Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 119:97-120

Òfin Olúwa ni ìfẹ́ pípé

97 Báwo ni èmi ti fẹ́ òfin rẹ tó!
    Èmi ń ṣe àṣàrò nínú rẹ̀
ní gbogbo ọjọ́ pípẹ́ wá.
98 Àṣẹ rẹ mú mi gbọ́n ju àwọn ọ̀tá mi lọ,
    nítorí wọ́n wà pẹ̀lú mi láé.
99 Èmi ní iyè inú ju gbogbo olùkọ́ mi lọ,
    nítorí èmi ń ṣe àṣàrò nínú òfin rẹ.
100 Èmi ni òye ju àwọn àgbà lọ,
    nítorí mo gba ẹ̀kọ́ rẹ.
101 Èmi ti pa ẹsẹ̀ mi mọ́ nínú gbogbo ọ̀nà ibi
    nítorí kí èmi lè gba ọ̀rọ̀ rẹ.
102 Èmi kò yà kúrò nínú òfin rẹ,
    nítorí ìwọ fúnrarẹ̀ ni ó kọ́ mi.
103 Báwo ni ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe dùn mọ́ mi lẹ́nu tó,
    ó dùn ju oyin lọ ní ẹnu mi!
104 Èmi rí òye gbà nínú ẹ̀kọ́ rẹ;
    nítorí náà èmi kórìíra gbogbo ọ̀nà tí kò tọ́.

Òfin Olúwa ni fìtílà mi

105 Ọ̀rọ̀ rẹ ni fìtílà sí ẹsẹ̀ mi
    àti ìmọ́lẹ̀ sí ipa ọ̀nà mi
106 Èmi ti ṣe ìbúra èmi sì ti tẹnumọ́ ọn
    wí pé èmi yóò máa tẹ̀lé òfin òdodo rẹ.
107 A pọ́n mi lójú gidigidi;
    Olúwa, sọ mi di ààyè, gẹ́gẹ́ bi ọ̀rọ̀ rẹ
108 Olúwa, gba ìyìn àtinúwá ẹnu mi,
    kí o sì kọ́ mi ní òfin rẹ̀.
109 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ayé mi wà ni ọwọ́ mi
    nígbà gbogbo,
    èmi kò ní gbàgbé òfin rẹ.
110 Àwọn ẹni búburú ti dẹ okùn sílẹ̀ fún mi,
    ṣùgbọ́n èmi kò ṣìnà kúrò nínú ẹ̀kọ́ rẹ.
111 Òfin rẹ ni ogún mi láéláé;
    àwọn ni ayọ̀ ọkàn mi.
112 Ọkàn mi ti lé pípa òfin rẹ mọ́
    láé dé òpin.

Òfin Olúwa ni Ààbò mi

113 Èmi kórìíra àwọn ọlọ́kàn méjì,
    ṣùgbọ́n èmi fẹ́ òfin rẹ.
114 Ìwọ ni ààbò mi àti asà mi;
    èmi ti mú ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ rẹ.
115 Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin olùṣe búburú,
    kí èmi lè pa àṣẹ Ọlọ́run mi mọ́!
116 Gbé mi sókè gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ,
    kí èmi kí ó lè yè
    Má sì jẹ́ kí ojú ìrètí mi kí ó tì mí.
117 Gbé mi sókè, èmí yóò sì wa láìléwu;
    nígbà gbogbo ni èmi yóò máa júbà òfin rẹ.
118 Ìwọ kọ gbogbo àwọn tí ó ṣìnà kúrò nínú òfin rẹ,
    nítorí ẹ̀tàn wọn asán ni.
119 Gbogbo àwọn ẹni búburú ní ayé ni ìwọ yọ kúrò bí i ìdàrọ́;
    nítorí náà, èmi fẹ́ òfin rẹ̀.
120 Ara mi wárìrì ní ìbẹ̀rù nítorí rẹ̀:
    èmi dúró ní ìbẹ̀rù òfin rẹ.

Saamu 81-82

Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí ti gittiti. Ti Asafu.

