Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 30

Saamu. Orin. Fún ìyàsímímọ́ Tẹmpili. Ti Dafidi.

30 Èmi yóò kókìkí i rẹ, Olúwa,
    nítorí ìwọ ni ó gbé mi lékè
    tí ìwọ kò sì jẹ́ kí àwọn ọ̀tá mi kí ó yọ̀ mí.
Olúwa Ọlọ́run mi, èmi ké pè ọ́, fún ìrànlọ́wọ́
    ìwọ sì ti wò mí sàn.
Olúwa, ìwọ ti yọ ọkàn mi jáde kúrò nínú isà òkú,
    mú mi padà bọ̀ sípò alààyè kí èmi má ba à lọ sínú ihò.

Kọ orin ìyìn sí Olúwa, ẹ̀yin olódodo;
    kí ẹ sì fi ọpẹ́ fún orúkọ rẹ̀ mímọ́.
Nítorí pé ìbínú rẹ̀ wà fún ìgbà díẹ̀,
    ojúrere rẹ̀ wà títí ayérayé;
Ẹkún lè pẹ́ títí di alẹ́,
    Ṣùgbọ́n ayọ̀ yóò wá ní òwúrọ̀.

Ní ìgbà ayé mi, mo wí pé,
    “a kì yóò ṣí mi ní ipò padà.”
Nípa ojúrere rẹ, Olúwa,
    ìwọ ti gbé mi kalẹ̀ bí òkè tí ó ní agbára;
ìwọ pa ojú rẹ mọ́,
    àyà sì fò mí.

Sí ọ Olúwa, ni mo ké pè é;
    àti sí Olúwa ni mo sọkún fún àánú:
“Èrè kí ni ó wà nínú ikú ìparun mi,
    nínú lílọ sí ihò mi?
Eruku yóò a yìn ọ́ bí?
    Ǹjẹ́ yóò sọ nípa òdodo rẹ?
10 Gbọ́, Olúwa, kí o sì ṣàánú fún mi;
    ìwọ Olúwa, jẹ́ olùrànlọ́wọ́ mi.”

11 Ìwọ ti yí ìkáàánú mi di ijó fún mi;
    ìwọ sì ti bọ́ aṣọ ọ̀fọ̀ mi, o sì fi aṣọ ayọ̀ wọ̀ mí,
12 nítorí ìdí èyí ni kí ọkàn mi máa yìn ọ́, kí o má sì ṣe dákẹ́.
    Ìwọ Olúwa Ọlọ́run mi, èmi yóò máa fi ọpẹ́ fún ọ títí láé.

Saamu 32

Ti Dafidi. Maskili.

32 (A)Ìbùkún ni fún àwọn
    tí a dárí ìrékọjá wọn jì,
    tí a sì bo ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́lẹ̀.
Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà
    ẹni tí Ọlọ́run kò ka ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ sí i lọ́rùn
    àti nínú ẹ̀mí ẹni tí kò sí ẹ̀tàn.

Nígbà tí mo dákẹ́,
    egungun mi di gbígbó dànù
    nípa ìkérora mi ní gbogbo ọjọ́.
Nítorí pé ni ọ̀sán àti ní òru
    ọwọ́ rẹ̀ wúwo sí mi lára;
agbára mi gbẹ tán
    gẹ́gẹ́ bí ooru ẹ̀ẹ̀rùn. Sela.

Èmi jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi sí ọ
    àti pé èmi kò sì fi àìṣòdodo mi pamọ́.
Èmi wí pé, “Èmi yóò jẹ́wọ́
    ẹ̀ṣẹ̀ mi fún Olúwa,”
ìwọ sì dárí
    ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí. Sela.

Nítorí náà jẹ́ kí gbogbo àwọn olódodo máa gbà àdúrà sí ọ
    ní ìgbà tí a lè rí ọ;
nítòótọ́ nígbà tí ìṣàn omi ńlá bá ru sókè,
    wọn kì yóò lè dé ọ̀dọ̀ rẹ̀.
Ìwọ ni ibi ìpamọ́ mi;
    ìwọ yóò pa mí mọ́ kúrò nínú ìyọnu;
    ìwọ yóò fi orin ìgbàlà yí mi ka. Sela.

