Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 88

Orin. Saamu ti àwọn ọmọ Kora. Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí ti mahalati leannoti. Maskili ti Hemani ará Esra.

88 Olúwa, Ọlọ́run tí ó gbà mí là,
    ní ọ̀sán àti ní òru ni mo kígbe sókè sí Ọ.
Jẹ́ kí àdúrà mi kí ó wá sí iwájú rẹ;
    dẹ etí rẹ sí igbe mi.

Nítorí ọkàn mi kún fún ìpọ́njú
    ọkàn mi sì súnmọ́ isà òkú.
A kà mí mọ́ àwọn tí wọ́n lọ sí ọ̀gbun ilẹ̀
    èmi dàbí ọkùnrin tí kò ni agbára.
A yà mí sọ́tọ̀ pẹ̀lú àwọn òkú
    bí ẹni tí a pa tí ó dùbúlẹ̀ ní ipò ikú,
ẹni tí ìwọ kò rántí mọ́,
    ẹni tí a gé kúrò lára àwọn tí ìwọ ń tọ́jú.

Ìwọ tí ó fi mí sí kòtò jíjìn,
    ní ibi ọ̀gbun tó ṣókùnkùn.
Ìbínú rẹ ṣubú lé mi gidigidi;
    ìwọ ti fi àwọn ìjì rẹ borí mi.
Ìwọ tí gba ọ̀rẹ́ mi tí ó súnmọ́ mi kúrò lọ́wọ́ mi
    ìwọ sì sọ mi di ìríra sí wọn.
A há mi mọ́, èmi kò sì le è jáde;
Ojú mi káàánú nítorí ìpọ́njú.

    Mo kígbe pè ọ́, Olúwa, ní gbogbo ọjọ́;
mo na ọwọ́ mi jáde sí ọ.
10 Ìwọ ó fi iṣẹ́ ìyanu rẹ hàn fún òkú bi?
    Àwọn òkú yóò ha dìde láti yìn ọ́ bí?
11 A ó ha fi ìṣeun ìfẹ́ rẹ hàn ní ibojì bí:
    Tàbí òtítọ́ rẹ ní ipò ìparun?
12 A ha lè mọ iṣẹ́ ìyanu rẹ ní òkùnkùn bí
    àti òdodo rẹ ní ilẹ̀ ìgbàgbé?

13 Ṣùgbọ́n mo kígbe sí ọ fún ìrànlọ́wọ́, Olúwa;
    ní òwúrọ̀ ni àdúrà mí wá sọ́dọ̀ rẹ.
14 Olúwa, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mí
    tí ìwọ fi ojú rẹ pamọ́ fún mi?

15 Láti ìgbà èwe mi, ìṣẹ́ ń ṣẹ́ mi,
    èmi múra àti kú;
nígbà tí ẹ̀rù rẹ bá ń bà mí,
    èmi di gbére-gbère
16 Ìbínú rẹ ti kọjá lára mi;
    ìbẹ̀rù rẹ ti gé mi kúrò
17 Ní gbogbo ọjọ́ ni wọn yí mi ká bí ìkún omi;
    wọ́n mù mí pátápátá.
18 Ìwọ ti mú ọ̀rẹ́ àti olùfẹ́ mi kúrò lọ́dọ̀ mi;
    òkùnkùn sì jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ mi.

Saamu 91-92

91 Ẹni tí ó gbé ibi ìkọ̀kọ̀ Ọ̀gá-ògo
    ni yóò sinmi ní ibi òjìji Olódùmarè.
Èmi yóò sọ nípa ti Olúwa pé,
    “Òun ni ààbò àti odi mi,
    Ọlọ́run mi, ẹni tí èmi gbẹ́kẹ̀lé”.

