Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 78

Maskili ti Asafu.

78 Ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ gbọ́ ẹ̀kọ́ mi;
    tẹ́tí rẹ sí ọ̀rọ̀ ẹnu mi.
(A)Èmi ó la ẹnu mi ní òwe,
    èmi o sọ ohun ìkọ̀kọ̀, ohun ti ọjọ́ pípẹ́;
Ohun tí a ti gbọ́ tí a sì ti mọ̀,
    ohun tí àwọn baba wa ti sọ fún wa.
Àwa kì yóò pa wọ́n mọ́
    kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọmọ,
ní fífi ìyìn Olúwa, àti ipa rẹ̀
    àti iṣẹ́ ìyanu tó ti ṣe hàn
fún ìran tí ń bọ̀.
Ó gbé ẹ̀rí kalẹ̀ ní Jakọbu
    o sì fìdí àṣẹ múlẹ̀ ní Israẹli,
èyí tí ó pàṣẹ fún àwọn baba ńlá wa
    láti kọ́ àwọn ọmọ wọn,
Nítorí náà, àwọn ìran tí ń bọ̀ yóò mọ̀ wọ́n
    bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ tí a kò tí ì bí
    tí yóò dìde tí wọn yóò sọ fún àwọn ọmọ wọn
Nígbà náà ni wọ́n ò fi ìgbẹ́kẹ̀lé wọn sínú Ọlọ́run
    wọn kò sì ní gbàgbé iṣẹ́ Ọlọ́run
    ṣùgbọ́n wọn ó pa àṣẹ rẹ̀ mọ́.
Kí wọn kí ó má ṣe dàbí àwọn baba ńlá wọn,
    ìran alágídí àti ọlọ́tẹ̀,
    ìran tí ọkàn wọn kò ṣọ òtítọ́ si olóore,
    àti ẹ̀mí ẹni tí kò bá Ọlọ́run dúró ṣinṣin.

Àwọn ọkùnrin Efraimu, tí ó há mọ́ ọ tí wọ́n mú ọrun,
    wọ́n yípadà ní ọjọ́ ogun
10 Wọn kò pa májẹ̀mú Ọlọ́run mọ́
    wọn sì kọ̀ láti máa gbé nínú òfin rẹ̀
11 Wọ́n gbàgbé ohun tí ó ti ṣe,
    àwọn ìyanu tí ó ti fihàn wọ́n.
12 Ó ṣe ìyanu níwájú àwọn baba wọn ní ilẹ̀ Ejibiti, ní agbègbè Ṣoani.
13 Ó pín Òkun ní yà, ó sì mú wọn kọjá
    Ó mù kí omi naà dúró bi odi gíga.
14 Ní ọ̀sán, ó fi ìkùùkuu àwọsánmọ̀ ṣe amọ̀nà wọn
    àti ní gbogbo òru pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ iná.
15 Ó sán àpáta ní aginjù
    ó sì fún wọn ní omi mímu lọ́pọ̀lọpọ̀
    bí ẹni pé láti inú ibú wá.
16 Ó mú ìṣàn omi jáde láti inú àpáta
    omi ṣíṣàn sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí odò.

