Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 61-62

Fún adarí orin. Ohun èlò orin olókùn. Ti Dafidi.

61 Gbọ́ ẹkún mi, Ọlọ́run;
    Tẹ́tí sí àdúrà mi.

Láti òpin ayé wá ni èmi yóò pè ọ́,
    mo pè nígbà àyà mi ń ṣàárẹ̀;
    mú mi lọ sí ibi àpáta tí ó ga jù mí lọ.
Nítorí ìwọ ti jẹ́ ibi ààbò mi,
    ilé ìṣọ́ agbára àwọn ọ̀tá.

Mo ń lépa láti máa gbé nínú àgọ́ rẹ títí láé
    kí n sì rí ààbò níbi ìyẹ́ apá rẹ.
Nítorí ìwọ ti gbọ́ àwọn ẹ̀jẹ́ mi, Ọlọ́run;
    Ìwọ ti fún mi ní ogún àwọn tí ó bẹ̀rù orúkọ rẹ.

Jẹ́ kí ẹ̀mí ọba kí ó gùn,
    ọdún rẹ̀ fún ìrandíran.
Kí ó máa jẹ ọba níwájú Ọlọ́run títí láé;
    pèsè àánú àti òtítọ́ rẹ tí yóò máa ṣe ìtọ́jú rẹ.

Nígbà náà ni èmi ó máa kọrin ìyìn sí orúkọ rẹ títí láé
    kí n san ẹ̀jẹ́ mi ní ojoojúmọ́.

Fún adarí orin. Fun Jedutuni. Saamu Dafidi.

62 Nínú Ọlọ́run nìkan ni ọkàn mi ti rí ìsinmi;
    ìgbàlà mi ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá.
Òun nìkan ní àpáta mi àti ìgbàlà mi;
    Òun ni ààbò mi, a kì yóò sí mi ní ipò padà.

Ẹ̀yin ó ti máa kọ́lú ènìyàn kan pẹ́ tó?
    Gbogbo yín ni ó fẹ́ pa á,
    bí ògiri tí ó fẹ́ yẹ̀, àti bí ọgbà tí ń wó lọ?
Kìkì èrò wọn ni láti bì ṣubú
    kúrò nínú ọlá rẹ̀;
    inú wọn dùn sí irọ́.
Wọ́n ń fi ẹnu wọn súre,
    ṣùgbọ́n wọ́n ń gégùn ún nínú ọkàn wọn. Sela.

Nínú Ọlọ́run nìkan ni ìsinmi wà, ìwọ Ọlọ́run mi.
    Ìrètí mi wá láti ọ̀dọ̀ rẹ.
Òun nìkan ní àpáta àti ìgbàlà mi;
    Òun ni ààbò mi, a kì yóò ṣí mi ní ipò.
Ìgbàlà mi àti ògo mi dúró nínú Ọlọ́run;
    Òun ní àpáta ńlá mi, àti ààbò mi.
Gbẹ́kẹ̀lé ní gbogbo ìgbà, ẹ̀yin ènìyàn;
    tú ọkàn rẹ jáde sí i,
nítorí Ọlọ́run ni ààbò wa.

Nítòótọ́, asán ni àwọn ọmọ ènìyàn, èké
    sì ni àwọn olóyè, wọ́n gòkè nínú ìwọ̀n,
    lápapọ̀ wọ́n jẹ́ èémí.
10 Má ṣe gbẹ́kẹ̀lé ìnilára,
    tàbí gbéraga nínú olè jíjà,
nítòótọ́ bí ọrọ̀ rẹ̀ ń pọ̀ sí i,
    má ṣe gbẹ́kẹ̀ rẹ lé wọn.

11 Ọlọ́run ti sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kejì, ni mo
    gbọ́ èyí pé, ti Ọlọ́run ni agbára
12 (A)Pẹ̀lúpẹ̀lú, Olúwa, tìrẹ ni àánú
    nítorí tí ìwọ san án fún olúkúlùkù ènìyàn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀.

Saamu 112

112 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run,
    tí ó ní inú dídùn ńlá sí àwọn òfin rẹ̀.