Èmi yóò kọ́ ọ, èmi yóò sì fi ẹsẹ̀ rẹ lé ọ̀nà tí ìwọ yóò rìn
    èmi yóò máa gbà ọ́ ní ìyànjú, èmi yóò sì máa fi ojú mi tọ́ ọ.
Má ṣe dàbí ẹṣin tàbí ìbáaka,
    tí kò ní òye
ẹnu ẹni tí a gbọdọ̀ fi ìjánu bọ̀,
    kí wọn má ba à súnmọ́ ọ.
10 Ọ̀pọ̀ ìkáàánú ní yóò wà fún ènìyàn búburú,
    ṣùgbọ́n ìfẹ́ Olúwa tí ó dúró ṣinṣin
    ni yóò yí àwọn tí ó ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa ká.

11 Ẹ yọ̀ nínú Olúwa, kí ẹ sì ní inú dídùn, ẹ̀yìn olódodo;
    ẹ sì máa kọrin, gbogbo ẹ̀yìn tí àyà yín dúró ṣinṣin.

Saamu 42-43

ÌWÉ KEJÌ

Saamu 42–72

Fún adarí orin. Maskili ti àwọn ọmọ Kora.

42 Bí àgbọ̀nrín ti ń mí hẹlẹ sí ipa odò omi,
    bẹ́ẹ̀ ni ọkàn mi ń mí hẹlẹ sí ọ Ọlọ́run.
Òùngbẹ Ọlọ́run ń gbẹ ọkàn mi, fún Ọlọ́run alààyè.
    Nígbà wo ni èmi ó lọ bá Ọlọ́run?
Oúnjẹ mi ni omijé mi
    ní ọ̀sán àti ní òru,
    nígbà tí àwọn ènìyàn ń wí fún mi ní gbogbo ọjọ́ pé,
    “Ọlọ́run rẹ dà?”
Nígbà tí mo bá rántí nǹkan yìí,
    èmi tú ọkàn mi jáde nínú mi:
èmi ti bá ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn lọ,
    èmi bá wọn lọ sí ilé Ọlọ́run
pẹ̀lú ohùn ayọ̀ àti ìyìn,
    pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ń pa ọjọ́ mímọ́ mọ́.

Èéṣe tí o fi ń rẹ̀wẹ̀sì, ìwọ ọkàn mi?
    Èéṣe tí ara rẹ kò fi lélẹ̀ nínú mi?
Ìwọ ṣe ìrètí ní ti Ọlọ́run,
    nítorí èmi yóò sá à máa yìn ín,
    Olùgbàlà mi àti Ọlọ́run mi.

Ọlọ́run mi, ọkàn mi ń rẹ̀wẹ̀sì nínú mi:
    nítorí náà, èmi ó rántí rẹ
láti ilẹ̀ Jordani wá,
    láti Hermoni láti òkè Mibsari.
Ibú omi ń pe ibú omi
    nípa híhó omi ṣíṣàn rẹ̀
gbogbo rírú omi àti bíbì omi rẹ̀
    bò mí mọ́lẹ̀.

Ní ọ̀sán ní Olúwa ran ìfẹ́ rẹ̀,
    àti ni àṣálẹ́ ni orin rẹ̀ wà pẹ̀lú mi
àdúrà sí Ọlọ́run ayé mi.

Èmi wí fún Ọlọ́run àpáta mi,
    “Èéṣe tí ìwọ fi gbàgbé mi?
Èéṣe tí èmi o fi máa rìn nínú ìbànújẹ́,
    nítorí ìnilára ọ̀tá?”
10 Bí ẹni pé idà egungun mi ni ẹ̀gàn tí
    àwọn ọ̀tá mi ń gàn mí,
Bí wọn ti ń béèrè ní gbogbo ọjọ́.
    “Níbo ni Ọlọ́run rẹ wà?”

