Book of Common Prayer
Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi. Nígbà ti wòlíì Natani tọ wá, lẹ́yìn tí Dafidi dá ẹ̀ṣẹ̀ àgbèrè rẹ̀ pẹ̀lú Batṣeba.
51 Ṣàánú fún mi, Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí
ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ rẹ̀,
gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ àánú rẹ̀
kí o sì pa gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi rẹ́.
2 Wẹ gbogbo àìṣedéédéé mi nù kúrò
kí o sì wẹ̀ mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ mi!
3 Nítorí mo mọ̀ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi,
nígbà gbogbo ni ẹ̀ṣẹ̀ mi wà níwájú mi.
4 (A)Sí ọ, ìwọ nìkan ṣoṣo, ni mo dẹ́ṣẹ̀ sí
ni mo sì ṣe búburú níwájú rẹ̀,
kí a lè dá ọ láre nígbà tí ìwọ bá ń sọ̀rọ̀,
kí o sì le wà láìlẹ́bi, nígbà tí ìwọ bá ń ṣe ìdájọ́.
5 Nítòótọ́, nínú ẹ̀ṣẹ̀ ni a ti bí mi,
nínú ẹ̀ṣẹ̀ ni ìyá mí sì lóyún mi.
6 Nítòótọ́ ìwọ fẹ́ òtítọ́ ní inú;
ìwọ kọ́ mi ní ọgbọ́n ní ìhà ìkọ̀kọ̀.
7 Wẹ̀ mí pẹ̀lú ewé hísópù, èmi yóò sì mọ́;
fọ̀ mí, èmi yóò sì funfun ju yìnyín lọ.
8 Jẹ́ kí n gbọ́ ayọ̀ àti inú dídùn;
jẹ́ kí gbogbo egungun tí ìwọ ti run kí ó máa yọ̀.
9 Pa ojú rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ mi
kí o sì pa gbogbo àwọn àìṣedéédéé mi rẹ́.
10 Dá ọkàn mímọ́ sí inú mi, Ọlọ́run,
kí o sì tún ẹ̀mí dídúró ṣinṣin ṣe sínú mi.
11 Má ṣe jù mi nù kúrò níwájú rẹ,
kí o má ṣe gba ẹ̀mí mímọ́ rẹ lọ́wọ́ mi.
12 Mú ayọ̀ ìgbàlà rẹ tọ̀ mí wá,
kí o sì fún mi ní ẹ̀mí ìfẹ́, tí yóò mú mi dúró.
13 Nígbà náà ni èmi yóò máa kọ́ àwọn olùrékọjá ní ọ̀nà rẹ,
àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ yóò sì yí padà sí ọ.
14 Gbà mí kúrò lọ́wọ́ ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀, Ọlọ́run,
ìwọ Ọlọ́run ìgbàlà mi,
ahọ́n mi yóò sì máa kọrin òdodo rẹ kíkan.
15 Olúwa, ṣí mi ní ètè mi gbogbo,
àti ẹnu mi yóò sì máa kéde ìyìn rẹ.
16 Nítorí ìwọ kò ní inú dídùn sí ẹbọ, tí èmi kò bá mú wá;
Ìwọ kò ní inú dídùn sí ọrẹ ẹbọ sísun.
17 Ẹbọ Ọlọ́run ni ìròbìnújẹ́ ọkàn ìròbìnújẹ́ àti ìrora àyà.
18 Ṣe rere ní dídùn inú rẹ sí Sioni,
ṣe rere; tún odi Jerusalẹmu mọ.
19 Nígbà náà ni inú rẹ yóò dùn sí ẹbọ òdodo,
pẹ̀lú ọrẹ ẹbọ sísun àti ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ọrẹ ẹbọ sísun,
nígbà náà ni wọn yóò fi akọ màlúù rú ẹbọ lórí pẹpẹ rẹ.
Fún adarí orin. Tí ohùn “Àwọn Lílì.” Ti Dafidi.
69 Gbà mí, Ọlọ́run,
nítorí omi ti kún dé ọrùn mi.
2 Mo ń rì nínú irà jíjìn,
níbi tí kò sí ibi ìfẹsẹ̀lé.
Mo ti wá sínú omi jíjìn;
ìkún omi bò mí mọ́lẹ̀.
3 Agara dá mi, mo ń pè fún ìrànlọ́wọ́;
ọ̀fun mí gbẹ, ojú mi ṣú,
nígbà tí èmi dúró de Ọlọ́run mi.
