Book of Common Prayer
Ti Dafidi.
37 Má ṣe ìkanra nítorí àwọn olùṣe búburú,
kí ìwọ má sì ṣe ṣe ìlara nítorí àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀;
2 nítorí pé wọn yóò gbẹ bí i koríko,
wọn yóò sì rẹ̀ dànù bí ewéko tútù.
3 Gbẹ́kẹ̀lé Olúwa, kí o sì máa ṣe rere;
torí pé ìwọ yóò gbé ilẹ̀ náà, kí o sì gbádùn ààbò rẹ̀.
4 Ṣe inú dídùn sí Olúwa;
òun yóò sì fún ọ ní ìfẹ́ inú rẹ̀.
5 Fi ọ̀nà rẹ lé Olúwa lọ́wọ́;
gbẹ́kẹ̀lé pẹ̀lú, òun yóò sì ṣe é.
6 Yóò sì mú kí òdodo rẹ̀ jáde bí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀,
àti ìdájọ́ rẹ̀ bí ọ̀sán gangan.
7 Ìwọ dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú Olúwa,
kí o sì fi sùúrù dúró dè é;
má ṣe ṣe ìkanra nítorí àwọn tí ń rí rere ní ọ̀nà wọn,
nítorí ọkùnrin náà ti mú èrò búburú ṣẹ.
8 Fàsẹ́yìn nínú inúbíbí, kí o sì kọ ìkáàánú sílẹ̀,
má ṣe ṣe ìkanra, kí ó má ba à ṣé búburú pẹ̀lú.
9 Nítorí tí á ó gé àwọn olùṣe búburú kúrò,
ṣùgbọ́n àwọn tí ó bá dúró de Olúwa àwọn ni yóò jogún ilẹ̀ náà.
10 Síbẹ̀ nígbà díẹ̀ sí i, àwọn ènìyàn búburú kì yóò sí mọ̀;
nítòótọ́ ìwọ yóò fi ara balẹ̀ wo ipò rẹ̀, wọn kì yóò sí níbẹ̀.
11 Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò jogún ilẹ̀ náà,
wọn yóò sì máa ṣe inú dídùn nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà.
12 Ènìyàn búburú di rìkíṣí sí olóòtítọ́,
wọ́n sì pa eyín wọn keke sí wọn;
13 ṣùgbọ́n Olúwa rẹ́rìn-ín sí àwọn ènìyàn búburú,
nítorí tí ó rí wí pé ọjọ́ wọn ń bọ̀.
14 Ènìyàn búburú fa idà yọ,
wọ́n sì tẹ àwọn ọrun wọn,
láti sọ tálákà àti aláìní kalẹ̀,
láti pa àwọn tí ó dúró ṣinṣin.
15 Idà wọn yóò wọ àyà wọn lọ,
àti wí pé ọrun wọn yóò sì ṣẹ́.
16 Ohun díẹ̀ tí olódodo ní,
sàn ju ọ̀pọ̀ ọrọ̀ ènìyàn búburú;
17 nítorí pé a óò ṣẹ́ ọwọ́ àwọn ènìyàn búburú,
ṣùgbọ́n Olúwa gbé olódodo sókè.
18 Olúwa mọ àwọn ọjọ́ àwọn tó dúró ṣinṣin,
àti wí pé ilẹ̀ ìní wọn yóò wà títí ayérayé;
19 Ojú kì yóò tì wọ́n ní àkókò ibi,
àti ní ọjọ́ ìyàn, a ó tẹ́ wọn lọ́rùn.
20 Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn búburú yóò ṣègbé.
Àwọn ọ̀tá Olúwa yóò dàbí ẹwà oko tútù;
wọn fò lọ; bi èéfín ni wọn yóò fò lọ kúrò.
21 Àwọn ènìyàn búburú yá, wọn kò sì san án padà,
ṣùgbọ́n àwọn olódodo a máa ṣàánú, a sì máa fi fún ni;
22 Nítorí àwọn tí Olúwa bá bùkún ni yóò jogún ilẹ̀ náà,
àwọn tí ó fi bú ni a ó gé kúrò.
