Book of Common Prayer
105 (A)Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, ké pe orúkọ rẹ̀:
Jẹ́ kí a mọ ohun tí ó ṣe láàrín àwọn orílẹ̀-èdè;
2 Kọrin sí i, kọrin ìyìn sí i;
sọ ti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ gbogbo.
3 Ṣògo nínú orúkọ mímọ́ rẹ̀:
Jẹ́ kí ọkàn àwọn tí ń wá Olúwa kí ó yọ̀.
4 Wá Olúwa àti ipá rẹ̀;
wa ojú rẹ̀ nígbà gbogbo.
5 Rántí àwọn ìyanu tí ó ti ṣe,
ìyanu rẹ̀, àti ìdájọ́ tí ó sọ,
6 Ẹ̀yin ìran Abrahamu ìránṣẹ́ rẹ̀,
ẹ̀yin ọmọkùnrin Jakọbu, àyànfẹ́ rẹ̀.
7 Òun ni Olúwa Ọlọ́run wa:
ìdájọ́ rẹ̀ wà ní gbogbo ayé.
8 (B)Ó rántí májẹ̀mú rẹ̀ láéláé,
ọ̀rọ̀ tí ó pàṣẹ, fún ẹgbẹgbẹ̀rún ìran,
9 májẹ̀mú tí ó dá pẹ̀lú Abrahamu,
ìbúra tí ó ṣe pẹ̀lú fún Isaaki.
10 Ó ṣe ìdánilójú u rẹ̀ fún Jakọbu gẹ́gẹ́ bí àṣẹ
sí Israẹli, gẹ́gẹ́ bi májẹ̀mú ayérayé:
11 “Fún ìwọ ni èmi ó fún ní ilẹ̀ Kenaani
gẹ́gẹ́ bí ìpín tí ìwọ ó jogún.”
12 Nígbà tí wọn kéré níye,
wọ́n kéré jọjọ, àti àwọn àjèjì níbẹ̀
13 wọ́n rìn kiri láti orílẹ̀-èdè sí orílẹ̀-èdè,
láti ìjọba kan sí èkejì.
14 Kò gba ẹnikẹ́ni láààyè láti pọ́n wọn lójú;
ó fi ọba bú nítorí tiwọn:
15 “Má ṣe fọwọ́ kan ẹni ààmì òróró mi, má sì ṣe wòlíì mi níbi.”
16 Ó pe ìyàn sórí ilẹ̀ náà
ó sì pa gbogbo ìpèsè oúnjẹ wọn run;
17 Ó sì rán ọkùnrin kan síwájú wọn
Josẹfu tí a tà gẹ́gẹ́ bí ẹrú.
18 Wọn fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ bọ ẹsẹ̀ rẹ̀
a gbé ọrùn rẹ̀ sínú irin
19 Títí ọ̀rọ̀ tí ó sọtẹ́lẹ̀ fi ṣẹ
títí ọ̀rọ̀ Olúwa fi dá a láre.
20 Ọba ránṣẹ́ lọ tú u sílẹ̀
àwọn aláṣẹ ènìyàn tú u sílẹ̀
21 Ó fi jẹ olúwa lórí ilẹ̀ rẹ̀
aláṣẹ lórí ohun gbogbo tí ó ní,
22 Gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀, kí ó máa
ṣe àkóso àwọn ọmọ-aládé
kí ó sì kọ́ àwọn àgbàgbà rẹ̀ ní ọgbọ́n.
23 Israẹli wá sí Ejibiti;
Jakọbu sì ṣe àtìpó ní ilé Hamu.
24 Olúwa, sì mú àwọn ọmọ rẹ̀ bí sí i
ó sì mú wọn lágbára jù
àwọn ọ̀tá wọn lọ
25 Ó yí wọn lọ́kàn padà láti kórìíra àwọn ènìyàn
láti ṣe àrékérekè sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.
26 Ó rán Mose ìránṣẹ́ rẹ̀
àti Aaroni tí ó ti yàn
27 Wọ́n ń ṣe iṣẹ́ ìyanu láàrín wọn
ó ṣe iṣẹ́ ìyanu ní Hamu.
28 Ó rán òkùnkùn, o sì mú ilẹ̀ ṣú
wọn kò sì sọ̀rọ̀-òdì sí ọ̀rọ̀ rẹ̀.
29 Ó sọ omi wọn di ẹ̀jẹ̀,
ó pa ẹja wọn.
30 Ilẹ̀ mú ọ̀pọ̀lọ́ jáde wá,
èyí tí ó lọ sí ìyẹ̀wù àwọn ọba wọn.
