Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 106

106 (A)Yin Olúwa! Ẹ fi ìyìn fún
    Olúwa, nítorí tí ó ṣeun.

Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa nítorí tí ó ṣeun;
    Nítorí tí ìfẹ́ rẹ̀ dúró láéláé.

Ta ni ó lè ròyìn iṣẹ́ agbára Olúwa,
    ta ní lè sọ nípa ìyìn rẹ̀?
Ìbùkún ni fún àwọn tí ń pa ìdájọ́ mọ́?
    Ẹni tí n ṣe ohun tí ó tọ́.

Rántí mi, Olúwa,
    Nígbà tí o bá fi ojúrere rẹ hàn,
    wá sí ìhà mi nígbà tí ìwọ bá gbà wọ́n,
Kí èmi kí ó lè jẹ ìgbádùn àlàáfíà àwọn tí ìwọ ti yàn,
    kí èmi kí ó sì darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn,
    ìní rẹ láti jọ yìn ọ́ lógo.

Àwa ti dẹ́ṣẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wa ti ṣe,
    àwa ti ṣe ohun tí kò dá a,
    a sì ti hùwà búburú
Nígbà tí àwọn baba wa wà ní Ejibiti,
    iṣẹ́ ìyanu rẹ kò yé wọn,
wọn kò rántí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àánú rẹ,
    gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ṣọ̀tẹ̀ sí ọ níbi Òkun, àní níbi Òkun pupa
Ṣùgbọ́n o gbà wọ́n là nítorí orúkọ rẹ
    láti jẹ́ kí agbára ńlá rẹ di mí mọ̀
O bá Òkun pupa wí, ó sì gbẹ;
    o sì mú wọn la ìbú já bí aginjù
10 O gbà wọ́n là kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn
    láti ọwọ́ ọ̀tá ni o ti gbà wọ́n
11 Omi ya lu àwọn ọ̀tá wọn, bẹ́ẹ̀ ni
    kò sí èyí tí ó yè nínú wọn.
12 Nígbà náà wọn gba ìpinnu rẹ gbọ́
    wọ́n sì kọrin ìyìn rẹ.

13 Ṣùgbọ́n wọn kò pẹ́ gbàgbé ohun tí o ṣe
    wọn kò sí dúró gba ìmọ̀ràn rẹ
14 Nínú aginjù ni wọ́n tí ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́
    nínú aṣálẹ̀, wọ́n dán Ọlọ́run wò
15 Nígbà náà, ó fún wọn ní ohun tí wọ́n béèrè fún
    ṣùgbọ́n ó rán àìsàn búburú sí wọn.

16 Nínú ibùdó ni wọ́n ṣe ìlara Mose
    pẹ̀lú Aaroni, ẹni tí ó jẹ́ mímọ́ sí Olúwa.
17 Ilẹ̀ la ẹnu ó sì gbé Datani mì
    ó bo ẹgbẹ́ Abiramu mọ́lẹ̀
18 Ọwọ́ iná yọ ní ẹgbẹ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀;
    iná jo àwọn ènìyàn búburú.
19 Ní Horebu wọ́n ṣe ẹgbọrọ màlúù
    wọ́n sì sin òrìṣà tí a ṣe láti ara irin.
20 Wọ́n pa ògo wọn dà
    sí àwòrán màlúù, tí ń jẹ koríko.
21 Wọ́n gbàgbé Ọlọ́run, ẹni tí ó gbà wọ́n
    ẹni tí ó ti ṣe ohun ńlá ní Ejibiti,
22 Iṣẹ́ ìyanu ní ilẹ̀ Hamu
    àti ohun ẹ̀rù ni ẹ̀bá Òkun pupa
23 Bẹ́ẹ̀ ni, ó sọ wí pé, òun yóò pa wọ́n run
    bí kò bá ṣe ti Mose, tí ó yàn,
tí ó dúró níwájú ẹ̀yà náà
    tí ó pa ìbínú rẹ̀ mọ́ láti má pa wọ́n run mọ́.

24 Nígbà náà, wọ́n kẹ́gàn ilẹ̀ dídára náà
    wọn kò gba ìlérí rẹ̀ gbọ́.
25 Wọ́n ń kùn nínú àgọ́ wọn
    wọn kò sì gbọ́rọ̀ sí Olúwa.
26 Bẹ́ẹ̀ ni ó búra fún wọn nípa gbígbé ọwọ́ rẹ̀ sókè
    kí òun lè jẹ́ kí wọn ṣubú nínú aginjù,
27 Láti jẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ̀ ṣubú lára orílẹ̀-èdè
    láti fọ́n wọn káàkiri lórí ilẹ̀.