Irú-ọmọ rẹ̀ yóò jẹ́ alágbára ní ayé:
    ìran àwọn olóòtítọ́ ni a ó bùkún fún.
Ọlá àti ọrọ̀ yóò wà nínú ilé rẹ̀;
    òdodo rẹ̀ sì dúró láé.
Fún olóòótọ́ ni ìmọ́lẹ̀ yóò tàn fún ní òkùnkùn:
    olóore-ọ̀fẹ́ àti aláàánú àti òdodo.
Ènìyàn rere fi ojúrere hàn,
    a sì wínni;
    ìmòye ni yóò máa fi la ọ̀nà iṣẹ́ rẹ̀.

Dájúdájú a kì yóò le yí ní ipò padà láéláé:
    olódodo ni a ó máa ṣe ìrántí rẹ láéláé.
Òun kì yóò béèrè ìyìn búburú:
    ọkàn rẹ̀ ti dúró, ó ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa.
Ó ti mú ọkàn rẹ̀ gbilẹ̀, ẹ̀rù kí yóò bà á,
    títí yóò fi rí ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ lórí àwọn ọ̀tá rẹ̀.
(A)Ó ti pín ká, ó ti fi fún àwọn olùpọ́njú;
    Nítorí òdodo rẹ̀ dúró láé;
    ìwo rẹ̀ ní a ó gbé sókè pẹ̀lú ọlá.

10 Ènìyàn búburú yóò ri, inú wọn yóò sì bàjẹ́,
    yóò sì pa eyín keke, yó sì yọ dànù:
    èròǹgbà ọkàn ènìyàn búburú ni yóò ṣègbé.

Saamu 115

115 Kì í ṣe fún wa, Olúwa kì í ṣe fún wa,
    ṣùgbọ́n fún orúkọ rẹ ni a fi ògo fún,
    fún àánú àti òtítọ́ rẹ.

Torí kí ni àwọn kèfèrí yóò ṣe sọ pé,
    níbo ni Ọlọ́run wa wà.
Ṣùgbọ́n Ọlọ́run wa wà lọ́run:
    tí ó ń ṣe èyí tí ó wù ú.
(A)Fàdákà òun wúrà ni èrè àwọn aláìkọlà,
    iṣẹ́ ọwọ́ ènìyàn ni,
Wọ́n ní ẹnu, ṣùgbọ́n wọn kò le sọ̀rọ̀,
    wọ́n ní ojú, ṣùgbọ́n wọn kò fi ríran.
Wọ́n ní etí, ṣùgbọ́n wọn kò fi gbọ́rọ̀:
    wọ́n ní imú, ṣùgbọ́n wọn kò fi gbóòórùn
Wọ́n ní ọwọ́, ṣùgbọ́n wọn kò lò ó,
    wọ́n ní ẹsẹ̀, ṣùgbọ́n wọn kò rìn;
    bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sọ̀rọ̀ nínú òfin wọn.
Àwọn tí ń ṣe wọ́n dàbí wọn;
    gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni olúkúlùkù ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé wọn.

Ìwọ Israẹli gbẹ́kẹ̀lé Olúwa:
    òun ni ìrànwọ́ àti ààbò wọn
10 Ẹ̀ yin ilé Aaroni, gbẹ́kẹ̀lé Olúwa:
    òun ni ìrànwọ́ àti ààbò wọn
11 Ẹ̀ yin tí ó bẹ̀rù Olúwa, gbẹ́kẹ̀lé Olúwa:
    òun ní ìrànwọ́ àti ààbò wọn.

12 Olúwa tí ń ṣe ìrántí wa; yóò bùkún ilé Israẹli;
    yóò bùkún ilé Aaroni.
13 (B)Ìbùkún ni fún àwọn tí ó bẹ̀rù Olúwa,
    àti kékeré àti ńlá.

14 Olúwa yóò mú ọ pọ̀ sí i síwájú àti síwájú,
    ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ̀.
15 Ẹ fi ìbùkún fún Olúwa
    ẹni tí ó dá ọ̀run òun ayé.

16 Ọ̀run àní ọ̀run ni ti Olúwa:
    ṣùgbọ́n ayé ló fi fún ọmọ ènìyàn.
17 Òkú kò lè yìn Olúwa,
    tàbí ẹni tí ó ti lọ sí ìsàlẹ̀ ìdákẹ́ jẹ́ẹ́.
18 Ṣùgbọ́n àwa ó fi ìbùkún fún Olúwa
    láti ìsinsin yìí lọ àti títí láéláé.

