Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 107:33-108:13

33 Ó sọ odò di aginjù,
    àti orísun omi di ilẹ̀ gbígbẹ.
34 Ilẹ̀ eléso di aṣálẹ̀
    nítorí ìwà búburú àwọn tí ó wà nínú rẹ̀;
35 O sọ aginjù di adágún omi àti
    ilẹ̀ gbígbẹ di orísun omi
36 Níbẹ̀ ó mú ẹni tí ebi ń pa wà,
    wọ́n sì pilẹ̀ ibi tí wọn ó máa gbé
37 Wọn fún irúgbìn, wọ́n sì gbin ọgbà àjàrà
    tí yóò máa so èso tí ó dára;
38 Ó bùkún wọn, wọ́n sì pọ̀ sí i ní iye
    kò sí jẹ́ kí ẹran ọ̀sìn wọn kí ó dínkù.

39 Nígbà náà, ọjọ́ wọn kúrú,
    ìnira, ìpọ́njú àti ìṣòro wọn sì dínkù
40 Ẹni tí ó da ẹ̀gàn lu ọmọ-aládé
    ó sì mú wọn rìn níbi tí ọ̀nà kò sí
41 Ṣùgbọ́n ó gbé aláìní sókè kúrò nínú ìnira
    ó mú ìdílé wọn pọ̀ bí agbo ẹran
42 Àwọn tí ó dúró sì rí i, inú wọn sì dùn
    ṣùgbọ́n gbogbo olùṣe búburú yóò pa ẹnu rẹ̀ mọ́.

43 Ẹni tí ó bá gbọ́n, jẹ́ kí ó kíyèsi nǹkan wọ̀nyí
    kí ó wo títóbi ìfẹ́ Olúwa.

Orin. Saamu ti Dafidi.

108 (A)Ọlọ́run, ọkàn mi dúró ṣinṣin
    èmi ó máa kọrin, èmi ó máa fi ọkàn mi kọrin
Jí ohun èlò orin àti haapu
    èmi ó jí ní kùtùkùtù
Èmi ó yìn ọ́, Ọlọ́run, nínú àwọn orílẹ̀-èdè
    èmi ó kọrin rẹ nínú àwọn ènìyàn
Nítorí tí o tóbi ní àánú rẹ
    ju àwọn ọ̀run lọ
    àti òdodo rẹ dé àwọsánmọ̀
Gbé ara rẹ ga, Ọlọ́run, lórí àwọn ọ̀run,
    àti ògo rẹ lórí gbogbo ayé.

(B)Kí a sì lè gba àwọn olùfẹ́ rẹ là;
    fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ ṣe ìgbàlà,
    kí o sì dá mi lóhùn
Ọlọ́run ti sọ̀rọ̀ láti ibi mímọ́ rẹ̀ pé:
    “Èmi yóò yọ̀, èmi yóò pín Ṣekemu,
    èmi yóò sì wọn Àfonífojì Sukkoti kúrò.
Gileadi ni tèmi, Manase ni tèmi,
    Efraimu ni ìbòrí mi,
    Juda ni olófin mi,
Moabu sì ni ìkòkò ìwẹsẹ̀ mi,
    lórí Edomu ni èmi ó bọ́ bàtà mi sí,
    lórí òkè Filistia ni èmi yóò hó ìhó ayọ̀.”

10 Ta ni yóò mú mi wá sí ìlú olódi?
    Ta ni yóò sìn mí wá sí Edomu?
11 Ìwọ Ọlọ́run ha kọ́, ìwọ tí ó ti kọ̀ wá sílẹ̀.
    Ọlọ́run ìwọ kì yóò bá àwọn jagunjagun wa jáde mọ́.
12 Fún wa ní ìrànlọ́wọ́ nínú ìpọ́njú,
    nítorí ìrànlọ́wọ́ ènìyàn asán ni.
13 Nípasẹ̀ Ọlọ́run ni àwa ó ṣe akin
    nítorí òun ó tẹ àwọn ọ̀tá wa mọ́lẹ̀.

Saamu 33

33 Ẹ yọ̀ nínú Olúwa, ẹ̀yin olódodo
    ìyìn si yẹ fún ẹni dídúró ṣinṣin.
Ẹ yin Olúwa pẹ̀lú dùùrù;
    ẹ máa fi ohun èlò olókùn mẹ́wàá kọrin sí i.
Ẹ kọ orin tuntun sí i;
    ẹ máa fi ọgbọọgbọ́n lu ohun èlò orin sí i, pẹ̀lú ariwo.