28 Wọ́n da ara wọn pọ̀ mọ́ Baali-Peori,
    wọ́n sì ń jẹ ẹbọ tí a rú sí àwọn òkú òrìṣà
29 Wọ́n mú Ọlọ́run bínú pẹ̀lú ohun búburú tí wọn ń ṣe
    àjàkálẹ̀-ààrùn jáde láàrín wọn.
30 Ṣùgbọ́n Finehasi dìde láti dá sí i,
    àjàkálẹ̀-ààrùn náà sì dáwọ́ dúró lọ́gán
31 A sì ka èyí sí òdodo fún un àti
    fún àwọn ìrandíran tí ń bọ̀
32 Níbi omi Meriba, wọ́n bí Ọlọ́run nínú,
    ohun búburú wá sí orí Mose nítorí wọn.
33 Nítorí tí wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí ẹ̀mí Ọlọ́run.
    Ọ̀rọ̀ àìdára sì ti ẹnu Mose wá.

34 Wọn kò pa àwọn ènìyàn run
    gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti sọ fún wọn,
35 Ṣùgbọ́n wọ́n dàpọ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀-èdè,
    wọ́n sì gbà láti ṣe bí àṣà wọn
36 Wọ́n sì sin àwọn òrìṣà wọn
    tí ó di ìkẹ́kùn fún wọn.
37 Wọ́n fi àwọn ọmọkùnrin wọn rú ẹbọ
    àti àwọn ọmọbìnrin fún òrìṣà.
38 Wọ́n ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀.
    Ẹ̀jẹ̀ àwọn ọmọkùnrin àti àwọn
ọmọbìnrin wọn.
    Wọ́n fi wọ́n rú ẹbọ sí ère Kenaani, ilẹ̀ náà sì di àìmọ́ fún ẹ̀jẹ̀
39 Wọ́n sì fi ìṣe wọn sọ ara wọn di aláìmọ́,
    wọ́n sì ṣe àgbèrè lọ pẹ̀lú iṣẹ́ wọn.

40 Nígbà náà ni Olúwa bínú sí àwọn ènìyàn rẹ̀
    ó sì kórìíra àwọn ènìyàn ìní rẹ̀
41 Ó sì fà wọ́n lé àwọn orílẹ̀-èdè lọ́wọ́,
    àwọn ọ̀tá wọn sì jẹ ọba lórí wọn.
42 Àwọn ọ̀tá wọn sì ń pọ́n wọn lójú
    wọn sì mú wọn sìn lábẹ́ àṣẹ wọn.
43 Ní ọ̀pọ̀ ìgbà òun gbà wọ́n,
    Síbẹ̀ wọ́n sì ń ṣọ̀tẹ̀ sí i
    wọ́n sì ṣòfò dànù nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
44 Ṣùgbọ́n ó kíyèsi wọn nítorí ìṣòro
    nígbà tí ó gbọ́ ẹkún wọn;
45 Ó rántí májẹ̀mú rẹ̀ nítorí wọn
    Nítorí agbára ìfẹ́ rẹ̀, ó ṣàánú wọn.
46 Lójú gbogbo àwọn tí ó kó wọn ní ìgbèkùn
    ó mú wọn rí àánú.

47 (B)Gbà wá, Olúwa Ọlọ́run wa,
    kí o sì ṣà wá jọ kúrò láàrín àwọn kèfèrí,
láti máa fi ọpẹ́ fún orúkọ mímọ́ rẹ
    láti máa ṣògo nínú ìyìn rẹ.

48 Olùbùkún ni Olúwa,
    Ọlọ́run Israẹli, láti ìrandíran.

Jẹ́ kí gbogbo ènìyàn kí ó wí pé, “Àmín!”

Ẹ fi ìyìn fún Olúwa!

1 Samuẹli 10:17-27

17 Samuẹli pé àwọn ọmọ Israẹli jọ sí iwájú Olúwa ní Mispa. 18 Ó sì wí fún wọn pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Israẹli sọ: ‘Èmi mú Israẹli jáde wá láti Ejibiti, Èmi sì gbà yín kúrò lọ́wọ́ agbára Ejibiti àti gbogbo ìjọba tí ó ń pọ́n ọn yín lójú.’ 19 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti kọ Ọlọ́run yín, tí ó gbà yín kúrò nínú gbogbo wàhálà àti ìpọ́njú yín. Ẹ̀yin sì ti sọ pé, ‘Rárá, yan ọba kan fún wa.’ Báyìí, ẹ kó ara yín jọ níwájú Olúwa ní ẹ̀yà àti ìdílé yín.”

