Book of Common Prayer
Òfin Olúwa ni ìfẹ́ pípé
97 Báwo ni èmi ti fẹ́ òfin rẹ tó!
Èmi ń ṣe àṣàrò nínú rẹ̀
ní gbogbo ọjọ́ pípẹ́ wá.
98 Àṣẹ rẹ mú mi gbọ́n ju àwọn ọ̀tá mi lọ,
nítorí wọ́n wà pẹ̀lú mi láé.
99 Èmi ní iyè inú ju gbogbo olùkọ́ mi lọ,
nítorí èmi ń ṣe àṣàrò nínú òfin rẹ.
100 Èmi ni òye ju àwọn àgbà lọ,
nítorí mo gba ẹ̀kọ́ rẹ.
101 Èmi ti pa ẹsẹ̀ mi mọ́ nínú gbogbo ọ̀nà ibi
nítorí kí èmi lè gba ọ̀rọ̀ rẹ.
102 Èmi kò yà kúrò nínú òfin rẹ,
nítorí ìwọ fúnrarẹ̀ ni ó kọ́ mi.
103 Báwo ni ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe dùn mọ́ mi lẹ́nu tó,
ó dùn ju oyin lọ ní ẹnu mi!
104 Èmi rí òye gbà nínú ẹ̀kọ́ rẹ;
nítorí náà èmi kórìíra gbogbo ọ̀nà tí kò tọ́.
Òfin Olúwa ni fìtílà mi
105 Ọ̀rọ̀ rẹ ni fìtílà sí ẹsẹ̀ mi
àti ìmọ́lẹ̀ sí ipa ọ̀nà mi
106 Èmi ti ṣe ìbúra èmi sì ti tẹnumọ́ ọn
wí pé èmi yóò máa tẹ̀lé òfin òdodo rẹ.
107 A pọ́n mi lójú gidigidi;
Olúwa, sọ mi di ààyè, gẹ́gẹ́ bi ọ̀rọ̀ rẹ
108 Olúwa, gba ìyìn àtinúwá ẹnu mi,
kí o sì kọ́ mi ní òfin rẹ̀.
109 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ayé mi wà ni ọwọ́ mi
nígbà gbogbo,
èmi kò ní gbàgbé òfin rẹ.
110 Àwọn ẹni búburú ti dẹ okùn sílẹ̀ fún mi,
ṣùgbọ́n èmi kò ṣìnà kúrò nínú ẹ̀kọ́ rẹ.
111 Òfin rẹ ni ogún mi láéláé;
àwọn ni ayọ̀ ọkàn mi.
112 Ọkàn mi ti lé pípa òfin rẹ mọ́
láé dé òpin.
Òfin Olúwa ni Ààbò mi
113 Èmi kórìíra àwọn ọlọ́kàn méjì,
ṣùgbọ́n èmi fẹ́ òfin rẹ.
114 Ìwọ ni ààbò mi àti asà mi;
èmi ti mú ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ rẹ.
115 Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin olùṣe búburú,
kí èmi lè pa àṣẹ Ọlọ́run mi mọ́!
116 Gbé mi sókè gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ,
kí èmi kí ó lè yè
Má sì jẹ́ kí ojú ìrètí mi kí ó tì mí.
117 Gbé mi sókè, èmí yóò sì wa láìléwu;
nígbà gbogbo ni èmi yóò máa júbà òfin rẹ.
118 Ìwọ kọ gbogbo àwọn tí ó ṣìnà kúrò nínú òfin rẹ,
nítorí ẹ̀tàn wọn asán ni.
119 Gbogbo àwọn ẹni búburú ní ayé ni ìwọ yọ kúrò bí i ìdàrọ́;
nítorí náà, èmi fẹ́ òfin rẹ̀.
120 Ara mi wárìrì ní ìbẹ̀rù nítorí rẹ̀:
èmi dúró ní ìbẹ̀rù òfin rẹ.
Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí ti gittiti. Ti Asafu.
81 Kọrin sókè sí Ọlọ́run agbára wa
Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Ọlọ́run Jakọbu!
2 Ẹ mú orin mímọ́, kí ẹ sì mú ìlù wá,
tẹ dùùrù dídùn pẹ̀lú ohun èlò orin mímọ́.