17 Wọ́n sì tún tẹ̀síwájú láti dẹ́ṣẹ̀ sí i
    ní ìṣọ̀tẹ̀ sí Ọ̀gá-ògo ní aginjù.
18 Wọ́n mọ̀ ọ́n mọ̀ dán Ọlọ́run wò
    nípa bíbéèrè fún oúnjẹ tí wọn bẹ̀bẹ̀ fún
19 Wọ́n sọ̀rọ̀-òdì sí Ọlọ́run, wí pé
    “Ọlọ́run ha lè tẹ́ tábìlì ní aginjù?
20 Nígbà tí ó lu àpáta, omi tú jáde,
    odò sì sàn lọ́pọ̀lọpọ̀
ṣùgbọ́n òun ha lè fún wa lóúnjẹ
    ó ha le pèsè ẹran fún àwọn ènìyàn rẹ̀”
21 Nígbà tí Olúwa gbọ́ wọn, ó bínú gidigidi;
iná rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ sí Jakọbu,
ìbínú rẹ̀ sì rú sí Israẹli,
22 Nítorí wọn kò gba Ọlọ́run gbọ́,
    wọn kò sì gbẹ́kẹ̀lé ìgbàlà rẹ̀.
23 Síbẹ̀ ó pàṣẹ fún ìràwọ̀ ojú ọ̀run,
    ó sì ṣí ìlẹ̀kùn ọ̀run sílẹ̀;
24 (B)Ó rọ manna fún àwọn ènìyàn láti jẹ,
    ó fún wọn ní ọkà láti ọ̀run.
25 Àwọn ènìyàn jẹ oúnjẹ àwọn angẹli;
    Ó fún wọn ní oúnjẹ ní àjẹyó,
26 Ó mú afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn láti ọ̀run wá
    ó mú afẹ́fẹ́ gúúsù wá nípa agbára rẹ̀.
27 Ó rọ òjò ẹran sílẹ̀ sórí wọn bí erùpẹ̀ ilẹ̀,
    àti ẹyẹ abìyẹ́ gẹ́gẹ́ bí iyanrìn etí Òkun
28 Ó jẹ́ kí wọn jáde ní ibùdó wọn,
    yíká àgọ́ wọn.
29 Wọ́n jẹ, wọ́n sì yó jọjọ
    nítorí ó ti fún wọn ní ohun tí wọn fìtara bẹ̀bẹ̀ fún
30 Ṣùgbọ́n wọn kò kúrò nínú oúnjẹ tí wọn fìtara bẹ̀bẹ̀ fún,
    nígbà tí oúnjẹ wọn sì wà ní ẹnu wọn,
31 Ìbínú Ọlọ́run dìde sí wọn
    ó pa àwọn tí ó jùlọ nínú wọn,
    ó sì lu àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin Israẹli bolẹ̀.

32 Nínú gbogbo ìwọ̀nyí, wọ́n ń dẹ́ṣẹ̀ síwájú;
    nínú gbogbo iṣẹ́ ìyanu rẹ̀, wọ́n kò gbàgbọ́
33 O fi òpin sí ayé wọn nínú asán
    àti ọdún wọn nínú ìpayà.
34 Nígbàkígbà tí Ọlọ́run bá pa wọ́n,
    wọn yóò wá a kiri;
    wọn yóò fi ìtara yípadà sí i.
35 Wọ́n rántí pé Ọlọ́run ní àpáta wọn;
    wí pé Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo jùlọ ni olùràpadà àpáta wọn
36 Ṣùgbọ́n nígbà náà ni wọ́n yóò pọ́n ọn pẹ̀lú ẹnu wọ́n
    wọ́n fi ahọ́n wọ́n purọ́ fún un;
37 (C)Ọkàn wọn kò sòtítọ́ sí i,
    wọn kò jẹ́ olódodo sí májẹ̀mú rẹ̀.
38 Síbẹ̀ ó ṣàánú;
    ó dárí àìṣedéédéé wọn jì
òun kò sì pa wọ́n run
    nígbà púpọ̀ ló ń yí ìbínú rẹ̀ padà
kò sì ru ìbínú rẹ̀ sókè
39 Ó rántí pé ẹlẹ́ran ara ni wọ́n,
    afẹ́fẹ́ tó ń kọjá tí kò lè padà.