Nítorí pé ọ̀rọ̀ Olúwa dúró ṣinṣin,
    gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ ni à ń ṣe nínú òtítọ́.
Ó fẹ́ òtítọ́ àti ìdájọ́;
    ilé ayé kún fún ìdúró ṣinṣin àti àánú Olúwa.

Nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ Olúwa ni a ṣe dá àwọn ọ̀run,
    àti gbogbo àwọn ẹgbẹ́ ogun wọn nípa ìmísí ẹnu rẹ̀.
Ó kó àwọn omi Òkun jọ gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó wà nínú ìgò;
    ó sì fi ibú ṣe ilé ìṣúra gbogbo.
Jẹ́ kí gbogbo ayé kí ó bẹ̀rù Olúwa:
    jẹ́ kí gbogbo àwọn olùgbé ayé kí ó wà nínú ìbẹ̀rù rẹ̀.
Nítorí tí ó sọ̀rọ̀, ó sì ti rí bẹ́ẹ̀; ó pàṣẹ
    ó sì dúró ṣinṣin.

10 Olúwa ti mú ìmọ̀ràn àwọn orílẹ̀-èdè wá sí asán;
    ó sì mú àrékérekè àwọn ènìyàn di ṣíṣákì í.
11 Ìgbìmọ̀ Olúwa dúró títí ayérayé,
    àní ìrò inú rẹ̀ láti ìrandíran ni.

12 Ìbùkún ni fún orílẹ̀-èdè náà, Ọlọ́run ẹni tí Olúwa jẹ́ tirẹ̀,
    àti àwọn ènìyàn náà tí ó ti yàn ṣe ìní rẹ̀.
13 Olúwa wò láti ọ̀run wá;
    Ó sì rí gbogbo ìran ènìyàn.
14 Níbi tí ó ti jókòó lórí ìtẹ́
    Ó wo gbogbo àwọn olùgbé ayé
15 ẹni tí ó ṣe àyà wọn bákan náà,
    ó sì kíyèsi ìṣe wọn.

16 A kò gba ọba kan là nípasẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ-ogun;
    kò sì sí jagunjagun tí a gbà sílẹ̀ nípa agbára ńlá rẹ̀.
17 Ohun asán ni ẹṣin fún ìṣẹ́gun;
    bẹ́ẹ̀ ni kì yóò fi agbára ńlá rẹ̀ gbani sílẹ̀.
18 Wò ó, ojú Olúwa wà lára àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,
    àti lára àwọn tí ó ní ìrètí nínú ìfẹ́ rẹ̀ tí ó dúró ṣinṣin.
19 Láti gba ọkàn wọn kúrò lọ́wọ́ ikú
    àti láti pa wọ́n mọ́ láààyè lọ́wọ́ ìyàn.

20 Ọkàn wa dúró de Olúwa;
    òun ni ìrànlọ́wọ́ wa àti asà wa.
21 Ọkàn wa yọ̀ nínú rẹ̀,
    nítorí pé, àwa gbẹ́kẹ̀lé orúkọ rẹ mímọ́.
22 Kí àánú rẹ, Olúwa, kí ó wà lára wa,
    àní gẹ́gẹ́ bí àwa ti ń ṣe ìrètí nínú rẹ.

2 Ọba 19:21-36

21 Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa ti sọ nípa rẹ̀:

“ ‘Wúńdíá ọmọbìnrin Sioni
    kẹ́gàn rẹ ó sì fi ọ́ ṣe ẹlẹ́yà.
Ọmọbìnrin Jerusalẹmu
    mi orí sí ọ gẹ́gẹ́ bí o ti sálọ.
22 Ta ni ìwọ ti bú tí o sì kẹ́gàn rẹ̀?
    Lórí ta ni ìwọ ti gbé ohùn rẹ
sókè tí ó sì gbé ojú sókè sí ọ ní ìgbéraga?
    Lórí ẹni mímọ́ ti Israẹli!
23 Nípa àwọn ìránṣẹ́ rẹ
    Ìwọ ti sọ̀rọ̀ búburú sí Olúwa.
Tì wọ sì wí pé,
    “Pẹ̀lú ọ̀pọ̀ kẹ̀kẹ́ mi
ni èmi sì fi dé orí àwọn òkè ńlá,
    sí ibi gíga jùlọ Lebanoni.
Èmi a sì ké igi kedari gíga rẹ̀ lulẹ̀,
    àti ààyò igi firi rẹ̀.
Èmi a sì lọ sí orí òkè ìbùwọ̀ rẹ̀
    sínú ibi tí ó dára jù nínú igbó rẹ̀.
24 Mo ti gbẹ́ kànga ní ilẹ̀ àjèjì
    Mo sì mu omi níbẹ̀.
Pẹ̀lú àtẹ́lẹsẹ̀ mi,
    Èmi ti gbẹ́ gbogbo omi odò tí ó wà ní Ejibiti.”