3 Ẹ fún ìpè ní oṣù tuntun
àní nígbà tí a yàn;
ní ọjọ́ àjọ wa tí ó ní ìrònú.
4 Èyí ni àṣẹ fún Israẹli,
àti òfin Ọlọ́run Jakọbu.
5 Ó fi múlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìlànà fún Josẹfu
nígbà tí ó la ilẹ̀ Ejibiti já.
Níbi tí a ti gbọ́ èdè tí kò yé wa.
6 Ó wí pé, “Mo gbé àjàgà kúrò ní èjìká yín,
a tú ọwọ́ wọn sílẹ̀ kúrò nínú apẹ̀rẹ̀.
7 Nínú ìnilára ni ẹ pè mo sì gbà yín là,
mo dá a yín lóhùn nínú ìkọ̀kọ̀ àrá,
mo dán an yín wò ní odò Meriba. Sela.
8 “Gbọ́, ẹ̀yin ènìyàn mi, èmi ó sì kìlọ̀ fún un yín,
bí ìwọ bá fetí sí mi, ìwọ Israẹli.
9 Ẹ̀yin kì yóò ní Ọlọ́run ilẹ̀ mìíràn láàrín yín;
ẹ̀yin kì yóò foríbalẹ̀ fún Ọlọ́run àjèjì.
10 Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ,
ẹni tí ó mú un yín jáde láti Ejibiti.
Ẹ la ẹnu yín gbòòrò, èmi yóò sì kún un.
11 “Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn mi kì yóò gbọ́ tèmi;
Israẹli kò ní tẹríba fún mi.
12 Nítorí náà ni mo ṣe fi wọ́n fún ọkàn líle wọn
láti máa rìn ní ọ̀nà ẹ̀tàn wọn.
13 “Bí àwọn ènìyàn mi yóò bá gbọ́ tèmi
bí Israẹli yóò bá tẹ̀lé ọ̀nà mi,
14 Ní kánkán ni èmi yóò ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá wọn
kí n sì yí ọwọ́ mi padà sí ọ̀tá wọn!
15 Àwọn tí ó kórìíra Olúwa yóò tẹríba níwájú rẹ̀.
Ìjìyà wọn yóò sì pẹ́ títí láé
16 Ṣùgbọ́n a ó fi ọkà tí ó dára bọ́ ọ yín
èmi ó tẹ́ ẹ yín lọ́rùn pẹ̀lú oyin inú àpáta.”
Saamu ti Asafu.
82 Ọlọ́run ń ṣàkóso nínú ìpéjọpọ̀ ńlá,
ó ṣe ìdájọ́ láàrín àwọn “ọlọ́run òrìṣà”.
2 “Yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò máa gbèjà àwọn aláìṣòdodo
kí ó sì ṣe ojú ìṣáájú sí àwọn ènìyàn búburú?
3 Gbèjà àwọn aláìlágbára àti aláìní baba;
ṣe ìtọ́jú ẹ̀tọ́ àwọn aláìní àti ẹni ìnilára.
4 Gba àwọn aláìlágbára àti aláìní;
gbà wọ́n kúrò lọ́wọ́ àwọn ènìyàn búburú.
5 “Wọn kò mọ̀ ohun kankan,
wọn kò lóye ohun kankan.
Wọn ń rìn kiri nínú òkùnkùn;
à si mí gbogbo ìpìlẹ̀ ayé.
6 (A)“Mo wí pé, ‘Ẹyin ní “Ọlọ́run òrìṣà”;
ẹ̀yin ní gbogbo ọmọ Ọ̀gá-ògo jùlọ.’
7 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ó kú bí ènìyàn lásán;
ẹ̀yin ó ṣubú bí ọ̀kan nínú ọmọ-aládé.”
8 Dìde, Ọlọ́run, ṣe ìdájọ́ ayé,
nítorí gbogbo orílẹ̀-èdè ni ìní rẹ.
Fa ọkàn rẹ ya
12 “Ǹjẹ́ nítorí náà nísinsin yìí,” ni Olúwa wí,
“Ẹ fi gbogbo ọkàn yín yípadà sí mi,
àti pẹ̀lú àwẹ̀, àti pẹ̀lú ẹkún, àti pẹ̀lú ọ̀fọ̀.”