23 Ìlànà ìgbésẹ̀ ènìyàn rere wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá,
o sì ṣe inú dídùn sí ọ̀nà rẹ̀;
24 Bí ó tilẹ̀ ṣubú a kì yóò ta á nù pátápátá,
nítorí tí Olúwa di ọwọ́ rẹ̀ mú.
25 Èmi ti wà ni èwe, báyìí èmi sì dàgbà;
síbẹ̀ èmi kò ì tí ì ri kí a kọ olódodo sílẹ̀,
tàbí kí irú-ọmọ rẹ̀ máa ṣagbe oúnjẹ.
26 Aláàánú ni òun nígbà gbogbo a máa yá ni;
a sì máa bùsi i fún ni.
27 Lọ kúrò nínú ibi, kí o sì máa ṣe rere;
nígbà náà ni ìwọ yóò gbé ní ilẹ̀ náà títí láéláé.
28 Nítorí pé Olúwa fẹ́ràn ìdájọ́ òtítọ́,
kò sì kọ àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ sílẹ̀.
Àwọn olódodo ni a ó pamọ́ títí ayérayé,
ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ènìyàn búburú ni a ó ké kúrò.
29 Olódodo ni yóò jogún ilẹ̀ náà,
yóò sì máa gbé ibẹ̀ títí ayérayé.
30 Ẹnu olódodo sọ̀rọ̀ ọgbọ́n,
ahọ́n rẹ̀ a sì máa sọ̀rọ̀ ìdájọ́.
31 Òfin Ọlọ́run rẹ̀ ń bẹ ní àyà wọn;
àwọn ìgbésẹ̀ rẹ̀ kì yóò yẹ̀.
32 Ènìyàn búburú ń ṣọ́ olódodo,
Ó sì ń wá ọ̀nà láti pa á.
33 Olúwa kì yóò fi lé e lọ́wọ́ kì yóò sì dá a lẹ́bi,
nígbà tí a bá ń ṣe ìdájọ́ rẹ̀.
34 Dúró de Olúwa,
kí o sì máa pa ọ̀nà rẹ̀ mọ́.
Yóò sì gbé ọ lékè láti jogún ilẹ̀ náà;
nígbà tí a bá gé àwọn ènìyàn búburú kúrò ìwọ yóò ri.
35 Èmi ti rí ènìyàn búburú tí ń hu ìwà ìkà,
ó sì fi ara rẹ̀ gbilẹ̀ bí igi tútù ńlá,
36 ṣùgbọ́n ní ìṣẹ́jú kan sí i ó kọjá lọ, sì kíyèsi, kò sì sí mọ́;
bi ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé mo wá a kiri, ṣùgbọ́n a kò le è ri.
37 Máa kíyèsi ẹni pípé, kí o sì wo ẹni tó dúró ṣinṣin;
nítorí àlàáfíà ni òpin ọkùnrin náà.
38 Ṣùgbọ́n àwọn olùrékọjá ni a ó parun papọ̀;
ìran àwọn ènìyàn búburú ni a ó gé kúrò.
39 Ìgbàlà àwọn onídùúró ṣinṣin wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa;
òun ni ààbò wọn ní ìgbà ìpọ́njú
40 Olúwa yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ yóò sì gbà wọ́n;
yóò gbà wọ́n lọ́wọ́ ènìyàn búburú, yóò sì gbà wọ́n là,
nítorí tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé e.
14 Nígbà tí àwọn ènìyàn gbéra láti ibùdó láti kọjá nínú odò Jordani, àwọn àlùfáà tí ó ru àpótí ẹ̀rí náà ń lọ níwájú wọn. 15 Odò Jordani sì máa ń wà ní kíkún ní gbogbo ìgbà ìkórè. Ṣùgbọ́n bí àwọn àlùfáà tí ó ru àpótí ẹ̀rí ti dé odò Jordani tí ẹsẹ̀ wọn sì kan etí omi, 16 omi tí ń ti òkè sàn wá dúró. Ó sì gbá jọ bí òkìtì ní òkèèrè, ní ìlú tí a ń pè ní Adamu, tí ó wà ní tòsí Saretani; nígbà tí omi tí ń sàn lọ sínú Òkun aginjù, (Òkun Iyọ̀) gé kúrò pátápátá. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ènìyàn kọjá sí òdìkejì ní ìdojúkọ Jeriko. 17 Àwọn àlùfáà tí ó ru àpótí ẹ̀rí Olúwa sì dúró ṣinṣin lórí ilẹ̀ gbígbẹ ní àárín Jordani, nígbà tí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ń kọjá títí gbogbo orílẹ̀-èdè náà fi rékọjá nínú odò Jordani lórí ilẹ̀ gbígbẹ.