81 Kọrin sókè sí Ọlọ́run agbára wa
    Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Ọlọ́run Jakọbu!
Ẹ mú orin mímọ́, kí ẹ sì mú ìlù wá,
    tẹ dùùrù dídùn pẹ̀lú ohun èlò orin mímọ́.

Ẹ fún ìpè ní oṣù tuntun
    àní nígbà tí a yàn;
ní ọjọ́ àjọ wa tí ó ní ìrònú.
Èyí ni àṣẹ fún Israẹli,
    àti òfin Ọlọ́run Jakọbu.
Ó fi múlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìlànà fún Josẹfu
    nígbà tí ó la ilẹ̀ Ejibiti já.

    Níbi tí a ti gbọ́ èdè tí kò yé wa.

Ó wí pé, “Mo gbé àjàgà kúrò ní èjìká yín,
    a tú ọwọ́ wọn sílẹ̀ kúrò nínú apẹ̀rẹ̀.
Nínú ìnilára ni ẹ pè mo sì gbà yín là,
    mo dá a yín lóhùn nínú ìkọ̀kọ̀ àrá,
    mo dán an yín wò ní odò Meriba. Sela.

“Gbọ́, ẹ̀yin ènìyàn mi, èmi ó sì kìlọ̀ fún un yín,
    bí ìwọ bá fetí sí mi, ìwọ Israẹli.
Ẹ̀yin kì yóò ní Ọlọ́run ilẹ̀ mìíràn láàrín yín;
    ẹ̀yin kì yóò foríbalẹ̀ fún Ọlọ́run àjèjì.
10 Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ,
    ẹni tí ó mú un yín jáde láti Ejibiti.
    Ẹ la ẹnu yín gbòòrò, èmi yóò sì kún un.

11 “Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn mi kì yóò gbọ́ tèmi;
    Israẹli kò ní tẹríba fún mi.
12 Nítorí náà ni mo ṣe fi wọ́n fún ọkàn líle wọn
    láti máa rìn ní ọ̀nà ẹ̀tàn wọn.

13 “Bí àwọn ènìyàn mi yóò bá gbọ́ tèmi
    bí Israẹli yóò bá tẹ̀lé ọ̀nà mi,
14 Ní kánkán ni èmi yóò ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá wọn
    kí n sì yí ọwọ́ mi padà sí ọ̀tá wọn!
15 Àwọn tí ó kórìíra Olúwa yóò tẹríba níwájú rẹ̀.
    Ìjìyà wọn yóò sì pẹ́ títí láé
16 Ṣùgbọ́n a ó fi ọkà tí ó dára bọ́ ọ yín
    èmi ó tẹ́ ẹ yín lọ́rùn pẹ̀lú oyin inú àpáta.”

Saamu ti Asafu.

82 Ọlọ́run ń ṣàkóso nínú ìpéjọpọ̀ ńlá,
    ó ṣe ìdájọ́ láàrín àwọn “ọlọ́run òrìṣà”.

“Yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò máa gbèjà àwọn aláìṣòdodo
    kí ó sì ṣe ojú ìṣáájú sí àwọn ènìyàn búburú?
Gbèjà àwọn aláìlágbára àti aláìní baba;
    ṣe ìtọ́jú ẹ̀tọ́ àwọn aláìní àti ẹni ìnilára.
Gba àwọn aláìlágbára àti aláìní;
    gbà wọ́n kúrò lọ́wọ́ àwọn ènìyàn búburú.

“Wọn kò mọ̀ ohun kankan,
    wọn kò lóye ohun kankan.
Wọn ń rìn kiri nínú òkùnkùn;
    à si mí gbogbo ìpìlẹ̀ ayé.

(A)“Mo wí pé, ‘Ẹyin ní “Ọlọ́run òrìṣà”;
    ẹ̀yin ní gbogbo ọmọ Ọ̀gá-ògo jùlọ.’
Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ó kú bí ènìyàn lásán;
    ẹ̀yin ó ṣubú bí ọ̀kan nínú ọmọ-aládé.”

Dìde, Ọlọ́run, ṣe ìdájọ́ ayé,
    nítorí gbogbo orílẹ̀-èdè ni ìní rẹ.