40 Nígbà gbogbo ní wọn ń ṣọ̀tẹ̀ sí i ní aginjù
    wọn mú un bínú nínú ilẹ̀ tí ó di ahoro!
41 Síwájú àti síwájú wọ́n dán Ọlọ́run wò;
    wọ́n mú ẹni mímọ́ Israẹli bínú.
42 Wọ́n kò rántí agbára rẹ̀:
    ní ọjọ́ tí ó rà wọ́n padà lọ́wọ́ àwọn aninilára,
43 Ní ọjọ́ tí ó fi iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ hàn ní Ejibiti,
    àti iṣẹ́ ààmì rẹ̀ ni ẹkùn Ṣoani
44 Ó sọ omi wọn di ẹ̀jẹ̀;
    wọn kò lè mu láti odò wọn.
45 Ó rán ọ̀wọ́ eṣinṣin láti pa wọ́n run,
    àti ọ̀pọ̀lọ́ tí ó bá wọn jẹun.
46 Ó fi ọkà wọn fún láńtata,
    àwọn ìre oko wọn fún eṣú.
47 Ó fi yìnyín ba àjàrà wọn jẹ́
    ó bá èso sikamore wọn jẹ́.
48 Ó fi ohun ọ̀sìn wọn fún yìnyín,
    agbo ẹran wọn fún mọ̀nàmọ́ná.
49 Ó mú kíkorò ìbínú rẹ̀ wá sí wọn lára,
    ìrunú àti ìkáàánú, àti ìpọ́njú,
    nípa rírán angẹli apanirun sí wọn.
50 Ó pèsè ipa fún ìbínú rẹ̀,
    òun kò gbà wọ́n lọ́wọ́ ikú,
    ṣùgbọ́n ó fi ẹ̀mí wọ́n fún àjàkálẹ̀-ààrùn.
51 Ó kọlu àwọn àkọ́bí ọmọ ọkùnrin Ejibiti
    Olórí agbára wọn nínú àgọ́ Hamu
52 Ṣùgbọ́n ó mú àwọn ènìyàn rẹ̀ jáde bí ọ̀wọ́ ẹran;
    ó ṣọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí àgùntàn nínú aginjù.
53 Ó dáàbò bò wọ́n dáradára, nítorí náà ni ẹ̀rù kò ṣe bà wọ́n
    ṣùgbọ́n Òkun padé mọ́ àwọn ọ̀tá wọn.
54 Bákan náà ni ó mú wọn wá sí etí ilẹ̀ mímọ́ rẹ̀
    òkè tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ ti gbà
55 Ó lé kèfèrí jáde níwájú wọn
    ó sì fi títa okùn pín ilẹ̀ náà fún wọn gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìní;
    ó mú àwọn ẹ̀yà Israẹli jókòó ní ilẹ̀ wọn.

56 Ṣùgbọ́n wọn dán Ọlọ́run wò
    wọn sì ṣọ̀tẹ̀ sí Ọ̀gá-ògo;
    wọn kò pa àṣẹ rẹ̀ mọ́.
57 Ṣùgbọ́n wọ́n yípadà,
    wọn jẹ́ aláìṣòdodo gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wọn
wọ́n sì pẹ̀yìndà sí apákan bí ọrun ẹ̀tàn.
58 Wọ́n bí i nínú pẹ̀lú ibi gíga wọn;
    wọn rú owú rẹ̀ sókè nípa òrìṣà wọn
59 Nígbà tí Ọlọ́run gbọ́ wọn,
    inú bí i gidigidi;
ó kọ Israẹli pátápátá.
60 Ó kọ àgọ́ Ṣilo sílẹ̀,
    àgọ́ tí ó ti gbé kalẹ̀ láàrín àwọn ènìyàn.
61 Ó rán àpótí ẹ̀rí, agbára rẹ̀ lọ sí ìgbèkùn,
    dídán ògo rẹ̀ lọ sí ọwọ́ àwọn ọ̀tá.
62 Ó fi àwọn ènìyàn rẹ̀ lé idà lọ́wọ́,
    ó sì bínú sí àwọn ohun ìní rẹ̀.
63 Iná run àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin wọn,
    àwọn ọmọbìnrin wọn kò sì ní orin ìgbéyàwó:
64 A fi àlùfáà wọn fún idà,
    àwọn opó wọn kò sì le è sọkún.