4 Nígbà tí gbogbo orílẹ̀-èdè náà kọjá nínú odò Jordani tan, Olúwa sọ fún Joṣua pé, 2 “Yan ọkùnrin méjìlá (12) nínú àwọn ènìyàn, ẹnìkan nínú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, 3 kí o sì pàṣẹ fún wọn pé Ẹ gbé òkúta méjìlá láti àárín odò Jordani ní ibi tí àwọn àlùfáà dúró sí, kí ẹ sì rù wọn kọjá, kí ẹ sì gbé wọn sí ibi tí ẹ̀yin yóò sùn ní alẹ́ yìí.”
4 Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua pe àwọn ọkùnrin méjìlá tí ó ti yàn nínú àwọn ọmọ Israẹli, ẹnìkan nínú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, 5 ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ kọjá lọ ní iwájú àpótí ẹ̀rí Olúwa Ọlọ́run yín sí àárín odò Jordani. Kí olúkúlùkù yín gbé òkúta kọ̀ọ̀kan lé èjìká a rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí iye ẹ̀yà àwọn ọmọ Israẹli, 6 kí ó sì jẹ́ ààmì láàrín yín. Ní ọjọ́ iwájú, nígbà tí àwọn ọmọ yín bá béèrè lọ́wọ́ yín pé, ‘Kí ni òkúta wọ̀nyí dúró fún?’ 7 Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò dá wọn lóhùn pé, nítorí a gé omi odò Jordani kúrò ní iwájú àpótí ẹ̀rí Olúwa. Nígbà tí a rékọjá a Jordani, a gé omi Jordani kúrò. Àwọn òkúta wọ̀nyí yóò sì jẹ́ ìrántí fún àwọn ọmọ Israẹli láéláé.”
Ẹbọ ààyè mímọ́
12 (A)Nítorí náà mo fi ìyọ́nú Ọlọ́run bẹ̀ yín ará, kí ẹ̀yin kí ó fi ara yín fún Ọlọ́run ní ẹbọ ààyè mímọ́, ìtẹ́wọ́gbà, èyí ni iṣẹ́ ìsìn yín tí ó tọ̀nà. 2 (B)Kí ẹ má sì da ara yín pọ̀ mọ́ ayé yìí; ṣùgbọ́n kí ẹ paradà láti di tuntun ní èrò inú yín, kí ẹ̀yin kí ó lè rí ìdí ìfẹ́ Ọlọ́run, tí ó dára, tí ó sì ṣe ìtẹ́wọ́gbà, ti ó sì pé.
Ìsìn ìrẹ̀lẹ̀ nínú Kristi
3 Ǹjẹ́ mo wí fún olúkúlùkù ènìyàn tí ó wà nínú yín, nípa oore-ọ̀fẹ́ tí a fi fún mi, kí ó má ṣe ro ara rẹ̀ ju bí ó ti yẹ ní rírò lọ; ṣùgbọ́n kí ó le rò níwọ́ntún-wọ́nsì, bí Ọlọ́run ti fi ìwọ̀n ìgbàgbọ́ fún olúkúlùkù. 4 (C)Nítorí gẹ́gẹ́ bí àwa ti ní ẹ̀yà púpọ̀ nínú ara kan, tí gbogbo ẹ̀yà kò sì ní iṣẹ́ kan náà: 5 (D)Bẹ́ẹ̀ ni àwa, tí a jẹ́ púpọ̀, a jẹ́ ara kan nínú Kristi, àti olúkúlùkù ẹ̀yà ara ọmọnìkejì rẹ̀. 6 (E)Ǹjẹ́ bí àwa sì ti ń rí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ẹ̀bùn gbà gẹ́gẹ́ bí oore-ọ̀fẹ́ tí a fi fún wa, bí ó ṣe ìsọtẹ́lẹ̀ ni, kí a máa sọtẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n ìgbàgbọ́; 7 Tàbí iṣẹ́ ìránṣẹ́, kí a kọjú sí iṣẹ́ ìránṣẹ́ wa tàbí ẹni tí ń kọ́ni, kí ó kọjú sí kíkọ́. 8 Tàbí ẹni tí ó ń gbani níyànjú, sí ìgbìyànjú; ẹni tí ń fi fún ni kí ó máa fi inú kan ṣe é; ẹni tí ń ṣe olórí, kí ó máa ṣe é ní ojú méjèèjì; ẹni tí ń ṣàánú, kí ó máa fi inú dídùn ṣe é.