2 Samuẹli 9

Dafidi àti Mefiboṣeti

Dafidi sì béèrè pé, ọ̀kan nínú àwọn ẹni tí ń ṣe ìdílé Saulu kù síbẹ̀ bí? Kí èmi lè ṣe oore fún un nítorí Jonatani.

Ìránṣẹ́ kan sì ti wà ní ìdílé Saulu, orúkọ rẹ̀ sí ń jẹ́ Ṣiba, Wọ́n sì pè é wá sọ́dọ̀ Dafidi, ọba sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ìwọ ni Ṣiba bí?”

Ó sì dáhùn wí pé, “ìránṣẹ́ rẹ ni.”

Ọba sì wí pé, “Kò ha sí ọ̀kan nínú ìdílé Saulu síbẹ̀, kí èmi ṣe oore Ọlọ́run fún un?”

Ṣiba sì wí fún ọba pé, “Jonatani ní ọmọ kan síbẹ̀ tó ya arọ.”

Ọba sì wí fún un pé, “Níbo ni ó gbé wà?”

Ṣiba sì wí fún ọba pé, “Wò ó, òun wà ní ilé Makiri, ọmọ Ammieli, ní Lo-Debari.”

Dafidi ọba sì ránṣẹ́, ó sì mú un láti ilé Makiri ọmọ Ammieli láti Lo-Debari wá.

Mefiboṣeti ọmọ Jonatani ọmọ Saulu sì tọ Dafidi wá, ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì bú ọlá fún un.

Dafidi sì wí pé, “Mefiboṣeti!”

Òun sì dáhùn wí pé, “Wò ó, ìránṣẹ́ rẹ!”

Dafidi sì wí fún un pé, “Má ṣe bẹ̀rù: nítorí pé nítòótọ́ èmi ó ṣe oore fún ọ nítorí Jonatani baba rẹ, èmi ó sì tún fi gbogbo ilé Saulu baba rẹ fún ọ: ìwọ ó sì máa bá mi jẹun nígbà gbogbo ní ibi oúnjẹ mi.”

Mefiboṣeti sì tẹríba, ó sì wí pé, “Kí ni ìránṣẹ́ rẹ jásí, tí ìwọ ó fi máa wo òkú ajá bí èmi.”

Ọba sì pe Ṣiba ìránṣẹ́ Saulu, ó sì wí fún un pé, “Gbogbo nǹkan tí í ṣe ti Saulu, àti gbogbo èyí tí í ṣe ti ìdílé rẹ̀ ni èmi fi fún ọmọ olúwa rẹ. 10 Ìwọ, àti àwọn ọmọ rẹ, àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ ni yóò sì máa ro ilẹ̀ náà fún un, ìwọ ni yóò sì máa mú ìkórè wá, ọmọ olúwa rẹ yóò sì máa rí oúnjẹ jẹ: ṣùgbọ́n Mefiboṣeti ọmọ olúwa rẹ yóò sì máa bá mi jẹun nígbà gbogbo ní ibi oúnjẹ mi.” (Ṣiba sì ní ọmọ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún àti ogún ìránṣẹ́kùnrin.)

11 Ṣiba sì wí fún ọba pé, “Gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí olúwa mi ọba ti pàṣẹ fún ìránṣẹ́ rẹ, bẹ́ẹ̀ náà ni ìránṣẹ́ rẹ ó ṣe.” Ọba sì wí pé, “Ní ti Mefiboṣeti, yóò máa jẹun ní ibi oúnjẹ mi, Gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ọba.”

12 Mefiboṣeti sì ní ọmọ kékeré kan, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mika. Gbogbo àwọn tí ń gbé ní ilé Ṣiba ni ó sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún Mefiboṣeti. 13 Mefiboṣeti sì ń gbé ní Jerusalẹmu: òun a sì máa jẹun nígbà gbogbo ní ibi oúnjẹ ọba; òun sì yarọ ní ẹsẹ̀ rẹ̀ méjèèjì.

Ìṣe àwọn Aposteli 19:1-10

Paulu ní Efesu

19 Nígbà ti Apollo wà ni Kọrinti, ti Paulu kọjá lọ sí apá òkè ìlú, ó sì wá sí Efesu: o sì rí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn kan; o wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ha gba Ẹ̀mí Mímọ́ náà nígbà tí ẹ̀yin gbàgbọ́?”