20 Nígbà tí Samuẹli mú gbogbo ẹ̀yà Israẹli súnmọ́ tòsí, ó yan ẹ̀yà Benjamini. 21 Ó kó ẹ̀yà Benjamini síwájú ní ìdílé ìdílé, a sì yan ìdílé Matiri. Ní ìparí a sì yan Saulu ọmọ Kiṣi. Ṣùgbọ́n ní ìgbà tí wọ́n wá a, a kò rí i, 22 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ìwádìí lọ́wọ́ Olúwa pé, “Ṣé ọkùnrin náà ti wá sí bí ni?”

Olúwa sì sọ pé, “Bẹ́ẹ̀ ni ó ti fi ara rẹ̀ pamọ́ láàrín àwọn ẹrù.”

23 Wọ́n sáré, wọ́n sì mú un jáde wá. Bí ó ti dúró láàrín àwọn ènìyàn, ó sì ga ju gbogbo àwọn tí ó kù lọ láti èjìká rẹ̀ sókè. 24 Samuẹli sọ fún gbogbo àwọn ènìyàn pé, “Ṣé ẹ ti ri ọkùnrin tí Olúwa ti yàn? Kò sí ẹnìkan bí i rẹ̀ láàrín gbogbo àwọn ènìyàn.”

Nígbà náà àwọn ènìyàn kígbe pé, “Kí ẹ̀mí ọba kí ó gùn!”

25 Samuẹli ṣàlàyé fún àwọn ènìyàn àwọn ìlànà ìjọba. Ó kọ wọ́n sínú ìwé, ó sì fi lélẹ̀ níwájú Olúwa. Lẹ́yìn náà, Samuẹli tú àwọn ènìyàn ká olúkúlùkù sí ilé e rẹ̀.

26 Saulu náà padà sí ilé e rẹ̀ ní Gibeah. Àwọn akọni ọkùnrin tí Ọlọ́run ti fi ọwọ́ tọ́ ọkàn wọ́n sì sìn ín. 27 Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Beliali wí pé, “Báwo ni ọkùnrin yìí yóò ti ṣe gbà wá?” Wọ́n kẹ́gàn rẹ̀, wọn kò sì mú ẹ̀bùn wá fún un, ṣùgbọ́n Saulu fọwọ́ lérán.

Ìṣe àwọn Aposteli 7:44-8:1

44 (A)“Àwọn baba wa ní àgọ́ ẹ̀rí pẹ̀lú wọn ní ijù. Èyí tí a ṣe gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run tí ó ba Mose sọ̀rọ̀ pé kí ó ṣe é, gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ tí ó ti rí. 45 (B)Ti àwọn baba wa tí ó tẹ̀lé wọn sí mú bá Joṣua wá sí ilẹ̀ ìní àwọn aláìkọlà, tí Ọlọ́run lè jáde kúrò níwájú àwọn baba wa, títí dí àkókò Dafidi. 46 (C)Ẹni tí ó rí ojúrere níwájú Ọlọ́run, tí ó sì tọrọ láti rí ibùgbé fún Ọlọ́run Jakọbu. 47 (D)Ṣùgbọ́n Solomoni ni ó kọ́ ilé fún un.

48 “Ṣùgbọ́n Ọ̀gá-ògo kì í gbé ilé ti a fi ọwọ́ kọ́: gẹ́gẹ́ bí wòlíì ti wí pé:

49 (E)“ ‘Ọ̀run ni ìtẹ́ mi,
    ayé ni àpótí ìtìsẹ̀ mi.
Irú ilé kín ní ẹ̀yin yóò kọ́ fún mi?
    ni Olúwa wí.
    Tàbí níbo ni yóò jẹ́ ibi ìsinmi mi?
50 Ọwọ́ mi kò ha ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí.’

51 (F)“Ẹ̀yin ọlọ́rùn líle àti aláìkọlà àyà àti etí! Bí àwọn baba yín gẹ́lẹ́ ni ẹ̀yin rí: Nígbà gbogbo ni ẹ̀yin máa ń dènà Ẹ̀mí Mímọ́! 52 Ǹjẹ́ ọ̀kan tilẹ̀ wà nínú àwọn wòlíì tí àwọn baba yín kò ṣe inúnibíni sí? Wọn sì ti pa àwọn ti ó ti ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa wíwá Ẹni Olódodo náà. Nísinsin yìí ẹ̀yin ti dalẹ̀ rẹ̀ ẹ̀yin sí ti pa. 53 Ẹ̀yin tí ó gba òfin, gẹ́gẹ́ bí àwọn angẹli ti fi fún ni, tí ẹ kò sì pa á mọ́.”