Nítòótọ́ òun yóò gbà mí nínú
    ìdẹ̀kùn àwọn pẹyẹpẹyẹ
    àti nínú àjàkálẹ̀-ààrùn búburú.
Òun yóò fi ìyẹ́ rẹ̀ bò mí,
    àti ni abẹ́ ìyẹ́ rẹ̀ ni èmi yóò ti rí ààbò;
    òtítọ́ rẹ̀ ni yóò ṣe ààbò àti odi mi.
Ìwọ kì yóò bẹ̀rù nítorí ẹ̀rù òru,
    tàbí fún ọfà tí ń fò ní ọ̀sán,
Tàbí fún àjàkálẹ̀-ààrùn tí ń rìn kiri ní òkùnkùn,
    tàbí fún ìparun tí ń rìn kiri ní ọ̀sán gangan.
Ẹgbẹ̀rún yóò ṣubú ní ẹ̀gbẹ́ rẹ,
    ẹgbàárùn-ún ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ
    ṣùgbọ́n kì yóò súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ
Ìwọ yóò máa wò ó pẹ̀lú ojú rẹ
    àti wo ìjìyà àwọn ẹni búburú.

Nítorí ìwọ fi Olúwa ṣe ààbò rẹ,
    ìwọ fi Ọ̀gá-ògo ṣe ibùgbé rẹ.
10 Búburú kan ki yóò ṣubú lù ọ́
    Bẹ́ẹ̀ ni ààrùnkárùn kì yóò súnmọ́ ilé rẹ.
11 (A)Nítorí yóò fi àṣẹ fún àwọn angẹli nípa tìrẹ
    láti pa ọ́ mọ́ ní gbogbo ọ̀nà rẹ;
12 Wọn yóò gbé ọ sókè ní ọwọ́ wọn,
    nítorí kí ìwọ má ba à fi ẹsẹ̀ rẹ gún òkúta.
13 (B)Ìwọ yóò rìn lórí kìnnìún àti paramọ́lẹ̀;
    ìwọ yóò tẹ kìnnìún ńlá àti ejò ńlá ni ìwọ yóò fi ẹsẹ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀.

14 “Nítorí ti ìfẹ́ rẹ sí mi, èmi yóò gbà ọ́;
    èmi yóò pa ọ́ mọ́, nítorí ìwọ jẹ́wọ́ orúkọ mi.
15 Òun yóò pè mí, èmi yóò sì dá a lóhùn;
    èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú ìpọ́njú,
    èmi yóò gbà á, èmi yóò sì bu ọlá fún un
16 Pẹ̀lú ẹ̀mí gígùn ni èmi yóò fi tẹ́ ẹ lọ́rùn
    èmi yóò sì fi ìgbàlà mi hàn án.”

Saamu. Orin. Fún ọjọ́ Ìsinmi

92 Ohun rere ni láti máa fi ọpẹ́ fún Olúwa
    àti láti máa kọrin sí orúkọ rẹ̀, Ọ̀gá-ògo,
Láti kéde ìfẹ́ rẹ̀ ní òwúrọ̀
    àti òtítọ́ rẹ̀ ní alẹ́
Lára ohùn èlò orin olókùn mẹ́wàá
    àti lára ohun èlò orin haapu.

Nítorí ìwọ ni ó mú inú mi dùn
    nípa iṣẹ́ rẹ Olúwa;
èmi kọrin ayọ̀ sí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.
Báwo ni iṣẹ́ rẹ tí tóbi tó, Olúwa?
    Èrò inú rẹ ìjìnlẹ̀ ni!
Òpè ènìyàn kò mọ̀ ọ́n,
    aṣiwèrè kò sì mọ̀ ọ́n,
Nígbà tí àwọn ènìyàn búburú
    bá rú jáde bí i koríko
àti gbogbo àwọn olùṣe
    búburú gbèrú,
wọn yóò run láéláé.

Ṣùgbọ́n ìwọ Olúwa ni a ó gbéga títí láé.

Nítorí nítòótọ́ àwọn ọ̀tá rẹ,
Olúwa,
    nítòótọ́ àwọn ọ̀tá rẹ yóò ṣègbé;
gbogbo àwọn olùṣe búburú
    ni a ó fọ́nká.
10 Ìwọ ti gbé ìwo mi ga bí i ti màlúù igbó;
    òróró dídára ni a dà sí mi ní orí.
11 Ojú mi ti rí ìṣubú àwọn ọ̀tá mi;
    ìparun sí àwọn ènìyàn búburú
    tí ó dìde sí mi.

