Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 72

Ti Solomoni

72 Fi ìdájọ́ fún àwọn ọba, Ọlọ́run,
    ọmọ-aládé ni ìwọ fi òdodo rẹ fún
Yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ pẹ̀lú òdodo,
    yóò sì máa fi ẹ̀tọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn tálákà rẹ̀.

Àwọn òkè ńlá yóò máa mú àlàáfíà fún àwọn ènìyàn
    àti òkè kéékèèkéé nípa òdodo
Yóò dáàbò bo àwọn tí a pọ́n lójú láàrín àwọn ènìyàn
    yóò gba àwọn ọmọ aláìní;
    yóò sì fa àwọn aninilára ya.
Àwọn òtòṣì àti aláìní
    yóò máa fi ọ̀wọ̀ ńlá fún ọ nígbà gbogbo,
níwọ̀n ìgbà tí oòrùn àti òṣùpá bá ń ràn,
    yóò ti pẹ́ tó, láti ìrandíran.
Yóò dàbí òjò tí ó ń rọ̀ sórí pápá ìrẹ́mọ́lẹ̀
    Bí ọwọ́ òjò tó ń rin ilẹ̀
Àwọn olódodo yóò gbilẹ̀ ni ọjọ́ rẹ̀
    ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà yóò sì wà;
    títí tí òṣùpá kò fi ní sí mọ́.

Yóò máa jẹ ọba láti Òkun dé Òkun
    àti láti odò Eufurate títí dé òpin ayé.
Àwọn tí ó wà ní aginjù yóò tẹríba fún un
    àwọn ọ̀tá rẹ̀ yóò máa lá erùpẹ̀ ilẹ̀.
10 Àwọn ọba Tarṣiṣi àti ti erékùṣù
    wọn yóò mú ọrẹ wá fún un;
àwọn ọba Ṣeba àti Seba
    wọn ó mú ẹ̀bùn wá fún un.
11 Gbogbo ọba yóò tẹríba fún un
    àti gbogbo orílẹ̀-èdè yóò sìn ín.

12 Nítorí yóò gba àwọn aláìní
    nígbà tí ó bá ń ké,
tálákà àti ẹni tí kò ní olùrànlọ́wọ́.
13 Yóò káàánú àwọn aláìlera àti aláìní
    yóò pa aláìní mọ́ kúrò nínú ikú.
14 Yóò ra ọkàn wọn padà lọ́wọ́ ẹ̀tàn àti ipá
    nítorí ẹ̀jẹ̀ wọn ṣọ̀wọ́n níwájú rẹ̀.

15 Yóò sì pẹ́ ní ayé!
    A ó sì fún un ní wúrà Ṣeba.
Àwọn ènìyàn yóò sì máa gbàdúrà fún un nígbà gbogbo
    kí a sì bùkún fún un lójoojúmọ́.
16 Kí ìkúnwọ́ ọkà wà lórí ilẹ̀;
    ní orí òkè ni kí ó máa dàgbà
kí èso rẹ̀ kí o gbilẹ̀ bí ti Lebanoni
    yóò máa gbá yìn bí i koríko ilẹ̀.
17 Kí orúkọ rẹ̀ kí ó wà títí láé;
    orúkọ rẹ̀ yóò máa gbilẹ̀ níwọ̀n bí oòrùn yóò ti pẹ́ tó.

Wọn ó sì máa bùkún fún ara wọn nípasẹ̀ rẹ.
    Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ní yóò máa pè mí ní alábùkún fún.

18 Olùbùkún ni Olúwa Ọlọ́run, Ọlọ́run Israẹli,
    ẹnìkan ṣoṣo tí ó ń ṣe ohun ìyanu.
19 Olùbùkún ni orúkọ rẹ̀ tí ó lógo títí láé;
    kí gbogbo ayé kún fún ògo rẹ̀.
Àmín àti Àmín.

20 Èyí ni ìparí àdúrà Dafidi ọmọ Jese.