Wọ́n sì wí fún un pé, “Àwa kò gbọ́ rárá pé Ẹ̀mí Mímọ́ kan wà.”

Ó sì wí pé, “Ǹjẹ́ irú bamitiisi wo ni a bamitiisi yín sí?”

Wọ́n sì wí pé, “Sí bamitiisi tí Johanu.”

Paulu sí wí pé, “Nítòótọ́, ní Johanu fi bamitiisi tí ìrònúpìwàdà bamitiisi, ó ń wí fún àwọn ènìyàn pé, kí wọ́n gba ẹni tí ń bọ̀ lẹ́yìn òun gbọ́, èyí sì ni Kristi Jesu.” Nígbà tí wọ́n sì gbọ́, a bamitiisi wọn lórúkọ Jesu Olúwa. Nígbà tí Paulu sì gbé ọwọ́ lé wọn, Ẹ̀mí Mímọ́ sì bà lé wọn: wọ́n sì ń fọ́ èdè mìíràn, wọ́n sì ń sọ àsọtẹ́lẹ̀. Iye àwọn ọkùnrin náà gbogbo tó méjìlá.

Nígbà tí ó sì wọ inú Sinagọgu lọ ó fi ìgboyà sọ̀rọ̀ ni oṣù mẹ́ta, ó ń fi ọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀, ó sì ń yí wọn lọ́kàn padà sí nǹkan tí i ṣe tí ìjọba Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n nígbà tí ọkàn àwọn mìíràn nínú wọn di líle, tí wọn kò sì gbàgbọ́, tí wọn ń sọ̀rọ̀ ibi sí ọ̀nà náà níwájú ìjọ ènìyàn, ó lọ kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó sì ya àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sọ́tọ̀, ó sì ń sọ àsọyé lójoojúmọ́ ni ilé ìwé Tirannusi. 10 Èyí n lọ bẹ́ẹ̀ fún ìwọ̀n ọdún méjì; tó bẹ́ẹ̀ tí gbogbo àwọn tí ń gbé Asia gbọ́ ọ̀rọ̀ Jesu Olúwa, àti àwọn Júù àti àwọn Giriki.

Marku 8:34-9:1

Ọ̀nà sí àgbélébùú

34 (A)Nígbà náà ni Jesu pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ àti ọ̀pọ̀ ènìyàn láti bá wọn sọ̀rọ̀, ó wí fún wọn pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó sẹ́ ara rẹ̀, kí ó si gbé àgbélébùú rẹ̀, kí ó si máa tọ̀ mi lẹ́yìn. 35 (B)Nítorí ẹni tó bá gbìyànjú láti gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là, yóò sọ ọ́ nù. Iye àwọn tí ó sọ ẹ̀mí wọn nù nìkan nítorí í tèmi àti nítorí ìhìnrere, òun náà ni yóò gbà á là. 36 Nítorí èrè kí ni ó jẹ́ fún ẹni tí ó jèrè gbogbo ayé, tí ó sọ ẹ̀mí rẹ̀ nù? 37 Tàbí kí ni ènìyàn yóò fi ṣe pàṣípàrọ̀ ẹ̀mí rẹ̀? 38 (C)Nítorí náà, bí ẹnikẹ́ni bá tijú àti gbà mí tàbí ọ̀rọ̀ mi nínú ìran panṣágà àti ẹlẹ́ṣẹ̀ yìí, tí ó kún fún àìgbàgbọ́ àti ẹ̀ṣẹ̀ báyìí, Ọmọ Ènìyàn yóò tijú rẹ̀ nígbà tí ó bá padà dé nínú ògo Baba rẹ̀, pẹ̀lú àwọn angẹli mímọ́.”

(D)Ó sì wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín àwọn mìíràn wa nínú àwọn tó dúró níhìn-ín yìí, tí kì yóò tọ́ ikú wò, títí yóò fi rí ìjọba Ọlọ́run tí yóò fi dé pẹ̀lú agbára.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.