Book of Common Prayer
Kíkígbe fún ìgbàlà
145 Èmi kígbe pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi:
dá mi lóhùn Olúwa,
èmi yóò sì gbọ́rọ̀ sí àṣẹ rẹ.
146 Èmi kígbe pè ọ́; gbà mí
èmi yóò sì pa òfin rẹ mọ́.
147 Èmi dìde ṣáájú àfẹ̀mọ́júmọ́ èmi ké fún ìrànlọ́wọ́;
èmi ti mú ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ rẹ.
148 Ojú mi ṣáájú ìṣọ́ òru,
nítorí kí èmi lè ṣe àṣàrò nínú ọ̀rọ̀ rẹ.
149 Gbọ́ ohùn mi ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ:
pa ayé mi mọ́, Olúwa, gẹ́gẹ́ bí òfin rẹ.
150 Àwọn tí ń gbìmọ̀ ìlànà búburú wà ní tòsí,
ṣùgbọ́n wọ́n jìnnà sí òfin rẹ.
151 Síbẹ̀ ìwọ wà ní tòsí, Olúwa,
àti gbogbo àṣẹ rẹ jẹ́ òtítọ́.
152 Láti ọjọ́ pípẹ́ wá èmi ti kọ́ nínú òfin rẹ
tí ìwọ ti fi ìdí wọn múlẹ̀ láéláé.
Pípa òfin mọ́ ni ìpọ́njú
153 Wo ìpọ́njú mi kí o sì gbà mí,
nítorí èmi kò gbàgbé òfin rẹ.
154 Gba ẹjọ́ mi rò kí o sì rà mí padà;
pa ayé mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ.
155 Ìgbàlà jìnnà sí àwọn ẹni búburú
nítorí wọn kò wá àṣẹ rẹ.
156 Ìyọ́nú rẹ̀ tóbi, Olúwa;
pa ayé mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí òfin rẹ.
157 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn ọ̀tá tí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí mi,
ṣùgbọ́n èmi kò tí ì yípadà kúrò nínú òfin rẹ.
158 Èmi wo àwọn ẹlẹ́tàn, inú mi sì bàjẹ́
nítorí wọn kò gba ọ̀rọ̀ rẹ gbọ́.
159 Wo bí èmi ṣe fẹ́ràn ẹ̀kọ́ rẹ;
pa ayé mi mọ́, Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ.
160 Òtítọ́ ni gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ;
gbogbo òfin òdodo rẹ láéláé ni.
161 Àwọn alákòóso ṣe inúnibíni sí mi láìnídìí,
ṣùgbọ́n ọkàn mi wárìrì sí ọ̀rọ̀ rẹ.
162 Èmi yọ̀ nínú ìpinnu rẹ
bí ẹni tí ó rí ìkógun púpọ̀.
163 Èmi kórìíra mo sì kọ èké ṣíṣe
ṣùgbọ́n mo fẹ́ràn òfin rẹ.
164 Èmi yìn ọ́ ní ìgbà méje lójúmọ́
nítorí òfin òdodo rẹ.
165 Àlàáfíà púpọ̀ wà fún àwọn tí ó ní ìfẹ́ sí òfin rẹ,
kò sì ṣí ohun tí ó lè mú wọn kọsẹ̀.
166 Èmi yóò dúró de ìgbàlà rẹ, Olúwa,
èmi yóò sì tẹ̀lé àṣẹ rẹ.
167 Èmi gba òfin rẹ gbọ́,
nítorí mo fẹ́ràn wọn púpọ̀púpọ̀
168 Èmi ṣe ìgbọ́ràn sí ẹ̀kọ́ rẹ àti òfin rẹ,
nítorí ìwọ mọ gbogbo ọ̀nà mi.
169 Jẹ́ kí igbe mi wá sí iwájú rẹ, Olúwa;
fún mi ní òye gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.
