Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 101

Ti Dafidi. Saamu.

101 Èmi yóò kọrin ìfẹ́ àti òdodo;
    sí ọ Olúwa, èmi yóò máa kọrin ìyìn.
Èmi yóò máa rin ìrìn mi pẹ̀lú ọgbọ́n láìlẹ́ṣẹ̀,
    ìgbà wo ni ìwọ yóò wá sí ọ̀dọ̀ mi?

Èmi yóò máa rìn ní ilé mi
    pẹ̀lú àyà pípé.
Èmi kì yóò gbé ohun búburú sí iwájú mi:
    iṣẹ́ àwọn tí ó yapa ni èmi kórìíra.

    Wọn kì yóò rọ̀ mọ́ mi.
Agídí ọkàn yóò kúrò lọ́dọ̀ mi;
    Èmi kì yóò mọ ènìyàn búburú.

Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń sọ̀rọ̀ ẹnìkejì rẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀,
    òun ní èmi yóò gé kúrò
ẹni tí ó bá gbé ojú rẹ̀ ga tí ó sì ní ìgbéraga àyà,
    òun ní èmi kì yóò faradà fún.

Ojú mi yóò wà lára àwọn olóòtítọ́ lórí ilẹ̀,
    kí wọn kí ó lè máa bá mi gbé;
ẹni tí ó bá n rin ọ̀nà pípé
    òun ni yóò máa sìn mí.

Ẹni tí ó bá ń ṣe ẹ̀tàn, kì yóò gbé ilé mi,
    kò sí ẹni tí ń ṣèké tí yóò dúró ní iwájú mi.

Ní ojoojúmọ́ ní èmi yóò wá máa pa a lẹ́nu mọ
    gbogbo àwọn ènìyàn búburú ilẹ̀ náà;
èmi yóò gé àwọn olùṣe búburú
    kúrò ní ìlú Olúwa.

Saamu 109:1-30

Fún adarí orin. Ti Dafidi. Saamu.

109 Ọlọ́run, ti èmi ń fi ìyìn fún
    Má ṣe dákẹ́
Nítorí àwọn ènìyàn búburú àti ẹlẹ́tàn
    ti ya ẹnu wọn sí mi
    wọ́n ti fi ahọ́n èké sọ̀rọ̀ sí mi
Wọ́n fi ọ̀rọ̀ ìríra yí mi káàkiri;
    wọ́n bá mi jà láìnídìí
Nípò ìfẹ́ mi, wọn ń ṣe ọ̀tá mi,
    ṣùgbọ́n èmi ń gba àdúrà.
Wọ́n sì fi ibi san ìre fún mi
    àti ìríra fún ìfẹ́ mi.

Yan àwọn ènìyàn búburú láti dojúkọ
    jẹ́ kí àwọn olùfisùn
    dúró ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀.
Kí a dá a lẹ́bi nígbà tí a bá ṣe ìdájọ́
    kí àdúrà rẹ̀ kí ó lè di ìkọ̀sílẹ̀
(A)Kí ọjọ́ rẹ̀ kí ó kúrú
    kí ẹlòmíràn kí ó rọ́pò iṣẹ́ rẹ̀
Kí àwọn ọmọ rẹ̀ di aláìní baba
    kí aya rẹ̀ sì di opó
10 Jẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ̀ máa ṣagbe kiri
    kí wọn máa tọrọ oúnjẹ jìnnà sí ibi ahoro wọn
11 Jẹ́ kí alọ́nilọ́wọ́gbà kí ó mú ohun gbogbo tí ó ní
    jẹ́ kí àlejò kí o kó èrè iṣẹ́ rẹ̀ lọ
12 Má ṣe jẹ́ kí ẹnìkan ṣe àánú fún un
    tàbí kí wọn káàánú lórí
    àwọn ọmọ rẹ̀ aláìní baba
13 Kí a gé àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ kúrò
    kí orúkọ wọn kí ó parẹ́ ní ìran tí ń bọ̀
14 Kí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba rẹ̀ kí
    ó wà ní ìrántí ní ọ̀dọ̀ Olúwa
    Má ṣe jẹ́ kí a yọ ẹ̀ṣẹ̀ ìyá wọn kúrò
15 Jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ wọn kí ó wà ní ìrántí níwájú Olúwa
    kí ó lè gé ìrántí wọn kúrò lórí ilẹ̀.

