Book of Common Prayer
Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi.
140 Olúwa, gbà mi lọ́wọ́ ọkùnrin búburú u nì,
yọ mí lọ́wọ́ ọkùnrin ìkà a nì;
2 Ẹni tí ń ro ìwà búburú ní inú wọn;
nígbà gbogbo ni wọ́n ń rú ìjà sókè sí mi.
3 Wọ́n ti pọ́n ahọ́n wọn bí ejò,
oró paramọ́lẹ̀ ń bẹ ní abẹ́ ètè wọn.
4 Olúwa, pa mí mọ́ kúrò lọ́wọ́ àwọn ènìyàn búburú;
yọ mí kúrò lọ́wọ́ ọkùnrin ìkà a nì
ẹni tí ó ti pinnu rẹ̀ láti bi ìrìn mi ṣubú
5 Àwọn agbéraga ti dẹkùn sílẹ̀ fún mi àti okùn:
wọ́n ti na àwọ̀n lẹ́bàá ọ̀nà;
wọ́n ti kẹ́kùn sílẹ̀ fún mi.
6 Èmi wí fún Olúwa pé ìwọ ni Ọlọ́run mi;
Olúwa, gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi.
7 Olúwa Olódùmarè, agbára ìgbàlà mi,
ìwọ ni ó bo orí mi mọ́lẹ̀ ní ọjọ́ ìjà.
8 Olúwa, máa ṣe fi ìfẹ́ ènìyàn búburú fún un;
Má ṣe kún ọgbọ́n búburú rẹ̀ lọ́wọ́;
kí wọn kí ó máa ba à gbé ara wọn ga. Sela.
9 Bí ó ṣe ti orí àwọn tí ó yí mi káàkiri ni,
jẹ́ kí ète ìka ara wọn kí ó bò wọ́n mọ́lẹ̀.
10 A ó da ẹ̀yin iná sí wọn lára:
Òun yóò wọ́ wọn lọ sínú iná,
sínú ọ̀gbun omi jíjìn,
kí wọn kí ó má ba à le dìde mọ́.
11 Má ṣe jẹ́ kí aláhọ́n búburú fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ ní ayé;
ibi ni yóò máa dọdẹ ọkùnrin ìkà nì láti bì í ṣubú.
12 Èmi mọ̀ pé, Olúwa yóò mú ọ̀nà olùpọ́njú dúró,
yóò sì ṣe ẹ̀tọ́ fún àwọn tálákà
13 Nítòótọ́ àwọn olódodo yóò
máa fi ọpẹ́ fún orúkọ rẹ;
àwọn ẹni dídúró ṣinṣin yóò máa gbé iwájú rẹ.
Maskili ti Dafidi. Nígbà tí ó wà nínú ihò òkúta. Àdúrà.
142 Èmi kígbe sókè sí Olúwa;
Èmi gbé ohùn mi sókè sí Olúwa fún àánú.
2 Èmi tú àròyé mí sílẹ̀ níwájú rẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ní èmi fi iṣẹ́ mi hàn níwájú rẹ̀.
3 Nígbà tí ẹ̀mí mi ṣàárẹ̀ nínú mi,
ìwọ ni ẹni tí ó mọ ọ̀nà mi.
Ní ipa ọ̀nà tí èmi ń rìn
ènìyàn ti dẹ okùn fún mi ní ìkọ̀kọ̀
4 Wo ọwọ́ ọ̀tún mi kí ó sì rì i
kò sí ẹni tí ó ṣe àníyàn mi
èmi kò ní ààbò;
kò sí ẹni tí ó náání ọkàn mi.
5 Èmi kígbe sí ọ, Olúwa:
èmi wí pé, “ìwọ ni ààbò mi,
ìpín mi ní ilẹ̀ alààyè.”
6 Fi etí sí igbe mi,
nítorí tí èmi wà nínú àìnírètí
gbà mí lọ́wọ́ àwọn tí ń lépa mi,
nítorí wọ́n lágbára jù mí lọ
7 Mú ọkàn mi jáde kúrò nínú túbú,
kí èmi lè máa yin orúkọ rẹ.
Nígbà náà ni àwọn olódodo yóò yí mi káàkiri
nítorí ìwọ yóò fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ba mi ṣe.
Saamu ti Dafidi.
141 Olúwa, èmi ké pè ọ́; yára wá sí ọ̀dọ̀ mi.
Gbọ́ ohùn mi, nígbà tí mo bá ń ké pè ọ́.
2 Jẹ́ kí àdúrà mi ó wá sí iwájú rẹ bí ẹbọ tùràrí
àti ìgbé ọwọ́ mi si òkè rí bí ẹbọ àṣálẹ́.
3 Fi ẹ̀ṣọ́ ṣọ́ ẹnu mi, Olúwa:
kí o sì máa pa ìlẹ̀kùn ètè mi mọ́.
