Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 97

97 Olúwa jẹ ọba, jẹ́ kí ayé kí ó yọ̀
    jẹ́ kí inú ọ̀pọ̀lọpọ̀ erékùṣù kí ó dùn
Ojú ọ̀run àti òkùnkùn yíká
    òdodo àti ìdájọ́ ni ó ṣe ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìtẹ́ rẹ̀.
Iná ń jó níwájú rẹ̀. Ó sì ń jó àwọn ọ̀tá rẹ̀ yíkákiri
Ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ tàn ó sì kárí ayé
    ayé rí i ó sì wárìrì
Òkè gíga yọ́ gẹ́gẹ́ bí ìda níwájú Olúwa,
    níwájú Olúwa gbogbo ayé.
Àwọn ọ̀run ròyìn òdodo rẹ̀, gbogbo ènìyàn sì rí ògo rẹ̀.

(A)Gbogbo àwọn tí ń sin ère fínfín ni ojú yóò tì,
    àwọn tí ń fi ère gbéraga,
    ẹ máa sìn ín, gbogbo ẹ̀yin ọlọ́run!

Sioni gbọ́, inú rẹ̀ sì dùn
    inú àwọn ilé Juda sì dùn
    Nítorí ìdájọ́ rẹ, Olúwa
Nítorí pé ìwọ, Olúwa, ni ó ga ju gbogbo ayé lọ
    ìwọ ni ó ga ju gbogbo òrìṣà lọ.
10 Jẹ kí gbogbo àwọn tí ó fẹ́
    Olúwa, kórìíra ibi, ó pa ọkàn àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ mọ́
    ó gbà wọ́n ní ọwọ́ àwọn ènìyàn búburú.
11 Ìmọ́lẹ̀ tàn sórí àwọn olódodo
    àti ayọ̀ nínú àlàyé ọkàn
12 Ẹ yọ̀ nínú Olúwa, ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ olódodo,
    kí ẹ sì yin orúkọ rẹ̀ mímọ́.

Saamu 99-100

99 Olúwa jẹ ọba;
    jẹ́ kí ayé kí ó wárìrì
Ó jókòó lórí ìtẹ́ kérúbù
    jẹ́ kí ayé kí ó wárìrì.
Olúwa tóbi ní Sioni;
    Ó sì ga jù gbogbo orílẹ̀-èdè lọ.
Kí wọ́n sì yin orúkọ rẹ̀ tí ó tóbi
    tí ó ni ẹ̀rù, Mímọ́ ni òun.

Ọba ní agbára, ó sì fẹ́ òdodo,
    ìwọ fi ìdí àìṣègbè múlẹ̀;
    ìwọ ṣe ohun tí ó tọ́ àti ohun tí ó yẹ nínú Jakọbu.
Gbígbéga ni Olúwa Ọlọ́run wa
    ẹ foríbalẹ̀ níbi ẹsẹ̀ rẹ̀; ó jẹ́ mímọ́.

Mose àti Aaroni wà nínú àwọn àlùfáà rẹ̀
    Samuẹli wà nínú àwọn tí ó ń ké pe orúkọ rẹ̀
    wọ́n ké pe Olúwa, ó sì dá wọn lóhùn.
Ó sọ̀rọ̀ sí wọn nínú ọ̀wọ́n àwọsánmọ̀,
    wọ́n pa ẹ̀rí rẹ̀ mọ́ àti ìlànà tí ó fún wọn.

Olúwa Ọlọ́run wa, ó dá wọn lóhùn;
    ó jẹ́ Ọlọ́run tí ó ń dáríjì àwọn ọmọ Israẹli
    ìwọ tí ó ń fi ìyà àìṣedéédéé wọn jẹ wọ́n
Gbígbéga ni Olúwa Ọlọ́run wa
    kí a sìn ín ní òkè mímọ́ rẹ̀
    nítorí Olúwa Ọlọ́run wa jẹ́ mímọ́.