16 Nítorí kò rántí láti ṣàánú,
    ṣùgbọ́n ó ṣe inúnibíni sí ọkùnrin tálákà àti olùpọ́njú,
    kí ó lè pa oníròbìnújẹ́ ọkàn.
17 Ó fẹ́ràn láti máa mú ègún wá sí orí rẹ̀:
    bi inú rẹ̀ kò ti dùn si ìre, bẹ́ẹ̀ ni kí ó jìnnà sí.
18 Bí ó ti fi ègún wọ ará rẹ̀ láṣọ bí ẹ̀wù
    bẹ́ẹ̀ ni kí ó wá sí inú rẹ̀ bí omi
19 Jẹ́ kí ó rí fún un bí aṣọ tí a dà bò ó ní
    ara, àti fún àmùrè tí ó fi gba ọ̀já nígbà gbogbo
20 Èyí ni èrè àwọn ọ̀tá mi láti ọwọ́ Olúwa wá;
    àti ti àwọn tí ń sọ̀rọ̀ ibi sí ọkàn mi.

21 Ṣùgbọ́n ìwọ, ìwọ ṣe fún mi Olúwa Olódùmarè,
    ṣe rere fún mi nítorí orúkọ rẹ
    Nítorí tí àánú rẹ dára, ìwọ gbà mí
22 Nítorí pé tálákà àti aláìní ni mí,
    àyà mi sì gbọgbẹ́ nínú mi.
23 Èmi ń kọjá lọ bí òjìji tí àṣálẹ́,
    mo ń gbọ̀n sókè bí eṣú.
24 Eékún mi di aláìlera nítorí àwẹ̀ gbígbà
    ẹran-ara mi sì gbẹ nítorí àìlera mi.
25 (B)Mo dàbí ẹ̀gàn fún àwọn olùfisùn mi;
    nígbà tí wọn wò mí, wọ́n gbọn orí wọn.

26 Ràn mí lọ́wọ́, Olúwa Ọlọ́run mi;
    gbà mí gẹ́gẹ́ bí ìṣeun ìfẹ́ rẹ.
27 Jẹ́ kí wọn mọ̀ pé ọwọ́ rẹ ni èyí
    wí pé ìwọ, Olúwa, ni ó ṣe é.
28 Wọ́n ó máa gégùn ún, ṣùgbọ́n ìwọ máa súre;
    Nígbà tí wọn bá dìde kí ojú kí ó tì wọ́n,
    ṣùgbọ́n ìránṣẹ́ rẹ yóò yọ̀
29 Jẹ́ kí a wọ àwọn ọ̀tá mi ní aṣọ ìtìjú
    kí á sì fi ìdàrúdàpọ̀ bọ̀ wọ́n lára bí ẹ̀wù.

30 Pẹ̀lú ẹnu mi èmi yóò máa yin Olúwa gidigidi
    ní àárín ọ̀pọ̀ ènìyàn èmi yóò máa yìn ín

Saamu 119:121-144

Olórin pa òfin Olúwa mọ́

121 Èmi ti ṣe ohun tí i ṣe òdodo àti ẹ̀tọ́:
    má ṣe fi mí sílẹ̀ fún àwọn tó ń ni mí lára.
122 Mú kí àlàáfíà ìránṣẹ́ rẹ dájú:
    má ṣe jẹ́ kí àwọn agbéraga ni mi lára.
123 Ojú mi kùnà, fún wíwo ìgbàlà rẹ,
    fún wíwo ìpinnu òdodo rẹ.
124 Ṣe pẹ̀lú ìránṣẹ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí dídúró ṣinṣin ìfẹ́ rẹ
    kí o sì kọ́ mi ní àṣẹ rẹ.
125 Èmi ni ìránṣẹ́ rẹ; ẹ fún mi ní òye
    kí èmi lè ní òye òfin rẹ
126 Ó tó àsìkò fún ọ láti ṣe iṣẹ́, Olúwa;
    nítorí òfin rẹ ti fọ́.
127 Nítorí èmi fẹ́ràn àṣẹ rẹ
    ju wúrà, àní ju wúrà dídára lọ,
128 Nítorí èmi kíyèsi gbogbo ẹ̀kọ́ òtítọ́ rẹ̀,
    èmi kórìíra gbogbo ipa ọ̀nà búburú.