13 Ẹ sì fa ọkàn yín ya,
kì í sì í ṣe aṣọ yín,
ẹ sì yípadà sí Olúwa Ọlọ́run yín,
nítorí tí o pọ̀ ní oore-ọ̀fẹ́,
ó sì kún fun àánú, ó lọ́ra láti bínú,
ó sì ṣeun púpọ̀, ó sì ronúpìwàdà láti ṣe búburú.
14 Ta ni ó mọ̀ bí òun yóò yípadà, kí o sì ronúpìwàdà,
kí ó sì fi ìbùkún sílẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀—
àní ọrẹ-jíjẹ àti ọrẹ mímu
fún Olúwa Ọlọ́run yín?
15 Ẹ fún ìpè ní Sioni,
ẹ ya àwẹ̀ kan sí mímọ́,
ẹ pe àjọ tí ó ni ìrònú.
16 Ẹ kó àwọn ènìyàn jọ,
ẹ ya ìjọ sí mímọ́;
ẹ pe àwọn àgbàgbà jọ,
ẹ kó àwọn ọmọdé jọ,
àti àwọn tí ń mú ọmú:
jẹ kí ọkọ ìyàwó kúrò nínú ìyẹ̀wù rẹ̀.
Kí ìyàwó sì kúrò nínú iyàrá rẹ̀
17 Jẹ́ kí àwọn àlùfáà, àwọn ìránṣẹ́ Olúwa,
sọkún láàrín ìloro àti pẹpẹ.
Sí jẹ́ kí wọn wí pé, “Dá àwọn ènìyàn rẹ sí, Olúwa.
Má sì ṣe fi ìní rẹ fun ẹ̀gàn,
tí yóò sì di òwe ní àárín àwọn kèfèrí.
Èéṣe tí wọn yóò fi wí láàrín àwọn ènìyàn pé,
‘Ọlọ́run wọn ha da?’ ”
18 Nígbà náà ní Olúwa yóò jowú fún ilẹ̀ rẹ̀,
yóò sì káàánú fún ènìyàn rẹ̀.
19 Nítòótọ́, Olúwa yóò dá wọn lóhùn:
“Yóò sì wí fun àwọn ènìyàn rẹ̀ pé,
Wò ó èmi yóò rán ọkà, àti ọtí wáìnì tuntun,
àti òróró sí i yín, a ó sì fi wọn tẹ́ yín lọ́rùn:
èmi kì yóò sì fi yín ṣe ẹ̀gàn mọ́ láàrín àwọn aláìkọlà.
Ẹni tó gun ẹṣin funfun
11 (A)Mo sì rí ọ̀run ṣí sílẹ̀, sì wò ó, ẹṣin funfun kan; ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀ ni à ń pè ní Olódodo àti Olóòtítọ́, nínú òdodo ni ó sì ń ṣe ìdájọ́, tí ó ń jagun. 12 (B)Ojú rẹ̀ dàbí ọ̀wọ́-iná, àti ní orí rẹ̀ ni adé púpọ̀ wà; ó sì ní orúkọ kan tí a kọ, tí ẹnikẹ́ni kò mọ́, bí kò ṣe òun tìkára rẹ̀. 13 A sì wọ̀ ọ́ ní aṣọ tí a tẹ̀ bọ inú ẹ̀jẹ̀: a sì ń pe orúkọ rẹ̀ ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. 14 Àwọn ogun tí ń bẹ ní ọ̀run tí a wọ̀ ní aṣọ ọ̀gbọ̀ wíwẹ́, funfun àti mímọ́, sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn lórí ẹṣin funfun. 15 (C)Àti láti ẹnu rẹ̀ ni idà mímú ti ń jáde lọ, kí ó lè máa fi sá àwọn orílẹ̀-èdè: “Òun ó sì máa fi ọ̀pá irin ṣe àkóso wọn.” Ó sì ń tẹ ìfúntí àti ìbínú Ọlọ́run Olódùmarè. 16 (D)Ó sì ní lára aṣọ rẹ̀ àti ni ìtàn rẹ̀ orúkọ kan tí a kọ:
ọba àwọn ọba àti olúwa àwọn olúwa.