25 “ ‘Ṣé ìwọ kò tí ì gbọ́?
    Ní ọjọ́ pípẹ́ sẹ́yìn mo yàn án.
Ní ọjọ́ ogbó ni mo ṣètò rẹ̀;
    nísinsin yìí mo ti mú wá sí ìkọjá
pé ìwọ ti yí ìlú olódi padà dí
    òkìtì àlàpà òkúta.
26 Àwọn ènìyàn wọn ń gbẹ nípa,
    wọ́n ti dà á láàmú
wọ́n sì ti ṣọ́ di ìtìjú.
    Wọ́n dàbí koríko igbó lórí pápá,
gẹ́gẹ́ bí ọkà tí ó rẹ̀ dànù kí ó tó dàgbàsókè,
    gẹ́gẹ́ bí fífún ọkà tí ó hù jáde.

27 “ ‘Ṣùgbọ́n èmi mọ ibi tí ìwọ
    dúró àti ìgbà tí ìwọ bá dé tàbí
    lọ àti bí ìwọ ṣe ìkáàánú rẹ: sí mi.
28 Ṣùgbọ́n ìkáàánú rẹ sí mi
    àti ìrora rẹ dé etí mi,
Èmi yóò gbé ìwọ̀ mi sí imú rẹ
    àti ìjánu mi sí ẹnu rẹ,
èmi yóò mú ọ padà
    nípa wíwá rẹ.’

29 “Èyí yóò jẹ́ ààmì fún ọ, ìwọ Hesekiah:

“Ọdún yìí ìwọ yóò jẹ ohun tí ó bá hù fún rara rẹ̀,
    àti ní ọdún kejì ohun tí ó bá hù jáde láti inú ìyẹn.
Ṣùgbọ́n ní ọdún kẹta, gbìn kí o sì kórè,
    gbin ọgbà àjàrà kí o sì jẹ èso rẹ̀.
30 Lẹ́ẹ̀kan sí i ìyókù ti ilé Juda
    yóò sì tún hu gbòǹgbò lábẹ́, yóò sì so èso lókè.
31 Láti inú Jerusalẹmu ní àwọn ìyókù yóò ti wá
    àti láti orí òkè Sioni ni ọ̀pọ̀ àwọn tí ó sá àsálà.

Ìtara Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò ṣe èyí.

32 “Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa sọ nípa ti ọba Asiria:

“Kò ní wọ ìlú yìí
    tàbí ta ọfà síbí.
Kò ní wá níwájú rẹ pẹ̀lú
    àpáta tàbí kó ìdọ̀tí àgbò sí ọ̀kánkán rẹ.
33 Nípa ọ̀nà tí ó gbà wá ni
    yóò padà; kì yóò wọ ìlú ńlá yìí,
    ni Olúwa wí.
34 Èmi yóò dá ààbò bo ìlú ńlá yìí,
    èmi yóò sì pa á mọ́ fún èmi tìkára mi àti fún Dafidi ìránṣẹ́ mi.”

35 Ní alẹ́ ọjọ́ náà, angẹli Olúwa jáde lọ ó sì pa ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ènìyàn ní ibùdó àwọn ará Asiria. Nígbà tí wọ́n sì dìde dúró ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì níbẹ̀ ni gbogbo òkú wà! 36 Bẹ́ẹ̀ ni Sennakeribu ọba Asiria wọ àgọ́ ó sì padà, ó sì padà sí Ninefe ó sì dúró níbẹ̀.

1 Kọrinti 10:1-13

Ìkìlọ̀ láti inú ìtàn àwọn ọmọ Israẹli

10 (A)Nítorí èmi kò fẹ́ kí ẹ̀yin jẹ́ òpè si òtítọ́, ẹ̀yin arákùnrin ọ̀wọ́n, a kó gbọdọ̀ gbàgbé ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ènìyàn wa nínú aginjù. Ọlọ́run ṣamọ̀nà wọn nípa rírán ìkùùkuu síwájú wọn, ó sì sìn wọ́n la omi Òkun pupa já. (B)A lè pe eléyìí ní ìtẹ̀bọmi ti Mose nínú ìkùùkuu àti nínú omi Òkun. (C)Nípa iṣẹ́ ìyanu, gbogbo wọn jẹ oúnjẹ ẹ̀mí kan náà. (D)Wọ́n mu nínú omi tí Kristi fi fún wọn. Wọ́n mu omi ẹ̀mí láti inú àpáta tí ó ń tẹ̀lé wọn, àpáta náà ni Kristi. Ó wà pẹ̀lú wọn nínú aginjù náà, òun ni àpáta tí ń fi omi ẹ̀mí tu ọkàn lára. (E)Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ni inú Ọlọ́run kò dún sí; nítorí a pa wọ́n run nínú aginjù.