4 (A)Àwọn tí ó kórìíra mi láìnídìí
wọ́n ju irun orí mi; lọ
púpọ̀ ni àwọn ọ̀tá mi láìnídìí,
àwọn tí ń wá láti pa mí run
A fi ipá mú mi
láti san ohun tí èmi kò jí.
5 Ìwọ mọ òmùgọ̀ mi, Ọlọ́run;
ẹ̀bi mi kò pamọ́ lójú rẹ.
6 Má ṣe dójútì àwọn tí ó ní ìrètí nínú rẹ
nítorí mi,
Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun;
Má ṣe jẹ́ kí àwọn tó ń wá ọ dààmú nítorí mi,
Ọlọ́run Israẹli.
7 Nítorí rẹ ni mo ń ru ẹ̀gàn,
ìtìjú sì bo ojú mi.
8 Mo jẹ́ àjèjì si àwọn arákùnrin mi;
àlejò sí àwọn arákùnrin ìyá mi;
9 (B)Nítorí ìtara ilé rẹ jẹ mí run,
àti ẹ̀gàn àwọn tí ń gàn ọ́ ṣubú lù mí.
10 Nígbà tí mo sọkún
tí mo sì ń fi àwẹ̀ jẹ ara mi ní ìyà
èyí náà sì dín ẹ̀gàn mi kù;
11 Nígbà tí mo wọ aṣọ àkísà,
àwọn ènìyàn ń pa òwe mọ́ mi.
12 Àwọn tí ó jókòó ní ẹnu ibodè ń bú mi,
mo sì di orin àwọn ọ̀mùtí.
13 Ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti èmi ni
ìwọ ni èmi ń gbàdúrà mi sí Olúwa,
ní ìgbà ìtẹ́wọ́gbà
Ọlọ́run, nínú ìfẹ́ títóbi rẹ,
dá mi lóhùn pẹ̀lú ìgbàlà rẹ tí ó dájú.
14 Gbà mí kúrò nínú ẹrẹ̀,
Má ṣe jẹ́ kí n rì;
gbà mí lọ́wọ́ àwọn tí ó kórìíra mi,
kúrò nínú ibú omi.
15 Má ṣe jẹ́ kí ìkún omi bò mí mọ́lẹ̀
bẹ́ẹ̀ ni má ṣe jẹ́ kí ọ̀gbìn gbé mi mì
kí o má sì ṣe jẹ́ kí ihò pa ẹnu rẹ̀ dé mọ́ mi.
16 Dá mí lóhùn, Olúwa, nínú ìṣeun ìfẹ́ rẹ;
nínú ọ̀pọ̀ àánú rẹ yípadà sí mi.
17 Má ṣe pa ojú rẹ mọ́ fún ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ:
yára dá mi lóhùn, nítorí mo wà nínú ìpọ́njú.
18 Súnmọ́ tòsí kí o sì gbà mí là;
rà mí padà nítorí àwọn ọ̀tá mi.
19 Ìwọ ti mọ ẹ̀gàn mi, ìtìjú mi àti àìlọ́lá;
Gbogbo àwọn ọ̀tá mi wà níwájú rẹ.
20 Ẹ̀gàn ba ọkàn mi jẹ́, wọ́n fi mí sílẹ̀ láìsí ìrànlọ́wọ́
Mo ń wá aláàánú, ṣùgbọ́n kò sí,
mo ń wá olùtùnú, ṣùgbọ́n n kò rí ẹnìkankan.
21 Wọ́n fi òróró fún mi pẹ̀lú ohun jíjẹ mi,
àti ní òùngbẹ mi, wọ́n fi ọtí kíkan fún mi.
22 Jẹ́ kí tábìlì wọn kí ó di ìkẹ́kùn
ní iwájú wọn, kí ó sì di okùn dídẹ
fún àwọn tó wà ní àlàáfíà.
23 Kí ojú wọn kì í ó ṣókùnkùn, kí wọn má ṣe ríran,
kí ẹ̀yin wọn di títẹ̀ títí láé.
1 Báwo ni ìlú ṣe jókòó nìkan,
nígbà kan tí ó sì kún fún ènìyàn!
Ó ti fìgbà kan jẹ́ ìlú olókìkí láàrín àwọn orílẹ̀-èdè,
tí ó wà ní ipò opó,
Ẹni tí ó jẹ́ ọmọ ọbabìnrin láàrín ìlú
ni ó padà di ẹrú.