Saamu 119:73-96

Ẹlẹgbẹ́ mi ni àwọn tó mọ òfin Olúwa

73 Ọwọ́ rẹ ni ó dá mi tí ó sì mọ mí;
    fún mi ní òye láti kọ́ àṣẹ rẹ.
74 Jẹ́ kí gbogbo àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ máa yọ̀ nígbà tí wọ́n bá rí mi,
    nítorí èmi ti mú ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ rẹ.
75 Èmi mọ, Olúwa, nítorí òfin rẹ òdodo ni,
    àti ní òtítọ́ ni ìwọ pọ́n mi lójú.
76 Kí ìfẹ́ rẹ tí kì í kùnà jẹ́ ìtùnú mi,
    gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ sí ìránṣẹ́ rẹ.
77 Jẹ́ kí àánú rẹ kí ó tọ̀ mí wá, kí èmi kí ó lè yè,
    nítorí òfin rẹ jẹ́ ìdùnnú mi.
78 Kí ojú kí ó ti àwọn agbéraga
    nítorí wọn pa mí lára láìnídìí
    ṣùgbọ́n èmi yóò máa ṣe àṣàrò nínú ẹ̀kọ́ rẹ.
79 Kí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ yí padà sí mi,
    àwọn tí ó ní òye òfin rẹ.
80 Jẹ́ kí ọkàn mi wà láìlẹ́bi sí òfin rẹ,
    kí ojú kí ó má ṣe tì mí.

Wíwá àlàáfíà

81 Ọkàn mi ń fojú ṣọ́nà nítorí ìgbàlà rẹ,
    ṣùgbọ́n èmi ti fi ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ rẹ.
82 Ojú mi kùnà, pẹ̀lú wíwo ìpinnu rẹ;
    èmi wí pé, “Nígbà wo ni ìwọ yóò tù mí nínú?”
83 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi dàbí awọ-wáìnì lójú èéfín,
    èmi kò gbàgbé ìlànà rẹ.
84 Báwo ni ìránṣẹ́ rẹ̀ yóò ṣe dúró pẹ́ tó?
    Nígbà wo ni ìwọ yóò bá àwọn
    tí ń ṣe inúnibíni sí mi wí?
85 Àwọn agbéraga wa ihò ìṣubú fún mi,
    tí ó lòdì sí òfin rẹ.
86 Gbogbo àṣẹ rẹ yẹ ní ìgbẹ́kẹ̀lé:
    ràn mí lọ́wọ́, nítorí ènìyàn
    ń ṣe inúnibíni sí mi láìnídìí.
87 Wọ́n fẹ́rẹ pa mí rẹ́ kúrò nínú ayé,
    ṣùgbọ́n èmi kò kọ ẹ̀kọ́ rẹ.
88 Pa ayé mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ,
    èmi yóò sì gba ẹ̀rí ẹnu rẹ̀ gbọ́.

Ọ̀rọ̀ Olúwa dúró títí láé

89 Ọ̀rọ̀ rẹ, Olúwa, títí láé ni;
    ó dúró ṣinṣin ní ọ̀run
90 Òtítọ́ rẹ̀ ń lọ dé gbogbo ìran dé ìran;
    ìwọ ti dá ayé, ó sì dúró ṣinṣin.
91 Òfin rẹ dúró di òní
    nítorí ohun gbogbo ń sìn ọ́.
92 Bí òfin rẹ̀ kò bá jẹ́ dídùn inú mi,
    èmi ìbá ti ṣègbé nínú ìpọ́njú mi.
93 Èmi kì yóò gbàgbé ẹ̀kọ́ rẹ láé,
    nítorí nípa wọn ni ìwọ ti pa ayé mi mọ́
94 Gbà mí, nítorí èmi jẹ́ tìrẹ
    èmi ti wá ẹ̀kọ́ rẹ.
95 Àwọn ẹni búburú dúró láti pa mí run,
    ṣùgbọ́n èmi yóò kíyèsi ẹ̀rí rẹ.
96 Sí ohun pípé gbogbo èmi ti rí òpin;
    ṣùgbọ́n àṣẹ rẹ aláìlópin ni.

Lefitiku 19:1-18

Àwọn onírúurú òfin

19 Olúwa sọ fún Mose pé, (A)“Bá gbogbo àpéjọpọ̀ àwọn ọmọ Israẹli sọ̀rọ̀, sì wí fún wọn pé: ‘Ẹ jẹ́ mímọ́ nítorí Èmi Olúwa Ọlọ́run yín jẹ́ mímọ́.