Àdúrà láti lè pa òfin Olúwa mọ́

129 Òfin rẹ̀ ìyanu ni:
    nítorí náà èmi gbà wọ́n gbọ́.
130 Ìṣípayá ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú ìmọ́lẹ̀ wá;
    ó fi òye fún àwọn òpè.
131 Èmi ya ẹnu mi mo sì mí hẹlẹ,
    nítorí èmi fojú ṣọ́nà sí àṣẹ rẹ.
132 Yí padà sí mi kí o sì ṣàánú fún mi,
    bí ìwọ ṣe máa ń ṣe nígbà gbogbo sí àwọn
    tí ó fẹ́ràn orúkọ rẹ.
133 Fi ìṣísẹ̀ mi múlẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ rẹ,
    má ṣe jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ borí mi.
134 Rà mí padà lọ́wọ́ aninilára ènìyàn,
    kí èmi lè gbọ́ ẹ̀kọ́ rẹ.
135 Jẹ́ kí ojú rẹ kí ó tàn sí ìránṣẹ́ rẹ lára
    kí ó sì kọ́ mi ní àṣẹ rẹ.
136 Omijé sàn jáde ní ojú mi,
    nítorí wọn kò gba pé òfin rẹ̀ jẹ́ òtítọ́.
137 Olódodo ni ìwọ Olúwa
    ìdájọ́ rẹ sì dúró ṣinṣin
138 Òfin ti ìwọ gbé kalẹ̀ jẹ́ òdodo:
    wọ́n yẹ ni ìgbẹ́kẹ̀lé.
139 Ìtara mi ti pa mí run,
    nítorí àwọn ọ̀tá mi fi ojú fo ọ̀rọ̀ rẹ dá.
140 Wọ́n ti dán ìpinnu rẹ wò pátápátá
    ìránṣẹ́ rẹ sì fẹ́ràn wọ́n.
141 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ àti ẹni ẹ̀gàn
    èmi kò ni gbàgbé ẹ̀kọ́ rẹ.
142 Òdodo rẹ wà títí láé
    òtítọ́ ni òfin rẹ̀.
143 Ìyọnu àti ìpọ́njú wá sórí mi,
    ṣùgbọ́n àṣẹ rẹ ni inú dídùn mi,
144 Òfin rẹ jẹ́ òtítọ́ láé;
    fún mi ní òye kí èmi lè yè.

Error: Book name not found: 1Macc for the version: Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
Ìfihàn 21:9-21

Ọ̀kan nínú àwọn angẹli méje, tí wọ́n ni ago méje, tí ó kún fún ìyọnu méje ìkẹyìn sì wá, ó sì ba mi sọ̀rọ̀ wí pé, “Wá níhìn-ín, èmi ó fi ìyàwó, aya Ọ̀dọ́-àgùntàn hàn ọ́.” 10 (A)Ó sì mu mi lọ nínú Ẹ̀mí si òkè ńlá kan tí o sì ga, ó sì fi ìlú náà hàn mi, Jerusalẹmu mímọ́, tí ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, 11 Tí ó ní ògo Ọlọ́run: ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ sì dàbí òkúta iyebíye gidigidi, àní bí òkúta Jasperi, ó mọ́ bí Kirisitali; 12 (B)Ó sì ní odi ńlá àti gíga, ó sì ni ẹnu ibodè méjìlá, àti ní àwọn ẹnu ibodè náà angẹli méjìlá àti orúkọ tí a kọ sára wọn tí i ṣe orúkọ àwọn ẹ̀yà méjìlá tí àwọn ọmọ Israẹli; 13 Ní ìhà ìlà-oòrùn ẹnu ibodè mẹ́ta; ní ìhà àríwá ẹnu ibodè mẹ́ta; ní ìhà gúúsù ẹnu ibodè mẹ́ta; àti ní ìhà ìwọ̀-oòrùn ẹnu ibodè mẹ́ta. 14 Odi ìlú náà sì ni ìpìlẹ̀ méjìlá, àti lórí wọn orúkọ àwọn Aposteli méjìlá tí Ọ̀dọ́-Àgùntàn.