4 Má ṣe jẹ́ kí ọkàn mi fà sí ohun tí ń ṣe ibi,
Láti máa bá àwọn tí ń ṣiṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ búburú
má sì ṣe jẹ́ kí èmi jẹ àdídùn wọn.
5 Jẹ́ kí olódodo lù mí: ìṣeun ni ó jẹ́:
jẹ́ kí ó bá mi wí, ó jẹ́ òróró ní orí mi.
Tí kì yóò fọ́ mi ní orí.
Síbẹ̀ àdúrà mi wá láìsí ìṣe àwọn olùṣe búburú
6 A ó ju àwọn alákòóso sílẹ̀ láti bẹ̀bẹ̀ òkúta,
àwọn ẹni búburú yóò kọ pé àwọn ọ̀rọ̀ mi dùn.
7 Wọn yóò wí pé, “Bí ẹni tí ó la aporo sórí ilẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ni egungun wa tànkálẹ̀ ní ẹnu isà òkú.”
8 Ṣùgbọ́n ojú mi ń bẹ lára rẹ, Olúwa Olódùmarè;
nínú rẹ̀ ni èmi ti rí ààbò, má ṣe fà mi fún ikú.
9 Pa mí mọ́ kúrò nínú okùn tí wọn ti dẹ sílẹ̀ fún mi,
kúrò nínú ìkẹ́kùn àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.
10 Jẹ́ kí àwọn ẹni búburú ṣubú sínú àwọ̀n ara wọn,
nígbà tí èmi bá kọjá lọ láìléwu.
Saamu ti Dafidi.
143 Olúwa gbọ́ àdúrà mi,
fetísí igbe mi fún àánú;
nínú òtítọ́ àti òdodo rẹ, wá fún ìrànlọ́wọ́ mi
2 (A)Má ṣe mú ìránṣẹ́ rẹ wá sí ìdájọ́,
nítorí kò sí ẹnìkan tí ó wà láààyè
tí ó ṣe òdodo níwájú rẹ.
3 Ọ̀tá ń lépa mi,
ó fún mi pamọ́ ilẹ̀;
ó mú mi gbé nínú òkùnkùn
bí àwọn tí ó ti kú ti pẹ́.
4 Nítorí náà ẹ̀mí mi ṣe rẹ̀wẹ̀sì nínú mi;
ọkàn mi nínú mi ṣì pòruurù.
5 Èmi rántí ọjọ́ tí ó ti pẹ́;
èmi ń ṣe àṣàrò lórí gbogbo iṣẹ́ rẹ
mo sì ṣe àkíyèsí ohun tí ọwọ́ rẹ ti ṣe.
6 Èmi na ọwọ́ mi jáde sí ọ:
òǹgbẹ rẹ gbẹ ọkàn mi bí i ìyàngbẹ ilẹ̀. Sela.
7 Dá mi lóhùn kánkán, Olúwa;
ó rẹ ẹ̀mí mi tán.
Má ṣe pa ojú rẹ mọ́ kúrò lára mi
kí èmi má ba à dàbí àwọn tí ó lọ sínú ihò
8 Mú mi gbọ́ ìṣeun ìfẹ́ rẹ ní òwúrọ̀:
nítorí ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀lé.
Fi ọ̀nà tí èmi i bá rìn hàn mí,
nítorí èmi gbé ọkàn mi sókè sí ọ.
9 Gbà mí kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi, Olúwa,
nítorí èmi fi ara mi pamọ́ sínú rẹ.
10 Kọ́ mi láti ṣe ìfẹ́ rẹ,
nítorí ìwọ ni Ọlọ́run mi
jẹ́ kí ẹ̀mí rẹ dídára
darí mi sí ilẹ̀ tí ó tẹ́jú.
11 Nítorí orúkọ rẹ, Olúwa, sọ mi di ààyè;
nínú òdodo rẹ, mú ọkàn mi jáde nínú wàhálà.
12 Nínú ìfẹ́ rẹ tí kì í kùnà, ké àwọn ọ̀tá mi kúrò,
run gbogbo àwọn tí ń ni ọkàn mi lára,
nítorí pé èmi ni ìránṣẹ́ rẹ.
Jehoiakimu ọba Juda
36 (A)Jehoiakimu jẹ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mọ́kànlá orúkọ ìyá rẹ̀ ni Sebida ọmọbìnrin Pedaiah ó wá láti Ruma. 37 Ó sì ṣe búburú lójú Olúwa gẹ́gẹ́ bí baba a rẹ̀ ti ṣe.