11 Èéṣe tí ìwọ fi ń rẹ̀wẹ̀sì, ìwọ ọkàn mi?
    Èéṣe tí ara rẹ kò fi lélẹ̀ nínú mi?
Fi ìrètí rẹ sínú Ọlọ́run,
    nítorí èmi yóò sì máa yìn ín, Òun ni
    Olùgbàlà mi àti Ọlọ́run mi.
43 Dá mi láre, Ọlọ́run mi,
    kí o sì gba ọ̀rọ̀ mi rò lọ́dọ̀ àwọn aláìláàánú orílẹ̀-èdè:
yọ mí kúrò lọ́wọ́ ẹlẹ́tàn àti àwọn ènìyàn búburú.
Ìwọ ni Ọlọ́run ibi agbára mi.
    Èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mi sílẹ̀?
Èéṣe tí èmi yóò máa rìn nínú ìbìnújẹ́,
    nítorí ìnilára lọ́dọ̀ àwọn ọ̀tá?
Rán ìmọ́lẹ̀ àti òtítọ́ rẹ jáde,
    jẹ́ kí wọn ó máa dáàbò bò mí;
jẹ́ kí wọn mú mi wá sí òkè mímọ́ rẹ,
    sí ibi tí ìwọ ń gbé.
Nígbà náà ni èmi ó lọ sí ibi pẹpẹ Ọlọ́run,
    sí Ọlọ́run ayọ̀ mi àti ìdùnnú mi,
èmi yóò yìn ọ́ pẹ̀lú dùùrù,
    ìwọ Ọlọ́run, Ọlọ́run mi.

Èéṣe tí o fi ń rẹ̀wẹ̀sì, ìwọ ọkàn mí?
    Èéṣe tí ó fi ń ru sókè nínú mi?
Fi ìrètí rẹ sínú Ọlọ́run,
    nítorí èmi yóò máa yìn ín, Òun ni
    Olùgbàlà mi àti Ọlọ́run mi.

1 Samuẹli 22

Dafidi ní Adullamu àti Mispa

22 Dafidi sì kúrò níbẹ̀, ó sì sá sí ihò Adullamu; nígbà tí àwọn arákùnrin rẹ̀ àti ìdílé baba rẹ̀ sì gbọ́, wọ́n sì sọ̀kalẹ̀ tọ̀ ọ́ wá níbẹ̀. Olúkúlùkù ẹni tí ó tí wà nínú ìpọ́njú, àti olúkúlùkù ẹni tí ó ti jẹ gbèsè, àti olúkúlùkù ẹni tí ó wà nínú ìbànújẹ́, sì kó ara wọn jọ sọ́dọ̀ rẹ̀, òun sì jẹ́ olórí wọn; àwọn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ sì tó ìwọ̀n irínwó ọmọkùnrin.

Dafidi sì ti ibẹ̀ náà lọ sí Mispa tí Moabu: ó sì wí fún ọba Moabu pé, “Jẹ́ kí baba àti ìyá mi, èmi bẹ̀ ọ́ wá bá ọ gbé, títí èmi yóò fi mọ ohun ti Ọlọ́run yóò ṣe fún mi.” Ó sì mú wọn wá síwájú ọba Moabu; wọ́n sì bá á gbé ní gbogbo ọjọ́ tí Dafidi fi wà nínú ihò náà.

Gadi wòlíì sí wí fún Dafidi pé, “Ma ṣe gbé inú ihò náà, yẹra, kí o sí lọ sí ilẹ̀ Juda.” Nígbà náà ni Dafidi sì yẹra, ó sì lọ sínú igbó Hereti.

Saulu pa àwọn àlùfáà Nobu

Saulu si gbọ́ pé a rí Dafidi àti àwọn ọkùnrin tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀; Saulu sì ń bẹ ní Gibeah lábẹ́ igi tamariski ní Rama; ọ̀kọ̀ rẹ̀ sì ń bẹ lọ́wọ́ rẹ̀, àti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì dúró tì í. Nígbà náà ni Saulu wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ó dúró tì í, pé, “Ǹjẹ́ ẹ gbọ́ ẹ̀yin ará Benjamini, ọmọ Jese yóò ha fún olúkúlùkù yín ni oko ọgbà àjàrà bí? Kí ó sì sọ gbogbo yin dì olórí ẹgbẹgbẹ̀rún àti olórí ọ̀rọ̀ọ̀rún bí? Tí gbogbo yín di ìmọ̀lù sí mi, tí kò sì sí ẹnìkan tí ó sọ létí mi pé, ọmọ mi ti bá ọmọ Jese mulẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kó sì sí ẹnìkan nínú yín tí ó ṣàánú mi, tí ó sì sọ ọ́ létí mi pé, ọmọ mi mú kí ìránṣẹ́ mi dìde sí mi láti ba dè mí, bí ó ti rí lónìí.”