170 Jẹ́ kí ẹ̀bẹ̀ mi wá sí iwájú rẹ;
gbà mí gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ.
171 Ètè mi yóò sọ ìyìn jáde,
nítorí ìwọ kọ́ mi ní ìlànà rẹ.
172 Jẹ́ kí ahọ́n mi kọ orin ọ̀rọ̀ rẹ,
nítorí gbogbo àṣẹ rẹ jẹ́ òdodo.
173 Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ ṣetán láti ràn mí lọ́wọ́,
nítorí èmi ti yan ẹ̀kọ́ rẹ.
174 Èmi wo ọ̀nà fún ìgbàlà rẹ, Olúwa,
àti òfin rẹ jẹ́ dídùn inú mi.
175 Jẹ́ kí èmi wà láààyè ki èmi lè yìn ọ́,
kí o sì jẹ́ kí òfin rẹ mú mi dúró.
176 Èmí ti ṣìnà bí àgùntàn tí ó
sọnù, wá ìránṣẹ́ rẹ,
nítorí èmi kò gbàgbé àṣẹ rẹ.
Orin fún ìgòkè.
Ìbẹ̀rù Olúwa dára
128 Ìbùkún ni fún gbogbo ẹni tí ó bẹ̀rù Olúwa:
tí ó sì ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀
2 Nítorí tí ìwọ yóò jẹ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ
ìbùkún ni fún ọ; yóò sì dára fún ọ
3 Obìnrin rẹ yóò dàbí àjàrà rere
eléso púpọ̀ ní àárín ilé rẹ;
àwọn ọmọ rẹ yóò dàbí igi olifi tí ó yí tábìlì rẹ ká.
4 Kíyèsi i pé, bẹ́ẹ̀ ni a ó bùsi i fún ọkùnrin náà,
tí ó bẹ̀rù Olúwa.
5 Kí Olúwa kí ó bùsi i fún ọ láti Sioni wá,
kí ìwọ kí ó sì máa rí ìre
Jerusalẹmu ní ọjọ́ ayé rẹ gbogbo.
6 Bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ kí ó sì máa rí àti ọmọdọ́mọ rẹ.
Láti àlàáfíà lára Israẹli.
Orin fún ìgòkè.
129 “Ìgbà púpọ̀ ni wọ́n ti pọ́n mi lójú
láti ìgbà èwe mi wá”
ni kí Israẹli kí ó wí nísinsin yìí;
2 “Ìgbà púpọ̀ ni wọ́n ti pọ́n mi lójú
láti ìgbà èwe mi wá;
síbẹ̀ wọn kò tí ì borí mi.
3 Àwọn awalẹ̀ walẹ̀ sí ẹ̀yìn mi:
wọ́n sì la aporo wọn gígùn.
4 Olódodo ni Olúwa:
ó ti ké okùn àwọn ènìyàn búburú kúrò.”
5 Kí gbogbo àwọn tí ó kórìíra Sioni kí ó dààmú,
kí wọn kí ó sì yí ẹ̀yìn padà.
6 Kí wọn kí ó dàbí koríko orí ilẹ̀
tí ó gbẹ dànù kí ó tó dàgbàsókè:
7 Èyí tí olóko pípa kó kún ọwọ́ rẹ̀:
bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ń di ìtí, kó kún apá rẹ̀.
8 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn tí ń kọjá lọ kò wí pé,
ìbùkún Olúwa kí ó pẹ̀lú yín:
àwa ń súre fún yin ní orúkọ Olúwa.
Orin fún ìgòkè.
130 Láti inú ibú wá ni
èmi ń ké pè é ọ́ Olúwa
2 Olúwa, gbóhùn mi,
jẹ́ kí etí rẹ kí o tẹ́ sílẹ̀ sí ohùn ẹ̀bẹ̀ mi.
3 (A)Olúwa, ìbá ṣe pé kí ìwọ máa sàmì ẹ̀ṣẹ̀,
Olúwa, tá ni ìbá dúró.