65 Olúwa sì jí gẹ́gẹ́ bí ẹni ojú oorun,
    gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin ti i jí kúrò nínú ìraníyè ọtí.
66 Ó kọlu àwọn ọ̀tá rẹ̀ padà;
    ó fi wọn sínú ìtìjú ayérayé.
67 Nígbà náà ni ó kọ́ àgọ́ Josẹfu,
    kò sì yan ẹ̀yà Efraimu;
68 Ṣùgbọ́n ó yan ẹ̀yà Juda,
    òkè Sioni, èyí tí ó fẹ́ràn.
69 Ó kọ́ ibi mímọ́ rẹ̀, ibi gíga,
    gẹ́gẹ́ bí ayé tí ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ títí láé.
70 Ó yan Dafidi ìránṣẹ́ rẹ̀
    ó mú láti inú àwọn agbo ẹran;
71 Ó mú un jáde nínú ìtọ́jú àgùntàn
    láti jẹ́ olùṣọ́-àgùntàn àwọn ènìyàn rẹ̀ Jakọbu
    àti Israẹli ogún un rẹ̀.
72 Dafidi sì ṣọ́ wọn pẹ̀lú òtítọ́ inú ọkàn;
    pẹ̀lú ọwọ́ òye ni ó fi darí wọn.

Nehemiah 9:26-38

26 “Ṣùgbọ́n wọ́n ṣe àìgbọ́ràn, wọ́n sì ṣọ̀tẹ̀ sí ọ; wọ́n gbàgbé òfin rẹ. Wọ́n pa àwọn wòlíì rẹ, tí o fi gbà wọn ni ìyànjú pé kí wọn yí padà sí ọ; wọ́n sì se ọ̀rọ̀-òdì tí ó burú jàì. 27 Nítorí náà, ìwọ fi wọ́n lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́, àwọn tí ó ni wọ́n lára. Ṣùgbọ́n nígbà tí a ni wọ́n lára wọ́n kígbe sí ọ. Ìwọ gbọ́ wọn láti ọ̀run wá àti nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àánú rẹ, ìwọ fún wọn ní olùgbàlà, tí ó gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn.

28 “Ṣùgbọ́n bí wọ́n bá ti wà nínú ìsinmi, wọn a sì túnṣe búburú lójú rẹ. Nígbà náà ni ìwọ kọ̀ wọ́n sílẹ̀ ṣọ́wọ́ àwọn ọ̀tá kí wọ́n lè jẹ ọba lórí wọn. Nígbà tí wọ́n bá sì tún kígbe sí ọ, ìwọ a gbọ́ láti ọ̀run wá, àti nínú àánú rẹ ni ìwọ gbà láti ìgbà dé ìgbà.

29 “Ìwọ kìlọ̀ fún wọn láti padà sínú òfin rẹ, ṣùgbọ́n wọ́n hu ìwà ìgbéraga, wọ́n sì ṣe àìgbọ́ràn si àṣẹ rẹ. Wọ́n ṣẹ̀ sí ìlànà rẹ, nípa èyí tí ènìyàn yóò yè tí wọ́n bá pa wọ́n mọ́. Nínú agídí ọkàn wọ́n kọ ẹ̀yìn sí ọ, wọ́n jẹ́ olórí kunkun wọn kò sì fẹ́ gbọ́. 30 Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ni ìwọ fi ní sùúrù pẹ̀lú wọn. Nípa ẹ̀mí rẹ ni ìwọ kìlọ̀ fún wọn nípasẹ̀ àwọn wòlíì. Síbẹ̀ wọn kò fi etí sílẹ̀, nítorí náà ni ìwọ ṣe fi wọ́n lé àwọn aládùúgbò wọn lọ́wọ́. 31 Ṣùgbọ́n nínú ọ̀pọ̀ àánú rẹ, ìwọ kò mú òpin bá wọn tàbí kọ̀ wọ́n sílẹ̀, nítorí ìwọ ni Ọlọ́run olóore-ọ̀fẹ́ àti aláàánú.