24 Nígbà ìjọba Jehoiakimu, Nebukadnessari ọba Babeli gbógun sí ilẹ̀ náà, Jehoiakimu sì di ẹrú rẹ̀ fún ọdún mẹ́ta. Ṣùgbọ́n nígbà náà ó yí ọkàn rẹ̀ padà ó sì ṣọ̀tẹ̀ sí Nebukadnessari. 2 Olúwa sì rán àwọn ará Babeli, àwọn ará Aramu, àwọn ará Moabu àti àwọn ọmọ Ammoni. Ó rán wọn láti pa Juda run, ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó ti sọ nípasẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wòlíì. 3 Nítòótọ́ eléyìí ṣẹlẹ̀ sí Juda gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Olúwa, láti mú wọn kúrò níwájú rẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ Manase àti gbogbo nǹkan tí ó ṣe. 4 Àti pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ tí a ta sílẹ̀ nítorí ó ti kún Jerusalẹmu pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ tí Olúwa kò sì fẹ́ láti dáríjì.
5 Ní ti ìyókù iṣẹ́ ìjọba Jehoiakimu, àti gbogbo nǹkan tí ó ṣe, ṣé wọn kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ọba Juda? 6 Jehoiakimu sùn pẹ̀lú baba rẹ̀, Jehoiakini ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.
7 Ọba Ejibiti kò sì tún jáde ní ìlú rẹ̀ mọ́, nítorí ọba Babeli ti gba gbogbo agbègbè rẹ̀ láti odò Ejibiti lọ sí odò Eufurate.
Jehoiakini ọba Juda
8 (B)Jehoiakini jẹ́ ẹni ọdún méjì-dínlógún nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún oṣù mẹ́ta. Orúkọ ìyá rẹ̀ a sì máa jẹ́ Nehuṣita ọmọbìnrin Elnatani; ó wá láti Jerusalẹmu. 9 Ó sì ṣe búburú ní ojú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí baba rẹ̀ ti ṣe.
10 Ní àkókò náà àwọn ìránṣẹ́ Nebukadnessari ọba Babeli gbé ogun wá Jerusalẹmu, wọ́n sì gbé dó ti ìlú náà, 11 Nebukadnessari ọba Babeli fúnrarẹ̀ wá sókè sí ìlú nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ fi ogun dó tì í. 12 Jehoiakini ọba Juda àti ìyá rẹ̀ àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àti àwọn ìwẹ̀fà àti àwọn ìjòyè gbogbo wọn sì jọ̀wọ́ ara wọn fún un.
Ní ọdún kẹjọ ìjọba rẹ̀ ti ọba Babeli ó mú Jehoiakini ẹlẹ́wọ̀n. 13 Gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ Nebukadnessari kó gbogbo ìṣúra láti inú ilé Olúwa àti láti ilé ọba, ó sì mú u lọ gbogbo ohun èlò wúrà ti Solomoni ọba Israẹli ti kọ́ fún Olúwa. 14 Ó kó wọn lọ sí ìgbèkùn gbogbo Jerusalẹmu: gbogbo ìjòyè àti àwọn akọni alágbára ọkùnrin, àti gbogbo oníṣọ̀nà àti ọlọ́nà tí àpapọ̀ rẹ̀ jẹ́ ẹgbàárùn-ún ún, àwọn tálákà ènìyàn ilẹ̀ náà nìkan ni ó kù.
15 Nebukadnessari mú Jehoiakini ní ìgbèkùn lọ sí Babeli. Ó sì tún mú ìyá ọba láti Jerusalẹmu lọ sí Babeli, ìyàwó rẹ̀ àwọn ìjòyè rẹ̀ àti àwọn olórí ilé náà. 16 Àti gbogbo àwọn ọkùnrin ọlọ́lá tí ó jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (7,000) alágbára ọkùnrin, àti àwọn oníṣọ̀nà àti alágbẹ̀dẹ, ẹgbẹ̀rún (1,000), gbogbo àwọn alágbára tí ó yẹ fún ogun ni ọba Babeli kó ní ìgbèkùn lọ sí Babeli 17 Ọba Babeli sì mú Mattaniah arákùnrin baba Jehoiakini, jẹ ọba ní ìlú rẹ̀ ó sì yí orúkọ rẹ̀ padà sí Sedekiah.
12 (A)Ara jẹ́ ọ̀kan tí ó ní àwọn ẹ̀yà púpọ̀, ṣùgbọ́n gbogbo àwọn ẹ̀yà ara tí ó pọ̀ wọ̀nyí ni ó papọ̀ láti jẹ́ ara kan ṣoṣo. Bákan náà ni ó rí pẹ̀lú ara Kristi tí í ṣe ìjọ. 13 (B)Nítorí pé nínú Ẹ̀mí kan ní a ti bamitiisi gbogbo wa sínú ara kan, ìbá à ṣe Júù, ìbá à ṣe Giriki, ìbá à ṣe ẹrú, ìbá à ṣe òmìnira, gbogbo wa ni a mu nínú Ẹ̀mí Mímọ́ kan náà. 14 Bẹ́ẹ̀ ni, ara, kì í ṣe ẹ̀yà kan ṣoṣo bí kò ṣe púpọ̀.