31 Ó sọ̀rọ̀, onírúurú eṣinṣin sì dìde,
ó sì hu kantíkantí ní ilẹ̀ wọn
32 Ó sọ òjò di yìnyín,
àti ọ̀wọ́-iná ní ilẹ̀ wọn;
33 Ó lu àjàrà wọn àti igi ọ̀pọ̀tọ́ wọn
ó sì dá igi orílẹ̀-èdè wọn.
34 Ó sọ̀rọ̀, eṣú sì dé,
àti kòkòrò ní àìníye,
35 Wọn sì jẹ gbogbo ewé ilẹ̀ wọn,
wọ́n sì jẹ èso ilẹ̀ wọn run
36 Nígbà náà, ó kọlu gbogbo àwọn ilẹ̀ wọn,
ààyò gbogbo ipá wọn.
37 Ó mú Israẹli jáde
ti òun ti fàdákà àti wúrà,
nínú ẹ̀yà rẹ̀ kò sí aláìlera kan.
38 Inú Ejibiti dùn nígbà tí wọn ń lọ,
nítorí ẹ̀rù àwọn Israẹli ń bá wọ́n.
39 Ó ta àwọsánmọ̀ fún ìbòrí,
àti iná láti fún wọn ní ìmọ́lẹ̀ lálẹ́
40 Wọn béèrè, ó sì mú ẹyẹ àparò wá,
ó sì fi oúnjẹ ọ̀run tẹ́ wọn lọ́rùn.
41 Ó sì la àpáta, ó sì mú omi jáde;
gẹ́gẹ́ bí odò tí ń sàn níbi gbígbẹ.
42 Nítorí ó rántí ìlérí mímọ́ rẹ̀
àti Abrahamu ìránṣẹ́ rẹ̀.
43 Ó sì fi ayọ̀ mú àwọn ènìyàn rẹ̀ jáde
pẹ̀lú ayọ̀ ní ó yan àyànfẹ́ rẹ̀
44 Ó fún wọn ní ilẹ̀ ìní náà,
wọ́n sì jogún iṣẹ́ àwọn ènìyàn náà,
45 Kí wọn kí ó lè máa pa àṣẹ rẹ̀ mọ́
kí wọn kí ó lè kíyèsi òfin rẹ̀.
Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
Israẹli béèrè fún ọba
8 Nígbà tí Samuẹli di arúgbó, ó yan àwọn ọmọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí adájọ́ fún Israẹli. 2 Orúkọ àkọ́bí rẹ̀ a máa jẹ́ Joeli àti orúkọ èkejì a máa jẹ́ Abijah, wọ́n ṣe ìdájọ́ ní Beerṣeba. 3 Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ rẹ̀, kò rìn ní ọ̀nà rẹ̀. Wọ́n yípadà sí èrè àìṣòótọ́, wọ́n gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, wọ́n sì ń yí ìdájọ́ po.
4 Bẹ́ẹ̀ ni, gbogbo àwọn àgbàgbà ti Israẹli péjọpọ̀, wọ́n sì wá sọ́dọ̀ Samuẹli ní Rama. 5 Wọ́n wí fún un pé, “Ìwọ ti di arúgbó, àwọn ọmọ rẹ kò sì rìn ní ọ̀nà rẹ: Nísinsin yìí, yan ọba fún wa kí ó lè máa darí wa gẹ́gẹ́ bí i tí gbogbo orílẹ̀-èdè.”
6 Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n wí pé, “Fún wa ní ọba tí yóò darí wa” Èyí kò tẹ́ Samuẹli lọ́rùn, ó sì gbàdúrà sí Olúwa. 7 Olúwa sì sọ fún Samuẹli pé: “Gbọ́ ohùn àwọn ènìyàn náà, ní gbogbo èyí tí wọ́n sọ fún ọ; nítorí kì í ṣe ìwọ ni wọ́n kọ̀, ṣùgbọ́n Èmi ni wọ́n kọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba lórí wọn. 8 Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe ní ọjọ́ tí mo mú wọn jáde wá láti Ejibiti títí di ọjọ́ òní, wọ́n kọ̀ mí sílẹ̀, wọ́n sì ń sin ọlọ́run mìíràn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń ṣe sí ọ. 9 Nísinsin yìí, gbọ́ tiwọn; ṣùgbọ́n kìlọ̀ fún wọn dáradára, kí o sì jẹ́ kí wọ́n mọ irú ohun tí ọba tí yóò jẹ́ lórí wọn yóò ṣe.”