A sọ Stefanu ní òkúta pa

54 Nígbà tí wọn sì gbọ́ nǹkan wọ̀nyí ọkàn wọn gbọgbẹ́ dé inú, wọn sì payínkeke sí i. 55 Ṣùgbọ́n Stefanu, ẹni tí ó kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, ó tẹjúmọ́ ọ̀run, ó sì rí ògo Ọlọ́run, àti Jesu dúró ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run. 56 Ó sì wí pé, “Wò ó, mo rí ọ̀run ṣí sílẹ̀, Ọmọ Ènìyàn sì dúró ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run.”

57 Nígbà náà ni wọn kígbe ní ohùn rara, wọn sí di etí wọ́n, gbogbo wọn sì sáré sí i, wọ́n sì rọ́ lù ú, 58 wọ́n sì wọ́ ọ sẹ́yìn òde ìlú, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sísọ ọ́ ní òkúta; àwọn ẹlẹ́rìí sì fi aṣọ wọn lélẹ̀ lẹ́sẹ̀ ọmọkùnrin kan tí a ń pè ní Saulu.

59 Bí wọ́n ti ń sọ Stefanu ní òkúta, ó sì ké pe Olúwa wí pé, “Jesu Olúwa, gba ẹ̀mí mi.” 60 Nígbà náà ni ó wólẹ̀ lórí eékún rẹ̀, ó kígbe sókè pé, “Olúwa, má ṣe ka ẹ̀ṣẹ̀ yìí sí wọn ní ọrùn.” Nígbà ti ó sì wí èyí tán, ó sùn lọ.

(G)Saulu sì wà níbẹ̀, ó sì fi àṣẹ sí ikú rẹ̀.

Wọ́n ṣe inúnibíni sí ìjọ, wọ́n sì túká

Ní àkókò náà, inúnibíni ńlá kan dìde sí ìjọ tí ó wà ni Jerusalẹmu, gbogbo wọn sì túká káàkiri agbègbè Judea àti Samaria, àyàfi àwọn aposteli.

Luku 22:52-62

52 Jesu wí fún àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn olórí ẹ̀ṣọ́ tẹmpili, àti àwọn alàgbà, tí wọ́n jáde tọ̀ ọ́ wá pé, “Ẹ̀yin ha jáde wá pẹ̀lú idà àti ọ̀kọ̀ bí ẹni tọ ọlọ́ṣà wá? 53 (A)Nígbà tí èmi wà pẹ̀lú yín lójoojúmọ́ ní tẹmpili, ẹ̀yin kò na ọwọ́ mú mi: ṣùgbọ́n àkókò tiyín ni èyí, àti agbára òkùnkùn n jẹ ọba.”

Peteru sẹ́ Jesu

54 (B)Wọ́n sì gbá a mú, wọ́n sì fà á lọ, wọ́n sì mú un wá sí ilé olórí àlùfáà. Ṣùgbọ́n Peteru tọ̀ ọ́ lẹ́yìn ní òkèrè. 55 Nígbà tí wọ́n sì ti dáná láàrín àgbàlá, tí wọ́n sì jókòó pọ̀, Peteru jókòó láàrín wọn. 56 (C)Ọmọbìnrin kan sì rí i bí ó ti jókòó níbi ìmọ́lẹ̀ iná náà, ó sì tẹjúmọ́ ọn, ó ní, “Eléyìí náà wà pẹ̀lú rẹ̀.”

57 Ṣùgbọ́n, ó wí pé, “Obìnrin yìí, èmi kò mọ̀ ọ́n.”

58 Kò pẹ́ lẹ́yìn náà ẹlòmíràn sì rí i, ó ní, “Ìwọ pẹ̀lú wà nínú wọn.”

Ṣùgbọ́n Peteru wí pé, “Ọkùnrin yìí, èmi kọ́.”

59 Ó sì tó bí i wákàtí kan síbẹ̀ ẹlòmíràn tẹnumọ́ ọn, wí pé, “Nítòótọ́ eléyìí náà wà pẹ̀lú rẹ̀: nítorí ará Galili ní í ṣe.”

60 Ṣùgbọ́n Peteru wí pé, “Ọkùnrin yìí, èmi kò mọ ohun tí ìwọ ń wí!” Lójúkan náà, bí ó tí ń wí lẹ́nu, àkùkọ kọ! 61 (D)Olúwa sì yípadà, ó wo Peteru. Peteru sì rántí ọ̀rọ̀ Olúwa, bí ó ti wí fún un pé, “Kí àkùkọ tó kọ, ìwọ ó sẹ́ mi lẹ́ẹ̀mẹ́ta.” 62 Peteru sì bọ́ sí òde, ó sọkún kíkorò.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.