17 (E)Mo sì rí angẹli kan dúró nínú oòrùn; ó sì fi ohùn rara kígbe, ó ń wí fún gbogbo àwọn ẹyẹ tí ń fò ní agbede-méjì ọ̀run pé: “Ẹ wá ẹ sì kó ara yín jọ pọ̀ sí àsè ńlá Ọlọ́run; 18 kí ẹ̀yin kí ó lè jẹ ẹran-ara àwọn ọba, àti ẹran-ara àwọn olórí ogun àti ẹran-ara àwọn ènìyàn alágbára, àti ẹran àwọn ẹṣin, àti ti àwọn tí ó jókòó lórí wọn, àti ẹran-ara ènìyàn gbogbo, àti ti òmìnira, àti ti ẹrú, àti ti èwe àti ti àgbà.”
19 Mo sì rí ẹranko náà àti àwọn ọba ayé, àti àwọn ogun wọn tí a gbá jọ láti bá ẹni tí ó jókòó lórí ẹṣin náà àti ogun rẹ̀ jagun. 20 A sì mú ẹranko náà, àti wòlíì èké nì pẹ̀lú rẹ̀, tí ó ti ń ṣe iṣẹ́ ìyanu níwájú rẹ̀, èyí tí ó fi ń tan àwọn tí ó gba ààmì ẹranko náà àti àwọn tí ń foríbalẹ̀ fún àwòrán rẹ̀ jẹ. Àwọn méjèèjì yìí ni a sọ láààyè sínú adágún iná tí ń fi sulfuru jó. 21 Àwọn ìyókù ni a sì fi idà ẹni tí ó jókòó lórí ẹṣin náà pa, àní idà tí ó ti ẹnu rẹ̀ jáde: Gbogbo àwọn ẹyẹ sì ti ipa ẹran-ara wọn yó.
Òwe àgùntàn tó sọnù
15 (A)Gbogbo àwọn agbowó òde àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ sì súnmọ́ ọn láti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀. 2 Àti àwọn Farisi àti àwọn akọ̀wé ń kùn pé, “Ọkùnrin yìí ń gba ẹlẹ́ṣẹ̀, ó sì ń bá wọn jẹun.”
3 Ó sì pa òwe yìí fún wọn, pé, 4 (B)“Ọkùnrin wo ni nínú yín, tí ó ní ọgọ̀rún-ún àgùntàn, bí ó bá sọ ọ̀kan nù nínú wọn, tí kì yóò sì tọ ipasẹ̀ èyí tí ó nù lọ, títí yóò fi rí i? 5 Nígbà tí ó bá sì rí i tán, yóò gbé e lé èjìká rẹ̀ pẹ̀lú ayọ̀. 6 Nígbà tí ó bá sì dé ilé yóò pe àwọn ọ̀rẹ́ àti aládùúgbò rẹ̀ jọ, yóò sì wí fún wọn pé, ‘Ẹ bá mí yọ̀; nítorí tí mo ti rí àgùntàn mi tí ó nù.’ 7 (C)Mo wí fún yín, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ayọ̀ yóò wà ní ọ̀run lórí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tí ó ronúpìwàdà, ju lórí olóòtítọ́ mọ́kàn-dínlọ́gọ́rùn-ún lọ, tí kò nílò ìrònúpìwàdà.
Òwe owó tó sọnù
8 “Tàbí obìnrin wo ni ó ní owó fàdákà mẹ́wàá bí ó bá sọ ọ̀kan nù, tí kì yóò tan fìtílà, kí ó fi gbá ilé, kí ó sì wá a gidigidi títí yóò fi rí i? 9 Nígbà tí ó sì rí i, ó pe àwọn ọ̀rẹ́ àti àwọn aládùúgbò rẹ̀ jọ, ó wí pé, ‘Ẹ bá mi yọ̀; nítorí mo rí owó fàdákà tí mo ti sọnù.’ 10 Mo wí fún yín, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ayọ̀ ń bẹ níwájú àwọn angẹli Ọlọ́run lórí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tí ó ronúpìwàdà.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.