2 Ọ̀gànjọ́ òru ni ó fi máa ń sọkún kíkorò
pẹ̀lú omijé ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀ tí ó dúró sí ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀.
Nínú gbogbo àwọn olólùfẹ́ rẹ̀
kò sí ọ̀kan nínú wọn láti rẹ̀ ẹ́ lẹ́kún.
Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ti jọ̀wọ́ rẹ̀
wọ́n ti di alátakò rẹ̀.
6 Gbogbo ẹwà ti di ohun ìgbàgbé
kúrò lọ́dọ̀ ọmọbìnrin Sioni.
Àwọn ìjòyè rẹ̀ dàbí i àgbọ̀nrín
tí kò rí ewé tútù jẹ;
nínú àárẹ̀ wọ́n sáré
níwájú ẹni tí ó ń lé wọn.
7 Ní ọjọ́ ìpọ́njú àti àrìnká rẹ̀ ni
Jerusalẹmu rántí àwọn ohun ìní dáradára rẹ̀
tí ó jẹ́ tirẹ̀ ní ọjọ́ pípẹ́.
Nígbà tí àwọn ènìyàn rẹ̀ ṣubú ṣọ́wọ́ àwọn ọ̀tá,
kò sì ṣí olùrànlọ́wọ́ fún un.
Àwọn ọ̀tá rẹ̀ wò ó
wọ́n sì ń fi ìparun rẹ̀ ṣẹlẹ́yà.
8 Jerusalẹmu sì ti dẹ́ṣẹ̀ púpọ̀
ó sì ti di aláìmọ́.
Àwọn tí ó ń tẹríba fún un sì kẹ́gàn rẹ̀,
nítorí wọ́n ti rí ìhòhò rẹ̀;
ó kérora fúnrarẹ̀,
ó sì lọ kúrò.
9 Ìdọ̀tí wà ní etí aṣọ rẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ni kò wo ọjọ́ iwájú rẹ̀,
Ìṣubú rẹ̀ ya ni lẹ́nu;
olùtùnú kò sì ṣí fún un.
“Wo ìpọ́njú mi, Olúwa,
nítorí àwọn ọ̀tá ti borí.”
10 Ọ̀tá ti gbọ́wọ́ lé
gbogbo ìní rẹ;
o rí pé àwọn orílẹ̀-èdè
tí wọ́n wọ ibi mímọ́ rẹ—
àwọn tí o ti kọ̀sílẹ̀
láti wọ ìpéjọpọ̀ rẹ.
11 Àwọn ènìyàn rẹ̀ ń kérora
bí wọ́n ti ń wá oúnjẹ;
wọ́n fi ohun ìní wọn ṣe pàṣípàrọ̀ oúnjẹ
láti mú wọn wà láààyè.
“Wò ó, Olúwa, kí o sì rò ó,
nítorí a kọ̀ mí sílẹ̀.”
12 “Kò ha jẹ́ nǹkan kan sí i yín?
Gbogbo ẹ̀yin tí ń rékọjá,
Ǹjẹ́ ẹnìkan ń jìyà bí èmi ti ń jìyà
tí a fi fún mi, ti
Olúwa mú wá fún mi
ní ọjọ́ ìbínú gbígbóná rẹ̀.
1 (A)Paulu aposteli Jesu Kristi nípa ìfẹ́ Ọlọ́run, àti Timotiu arákùnrin wá, sí ìjọ Ọlọ́run tí ó wà ní Kọrinti pẹ̀lú gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́ tí ó wà ní gbogbo Akaia:
2 (B)Oore-ọ̀fẹ́ sí yín àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa, àti Jesu Kristi Olúwa.
Ọlọ́run gbogbo ìtùnú
3 (C)Olùbùkún ni Ọlọ́run, àti Baba Jesu Kristi Olúwa wa, Baba ìyọ́nú, àti Ọlọ́run ìtùnú gbogbo; 4 (D)Ẹni tí ń tù wá nínú ni gbogbo ìdààmú wa, ki àwa pẹ̀lú lè máa tu àwọn tí ó wá nínú ìdààmú nínú, nípá ìtùnú náà ti a fi ń tú àwa fúnra wa nínú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá. 5 Nítorí pé bí àwa ti pín nínú ìjìyà Kristi, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ nì ìtùnú wa dí púpọ̀ pẹ̀lú nípa Kristi. 6 Ṣùgbọ́n bí a bá sì ń pọ́n wa lójú, ó jẹ́ fún ìtùnú àti ìgbàlà yín; tàbí bi a bá ń tù wá nínú, ó jẹ́ fún ìtùnú yín ti ń ṣiṣẹ́ sùúrù láti mú yin ní irú ìfaradà ìyà kan náà ti àwa pẹ̀lú ń jẹ́. 7 Àti pé ìrètí wa nípa tiyín dúró ṣinṣin, àwa si mọ̀ pé, bí ẹ̀yin ti jẹ alábápín nínú ìyà wa, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin ń pín nínú ìtùnú náà pẹ̀lú.