Doegi ará Edomu tí a fi jẹ olórí àwọn ìránṣẹ́ Saulu, sì dáhùn wí pé, “Èmi rí ọmọ Jese, ó wá sí Nobu, sọ́dọ̀ Ahimeleki ọmọ Ahitubu. 10 Òun sì béèrè lọ́dọ̀ Olúwa fún un, ó sì fún un ní oúnjẹ, ó sí fún un ni idà Goliati ará Filistini.”

11 Ọba sì ránṣẹ́ pe Ahimeleki àlùfáà, ọmọ Ahitubu àti gbogbo ìdílé baba rẹ̀, àwọn àlùfáà tí ó wà ni Nobu: gbogbo wọn ni ó sì wá sọ́dọ̀ ọba. 12 Saulu sì wí pé, “Ǹjẹ́ gbọ́, ìwọ ọmọ Ahitubu.”

Òun sì wí pé, “Èmi nìyìí olúwa mi.”

13 Saulu sì wí fún un pé, “Kí ni ó dé tí ẹ̀yin fi ṣọ̀tẹ̀ sí mi, ìwọ àti ọmọ Jese, tí ìwọ fi fún un ní àkàrà, àti idà, àti ti ìwọ fi béèrè fún un lọ́dọ̀ Ọlọ́run kí òun lè dìde sí mi, láti ba dè mí, bí ó ti rí lónìí.”

14 Ahimeleki sì dá ọba lóhùn, ó sì wí pé, “Ta ni ó jẹ́ olóòtítọ́ nínú gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ bí Dafidi, ẹni tí ó jẹ́ àna ọba, ẹni tí ó ń gbọ́ tìrẹ, tí ó sì ni ọlá ní ilé rẹ. 15 Òní lèmi ó ṣẹ̀ṣẹ̀ máa béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run fún un bí? Kí èyí jìnnà sí mi: kí ọba má ṣe ka nǹkan kan sí ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́rùn, tàbí sí gbogbo ìdílé baba mi: nítorí pé ìránṣẹ́ rẹ̀ kò mọ̀kan nínú gbogbo nǹkan yìí, díẹ̀ tàbí púpọ̀.”

16 Ọba sì wí pé, “Ahimeleki, kíkú ni ìwọ yóò kú, ìwọ àti gbogbo ìdílé baba rẹ̀.”

17 Ọba sì wí fún àwọn aṣáájú ti máa ń sáré níwájú ọba, tí ó dúró tì í pé, “Yípadà kí ẹ sì pa àwọn àlùfáà Olúwa; nítorí pé ọwọ́ wọn wà pẹ̀lú Dafidi, àti nítorí pé wọ́n mọ ìgbà tí òun sá, wọn kò sì sọ ọ́ létí mi.”

Ṣùgbọ́n àwọn ìránṣẹ́ ọba kò sì jẹ́ fi ọwọ́ wọn lé àwọn àlùfáà Olúwa láti pa wọ́n.

18 Ọba sì wí fún Doegi pé, “Ìwọ yípadà, kí o sì pa àwọn àlùfáà!” Doegi ará Edomu sì yípadà, ó sì kọlu àwọn àlùfáà, ó sì pa wọ́n ní ọjọ́ náà, àrùnlélọ́gọ́rin (85) ènìyàn ti ń wọ aṣọ ọ̀gbọ̀ efodu. 19 Ó sì fi ojú idà pa ara Nobu, ìlú àwọn àlùfáà náà àti ọkùnrin àti obìnrin, ọmọ wẹ́wẹ́, àti àwọn tí ó wà lẹ́nu ọmú, àti màlúù, àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àti àgùntàn.