4 Nítorí ìdáríjì wà lọ́dọ̀ rẹ,
kí a lè máa bẹ̀rù rẹ.
5 Èmi dúró de Olúwa, ọkàn mi dúró,
àti nínú ọ̀rọ̀ rẹ ni èmi ń ṣe ìrètí
6 Ọkàn mi dúró de Olúwa,
ju àwọn tí ń ṣọ́nà òwúrọ̀ lọ,
àní ju àwọn tí ń ṣọ́nà òwúrọ̀ lọ.
7 Israẹli, ìwọ ní ìrètí ní ti Olúwa:
nítorí pé lọ́dọ̀ Olúwa ni àánú wà,
àti lọ́dọ̀ rẹ̀ ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdáǹdè wà.
8 Òun ó sì dá Israẹli ní ìdè
kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ gbogbo.
15 “Nítorí ọjọ́ Olúwa súnmọ́ etílé
lórí gbogbo àwọn kèfèrí.
Bí ìwọ ti ṣe, bẹ́ẹ̀ ni a ó ṣe sí ìwọ náà;
ẹ̀san rẹ yóò sì yípadà sí orí ara rẹ.
16 Gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀ ṣe mu lórí òkè mímọ́ mi
bẹ́ẹ̀ ni gbogbo kèfèrí yóò máa mu títí
Wọn yóò mu wọn yóò sì mu àmutẹ́rùn
wọn yóò sì wà bí ẹni pé wọn kò wà rí
17 Ṣùgbọ́n ìgbàlà yóò wà lórí òkè Sioni
Wọn yóò sì jẹ́ mímọ́
àti ilé Jakọbu yóò sì ní ìní wọn
18 Ilé Jakọbu yóò sì jẹ́ iná
àti ilé Josẹfu ọwọ́ iná
ilé Esau yóò jẹ àgékù koríko
wọn yóò fi iná sí i,
wọn yóò jo run.
Kì yóò sí ẹni tí yóò kù ní ilé Esau.”
Nítorí Olúwa ti sọ̀rọ̀.
19 Àwọn ará gúúsù yóò ni òkè Esau,
àwọn ará ẹsẹ̀ òkè yóò ni
ilẹ̀ àwọn ará Filistini ní ìní.
Wọn yóò sì ni oko Efraimu àti Samaria;
Benjamini yóò ní Gileadi ní ìní.
20 Àwọn ìgbèkùn Israẹli tí ó wà ní Kenaani
yóò ni ilẹ̀ títí dé Sarefati;
àwọn ìgbèkùn láti Jerusalẹmu tí ó wà ní Sefaredi
yóò ni àwọn ìlú gúúsù ní ìní
21 Àwọn tó ń gba ni là yóò sì gòkè Sioni wá
láti jẹ ọba lé orí àwọn òkè Esau.
Ìjọba náà yóò sì jẹ́ ti Olúwa.
2 Nítorí náà, ẹ fi àrankàn gbogbo sílẹ̀ ni apá kan, àti ẹ̀tàn gbogbo, àti àgàbàgebè, àti ìlara, àti sísọ ọ̀rọ̀ búburú gbogbo. 2 Bí ọmọ ọwọ́ tuntun, kí ẹ máa fẹ́ wàrà ti Ẹ̀mí, èyí tí kò lẹ́tàn, kí ẹ̀yin lè máa tipasẹ̀ rẹ̀ dàgbà sí ìgbàlà, 3 (A)nísinsin yìí tí ẹ̀yin ti tọ́ ọ wò pé rere ni Olúwa.