Ìdìtẹ̀ mọ́ Jesu
26 (A)Nígbà tí Jesu ti parí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó wí fún wọn pé, 2 (B)“Bí ẹ̀yin tí mọ̀ ní ọjọ́ méjì sí i, àjọ ìrékọjá yóò bẹ̀rẹ̀. Àti pé, a ó fi Ọmọ Ènìyàn lé wọn lọ́wọ́, a ó sì kàn mí mọ́ àgbélébùú.”
3 Ní àsìkò tí Jesu ń sọ̀rọ̀ yìí, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbàgbà kó ara wọn jọ ní ààfin olórí àlùfáà náà tí à ń pè ní Kaiafa. 4 Láti gbèrò àwọn ọ̀nà tí wọ́n yóò fi mú Jesu pẹ̀lú ẹ̀tàn, kí wọn sì pa á. 5 Ṣùgbọ́n wọ́n fohùn ṣọ̀kan pé, “Kì í ṣe lásìkò àsè àjọ ìrékọjá, nítorí rògbòdìyàn yóò ṣẹlẹ̀.”
A fi òróró kun Jesu lára ní Betani
6 (C)Nígbà tí Jesu wà ní Betani ní ilé ọkùnrin tí à ń pè ní Simoni adẹ́tẹ̀; 7 Bí ó ti ń jẹun, obìnrin kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú alabasita òróró ìkunra iyebíye, ó sì dà á sí i lórí.
8 Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rí i, inú bí wọn. Wọ́n wí pé, “Irú ìfowóṣòfò wo ni èyí? 9 Èéha ti ṣe, obìnrin yìí ìbá tà á ní owó púpọ̀, kí a sì fi owó náà fún àwọn aláìní.”
10 Jesu ti mọ èrò ọkàn wọn, ó wí pé, “Èéṣe ti ẹ̀yin fi ń dá obìnrin yìí lẹ́bi? Ó ṣe ohun tí ó dára fún mi 11 Ẹ̀yin yóò ní àwọn aláìní láàrín yín nígbà gbogbo, ṣùgbọ́n, ẹ̀yin kò le rí mi nígbà gbogbo. 12 Nípa dída òróró ìkunra yìí sí mi lára, òun ń ṣe èyí fún ìsìnkú mi ni. 13 Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, a ó sì máa ṣe ìrántí rẹ̀ nígbà gbogbo fún ìṣesí rẹ̀ yìí. Níbikíbi tí a bá ti wàásù ìhìnrere yìí ní gbogbo àgbáyé ni a ó ti sọ ìtàn ohun tí obìnrin yìí ṣe.”
Judasi gbà láti fi Jesu hàn
14 (D)Nígbà náà ni ọ̀kan nínú àwọn aposteli méjìlá ti à ń pè ní Judasi Iskariotu lọ sọ́dọ̀ àwọn olórí àlùfáà. 15 (E)Òun sì béèrè pé, “Kí ni ẹ̀yin yóò san fún mi bí mo bá fi Jesu lé yín lọ́wọ́?” Wọ́n sì fún un ní ọgbọ́n owó fàdákà. Ó sì gbà á. 16 Láti ìgbà náà lọ ni Judasi ti bẹ̀rẹ̀ sí i wá ọ̀nà láti fà á lé wọn lọ́wọ́.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.