15 Tí ẹsẹ̀ bá wí pé, “Nítorí èmi kì í ṣe ọwọ́, èmi kì í ṣe ti ara,” èyí kò wí pé kì í ṣe ọ̀kan lára nínú ẹ̀yà ara. 16 Bí etí bá wí pé, “Nítorí èmi kì í ṣe ojú, èmi kì í ṣe apá kan ara,” èyí kò le mú kí ó má jẹ́ apá kan ara mọ́ 17 Bí gbogbo ara bá jẹ́ ojú, níbo ni ìgbọ́ran ìbá gbé wà? Bí gbogbo ara bá jẹ́ etí, níbo ni ìgbóórùn ìbá gbé wà? 18 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti fi àwọn ẹ̀yà ara si ara wa, ó sí fi ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan sí ibi tí ó fẹ́ kí ó wà. 19 Bí gbogbo wọn bá sì jẹ́ ọ̀kan ṣoṣo nínú ẹ̀yà ara, níbo ni ara yóò gbé wà. 20 Ọlọ́run dá ẹ̀yà ara púpọ̀, ṣùgbọ́n ara kan ṣoṣo ni.
21 Bí ó tí rí yìí, ojú kò lè sọ fún ọwọ́ pé, “Èmi kò nílò rẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni orí kò le sọ fún ẹsẹ̀ pé, “Èmi kò nílò rẹ.” 22 Àwọn ẹ̀yà ara tí ó dàbí ẹni pé wọ́n ṣe aláìlágbára jùlọ, tí ó dàbí ẹni pé kò ṣe pàtàkì rárá, àwọn gan an ni a kò le ṣe aláìnílò. 23 Bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yà ara tí a rò pé kò lọ́lá rárá ni àwa ń fi ọlá fún jùlọ. Àwọn ẹ̀yà ara tí a rò pé ko yẹ rárá ni àwa ń fi si ipò ọlá ẹ̀yẹ tí ó ga jùlọ. 24 Nítorí pé àwọn ibi tí ó ní ẹ̀yẹ ní ara wa kò nílò ìtọ́jú ọ̀tọ̀. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti pa gbogbo ẹ̀yà ara pọ̀ ṣọ̀kan lọ́nà kan, ó sì ti fi ẹ̀yẹ tó ga jùlọ fún ibi tí ó ṣe aláìní. 25 Kí ó má ṣe sí ìyàtọ̀ nínú ara, ṣùgbọ́n kí àwọn ẹ̀yà ara le máa jẹ́ olùrànlọ́wọ́ fún ara wọn. 26 Bí ẹ̀yà ara kan bá ń jìyà, gbogbo àwọn ẹ̀yà ara ìyókù a máa bá a pín nínú ìyà náà. Tí a bá sì bu ọlá fún ẹ̀yà ara kan, gbogbo ẹ̀yà ara ìyókù a máa bá a yọ̀.
Jesu wo afọ́jú àti odi sàn
27 (A)Nígbà tí Jesu sì jáde níbẹ̀, àwọn ọkùnrin afọ́jú méjì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, wọ́n ń kígbe sókè wí pé, “Ṣàánú fún wa, ìwọ ọmọ Dafidi.”
28 Nígbà tí ó sì wọ̀ ilé, àwọn afọ́jú náà tọ̀ ọ́ wá, Jesu bi wọ́n pé, “Ẹ̀yin gbàgbọ́ pé mo le ṣe èyí?”
Wọn sì wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa, ìwọ lè ṣe é.”
29 Ó sì fi ọwọ́ bà wọ́n ní ojú, ó wí pé, “Kí ó rí fún yín gẹ́gẹ́ bí ìgbàgbọ́ yín.” 30 Ojú wọn sì là; Jesu sì kìlọ̀ fún wọn gidigidi, wí pé, “Kíyèsi i, kí ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnìkan kí ó mọ̀ nípa èyí.” 31 Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n lọ, wọ́n ròyìn rẹ̀ yí gbogbo ìlú náà ká.
32 (B)Bí wọ́n tí ń jáde lọ, wò ó wọ́n mú ọkùnrin odi kan tí ó ní ẹ̀mí èṣù tọ Jesu wá. 33 Nígbà tí a lé ẹ̀mí èṣù náà jáde, ọkùnrin tí ó ya odi sì fọhùn. Ẹnu sì ya àwọn ènìyàn, wọ́n wí pé, “A kò rí irú èyí rí ní Israẹli.”
34 Ṣùgbọ́n àwọn Farisi wí pé, “Agbára olórí àwọn ẹ̀mí èṣù ni ó fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.