẹ̀ṣẹ̀ Samaria búra,
    tí wọ́n sì wí pé, ‘Bí ó ti dájú pé ọlọ́run rẹ ń bẹ láààyè, ìwọ Dani,’
    Bí ó ti dájú pè ọlọ́run rẹ ń bẹ láààyè, ìwọ Beerṣeba
Wọ́n yóò ṣubú,
    Wọn kì yóò si tún dìde mọ.”

Ìfihàn 1:17-2:7

17 (A)Nígbà tí mo rí i, mo wólẹ̀ ní ẹsẹ̀ rẹ̀ bí ẹni tí ó kú. Ó sì fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ lé mi, ó ń wí fún mi pé, “Má ṣe bẹ̀rù. Èmi ni ẹni ìṣáájú àti ẹni ìkẹyìn. 18 Èmi ni ẹni tí ó ń bẹ láààyè, tí ó sì ti kú; sì kíyèsi i, èmi sì ń bẹ láààyè sí i títí láé! Mo sì ní kọ́kọ́rọ́ ikú àti ti ipò òkú lọ́wọ́.

19 “Kọ̀wé nítorí náà ohun tí ìwọ ti rí, àti ti ohun tí ń bẹ, àti ti ohun tí yóò hù lẹ́yìn èyí; 20 ohun ìjìnlẹ̀ tí ìràwọ̀ méje náà tí ìwọ rí ní ọwọ́ ọ̀tún mi, àti ọ̀pá wúrà fìtílà méje náà. Ìràwọ̀ méje ni àwọn angẹli ìjọ méje náà: àti ọ̀pá fìtílà méje náà ní àwọn ìjọ méje.

Sí ìjọ Efesu

“Sí angẹli ìjọ ní Efesu kọ̀wé:

Nǹkan wọ̀nyí ní ẹni tí ó mú ìràwọ̀ méje náà ni ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ wí, ẹni tí ń rìn ní àárín ọ̀pá wúrà fìtílà méje:

Èmi mọ iṣẹ́ rẹ, àti làálàá rẹ, àti ìfaradà rẹ, àti bí ara rẹ kò ti gba àwọn ẹni búburú: àti bí ìwọ sì ti dán àwọn tí ń pe ara wọn ní aposteli, tí wọ́n kì í sì í ṣe bẹ́ẹ̀ wo, tí ìwọ sì rí pé èké ni wọ́n; Tí ìwọ sì faradà ìyà, àti nítorí orúkọ mi tí ó sì rọ́jú, tí àárẹ̀ kò sì mú ọ.

Síbẹ̀ èyí ni mo rí wí sí ọ, pé, ìwọ ti fi ìfẹ́ ìṣáájú rẹ sílẹ̀. Rántí ibi tí ìwọ ti gbé ṣubú! Ronúpìwàdà, kí ó sì ṣe iṣẹ́ ìṣáájú; bí kò sì ṣe bẹ́ẹ̀, èmi ó sì tọ̀ ọ́ wá, èmi ó sì ṣí ọ̀pá fìtílà rẹ̀ kúrò ní ipò rẹ̀, bí kò ṣe bí ìwọ bá ronúpìwàdà. Ṣùgbọ́n èyí ni ìwọ ní, pé ìwọ kórìíra ìṣe àwọn Nikolatani, èyí tí èmi pẹ̀lú sì kórìíra.

(B)Ẹni tí ó bá ní etí kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ. Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun ni èmi yóò fi èso igi ìyè nì fún jẹ, tí ń bẹ láàrín Paradise Ọlọ́run.

Matiu 23:1-12

Ìdí méje fún ìdájọ́

23 Nígbà náà ni Jesu wí fún ọ̀pọ̀ ènìyàn àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Àwọn olùkọ́ òfin àti àwọn Farisi jókòó ní ipò Mose, Nítorí náà, ẹ gbọdọ̀ gbọ́ tiwọn, kí ẹ sì ṣe ohun gbogbo tí wọ́n bá sọ fún yín. Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe ohun tí wọ́n ṣe, nítorí àwọn pàápàá kì í ṣe ohun tí wọn kọ́ yín láti ṣe. Wọ́n á di ẹrù wúwo tí ó sì ṣòro láti rù, wọ́n a sì gbé e le àwọn ènìyàn léjìká, ṣùgbọ́n àwọn tìkára wọn kò jẹ́ fi ìka wọn kan an.

(A)“Ohun gbogbo tí wọ́n ń ṣe, wọ́n ń ṣe é kí àwọn ènìyàn ba à lè rí wọn ni: Wọ́n ń sọ filakteri wọn di gbígbòòrò. Wọ́n tilẹ̀ ń bùkún ìṣẹ́tí aṣọ oyè wọn nígbà gbogbo kí ó ba à lè máa tóbi sí i. Wọ́n fẹ́ ipò ọlá ní ibi àsè, àti níbi ìjókòó ìyàsọ́tọ̀ ni Sinagọgu. Wọ́n fẹ́ kí ènìyàn máa kí wọn ní ọjà, kí àwọn ènìyàn máa pè wọ́n ní ‘Rabbi.’

(B)“Ṣùgbọ́n kí a má ṣe pè yín ni Rabbi, nítorí pé ẹnìkan ni Olùkọ́ yín, àní Kristi, ará sì ni gbogbo yín. Ẹ má ṣe pe ẹnikẹ́ni ní baba yín ni ayé yìí, nítorí baba kan náà ni ẹ ní tí ó ń bẹ ní ọ̀run. 10 Kí a má sì ṣe pè yín ní Olùkọ́ nítorí Olùkọ́ kan ṣoṣo ni ẹ̀yin ní, òun náà ni Kristi. 11 Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá pọ̀jù nínú yín, ni yóò jẹ́ ìránṣẹ́ yín. 12 Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga ni a ó sì rẹ̀ sílẹ̀, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì rẹ ara wọn sílẹ̀ ni a ó gbéga.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.