12 Olódodo yóò gbèrú bí i igi ọ̀pẹ,
    wọn yóò dàgbà bí i igi kedari Lebanoni;
13 Tí a gbìn sí ilé Olúwa,
    Wọn yóò rúwé nínú àgbàlá Ọlọ́run wa.
14 Wọn yóò máa so èso ní ìgbà ogbó,
    wọn yóò dúró ní àkọ̀tun, wọn yóò sì tutù nini,
15 Láti fihàn pé “Ẹni ìdúró ṣinṣin ni Olúwa;
    òun ni àpáta mi, kò sì ṣí aburú
    kankan nínú rẹ̀.”

Error: Book name not found: 1Macc for the version: Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
Ìfihàn 19:11-16

Ẹni tó gun ẹṣin funfun

11 (A)Mo sì rí ọ̀run ṣí sílẹ̀, sì wò ó, ẹṣin funfun kan; ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀ ni à ń pè ní Olódodo àti Olóòtítọ́, nínú òdodo ni ó sì ń ṣe ìdájọ́, tí ó ń jagun. 12 (B)Ojú rẹ̀ dàbí ọ̀wọ́-iná, àti ní orí rẹ̀ ni adé púpọ̀ wà; ó sì ní orúkọ kan tí a kọ, tí ẹnikẹ́ni kò mọ́, bí kò ṣe òun tìkára rẹ̀. 13 A sì wọ̀ ọ́ ní aṣọ tí a tẹ̀ bọ inú ẹ̀jẹ̀: a sì ń pe orúkọ rẹ̀ ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. 14 Àwọn ogun tí ń bẹ ní ọ̀run tí a wọ̀ ní aṣọ ọ̀gbọ̀ wíwẹ́, funfun àti mímọ́, sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn lórí ẹṣin funfun. 15 (C)Àti láti ẹnu rẹ̀ ni idà mímú ti ń jáde lọ, kí ó lè máa fi sá àwọn orílẹ̀-èdè: “Òun ó sì máa fi ọ̀pá irin ṣe àkóso wọn.” Ó sì ń tẹ ìfúntí àti ìbínú Ọlọ́run Olódùmarè. 16 (D)Ó sì ní lára aṣọ rẹ̀ àti ni ìtàn rẹ̀ orúkọ kan tí a kọ:

Matiu 16:13-20

Peteru jẹ́wọ́ Kristi

13 (A)Nígbà tí Jesu sì dé Kesarea-Filipi, ó bi àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ta ni àwọn ènìyàn ń fi Ọmọ ènìyàn pè?”

14 (B)Wọ́n dá a lóhùn pé, “Àwọn kan ni Johanu onítẹ̀bọmi ni, àwọn mìíràn wí pé, Elijah ni, àwọn mìíràn wí pé, Jeremiah ni, tàbí ọ̀kan nínú àwọn wòlíì.”

15 “Ṣùgbọ́n ẹyin ń kọ?” Ó bi í léèrè pé, “Ta ni ẹ̀yin ń fi mi pè?”

16 (C)Simoni Peteru dáhùn pé, “Ìwọ ni Kristi náà, Ọmọ Ọlọ́run alààyè.”

17 (D)Jesu sì wí fún un pé, “Alábùkún fún ni ìwọ Simoni ọmọ Jona, nítorí ẹran-ara àti ẹ̀jẹ̀ kọ́ ló fi èyí hàn bí kò ṣe Baba mi tí ó ń bẹ ní ọ̀run. 18 Èmi wí fún ọ, ìwọ ni Peteru àti pé orí àpáta yìí ni èmi yóò kọ́ ìjọ mi lé, àti ẹnu-ọ̀nà ipò òkú kì yóò lè borí rẹ̀. 19 Èmi yóò fún ní àwọn kọ́kọ́rọ́ ìjọba Ọ̀run; Ohun tí ìwọ bá dè ní ayé, òun ni a ó dè ní ọ̀run. Ohunkóhun tí ìwọ bá sì tú ní ayé yìí, a ó sì tú ní ọ̀run.” 20 (E)Nígbà náà ó kìlọ̀ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé wọn kò gbọdọ̀ sọ fún ẹnikẹ́ni pé Òun ni Kristi náà.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.