10 Samuẹli sọ gbogbo ọ̀rọ̀ Olúwa sí àwọn ọmọ ènìyàn tí ó ń béèrè fún ọba lọ́wọ́ rẹ̀. 11 Ó wí pé, “Èyí ni ohun tí ọba tí yóò jẹ lórí yín yóò ṣe. Yóò kó àwọn ọmọkùnrin yín, yóò sì mú wọn ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ àti fún ẹlẹ́ṣin rẹ, wọn yóò sì máa sáré níwájú kẹ̀kẹ́ rẹ̀. 12 Yóò yan díẹ̀ láti jẹ́ olórí ẹgbẹ̀rún àti olórí àádọ́ta àti àwọn mìíràn. Yóò yan wọ́n láti máa tulẹ̀ oko rẹ̀ àti láti máa kórè rẹ̀ àti àwọn mìíràn láti máa ṣe ohun èlò ogun àti ohun èlò kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀. 13 Yóò mú àwọn ọmọbìnrin yín láti máa ṣe olùṣe ìkunra olóòórùn dídùn àti láti máa ṣe àsè àti láti máa ṣe àkàrà. 14 Yóò mú èyí tí ó dára jù nínú oko yín, àti nínú ọgbà àjàrà yín àti nínú igi olifi yín, yóò sì fi wọ́n fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀. 15 Yóò mú ìdásímẹ́wàá hóró ọkà yín àti àká èso àjàrà yín, yóò sì fi fún àwọn oníṣẹ́ àti ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀. 16 Àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin yín àti èyí tí ó dára jù nínú ẹran ọ̀sìn àti àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ yín ni yóò mú fún ìlò ti ara rẹ̀. 17 Yóò sì mú ìdámẹ́wàá nínú àwọn agbo ẹran yín, yóò sì máa ṣe ẹrú u rẹ̀. 18 Tí ọjọ́ náà bá dé, ẹ̀yin yóò kígbe fún ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ ọba tí ẹ̀yin ti yàn. Olúwa kò sì ní dá a yín lóhùn ní ọjọ́ náà.”
19 Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn náà kọ̀ láti tẹ́tí sí Samuẹli wọ́n wí pé, “Rárá! A bí ìwọ fẹ́ jẹ́ ọba lórí i wa? 20 Nígbà náà àwa yóò dàbí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, pẹ̀lú ọba láti darí i wa àti láti jáde lọ níwájú wa láti ja ogun wa.”
21 Nígbà tí Samuẹli gbọ́ gbogbo ohun tí àwọn ènìyàn sọ, ó tún tún un sọ níwájú Olúwa. 22 Olúwa dáhùn pé, “Tẹ́tí sí wọn, kí o sì yan ọba fún wọn.”
Nígbà náà, Samuẹli sọ fún àwọn ọkùnrin Israẹli pé, “Kí olúkúlùkù padà sí ìlú u rẹ̀.”
15 Gbogbo àwọn tí ó sì jókòó ni àjọ ìgbìmọ̀ tẹjúmọ́ Stefanu, wọ́n sì rí ojú rẹ̀ dàbí ojú angẹli.
Ọ̀rọ̀ Stefanu sí àwọn àjọ ìgbìmọ̀
7 Nígbà náà ni olórí àlùfáà wí pé, “Òtítọ́ ha ni àwọn ẹ̀sùn tí wọ́ fi kàn ọ́ bí?”
2 (A)Ní ìdáhùn sí èyí ó wí pé, “Ẹ̀yin arákùnrin àti ẹ̀yin baba, ẹ fetísílẹ̀ sí mi! Ọlọ́run ògo fi ara hàn fún Abrahamu baba wa, nígbà tí ó wà ni Mesopotamia, kí ó to ṣe àtìpó ni Harani. 3 (B)Ọlọ́run wí fún un pé, ‘Jáde kúrò ní orílẹ̀-èdè rẹ àti kúrò lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ, lọ sí ilẹ̀ kan tí èmi yóò fihàn ọ́.’