32 “Ǹjẹ́ nítorí náà, Ọlọ́run wa, Ọlọ́run tí ó tóbi, tí ó lágbára, tí ó sì ní ẹ̀rù, ẹni tí ó pa májẹ̀mú ìfẹ́ mọ́, má ṣe jẹ́ gbogbo ìnira yìí dàbí ohun kékeré ní ojú rẹ—ìnira tí ó ti wá sórí wa, sórí àwọn ọba wa àti àwọn olórí wa, sórí àwọn àlùfáà wa àti àwọn wòlíì, sórí àwọn baba wa àti sórí gbogbo ènìyàn rẹ̀, láti àwọn ọjọ́ àwọn ọba Asiria wá títí di òní. 33 Ìwọ jẹ́ olódodo nínú ohun gbogbo tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí wa; ìwọ sì ti ṣe òtítọ́, nígbà tí a bá ṣe búburú. 34 Àwọn ọba wa, àwọn olórí wa, àwọn àlùfáà wa, àti àwọn baba wa kò tẹ̀lé òfin rẹ; wọn kò fetísílẹ̀ sí àṣẹ rẹ tàbí àwọn ìkìlọ̀ tí ìwọ fún wọn. 35 Àní nígbà tí wọ́n wà nínú ìjọba wọn, tí wọ́n ń gbádùn oore ńlá tí ìwọ fi fún wọn, ní ilẹ̀ tí ó tóbi tí ó sì lọ́ràá, wọn kò sìn ọ́ tàbí padà kúrò nínú àwọn ọ̀nà búburú wọn.

36 “Ṣùgbọ́n wò ó, àwa jẹ́ ẹrú lónìí, àwa jẹ́ ẹrú ní ilẹ̀ tí ìwọ fún àwọn baba ńlá wa, nítorí kí wọn bá máa jẹ èso rẹ̀ àti ìre mìíràn tí ó mú jáde. 37 Nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìkórè rẹ lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ọba tí ó fi ṣe olórí wa. Wọ́n ń ṣe àkóso lórí wa àti lórí ẹran wa bí ó ti wù wọ́n, àwa sì wà nínú ìpọ́njú ńlá.

Àdéhùn àwọn ènìyàn

38 “Nítorí gbogbo èyí, a ń ṣe àdéhùn tí ó fẹsẹ̀múlẹ̀, a sì kọ ọ́ sínú ìwé, àwọn olórí ọmọ Lefi àwọn àlùfáà sì fi èdìdì dì í.”

Ìfihàn 18:9-20

(A)“Àti àwọn ọba ayé, tí ó ti ń bá a ṣe àgbèrè, tiwọn sì ń hùwà wọ̀bìà, yóò sì pohùnréré ẹkún lé e lórí, nígbà tí wọn bá wo èéfín ìjóná rẹ̀. 10 Wọ́n ó dúró ní òkèrè réré nítorí ìbẹ̀rù iṣẹ́ oró rẹ̀, wọn ó máa wí pé:

“ ‘Ègbé! Ègbé, ni fún ìlú ńlá náà,
    Babeli ìlú alágbára nì!
Nítorí ní wákàtí kan ni ìdájọ́ rẹ dé!’

11 (B)“Àwọn oníṣòwò ayé sì ń sọkún, wọn sì ń ṣọ̀fọ̀ lórí rẹ̀, nítorí pé ẹnikẹ́ni kò rà ọjà wọn mọ́: 12 (C)Ọjà wúrà, àti ti fàdákà, àti ti òkúta iyebíye, àti ti Pearli, àti ti aṣọ ọ̀gbọ̀ wíwẹ́, àti tí elése àlùkò, àti ti ṣẹ́dà, àti ti òdòdó, àti ti gbogbo igi olóòórùn dídùn, àti ti olúkúlùkù ohun èlò tí a fi igi iyebíye ṣe, àti ti idẹ, àti ti irin, àti ti òkúta mabu. 13 Àti ti Kinamoni, àti ti onírúurú ohun olóòórùn dídùn, àti ti ohun ìkunra, àti tí tùràrí, àti ti ọtí wáìnì, àti ti òróró, àti ti ìyẹ̀fun dáradára, àti ti alikama, àti ti ẹran ńlá, àti ti àgùntàn, àti ti ẹṣin, àti ti kẹ̀kẹ́, àti ti ẹrú, àti ti ọkàn ènìyàn.