Saamu. Fún ọpẹ́

100 Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Olúwa, gbogbo ayé
Ẹ fi ayọ̀ sin Olúwa:
    Ẹ wá síwájú rẹ̀ pẹ̀lú orin dídùn
Olúwa Ọlọ́run ni ó dá wa,
    kí ẹ̀yin kí ó mọ̀ pé
tirẹ̀ ni àwa; Àwa ní ènìyàn rẹ̀
    àti àgùntàn pápá rẹ̀.

Ẹ lọ sí ẹnu-ọ̀nà rẹ̀ pẹ̀lú ọpẹ́
    àti sí àgbàlá rẹ̀ pẹ̀lú ìyìn;
    ẹ fi ọpẹ́ àti ìyìn fún orúkọ rẹ̀.
Nítorí tí Olúwa pọ̀ ní oore
    ìfẹ́ rẹ̀ sì wà títí láé;
    àti òtítọ́ rẹ̀ láti ìran de ìran.

Saamu 94-95

94 Olúwa Ọlọ́run ẹni tí ń gbẹ̀san,
    Ọlọ́run ẹni tí ń gbẹ̀san.
Gbé ara rẹ sókè, ìwọ onídàájọ́ ayé;
    san ẹ̀san fún agbéraga
    ohun tí ó yẹ wọ́n.
Báwo ní yóò ti pẹ́ tó,
    Olúwa
tí àwọn ẹni búburú
    yóò kọ orin ayọ̀?

Wọ́n ń sọ̀rọ̀ ìgbéraga jáde;
    gbogbo àwọn olùṣe búburú
kún fún ìṣògo.
Wọ́n fọ́ àwọn ènìyàn rẹ túútúú, Olúwa:
    wọ́n pọ́n ilẹ̀ ìní rẹ̀ lójú.
Wọ́n pa àwọn opó àti àlejò,
    wọ́n sì pa àwọn ọmọ aláìní baba,
Wọ́n sọ pé, “Olúwa kò rí i;
    Ọlọ́run Jakọbu kò sì kíyèsi i.”

Kíyèsi i, ẹ̀yin aláìlóye nínú àwọn ènìyàn
    ẹ̀yin aṣiwèrè, nígbà wo ni ẹ̀yin yóò lóye?
Ẹni tí ó gbin etí, ó lè ṣe aláìgbọ́ bí?
    Ẹni tí ó dá ojú?
Ó ha lè ṣe aláìríran bí?
10 Ẹni tí ń bá orílẹ̀-èdè wí, ṣé kò lè tọ́ ni ṣọ́nà bí?
    Ẹni tí ń kọ́ ènìyàn ha lè ṣàìní ìmọ̀ bí?
11 (A)Olúwa mọ èrò inú ènìyàn;
    ó mọ̀ pé asán ni wọ́n.

12 Ìbùkún ni fún ènìyàn náà tí
    ìwọ bá wí, Olúwa,
ẹni tí ìwọ kọ́ nínú òfin rẹ;
13 Ìwọ gbà á kúrò nínú ọjọ́ ibi,
    títí a ó fi wa ihò sílẹ̀ fún ẹni búburú.
14 Nítorí Olúwa kò ní kọ àwọn ènìyàn rẹ̀ sílẹ̀;
Òun kò sì ní kọ ilẹ̀ ìní rẹ̀ sílẹ̀.
15 Ìdájọ́ yóò padà sí òdodo,
    àti gbogbo àwọn ọlọ́kàn
    dídúró ṣinṣin yóò tẹ̀lé e lẹ́yìn.

16 Ta ni yóò dìde fún mi
    sí àwọn olùṣe búburú?
    Tàbí ta ni yóò dìde sí àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ fún mi?
17 Bí kò ṣe pé Olúwa fún mi ní ìrànlọ́wọ́,
    èmi fẹ́rẹ̀ máa gbé ní ilẹ̀ tí ó dákẹ́
18 Nígbà tí mo sọ pé “Ẹsẹ̀ mi ń yọ̀”,
    Olúwa, ìfẹ́ rẹ̀ ni ó tì mí lẹ́yìn.
19 Nígbà tí àníyàn ńlá wà nínú mi,
    ìtùnú rẹ̀ mú ayọ̀ sí ọkàn mi.