(B)“ ‘Ẹnìkọ̀ọ̀kan yín gbọdọ̀ bọ̀wọ̀ fún ìyá àti baba rẹ̀, kí ẹ sì ya ọjọ́ ìsinmi mi sí mímọ́. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.

(C)“ ‘Ẹ má ṣe yípadà tọ ère òrìṣà lẹ́yìn, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ rọ ère òrìṣà idẹ fún ara yín. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.

“ ‘Nígbà tí ẹ̀yin bá sì rú ẹbọ àlàáfíà sí Olúwa, kí ẹ̀yin kí ó ṣe é ní ọ̀nà tí yóò fi jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà dípò yín. Ní ọjọ́ tí ẹ bá rú u náà ni ẹ gbọdọ̀ jẹ ẹ́ tàbí ní ọjọ́ kejì; èyí tí ó bá ṣẹ́kù di ọjọ́ kẹta ni kí ẹ fi iná sun. Bí ẹ bá jẹ nínú èyí tí ó ṣẹ́kù di ọjọ́ kẹta, àìmọ́ ni èyí jẹ́, kò ní jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà. Nítorí náà ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ẹ́ ni a ó di ẹ̀bi rẹ̀ rù, nítorí pé ó ti ba ohun mímọ́ Olúwa jẹ́, irú ẹni bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ gé kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀.

(D)“ ‘Nígbà tí ẹ̀yin bá kórè nǹkan oko yín, kí ẹ̀yin kí ó fi díẹ̀ sílẹ̀ láìkórè ní àwọn igun oko yín, ẹ̀yin kò sì gbọdọ̀ ṣa ẹ̀ṣẹ́ (nǹkan oko tí ẹ ti gbàgbé tàbí tí ó bọ́ sílẹ̀). 10 Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ kórè oko yín tan pátápátá, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin kò gbọdọ̀ ṣa èso tí ó rẹ̀ bọ́ sílẹ̀ nínú ọgbà àjàrà yín. Ẹ fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn aláìní àti fún àwọn àlejò. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.

11 (E)“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ jalè.

“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ parọ́.

“ ‘Ẹ kò gbọdọ̀ tan ara yín jẹ.

12 (F)“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ fi orúkọ mi búra èké: kí o sì tipa bẹ́ẹ̀ ba orúkọ Ọlọ́run rẹ jẹ́. Èmi ni Olúwa.

13 (G)“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ rẹ́ aládùúgbò rẹ jẹ bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ jà á lólè.

“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ dá owó iṣẹ́ alágbàṣe dúró di ọjọ́ kejì.

14 (H)“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣépè lé adití: bẹ́ẹ̀ ni o kò gbọdọ̀ fi ohun ìdìgbòlù sí iwájú afọ́jú, ṣùgbọ́n bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run rẹ: Èmi ni Olúwa.

15 (I)“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ yí ìdájọ́ po, má ṣe ojúsàájú sí ẹjọ́ tálákà: bẹ́ẹ̀ ni o kò gbọdọ̀ gbé ti ọlọ́lá lẹ́yìn: ṣùgbọ́n fi òdodo ṣe ìdájọ́, àwọn aládùúgbò rẹ.

16 “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ máa ṣèyíṣọ̀hún bí olóòfófó láàrín àwọn ènìyàn rẹ.

“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ohunkóhun tí yóò fi ẹ̀mí aládùúgbò rẹ wéwu: Èmi ni Olúwa.

17 “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ kórìíra arákùnrin rẹ lọ́kàn rẹ, bá aládùúgbò rẹ wí, kí o má ba à jẹ́ alábápín nínú ẹ̀bi rẹ̀.

18 (J)“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ gbẹ̀san: má sì ṣe bínú sí èyíkéyìí nínú àwọn ènìyàn rẹ. Ṣùgbọ́n, kí ìwọ kí ó fẹ́ ẹnìkejì rẹ bí ara rẹ, Èmi ni Olúwa.