Jesu palẹ̀ tẹmpili mọ́
12 (A)Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, bí wọ́n ti kúrò ní Betani, ebi ń pa Jesu. 13 Ó rí igi ọ̀pọ̀tọ́ kan lọ́ọ̀ọ́kán tí ewé kún orí rẹ̀. Nígbà náà, ó lọ sí ìdí rẹ̀ láti wò ó bóyá ó léso tàbí kò léso. Nígbà tí ó dé ibẹ̀, ewé lásán ni ó rí, kò rí èso lórí rẹ̀. Nítorí pé àkókò náà kì í ṣe àkókò tí igi ọ̀pọ̀tọ́ máa ń so. 14 Lẹ́yìn náà, Jesu pàṣẹ fún igi náà pé, “Kí ẹnikẹ́ni má ṣe jẹ èso lórí rẹ mọ́ títí láé.” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ gbọ́ nígbà tí ó wí bẹ́ẹ̀.
15 (B)Nígbà ti wọ́n padà sí Jerusalẹmu, ó wọ inú tẹmpili. Ó bẹ̀rẹ̀ sí nílé àwọn oníṣòwò àti àwọn oníbàárà wọn síta. Ó ti tábìlì àwọn tí ń pààrọ̀ owó nínú tẹmpili ṣubú. Bákan náà ni ó ti ìjókòó àwọn tí ń ta ẹyẹlé lulẹ̀. 16 Kò sì gba ẹnikẹ́ni láààyè láti gbé ẹrù ọjà títà gba inú tẹmpili wọlé. 17 (C)Gẹ́gẹ́ bí ó ti kọ́ wọn, ó wí pé, “Ṣé a kò ti kọ ọ́ pé: ‘Ilé àdúrà ni a o máa pe ilé mi, ní gbogbo orílẹ̀-èdè?’ Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti sọ ọ́ di ibùgbé àwọn ọlọ́ṣà.”
18 Nígbà tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin gbọ́ ohun tí ó ti ṣe, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ń gbà èrò bí wọn yóò ti ṣe pa á. Wọ́n bẹ̀rù rògbòdìyàn tí yóò bẹ́ sílẹ̀, nítorí tí àwọn ènìyàn ní ìgbóná ọkàn sí ẹ̀kọ́ rẹ̀.
19 (D)Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà, bí ìṣe wọn, Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ jáde kúrò ní ìlú Jerusalẹmu.
Igi ọ̀pọ̀tọ́ tí kò ní eṣo
20 (E)Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, bí wọ́n ti ń kọjá lọ, wọ́n rí igi ọ̀pọ̀tọ́ tí Jesu fi bú. Wọ́n rí i pé ó ti gbẹ tigbòǹgbò tigbòǹgbò. 21 Peteru rántí pé Jesu ti bá igi náà wí. Nígbà náà ni ó sọ fún Jesu pé, “Rabbi, Wò ó! Igi ọ̀pọ̀tọ́ tí ìwọ fi bú ti gbẹ!”
22 Jesu sì dáhùn pé, “Ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, 23 Lóòótọ́ ni mò wí fún un yín, bí ẹnikẹ́ni bá wí fún òkè ‘ṣídìí, gbé ara rẹ sọ sínú Òkun’ ti kò sì ṣe iyèméjì nínú ọkàn rẹ̀ ṣùgbọ́n tí ó gbàgbọ́ pé ohun tí òun wí yóò ṣẹ, yóò rí bẹ́ẹ̀ fún un. 24 (F)Torí náà, mo wí fún yín ohunkóhun tí ẹ bá béèrè fún nínú àdúrà, ẹ ní ìgbàgbọ́ pé, ó tí tẹ̀ yín lọ́wọ́, yóò sì jẹ́ tiyín. 25 (G)Nígbà tí ẹ bá ń gbàdúrà, ẹ kọ́kọ́ dáríjì, bí ẹ̀yin bá ní ohunkóhun sí ẹnikẹ́ni, kí baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run bá à le dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tiyín náà jì yín.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.