20 Ìjọba ìbàjẹ́ ha lè kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú rẹ
    ẹni tí ń fi òfin dì mọ́ ìwà ìkà?
21 Wọ́n kó ara wọn jọ sí olódodo
    wọ́n sì ń dá àwọn aláìṣẹ̀ lẹ́bi sí ikú.
22 Ṣùgbọ́n, Olúwa ti di odi alágbára mi,
    àti Ọlọ́run mi ni àpáta nínú ẹni
    tí mo ti ń gba ààbò.
23 Òun yóò san ẹ̀san ibi wọn fún wọn
    yóò sì pa wọ́n run nítorí búburú wọn
    Olúwa Ọlọ́run wa yóò pa wọ́n run.
95 Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a kọ orin ayọ̀ sí Olúwa
    Ẹ jẹ́ kí a kígbe sókè sí àpáta ìgbàlà wa.
Ẹ jẹ́ kí a wá sí iwájú rẹ̀ pẹ̀lú ọpẹ́
    kí a sì pòkìkí rẹ̀ pẹ̀lú ohun èlò
    orin àti ìyìn.

Nítorí Olúwa Ọlọ́run títóbi ni,
    ọba tí ó tóbi ju gbogbo òrìṣà lọ.
Ní ọwọ́ rẹ̀ ni ọ̀gbun ilẹ̀ wà,
    ṣóńṣó orí òkè tirẹ̀ ní ṣe.
Tirẹ̀ ni Òkun, nítorí òun ni ó dá a
    àti ọwọ́ rẹ̀ ni ó fi dá ìyàngbẹ ilẹ̀.

Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a foríbalẹ̀ kí a sìn ín,
    Ẹ jẹ́ kí a kúnlẹ̀ níwájú
Olúwa ẹni tí ó dá wa;
(B)Nítorí òun ni Ọlọ́run wa
    àwa sì ni ènìyàn pápá rẹ̀,
àti ọ̀wọ́ ẹran ni abẹ́ ìpamọ́ rẹ̀.

    Lónìí tí ìwọ bá gbọ́ ohùn rẹ̀,
“Ẹ má ṣe sé ọkàn yín le gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ṣe ní Meriba,
    àti bí ẹ ti ṣe ní ọjọ́ náà ní Massa ní aginjù,
Nígbà tí àwọn baba yín dán mi wò
    tí wọn wádìí mi,
tí wọn sì rí iṣẹ́ mi
10 Fún ogójì ọdún ni èmi fi bínú sí ìran náà;
    mo wí pé, ‘Wọ́n jẹ́ ènìyàn tí ọkàn wọn ṣáko lọ
    wọn kò sì mọ ọ̀nà mi.’
11 Nítorí náà ni mo kéde ìbúra nínú ìbínú mi
    ‘Wọn kì yóò wọ ibi ìsinmi mi.’ ”

Gẹnẹsisi 49:29-50:14

Ikú Jakọbu

29 Nígbà náà ni ó fún wọn ní àwọn ìlànà yìí, “Ọjọ́ ikú mi kù fẹ́ẹ́rẹ́. Kí ẹ sin mí sí ibojì pẹ̀lú àwọn baba mi ní inú àpáta ní ilẹ̀ Hiti ará Efroni. 30 (A)Ihò àpáta tí ó wà ní ilẹ̀ Makpela, nítòsí Mamre ní Kenaani, èyí tí Abrahamu rà gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìsìnkú lọ́wọ́ Efroni ará Hiti pẹ̀lú ilẹ̀ rẹ̀. 31 (B)Níbẹ̀ ni a sin Abrahamu àti aya rẹ̀ Sara sí, níbẹ̀ ni a sin Isaaki àti Rebeka aya rẹ̀ sí, níbẹ̀ sì ni mo sìnkú Lea sí. 32 Ilẹ̀ náà àti ihò àpáta tí ó wà nínú rẹ̀ ni a rà lọ́wọ́ ará Hiti.”