1 Tẹsalonika 5:12-28

Ọ̀rọ̀ ìkẹyìn

12 (A)Ẹ̀yin ará, ẹ fi ọlá fún àwọn olórí tí ń ṣe iṣẹ́ àṣekára láàrín yín tí wọn ń kìlọ̀ fún yín nínú Olúwa. 13 (B)Ẹ bu ọlá fún wọn gidigidi nínú ìfẹ́, nítorí iṣẹ́ wọn. Ẹ sì máa wà ní àlàáfíà láàrín ara yín. 14 (C)Ẹ̀yin ará mi, ẹ kìlọ̀ fún àwọn ọ̀lẹ ti ó wà láàrín yín, ẹ gba àwọn tí ẹ̀rù ń bà ní ìyànjú, ẹ tọ́jú àwọn aláìlera pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́, kí ẹ sì ní sùúrù pẹ̀lú gbogbo ènìyàn. 15 (D)Ẹ rí i pé kò sí ẹni tí ó fi búburú san búburú, ṣùgbọ́n ẹ máa lépa èyí tí í ṣe rere láàrín ara yín àti sí ènìyàn gbogbo.

16 (E)Ẹ máa yọ̀ nígbà gbogbo 17 (F)Ẹ máa gbàdúrà nígbà gbogbo 18 (G)Ẹ máa dúpẹ́ nígbà gbogbo nínú ipòkípò tí o wù kí ẹ wà; nítorí pé, èyí ni ìfẹ́ Ọlọ́run fún yin nínú Kristi Jesu nítòótọ́.

19 (H)Ẹ má ṣe pa iná Ẹ̀mí Mímọ́. 20 (I)Ẹ má ṣe kẹ́gàn àwọn ti ń sọtẹ́lẹ̀. 21 (J)Ṣùgbọ́n ẹ dán gbogbo nǹkan wò. Ẹ di èyí tí ṣe òtítọ́ mú. 22 Ẹ yẹra fún ohunkóhun tí í ṣe ibi.

23 (K)Kí Ọlọ́run fúnra rẹ̀, Ọlọ́run àlàáfíà, sọ yín di mímọ́ pátápátá. Kí Ọlọ́run pa ẹ̀mí àti ọkàn pẹ̀lú ara yín mọ́ pátápátá ní àìlábùkù, títí di ìgbà wíwá Jesu Kristi Olúwa wa. 24 Olóòtítọ́ ni ẹni tí ó pè yín, yóò sì ṣe.

25 Ẹ̀yin ará, ẹ gbàdúrà fún wa.

26 (L)Ẹ fi ìfẹ́nukonu mímọ́ ki ara yin.

27 (M)Mo pàṣẹ fún yín níwájú Olúwa pé, kí ẹ ka lẹ́tà yìí fún gbogbo àwọn ará.

28 (N)Ki oore-ọ̀fẹ́ Jesu Kristi Olúwa wa, wà pẹ̀lú yín.

Matiu 6:19-24

Títo ìṣúra jọ sí Ọ̀run

19 (A)“Má ṣe to àwọn ìṣúra jọ fún ara rẹ ní ayé yìí, níbi tí kòkòrò ti le jẹ ẹ́, tí ó sì ti le bàjẹ́ àti ibi tí àwọn olè lè fọ́ tí wọ́n yóò sì jí i lọ. 20 Dípò bẹ́ẹ̀ to ìṣúra rẹ jọ sí ọ̀run, níbi ti kòkòrò àti ìpáàrà kò ti lè bà á jẹ́, àti ní ibi tí àwọn olè kò le fọ́ wọlé láti jí í lọ. 21 Nítorí ibi tí ìṣúra yín bá wà níbẹ̀ náà ni ọkàn yín yóò wà pẹ̀lú.

22 (B)“Ojú ni fìtílà ara. Bí ojú rẹ bá mọ́lẹ̀ kedere, gbogbo ara rẹ yóò jẹ́ kìkì ìmọ́lẹ̀. 23 Ṣùgbọ́n bí ojú rẹ kò bá dára, gbogbo ara rẹ ni yóò kún fún òkùnkùn. Bí ìmọ́lẹ̀ ti ó wà nínú rẹ bá wá jẹ́ òkùnkùn, òkùnkùn náà yóò ti pọ̀ tó!

24 (C)“Kò sì í ẹnìkan tí ó lè sin ọ̀gá méjì. Òun yóò yà kórìíra ọ̀kan tí yóò fẹ́ràn èkejì, tàbí kí ó fi ara mọ́ ọ̀kan kí ó sì yan èkejì ní ìpọ̀sí. Ẹ̀yin kò lè sin Ọlọ́run àti owó papọ̀.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.