20 Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Ahimeleki ọmọ Ahitubu tí a ń pè ní Abiatari sì bọ́; ó sì sá àsálà tọ Dafidi lọ. 21 Abiatari sì fihan Dafidi pé Saulu pa àwọn àlùfáà Olúwa tán. 22 Dafidi sì wí fún Abiatari pé, “Èmi ti mọ̀ ní ọjọ́ náà, nígbà tí Doegi ará Edomu ti wà níbẹ̀ pé, nítòótọ́ yóò sọ fún Saulu: nítorí mi ni a ṣe pa gbogbo ìdílé baba rẹ. 23 Ìwọ jókòó níhìn-ín lọ́dọ̀ mi, má ṣe bẹ̀rù, nítorí pé ẹni ti ń wá ẹ̀mí mi, ó ń wá ẹ̀mí rẹ: Ṣùgbọ́n lọ́dọ̀ mi ni ìwọ ó wà ní àìléwu.”

Ìṣe àwọn Aposteli 13:26-43

26 (A)“Ará, ẹ̀yin ọmọ ìran Abrahamu, àti ẹ̀yin ti ó bẹ̀rù Ọlọ́run, àwa ni a rán ọ̀rọ̀ ìgbàlà yìí sí. 27 Nítorí àwọn tí ń gbé Jerusalẹmu, àti àwọn olórí wọn, nítorí tiwọn kò mọ̀ Jesu, tí wọn kò sì ní òye ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì, tí a ń kà ní ọjọọjọ́ ìsinmi fún wọn, kò yé wọn, wọ́n mú ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì yìí ṣẹ nípa dídá a lẹ́bi. 28 Àti bí wọn kò tilẹ̀ ti rí ọ̀ràn ikú sí i, síbẹ̀ wọn rọ Pilatu láti pa á. 29 Bí wọ́n ti mú nǹkan gbogbo ṣẹ ti a kọ̀wé nítorí rẹ̀, wọn sì sọ̀ ọ́ kalẹ̀ kúrò lórí igi, wọ́n sì tẹ́ ẹ sí ibojì. 30 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run jí i dìde kúrò nínú òkú, 31 o sì farahàn lọ́jọ́ púpọ̀ fún àwọn tí ó bá a gòkè láti Galili wá sí Jerusalẹmu, àwọn tí í ṣe ẹlẹ́rìí rẹ̀ nísinsin yìí fún àwọn ènìyàn.

32 “Àwa sì mú ìhìnrere wá fún yín pé: Ìlérí èyí tí Ọlọ́run ti ṣe fún àwọn baba wa, 33 (B)èyí ni Ọlọ́run ti mú ṣẹ fún àwa ọmọ wọn, nípa gbígbé Jesu dìde: Bí a sì ti kọ̀wé rẹ̀ nínú Saamu kejì pé:

“ ‘Ìwọ ni Ọmọ mi;
    lónìí ni mo bí ọ.’

34 (C)Àti ni tí pé Ọlọ́run jí i dìde kúrò nínú òkú, ẹni tí kì yóò tún padà sí ìbàjẹ́ mọ́, ó wí báyìí pé:

“ ‘Èmi ó fún yín ní ọ̀rẹ́ mímọ́ Dafidi, tí ó dájú.’

35 (D)Nítorí ó sì wí nínú Saamu mìíràn pẹ̀lú pé:

“ ‘Ìwọ kí yóò jẹ́ kí Ẹni Mímọ́ rẹ rí ìdíbàjẹ́.’

36 “Nítorí lẹ́yìn ìgbà ti Dafidi ti sin ìran rẹ tan nípa ìfẹ́ Ọlọ́run, ó sùn, a sì tẹ́ ẹ ti àwọn baba rẹ̀, ara rẹ̀ sì rí ìdíbàjẹ́. 37 Ṣùgbọ́n ẹni tí Ọlọ́run jí dìde kò rí ìdíbàjẹ́.

38 “Ǹjẹ́ kí ó yé yín, ará pé nípasẹ̀ Jesu yìí ni a ń wàásù ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ fún yín. 39 Nípa rẹ̀ ni a ń dá olúkúlùkù ẹni tí ó gbàgbọ́ láre kúrò nínú ohun gbogbo, tí a kò lè dá yín láre rẹ̀ nínú òfin Mose. 40 Nítorí náà, ẹ kíyèsára, kí èyí tí a ti sọ nínú ìwé àwọn wòlíì má ṣe dé bá yín pé:

41 (E)“ ‘Ẹ wò ó, ẹ̀yin ẹlẹ́gàn,
    kí ẹnu sì yà yín, kí a sì fẹ́ yín kù;
nítorí èmi ó ṣe ohun kan ní ọjọ́ yín,
    tí ẹ̀yin kò jẹ́ gbàgbọ́,
    bí a tilẹ̀ sọ fún yin.’ ”