33 (C)Nígbà tí Jakọbu ti pàṣẹ yìí fún àwọn ọmọ rẹ̀, ó gbé ẹsẹ̀ rẹ̀ sókè sórí ibùsùn, ó sì kú, a sì ko jọ pọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀.

50 Josẹfu sì ṣubú lé baba rẹ̀, ó sọkún, ó sì fẹnukò ó ní ẹnu. Nígbà náà ni Josẹfu pàṣẹ fún àwọn oníṣègùn tí ó wà ní ìkáwọ́ rẹ̀ pé kí wọn kí ó ṣe òkú Israẹli baba rẹ̀ lọ́jọ̀, àwọn oníṣègùn náà sì ṣe bẹ́ẹ̀, Fún ogójì ọjọ́ ni wọ́n fi ṣe èyí, nítorí èyí ni àsìkò tí a máa ń fi ṣe ẹ̀ǹbáàmù òkú. Àwọn ará Ejibiti sì ṣọ̀fọ̀ rẹ̀ fún àádọ́rin ọjọ́.

Nígbà tí ọjọ́ ìṣọ̀fọ̀ náà kọjá. Josẹfu wí fún àwọn ará ilé Farao pé, “Bí mo bá bá ojúrere yín pàdé, ẹ bá mi sọ fún Farao. (D)‘Baba mi mú mi búra ó sì wí fún mi pé, “Mo ti fẹ́rẹ kú: sinmi sínú ibojì tí mo gbẹ́ fún ara mi ní ilẹ̀ Kenaani.” Nísinsin yìí, jẹ́ kí n lọ kí n sì sìnkú baba mi, lẹ́yìn náà èmi yóò padà wa.’ ”

Farao wí pé, “Gòkè lọ, kí o sì sin baba rẹ, bí ó tí mú ọ búra.”

Báyìí ni Josẹfu gòkè lọ láti sìnkú baba rẹ̀. Gbogbo àwọn ìjòyè Farao ni ó sìn ín lọ—àwọn àgbàgbà ilé rẹ̀, àti gbogbo àwọn àgbàgbà ilẹ̀ Ejibiti. Yàtọ̀ fún gbogbo àwọn ará ilé Josẹfu àti ti àwọn arákùnrin rẹ̀ àti àwọn tí ó jẹ́ ilé baba rẹ̀, àwọn ọmọ wọn nìkan àti agbo ẹran pẹ̀lú agbo màlúù ni ó sẹ́ kù ní Goṣeni. Kẹ̀kẹ́-ẹṣin àti àwọn ẹlẹ́ṣin pẹ̀lú gòkè lọ. Àìmoye ènìyàn ni ó lọ.

10 Nígbà tí wọ́n dé ilẹ̀ ìpakà Atadi, ní ẹ̀bá Jordani, wọn pohùnréré ẹkún; Níbẹ̀ ni Josẹfu sì tún dúró ṣọ̀fọ̀ baba rẹ̀ fún ọjọ́ méje. 11 Nígbà tí àwọn ará Kenaani tí ń gbé níbẹ̀ rí i bí wọ́n ti ń ṣọ̀fọ̀ náà ni ilẹ̀ ìpakà Atadi, wọ́n wí pé, “Ọ̀fọ̀ ńlá ni àwọn ará Ejibiti ń ṣe yìí.” Ìdí èyí ni a fi ń pe ibẹ̀ ní Abeli-Misraimu (Ìṣọ̀fọ̀ àwọn ará Ejibiti). Kò sì jìnnà sí Jordani.