Ẹ yin Olúwa.

Sefaniah 3:14-20

14 Kọrin, ìwọ ọmọbìnrin Sioni,
    kígbe sókè, ìwọ Israẹli!
Fi gbogbo ọkàn yọ̀, kí inú rẹ kí ó sì dùn,
    ìwọ ọmọbìnrin Jerusalẹmu.
15 Olúwa ti mú ìdájọ́ rẹ wọ̀n-ọn-nì
    kúrò, ó sì ti ti àwọn ọ̀tá rẹ padà sẹ́yìn.
Olúwa, ọba Israẹli wà pẹ̀lú rẹ,
    Ìwọ kì yóò sì bẹ̀rù ibi kan mọ́.
16 Ní ọjọ́ náà, wọn yóò sọ fún Jerusalẹmu pé,
    “Má ṣe bẹ̀rù Sioni;
    má sì ṣe jẹ́ kí ọwọ́ rẹ kí ó dẹ̀.
17 Olúwa Ọlọ́run rẹ wà pẹ̀lú rẹ,
    Ó ní agbára láti gbà ọ là.
Yóò yọ̀ ni orí rẹ fún ayọ̀;
    Yóò tún ọ ṣe nínú ìfẹ́ rẹ̀,
    Yóò sì fi orin yọ̀ ní orí rẹ.”

18 “Èmi ó kó àwọn tí ó ń banújẹ́ fún àjọ̀dún tí a yàn jọ,
    àwọn tí ó jẹ́ tirẹ̀;
    àwọn tí ẹ̀gàn rẹ̀ jásí ẹ̀rù.
19 Ní àkókò náà
    ni èmi yóò dojúkọ àwọn
tí ń ni yín lára,
    èmi yóò gba àtiro là,
èmi yóò sì ṣa àwọn tí ó ti fọ́nká jọ,
    èmi yóò fi ìyìn àti ọlá fún wọn ní
    gbogbo ilẹ̀ tí a bá ti dójútì wọ́n.
20 Ní àkókò náà ni èmi yóò ṣà yín jọ;
    Nígbà náà ni èmi yóò mú un yín padà wá sílé.
Èmi yóò fi ọlá àti ìyìn fún un yín
    láàrín gbogbo ènìyàn àgbáyé,
nígbà tí èmi yóò yí ìgbèkùn yín
    padà bọ sípò ní ojú ara yín,”
    ni Olúwa wí.

Titu 1

Paulu, ìránṣẹ́ Ọlọ́run àti aposteli Jesu Kristi, gẹ́gẹ́ bí ìgbàgbọ́ àwọn àyànfẹ́ Ọlọ́run àti ìmọ̀ òtítọ́ irú èyí tí í máa darí ènìyàn sí ìgbé ayé ìwà-bí-Ọlọ́run— ìgbàgbọ́ àti ìmọ̀ tí ó dúró lórí ìrètí iyè àìnípẹ̀kun, èyí tí Ọlọ́run tí kì í purọ́ ti ṣe ìlérí rẹ̀ ṣáájú kí ayé tó bẹ̀rẹ̀, àti pé ní àkókò tirẹ̀, òun ti fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ hàn nínú ìwàásù tí a fi lé mi lọ́wọ́ nípa àṣẹ Ọlọ́run Olùgbàlà wa.

(A)Sí Titu, ọmọ mi tòótọ́ nínú ìgbàgbọ́ wa kan náà.

Oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run baba àti Kristi Jesu Olùgbàlà wa.