4 (C)“Nígbà náà ni ó jáde kúrò ní ilẹ̀ àwọn ará Kaldea, ó sì ṣe àtìpó ni Harani. Lẹ́yìn ìgbà tí baba rẹ̀ sì kú, Ọlọ́run mú un sípò padà wá sí ilẹ̀ yìí, níbi tí ẹ̀yin ń gbé báyìí. 5 (D)Kò sí fún un ni ìní kan, ànító bi ìwọ̀n ààyè ẹsẹ̀ kan. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ṣe ìlérí fún pé, òun yóò fi ilẹ̀ ìní náà fún un àti fún àwọn irú-ọmọ rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀, nígbà tí kò tí ì ní ọmọ. 6 (E)Ọlọ́run sì sọ báyìí pé: ‘Irú-ọmọ rẹ yóò ṣe àtìpó ní ilẹ̀ àjèjì; wọn ó sì sọ wọn di ẹrú, wọn ó sì pọ́n wọn lójú fún irínwó ọdún (400). 7 (F)Ọlọ́run wí pé, Orílẹ̀-èdè náà tí wọn yóò máa sìn, ni èmi ó dá lẹ́jọ́; lẹ́yìn náà ni wọn ó sì jáde kúrò, wọn ó sì wá sìn mí níhìn-ín yìí.’ 8 (G)Ó sì fún Abrahamu ni májẹ̀mú ìkọlà. Abrahamu bí Isaaki, ó kọ ọ́ ní ilà ni ọjọ́ kẹjọ tí ó bí i. Isaaki sí bí Jakọbu, Jakọbu sì bí àwọn baba ńlá méjìlá.
9 (H)(I) “Àwọn baba ńlá sí ṣe ìlara Josẹfu, wọ́n sì tà á sí Ejibiti; ṣùgbọ́n Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀, 10 (J)ó sì yọ ọ́ kúrò nínú ìpọ́njú rẹ̀ gbogbo. Ó sì fún Josẹfu ní ọgbọ́n, ó sì mú kí ó rí ojúrere Farao ọba Ejibiti; òun sì fi jẹ baálẹ̀ Ejibiti àti gbogbo ilé rẹ̀.
11 (K)“Ìyàn kan sì mú ni gbogbo ilẹ̀ Ejibiti àti ni Kenaani, àti ìpọ́njú ńlá, àwọn baba wa kò sì rí oúnjẹ. 12 (L)Ṣùgbọ́n nígbà tí Jakọbu gbọ́ pé alikama ń bẹ ni Ejibiti, ó rán àwọn baba wa lọ lẹ́ẹ̀kínní. 13 (M)Nígbà kejì Josẹfu fi ara rẹ̀ hàn fún àwọn arákùnrin rẹ̀, a sì tún fi wọ́n hàn fún Farao. 14 (N)(O)Lẹ́yìn èyí, Josẹfu ránṣẹ́ pe Jakọbu baba rẹ̀, àti àwọn ìbátan rẹ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ, gbogbo wọ́n sì tó àrùndínlọ́gọ́rin ọkàn. 15 Nígbà náà ni Jakọbu sọ̀kalẹ̀ lọ sí Ejibiti, ní ibi tí òun àti àwọn baba wa kú sí. 16 (P)A sì gbé òkú wọn padà wá sí Ṣekemu, a sì tẹ́ wọn sínú ibojì ti Abrahamu rà ni ọwọ́ àwọn ọmọ Amori ní Ṣekemu ní iye owó wúrà kan.
24 (A)Ìjà kan sì ń bẹ láàrín wọn, ní ti ẹni tí a kà sí olórí nínú wọn. 25 (B)Ó sì wí fún wọn pé, “Àwọn ọba aláìkọlà a máa fẹlá lórí wọn: a sì máa pe àwọn aláṣẹ wọn ní olóore. 26 (C)Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kì yóò rí bẹ́ẹ̀; ṣùgbọ́n ẹni tí ó ba pọ̀jù nínú yín kí ó jẹ́ bí ẹni tí o kéré ju àbúrò; ẹni tí ó sì ṣe olórí, bí ẹni tí ń ṣe ìránṣẹ́. 27 Nítorí ta ni ó pọ̀jù, ẹni tí ó jókòó tí oúnjẹ, tàbí ẹni tí ó ń ṣe ìránṣẹ́. Ẹni tí ó jókòó ti oúnjẹ kọ́ bí? Ṣùgbọ́n èmi ń bẹ láàrín yín bí ẹni tí ń ṣe ìránṣẹ́. 28 (D)(E)Ẹ̀yin ni àwọn tí ó ti dúró tì mí nínú ìdánwò mi. 29 (F)Mo sì yan ìjọba fún yín, gẹ́gẹ́ bí Baba mi ti yàn fún mi: 30 (G)Kí ẹ̀yin lè máa jẹ, kí ẹ̀yin sì lè máa mu lórí tábìlì mi ní ìjọba mi, kí ẹ̀yin lè jókòó lórí ìtẹ́, àti kí ẹ̀yin lè máa ṣe ìdájọ́ fún àwọn ẹ̀yà Israẹli méjìlá.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.