(F)Àwọn nǹkan wọ̀nyí sì jásí àpẹẹrẹ fún àwa, kí a má ṣe ní ìfẹ́ sí àwọn ohun búburú gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn yìí ṣe ní ìfẹ́ si. (G)Kí ẹ̀yin kí ó má ṣe jẹ́ abọ̀rìṣà gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe; gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, “Àwọn ènìyàn náà jókòó láti jẹ àti láti mu, wọ́n sì dìde dúró láti ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́.” (H)Bẹ́ẹ̀ ni kí àwa kí ó má ṣe ṣe àgbèrè gẹ́gẹ́ bí àwọn mìíràn nínú wọn ti ṣe, tí ẹgbàá-mọ̀kànlá-lé-ẹgbẹ̀rún ènìyàn sì kú ní ọjọ́ kan. (I)Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin má ṣe dán Olúwa wò, gẹ́gẹ́ bí àwọn mìíràn nínú wọn ti dán an wò, tí a sì fi ejò run wọ́n. 10 (J)Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin kí ó má ṣe kùn, gẹ́gẹ́ bí àwọn mìíràn nínú wọ́n ṣe kùn, tí a sì ti ọwọ́ olùparun run wọ́n.

11 Gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí ṣẹlẹ̀ sí wọn bí àpẹẹrẹ fún wa, a sì kọ̀wé wọn fún ìkìlọ̀ fún wa, àwa ẹni tí ìgbẹ̀yìn ayé dé bá. 12 Nítorí náà, ẹni tí ó bá rò pé òun dúró, kí ó kíyèsára kí ó ma ba à ṣubú. 13 (K)Kò sí ìdánwò kan tí ó ti bá yín, bí kò ṣe irú èyí tí ó mọ níwọ̀n fún ènìyàn, ṣùgbọ́n olódodo ni Ọlọ́run, ẹni ti kì yóò jẹ́ kí á dán an yín wò ju bí ẹ̀yin ti le gbà, ṣùgbọ́n tí yóò sì ṣe ọ̀nà àbáyọ pẹ̀lú nínú ìdánwò náà, kí ẹ̀yin ba à lè faradà á.

Matiu 8:18-27

Ohun tí o gbà láti tẹ̀lé Jesu

18 (A)Nígbà tí Jesu rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn tó yí i ká, ó pàṣẹ pé kí wọ́n rékọjá sí òdìkejì adágún. 19 Olùkọ́ òfin kan sì tọ̀ ọ́ wá, ó wí fún un pé, “Olùkọ́, èmi ó má tọ̀ ọ́ lẹ́yìn níbikíbi tí ìwọ bá ń lọ.”

20 Jesu dá lóhùn pé, “Àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ní ihò, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ni ìtẹ́; ṣùgbọ́n Ọmọ Ènìyàn kò ní ibi tí yóò fi orí rẹ̀ lé.”

21 Ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ mìíràn sì wí fún un pé, “Olúwa, kọ́kọ́ jẹ́ kí èmi kí ó kọ́ lọ sìnkú baba mi ná.”

22 (B)Ṣùgbọ́n Jesu wí fún un pé, “Máa tọ̀ mí lẹ́yìn, sì jẹ́ kí àwọn òkú kí ó máa sin òkú ara wọn.”

Jesu dá ìjì líle dúró

23 (C)Nígbà náà ni ó bọ́ sínú ọkọ̀ ojú omi, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tẹ̀lé e. 24 Ní àìròtẹ́lẹ̀, ìjì líle dìde lórí Òkun tó bẹ́ẹ̀ tí rírú omi fi bò ọkọ̀ náà mọ́lẹ̀; ṣùgbọ́n Jesu ń sùn. 25 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọn jí i, wọ́n wí pe, “Olúwa, gbà wá! Àwa yóò rì!”

26 (D)Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin onígbàgbọ́ kékeré. Èéṣe ti ẹ̀yin fi ń bẹ̀rù?” Nígbà náà ní ó dìde dúró, ó sì bá ìjì àti rírú Òkun náà wí, gbogbo rẹ̀ sì parọ́rọ́.

27 Ṣùgbọ́n ẹnu yà àwọn ọkùnrin náà, wọ́n sì béèrè pé, “Irú ènìyàn wo ni èyí? Kódà ìjì líle àti rírú omi Òkun gbọ́ tirẹ̀?”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.