15 (C)Ẹni tí o sì ń bá mi sọ̀rọ̀ ní ọ̀pá-ìwọ̀n wúrà kan láti fi wọn ìlú náà àti àwọn ẹnu ibodè rẹ̀, àti odi rẹ̀. 16 Ìlú náà sì wà ní ibú mẹ́rin lọ́gbọọgba, gígùn rẹ̀ àti ìbú rẹ̀ sì dọ́gba: ó sì fi ọ̀pá-ìwọ̀n náà wọn ìlú náà wò, ó jẹ ẹgbàafà ibùsọ̀ gígùn rẹ̀ àti ìbú rẹ̀, àti gíga rẹ̀ sì dọ́gba. 17 Ó sì wọn odi rẹ̀ ó jẹ́ ogóje ìgbọ̀nwọ́ lé mẹ́rin (144), gẹ́gẹ́ bí òṣùwọ̀n ènìyàn, bẹ́ẹ̀ ni tí angẹli náà. 18 A sì fi jasperi mọ odi ìlú náà. Ìlú náà sì jẹ́ kìkì wúrà, ó dàbí dígí tí o mọ́ kedere. 19 (D)A fi onírúurú òkúta iyebíye ṣe ìpìlẹ̀ ògiri ìlú náà lọ́ṣọ̀ọ́. Ìpìlẹ̀ èkínní jẹ́ jasperi; èkejì, safiru; ẹ̀kẹta, kalkedoni ẹ̀kẹrin, emeradi, 20 ẹ̀karùnún, sardoniki; ẹ̀kẹfà, kaneliani; èkeje, krisoliti; ẹ̀kẹjọ, bereli; ẹ̀kẹsànán, topasi; ẹ̀kẹwàá, krisoprasu; ẹ̀kọkànlá, jakiniti; èkejìlá, ametisiti. 21 Ẹnu ibodè méjèèjìlá jẹ́ pearli méjìlá: olúkúlùkù ẹnu ibodè jẹ́ peali kan; ọ̀nà ìgboro ìlú náà sì jẹ́ kìkì wúrà, ó dàbí dígí dídán.

Matiu 17:22-27

22 (A)Nígbà tí wọ́n sì ti wà ní Galili, Jesu sọ fún wọn pé, “Láìpẹ́ yìí a ó fi Ọmọ ènìyàn lé àwọn ènìyàn lọ́wọ́. 23 Wọn yóò sì pa á, ní ọjọ́ kẹta lẹ́yìn èyí, yóò sì jí dìde sí ìyè.” Ọkàn àwọn Ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì kún fún ìbànújẹ́ gidigidi.

Owó tẹmpili

24 (B)Nígbà tí Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì dé Kapernaumu, àwọn agbowó òde tí ń gba owó idẹ méjì tó jẹ́ owó tẹmpili tọ Peteru wá wọ́n sì bí i pé, “Ǹjẹ́ olùkọ́ yín ń san owó tẹmpili?”

25 (C)Peteru sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, ó ń san.”

Nígbà tí Peteru wọ ilé láti bá Jesu sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, Jesu ni ó kọ́kọ́ sọ̀rọ̀, Jesu bí i pé, “Kí ni ìwọ rò, Simoni? Ǹjẹ́ àwọn ọba ayé ń gba owó orí lọ́wọ́ àwọn ọmọ wọn tàbí lọ́wọ́ àwọn àlejò?”

26 Peteru dáhùn pé, “Lọ́wọ́ àwọn àlejò ni.”

Jesu sì tún wí pé, “Èyí jẹ́ wí pé àwọn ọmọ onílẹ̀ kì í san owó òde? 27 Síbẹ̀síbẹ̀, àwa kò fẹ́ mú wọn bínú. Nítorí náà, ẹ lọ sí etí Òkun, kí ẹ sì sọ ìwọ̀ sí omi. Ẹ mú ẹja àkọ́kọ́ tí ẹ kọ́ fà sókè, ẹ ya ẹnu rẹ̀, ẹ̀yin yóò sì rí owó idẹ kan níbẹ̀, ki ẹ fi fún wọn fún owó orí tèmi àti tirẹ̀.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.