12 Báyìí ni àwọn ọmọ Jakọbu ṣe ohun tí baba wọn pàṣẹ fún wọn. 13 (E)Wọ́n gbé e lọ sí ilẹ̀ Kenaani, wọ́n sì sin ín sínú ihò àpáta tí ó wà ní oko Makpela, ní tòsí i Mamre tí Abrahamu rà gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìsìnkú lọ́wọ́ Efroni ará Hiti, pẹ̀lú ilẹ̀ náà. 14 Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti sìnkú baba rẹ̀ tan, Josẹfu padà sí Ejibiti pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀ àti àwọn mìíràn tí ó tẹ̀lé e lọ láti sin baba rẹ̀.

1 Kọrinti 11:17-34

Oúnjẹ alẹ́ Olúwa

17 Nínú àwọn àlàkalẹ̀ èmi ko ni yìn yín nítorí pé bí ẹ bá péjọ kì í ṣe fún rere bí ko ṣe fún búburú. 18 (A)Lọ́nà kìn-ín-ní, mo gbọ́ pe ìyapa máa ń wà láàrín yín ní ìgbà tí ẹ bá péjọpọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìjọ, mo sì gba èyí gbọ́ dé ààyè ibìkan. 19 Kò sí àní àní, ìyàtọ̀ gbọdọ̀ wa láàrín yín, kí àwọn tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run láàrín yín le farahàn kedere. 20 Nígbà tí ẹ bá pàdé láti jẹun, kì í ṣe oúnjẹ alẹ́ Olúwa ni ẹ máa ń jẹ. 21 Ṣùgbọ́n tí ara yín, nígbà tí ẹ bá fẹ́ jẹun, olúkúlùkù yín a máa sáré jẹ oúnjẹ rẹ̀ láìdúró de ẹnìkejì rẹ̀. Ebi a sì máa pa wọ́n, ẹlòmíràn wọ́n sì ń mu àmuyó àti àmupara. 22 Ṣé ẹ̀yin kò ní ilé tí ẹ ti lè jẹ, tí ẹ sì ti lè mu ni? Tàbí ẹ̀yin ń gan ìjọ Ọlọ́run ni? Ẹ̀yin sì ń dójútì àwọn aláìní? Kín ni kí èmi ó wí fún un yín? Èmi yóò ha yìn yín nítorí èyí? A! Rárá o. Èmi kọ́, n kò ní yìn yín.

23 Nítorí èyí tí èmi gbà lọ́wọ́ Olúwa ni mo ti fi fún un yin. Ní alẹ́ ọjọ́ tí Judasi fihàn, Olúwa Jesu Kristi mú àkàrà. 24 Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún àkàrà náà tan, ó bù ú, ó fi fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó sì wí pé, “Ẹ gbà kí ẹ sì jẹ, èyí ní ara mi tí a fi fún un yín. Ẹ máa ṣe eléyìí ni rántí mi.” 25 (B)Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ lẹ́yìn oúnjẹ alẹ́, ó sì mú ago wáìnì, ó sì wí pé, “Ago yìí ni májẹ̀mú tuntun nínú ẹ̀jẹ̀ mi, ẹ máa ṣe èyí, nígbàkígbà ti ẹ̀yìn bá ń mu ú, ní ìrántí mi.” 26 (C)Nítorí nígbàkúgbà tí ẹ bá ń jẹ lára àkàrà yìí, tí ẹ sì ǹ mu nínú ago yìí, ni ẹ tún sọ nípa ikú Olúwa. Ẹ máa ṣe eléyìí títí yóò fi padà dé.