Iṣẹ́ Titu sí Krete

Ìdí tí mo fi fi ọ́ sílẹ̀ ní Krete ni pé kí o lè ṣe àṣepé àwọn iṣẹ́ tó ṣẹ́kù. Mo sì ń rọ̀ ọ́ kí o yan àwọn alàgbà ní ìlú kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí mo ṣe darí rẹ̀. Ẹni tí yóò jẹ́ alàgbà gbọdọ̀ jẹ́ aláìlábùkù, wọ́n gbọdọ̀ jẹ́ onìyàwó kan, ọmọ wọn náà gbọdọ̀ jẹ́ onígbàgbọ́ tí kò ní ẹ̀sùn ìwà ipá tàbí ẹ̀sùn àìgbọ́ràn kankan. Alábojútó jẹ́ ẹni tí a gbé iṣẹ́ Ọlọ́run lé lọ́wọ́, nítorí náà, kò gbọdọ̀ ní àbùkù kankan tàbí agbéraga, oníjà, kò gbọdọ̀ jẹ́ ọ̀mùtí tàbí alágídí tàbí olójúkòkòrò. Wọ́n ní láti jẹ́ olùfẹ́ àlejò ṣíṣe, olùfẹ́ ohun tí ó dára. Wọ́n ní láti jẹ́ ẹni tí ó kò ara rẹ̀ ní ìjánu, ẹni dúró ṣinṣin, ọlọ́kàn mímọ́, àti ẹni oníwàtítọ́. Ó gbọdọ̀ di ẹ̀kọ́ nípa ìdúró ṣinṣin mú dáradára gẹ́gẹ́ bí ó ti kọ́ ọ, kí ó lè fi ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro kọ́ àwọn ẹlòmíràn. Nípa èyí, yóò lè fi ìdí òtítọ́ múlẹ̀ fún àwọn alátakò.

10 Nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni ọlọ̀tẹ̀, asọ̀rọ̀ asán àti ẹlẹ́tàn pàápàá jùlọ láàrín àwọn onílà. 11 Ó gbọdọ̀ pa wọ́n lẹ́nu mọ́, nítorí wí pé wọ́n ń pa agbo Ọlọ́run run, nípasẹ̀ àwọn ẹ̀kọ́ tí kò jẹ́ èyí tí wọ́n ń kọ́ni. Èyí ni wọ́n ń ṣe fún ère àìṣòdodo. 12 Ọ̀kan nínú àwọn wòlíì wọn pàápàá sọ wí pé. “Òpùrọ́ ní àwọn ará Krete, wọ́n jẹ́ ẹranko búburú tí kò sé tù lójú, ọ̀lẹ, àti oníwọra”. 13 Òtítọ́ ni ẹ̀rí yìí. Nítorí náà, bá wọn wí gidigidi, kí wọn ba à lè yè koro nínú ìgbàgbọ́ 14 kí àwọn má ṣe fiyèsí ìtàn lásán ti àwọn Júù, àti òfin àwọn ènìyàn tí wọ́n yípadà kúrò nínú òtítọ́. 15 Sí ọlọ́kàn mímọ́, ohun gbogbo ló jẹ́ mímọ́, ṣùgbọ́n àwọn tó ti díbàjẹ́ tí wọ́n kò sí ka ohunkóhun sí mímọ́. Nítòótọ́, àti ọkàn àti ẹ̀rí ọkàn wọn ló ti díbàjẹ́. 16 Wọ́n ń fẹnu sọ wí pé àwọn mọ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n wọ́n sẹ́ ẹ nípa ìṣe wọn. Wọ́n díbàjẹ́, wọn si jẹ aláìgbọ́ràn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kò wúlò lọ́nàkọnà ní ti iṣẹ́ rere gbogbo.

Luku 1:1-25

Ọ̀pọ̀ ènìyàn ni ó ti dáwọ́lé títo àwọn nǹkan wọ̀n-ọn-nì jọ lẹ́sẹẹsẹ, èyí tí ó ti múlẹ̀ ṣinṣin láàrín wa, (A)àní gẹ́gẹ́ bí àwọn ìránṣẹ́ ọ̀rọ̀ náà, tí ó ṣe ojú wọn láti ìbẹ̀rẹ̀ ti fi lé wa lọ́wọ́. (B)Nítorí náà, ó sì yẹ fún èmi pẹ̀lú, láti kọ̀wé sí ọ lẹ́sẹẹsẹ bí mo ti wádìí ohun gbogbo fínní fínní sí láti ìpilẹ̀ṣẹ̀, Teofilu ọlọ́lá jùlọ, (C)kí ìwọ kí ó le mọ òtítọ́ ohun wọ̀n-ọn-nì, tí a ti kọ́ ọ.