Àpáta iyè àti ènìyàn tí a yàn
4 (B)Ẹni tí ẹ̀yin ń tọ̀ bọ̀, sí bi òkúta ààyè náà, èyí ti a ti ọwọ́ ènìyàn kọ̀ sílẹ̀ nítòótọ́, ṣùgbọ́n lọ́dọ̀ Ọlọ́run, àṣàyàn òkúta iyebíye. 5 Ẹ̀yin pẹ̀lú, bí òkúta ààyè, ni a kọ́ ní ilé ẹ̀mí, àlùfáà mímọ́, láti máa rú ẹbọ ẹ̀mí, tí i ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run nípa Jesu Kristi. 6 (C)Nítorí nínú Ìwé Mímọ́, ó wí pe:
“Kíyèsi i, mo fi pàtàkì òkúta igun ilé àṣàyàn,
iyebíye, lélẹ̀ ni Sioni:
ẹni tí ó bá sì gbà á gbọ́
ojú kì yóò tì í.”
7 (D)Báyìí fún ẹ̀yin ti ẹ gbà á gbọ́, ó ṣe iyebíye; ṣùgbọ́n fún àwọn tí kò gbà á gbọ́,
“Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀sílẹ̀,
òun ni ó di pàtàkì igun ilé,”
8 (E)àti pẹ̀lú,
“Òkúta ìdìgbòlù,
àti àpáta ìkọ̀sẹ̀.”
Nítorí wọ́n kọsẹ̀ nípa ṣíṣe àìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ náà, sínú èyí tí a gbé yàn wọ́n sí pẹ̀lú.
9 (F)Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ni ìran tí a yàn olú àlùfáà, Orílẹ̀-èdè mímọ́, Ènìyàn ọ̀tọ̀ ki ẹ̀yin lè fi ọláńlá ẹni tí ó pè yín jáde kúrò nínú òkùnkùn sínú ìmọ́lẹ̀ ìyanu rẹ̀ hàn: 10 (G)Ẹ̀yin tí kì í ṣe ènìyàn nígbà kan rí, ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ẹ̀yin ti di ènìyàn Ọlọ́run, ẹ̀yin tí kò rí àánú gbà rí, ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ẹ ti rí àánú gbà.
23 (A)Nígbà náà, ní Jesu wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín pé, ó ṣòro fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọ̀run.” 24 Mo tún wí fún yín pé, “Ó rọrùn fún ìbákasẹ láti wọ ojú abẹ́rẹ́ jù fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọ́run.”
25 Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn gbọ́ èyí, ẹnu sì yà wọn gidigidi, wọ́n béèrè pé, “Ǹjẹ́ ta ni ó ha le là?”
26 (B)Ṣùgbọ́n Jesu wò wọ́n, ó sì wí fún wọn pé, “Ènìyàn ni èyí ṣòro fún; ṣùgbọ́n fún Ọlọ́run ohun gbogbo ni ṣíṣe.”
27 (C)Peteru sì wí fún un pé, “Àwa ti fi ohun gbogbo sílẹ̀, a sì tẹ̀lé ọ, kí ni yóò jẹ́ èrè wa?”
28 (D)Jesu dáhùn pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín pé, ‘Nígbà ìsọdọ̀tun ohun gbogbo, nígbà tí Ọmọ Ènìyàn yóò jókòó lórí ìtẹ́ tí ó lógo, dájúdájú, ẹ̀yin ọmọ-ẹ̀yìn mi yóò sì jókòó lórí ìtẹ́ méjìlá láti ṣe ìdájọ́ ẹ̀yà Israẹli méjìlá. 29 Àti pé ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ilé tàbí arákùnrin tàbí arábìnrin tàbí baba tàbí ìyá tàbí àwọn ọmọ, tàbí ohun ìní rẹ̀ sílẹ̀ nítorí orúkọ mí, yóò gba ọgọọgọ́rùn-ún èrè rẹ̀ láyé, wọn ó sì tún jogún ìyè àìnípẹ̀kun. 30 Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ àwọn tí ó síwájú nísinsin yìí ni yóò kẹ́yìn, àwọn tí ó kẹ́yìn ni yóò sì síwájú.’
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.