42 Bí Paulu àti Barnaba sì ti ń jáde láti inú Sinagọgu, wọ́n bẹ̀bẹ̀ pé kí a sọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí i fún wọn lọ́jọ́ ìsinmi tí ń bọ̀. 43 Nígbà tí wọn sì jáde nínú Sinagọgu, ọ̀pọ̀ nínú àwọn Júù àti nínú àwọn olùfọkànsìn aláwọ̀ṣe Júù tẹ̀lé Paulu àti Barnaba, àwọn ẹni tí ó bá wọn sọ̀rọ̀ tí wọ́n sì rọ̀ wọ́n láti dúró nínú oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run.

Marku 3:19-35

19 (A)Àti Judasi Iskariotu, ẹni tí ó fi í hàn níkẹyìn.

Jesu àti Beelsebulu

20 (B)Nígbà náà ni Jesu sì wọ inú ilé kan, àwọn èrò sì tún kórajọ, tó bẹ́ẹ̀ tí Òun àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kò rí ààyè láti jẹun. 21 (C)Nígbà tí àwọn ẹbí rẹ̀ gbọ́ èyí, wọ́n wá láti mú un lọ ilé, nítorí tí wọn wí pé, “Orí rẹ̀ ti dàrú.”

22 (D)(E) Àwọn olùkọ́ni ní òfin sọ̀kalẹ̀ wá láti Jerusalẹmu, wọ́n sì wí pé, “Ó ni Beelsebulu, olórí àwọn ẹ̀mí èṣù, ni ó sì fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde!”

23 Jesu pè wọ́n, ó sì fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀: “Báwo ni Èṣù ṣe lè lé èṣù jáde? 24 Bí ìjọba kan bá yapa sí ara rẹ̀, ìjọba náà yóò wó lulẹ̀. 25 Bákan náà, bí ilé kan bá sì yapa sí ara rẹ, ilé náà kí yóò le è dúró. 26 Bí Èṣù bá sì dìde sí ara rẹ̀, tí ó sì yapa, òun kí yóò le è dúró ṣùgbọ́n òpin rẹ̀ yóò dé. 27 (F)Kò sí ẹni tí ó le wọ ilé ọkùnrin alágbára kan lọ, kí ó sì kó o ní ẹrù lọ, bí kò ṣe pé ó kọ́kọ́ de ọkùnrin alágbára náà ní okùn, nígbà náà ni yóò lè kó ẹrù ní ilé rẹ̀. 28 (G)Lóòótọ́ ní mo wí fún yín, gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ni a ó dáríjì àwọn ọmọ ènìyàn, àti gbogbo ọ̀rọ̀-òdì. 29 Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá sọ̀rọ̀-òdì sí Ẹ̀mí Mímọ́, kì yóò rí ìdáríjì títí ayé, ṣùgbọ́n ó wà nínú ewu ẹ̀bi àìnípẹ̀kun.”

30 Òun sọ eléyìí fún wọn, nítorí tí wọ́n sọ pé, “Nípa agbára ẹ̀mí àìmọ́ ló ń ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu rẹ̀.”

Ìyá àti àwọn Arákùnrin Jesu

31 (H)Nígbà náà ni àwọn arákùnrin rẹ̀ àti ìyá wá, wọ́n dúró lóde, wọ́n sì ránṣẹ́ sí i, wọ́n ń pè é. 32 Àwọn ènìyàn tí wọ́n jókòó lọ́dọ̀ rẹ̀ sì wí fún un pé, “Ìyá àti àwọn arákùnrin rẹ wà lóde.”

33 Ṣùgbọ́n ó dá wọn lóhùn wí pé, “Ta ni í ṣe ìyá mi tàbí àwọn arákùnrin mi?”

34 Ó sì wò gbogbo àwọn tí ó jókòó lọ́dọ̀ rẹ̀ yíká, ó sì wí pé, “Àwọn wọ̀nyí ni ìyá mi àti àwọn arákùnrin mi: 35 Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, òun ni arákùnrin mi àti arábìnrin mi àti ìyá mi.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.