27 Nítorí náà tí ẹnikẹ́ni bá jẹ lára àkàrà yìí, tí ẹ sì ń mu nínú ago Olúwa yìí, ní ọ̀nà tí kò bójúmu, yóò jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ sí ara àti ẹ̀jẹ̀ Olúwa. 28 Ìdí nìyìí tí ó fi yẹ kí ènìyàn yẹ ara rẹ̀ wò dáradára kí ó tó jẹ lára àkàrà nà án àti kí ó tó mu nínú ago náà. 29 Nítorí tí ẹ bá jẹ lára àkàrà, tí ẹ sì mu nínú ago láìyẹ, tí ẹ kò ronú ara Kristi àti nǹkan tí ó túmọ̀ sí, ẹ̀ ń jẹ, ẹ sì ń mú ẹ̀bi ìdájọ́ Ọlọ́run wá sórí ara yín. 30 Ìdí nìyìí tí ọ̀pọ̀ yín fi di ẹni tí kò lágbára mọ́, tí ọ̀pọ̀ yín sì ń ṣàìsàn, àwọn mìíràn nínú yín tilẹ̀ ti sùn. 31 Ṣùgbọ́n tí ẹ bá yẹ ara yín wò dáradára, kí ẹ tó jẹ ẹ́, a kì yóò dá yín lẹ́jọ́. 32 (D)Ṣùgbọ́n nígbà tí a bá dá wa lẹ́jọ́, láti ọwọ́ Olúwa ni a ti nà wá, kí a má ba à dá wa lẹ́bi pẹ̀lú ayé.

33 Nítorí náà, ẹ̀yin arákùnrin mi ọ̀wọ́n, nígbàkúgbà ti ẹ bá péjọ láti jẹ́ oúnjẹ alẹ́ Olúwa, tàbí fún ìsìn oúnjẹ alẹ́ Olúwa, ẹ dúró de ara yín. 34 (E)Bí ebi bá ń pa ẹnikẹ́ni nínú yin, kí ó jẹun láti ilé wá, kí ó má ba á mú ìjìyà wá sórí ara rẹ̀ nígbà tí ẹ bá péjọ.

Tí mo bá dé, èmi yóò máa sọ̀rọ̀ lórí àwọn kókó-ọ̀rọ̀ ìyókù tí n kò ì ti fẹnu bà lẹ́sẹẹsẹ.

Marku 8:1-10

Jesu bọ́ ẹgbàajì ènìyàn

(A)Ní ọjọ́ kan, bí ọ̀pọ̀ ènìyàn ti péjọ, kò sí oúnjẹ fún wọn mọ́ láti jẹ. Jesu pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Ó wí fún wọn pé, “Àánú ọ̀pọ̀ ènìyàn wọ̀nyí ṣe mí nítorí pé ó tó ọjọ́ mẹ́ta tí wọ́n ti wà níhìn-ín, kò sì sí ohun kan tí ó kù sílẹ̀ fún wọn láti jẹ. Bí mo bá sọ fún wọn láti máa lọ sí ilé wọn bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ebi, wọn yóò dákú lójú ọ̀nà, nítorí pé àwọn mìíràn nínú wọn ti ọ̀nà jíjìn wá.”

Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ béèrè pé, “Níbo ni a ó ti rí àkàrà tí ó tó láti fi bọ́ wọn nínú aṣálẹ̀ yìí?”

Jesu béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “ìṣù àkàrà mélòó lẹ ní lọ́wọ́?”

Wọ́n fèsì pé, “ìṣù àkàrà méje.”

Nítorí náà, ó pàṣẹ fún àwọn ènìyàn náà láti jókòó lórí ilẹ̀. Ó sì mú odindi àkàrà méje náà, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, ó sì bù wọ́n sí wẹ́wẹ́, ó pín wọn fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ láti gbé ka iwájú àwọn ènìyàn, wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀. Wọ́n rí àwọn ẹja wẹ́wẹ́ díẹ̀ pẹ̀lú. Jesu tún dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún ìpèsè náà, ó sì pàṣẹ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ láti pín wọn fún àwọn ènìyàn náà. Gbogbo ọ̀pọ̀ ènìyàn náà ló jẹ àjẹyó àti àjẹtẹ́rùn. Lẹ́yìn èyí wọ́n kó àjẹkù ti ó kù jọ, agbọ̀n méje sì kún. Àwọn tí ó jẹ ẹ́ tó ìwọ̀n ẹgbàajì (4,000) ènìyàn, ó sì rán wọn lọ. 10 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, lẹ́yìn èyí, Jesu wọ inú ọkọ̀ ojú omi pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, wọ́n sì gúnlẹ̀ sí agbègbè Dalmanuta.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.