14 “Àti àwọn èso tí ọkàn rẹ̀ ń ṣe. Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí, si lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ, àti ohun gbogbo tí ó dùn tí ó sì dára ṣègbé mọ́ ọ lójú, kì yóò sì tún rí wọn mọ́ láé. 15 (D)Àwọn oníṣòwò nǹkan wọ̀nyí, tí a ti ipa rẹ̀ sọ di ọlọ́rọ̀, yóò dúró ní òkèrè réré nítorí ìbẹ̀rù iṣẹ́ oró rẹ̀, wọn o máa sọkún, wọ́n ó sì máa ṣọ̀fọ̀, 16 wí pé:

“ ‘Ègbé! Ègbé, ni fún ìlú ńlá nì,
    tí a wọ̀ ní aṣọ ọ̀gbọ̀ wíwẹ́,
    àti ti elése àlùkò, àti ti òdòdó, àti ti a sì fi wúrà ṣe ní ọ̀ṣọ́, pẹ̀lú òkúta iyebíye àti peali!
17 (E)Nítorí pé ní wákàtí kan ni ọrọ̀ ti o pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ di asán!’

“Àti olúkúlùkù ẹni tí ń rin ojú omi lọ sí ibikíbi, àti àwọn ti ń ṣiṣẹ́ nínú ọkọ àwọn ti ń ṣòwò ojú Òkun dúró ní òkèrè réré, 18 wọ́n sì kígbe nígbà tí wọ́n rí èéfín jíjóná rẹ́, wí pé, ‘Ìlú wo ni o dàbí ìlú yìí?’ 19 (F)Wọ́n sì kú ekuru sí orí wọn, wọ́n kígbe, wọ́n sọkún, wọn sì ń ṣọ̀fọ̀, wí pé:

“ ‘Ègbé! Ègbé, ni fún ìlú ńlá náà,
    nínú èyí tí a sọ gbogbo àwọn tí ó ni ọkọ̀
    ní Òkun di ọlọ́rọ̀ nípa ohun iyebíye rẹ̀!
Nítorí pé ni wákàtí kan, a sọ ọ́ di ahoro.’

20 (G)“Yọ̀ lórí rẹ̀, ìwọ ọ̀run!
    Ẹ yọ̀, ẹ̀yin ènìyàn Ọlọ́run!
    Ẹ yọ̀, ẹ̀yin aposteli mímọ́ àti wòlíì!
Nítorí Ọlọ́run ti gbẹ̀san yín lára rẹ̀
    nítorí ìdájọ́ tí ó gbé ka orí rẹ.”

Matiu 15:21-28

21 (A)Jesu sì ti ibẹ̀ kúrò lọ sí Tire àti Sidoni. 22 Obìnrin kan láti Kenaani, tí ó ń gbé ibẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Ó ń bẹ̀bẹ̀, ó sì kígbe pé, “Olúwa, ọmọ Dafidi, ṣàánú fún mi; ọmọbìnrin mi ní ẹ̀mí èṣù ti ń dá a lóró gidigidi.”

23 Ṣùgbọ́n Jesu kò fún un ní ìdáhùn, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì gbà á níyànjú pé, “Lé obìnrin náà lọ, nítorí ó ń kígbe tọ̀ wá lẹ́yìn.”

24 (B)Ó dáhùn pé, “Àgùntàn ilẹ̀ Israẹli tí ó nù nìkan ni a rán mi sí.”

25 (C)Obìnrin náà wá, ó wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó bẹ̀bẹ̀ sí i pé, “Olúwa ṣàánú fún mi.”

26 Ó sì dáhùn wí pé, “Kò tọ́ kí a gbé oúnjẹ àwọn ọmọ fún àwọn ajá.”

27 Obìnrin náà sì wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, síbẹ̀síbẹ̀ àwọn ajá a máa jẹ èrúnrún tí ó ti orí tábìlì olówó wọn bọ́ sílẹ̀.”

28 (D)Jesu sì sọ fún obìnrin náà pé, “Ìgbàgbọ́ ńlá ni tìrẹ! A sì ti dáhùn ìbéèrè rẹ.” A sì mú ọmọbìnrin rẹ̀ láradá ní wákàtí kan náà.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.