Àsọtẹ́lẹ̀ nípa ibí Johanu onítẹ̀bọmi

(D)Nígbà ọjọ́ Herodu ọba Judea, àlùfáà kan wà, láti ìran Abijah, orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Sekariah: aya rẹ̀ sì ṣe ọ̀kan nínú àwọn ọmọbìnrin Aaroni, orúkọ rẹ̀ a sì máa jẹ́ Elisabeti. Àwọn méjèèjì sì ṣe olódodo níwájú Ọlọ́run, wọ́n ń rìn ní gbogbo òfin àti ìlànà Olúwa ní àìlẹ́gàn. Ṣùgbọ́n wọn kò ní ọmọ, nítorí tí Elisabeti yàgàn; àwọn méjèèjì sì di arúgbó.

Ó sì ṣe, nígbà tí ó ń ṣe iṣẹ́ àlùfáà níwájú Ọlọ́run ni àkókò tirẹ̀ (E)Bí ìṣe àwọn àlùfáà, ipa tirẹ̀ ni láti máa fi tùràrí jóná, nígbà tí ó bá wọ inú tẹmpili Olúwa lọ. 10 Gbogbo ìjọ àwọn ènìyàn sì ń gbàdúrà lóde ní àkókò sísun tùràrí.

11 (F)Angẹli Olúwa kan sì fi ara hàn án, ó dúró ní apá ọ̀tún pẹpẹ tùràrí. 12 Nígbà tí Sekariah sì rí i, orí rẹ̀ wú, ẹ̀rù sì bà á. 13 (G)Ṣùgbọ́n angẹli náà wí fún un pé, “Má bẹ̀rù, Sekariah: nítorí tí àdúrà rẹ gbà; Elisabeti aya rẹ yóò sì bí ọmọkùnrin kan fún ọ, ìwọ ó sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Johanu. 14 Òun yóò sì jẹ́ ayọ̀ àti ìdùnnú fún ọ: ènìyàn púpọ̀ yóò sì yọ̀ sí ìbí rẹ. 15 (H)Nítorí òun ó pọ̀ níwájú Olúwa, kì yóò sì mu ọtí wáìnì, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sì mu ọtí líle; yóò sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́ àní láti inú ìyá rẹ̀ wá. 16 Òun ó sì yí ènìyàn púpọ̀ padà nínú àwọn ọmọ Israẹli sí Olúwa Ọlọ́run wọn. 17 (I)Ẹ̀mí àti agbára Elijah ni Olúwa yóò sì fi ṣáájú rẹ̀ lọ, láti pa ọkàn àwọn baba dà sí ti àwọn ọmọ, àti ti àwọn aláìgbọ́ràn sí ọgbọ́n àwọn olóòtítọ́; kí ó le pèsè àwọn ènìyàn tí a múra sílẹ̀ de Olúwa.”

18 Sekariah sì wí fún angẹli náà pé, “Ààmì wo ni èmi ó fi mọ èyí? Èmi sá ti di àgbà, àti Elisabeti aya mi sì di arúgbó.”

19 (J)Angẹli náà sì dáhùn ó wí fún un pé, “Èmi ni Gabrieli, tí máa ń dúró níwájú Ọlọ́run; èmi ni a rán wá láti sọ fún ọ, àti láti mú ìròyìn ayọ̀ wọ̀nyí fún ọ wá. 20 Sì kíyèsi i, ìwọ ó yadi, ìwọ kì yóò sì le fọhùn, títí ọjọ́ náà tí nǹkan wọ̀nyí yóò fi ṣẹ, nítorí ìwọ kò gba ọ̀rọ̀ mi gbọ́ tí yóò ṣẹ ní àkókò wọn.”

21 Àwọn ènìyàn sì ń dúró de Sekariah, ẹnu sì yà wọ́n nítorí tí ó pẹ́ nínú tẹmpili. 22 Nígbà tí ó sì jáde wá, òun kò le bá wọn sọ̀rọ̀. Wọn sì kíyèsi wí pé ó ti rí ìran nínú tẹmpili, ó sì ń ṣe àpẹẹrẹ sí wọn, nítorí tí ó yadi.

23 Ó sì ṣe, nígbà tí ọjọ́ iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ pé, ó lọ sí ilé rẹ̀. 24 Lẹ́yìn èyí ni Elisabeti aya rẹ̀ lóyún, ó sì fi ara rẹ̀ pamọ́ ní oṣù márùn-ún, 25 Ó sì wí pé “Báyìí ni Olúwa ṣe fún mi ní ọjọ́ tí ó ṣíjú wò mí, láti mú ẹ̀gàn mi kúrò láàrín àwọn ènìyàn.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.