Book of Common Prayer
Ti Dafidi.
103 Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi; àti gbogbo ohun tí ó wà nínú mi, yín orúkọ rẹ̀ mímọ́.
2 Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi, kí o má ṣe gbàgbé gbogbo oore rẹ̀
3 Ẹni tí ó dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jì ọ́
tí ó sì wo gbogbo ààrùn rẹ̀ sàn,
4 Ẹni tí ó ra ẹ̀mí rẹ padà kúrò nínú kòtò ikú
ẹni tí ó fi ìṣeun ìfẹ́ àti ìyọ́nú dé ọ ní adé,
5 Ẹni tí ó fi ohun dídára tẹ́ ọ lọ́rùn
kí ìgbà èwe rẹ̀ lè di ọ̀tún bí ti ẹyẹ idì.
6 Olúwa ń ṣe òdodo àti ìdájọ́ fún
gbogbo àwọn tí a ni lára.
7 Ó fi ọ̀nà rẹ̀ hàn fún Mose, iṣẹ́ rẹ̀ fun àwọn ọmọ Israẹli;
8 (A)Olúwa ni aláàánú àti olóore,
ó lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ ní ìfẹ́.
9 Òun kì í bá ni wí ní ìgbà gbogbo
bẹ́ẹ̀ ni kì í pa ìbínú rẹ mọ́ láéláé;
10 Òun kì í ṣe sí wa gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ wa
bẹ́ẹ̀ ni kì í san án fún wa gẹ́gẹ́
bí àìṣedéédéé wa.
11 Nítorí bí ọ̀run ṣe ga sílẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ rẹ̀ tóbi sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀.
12 Bí ìlà-oòrùn ti jìnnà sí ìwọ̀-oòrùn
bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe mú ìrékọjá wá jìnnà sí wa.
13 Bí baba ti ń ṣe ìyọ́nú sí àwọn ọmọ rẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ni Olúwa ń ṣe ìyọ́nú sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀;
14 Nítorí tí ó mọ dídá wa,
ó rántí pé erùpẹ̀ ni wá.
15 Bí ó ṣe ti ènìyàn ni, ọjọ́ rẹ̀ dàbí koríko,
ó gbilẹ̀ bí ìtànná ewéko igbó;
16 Afẹ́fẹ́ fẹ́ kọjá lọ lórí rẹ̀,
kò sì rántí ibùjókòó rẹ̀ mọ́.
17 (B)Ṣùgbọ́n láti ayérayé ni ìfẹ́
Olúwa ti wà pẹ̀lú àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,
àti òdodo rẹ̀ wà láti ọmọdọ́mọ
18 Sí àwọn tí ó pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́
àti àwọn tí ó rántí òfin rẹ̀ láti ṣe wọ́n.
19 Olúwa ti pèsè ìtẹ́ rẹ̀ nínú ọ̀run,
ìjọba rẹ̀ ní ó sì borí ohun gbogbo.
20 Yin Olúwa, ẹ̀yin angẹli rẹ̀,
tí ó ní ipá, tí ó pa òfin ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́
21 Yin Olúwa, ẹ̀yin ogun ọ̀run rẹ̀ gbogbo,
ẹ̀yin ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀.
22 Yin Olúwa, gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ ní
ibi gbogbo ìjọba rẹ̀.
Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi.
Àsọtẹ́lẹ̀ nípa ibí Johanu onítẹ̀bọmi
5 (A)Nígbà ọjọ́ Herodu ọba Judea, àlùfáà kan wà, láti ìran Abijah, orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Sekariah: aya rẹ̀ sì ṣe ọ̀kan nínú àwọn ọmọbìnrin Aaroni, orúkọ rẹ̀ a sì máa jẹ́ Elisabeti. 6 Àwọn méjèèjì sì ṣe olódodo níwájú Ọlọ́run, wọ́n ń rìn ní gbogbo òfin àti ìlànà Olúwa ní àìlẹ́gàn. 7 Ṣùgbọ́n wọn kò ní ọmọ, nítorí tí Elisabeti yàgàn; àwọn méjèèjì sì di arúgbó.
8 Ó sì ṣe, nígbà tí ó ń ṣe iṣẹ́ àlùfáà níwájú Ọlọ́run ni àkókò tirẹ̀ 9 (B)Bí ìṣe àwọn àlùfáà, ipa tirẹ̀ ni láti máa fi tùràrí jóná, nígbà tí ó bá wọ inú tẹmpili Olúwa lọ. 10 Gbogbo ìjọ àwọn ènìyàn sì ń gbàdúrà lóde ní àkókò sísun tùràrí.
11 (C)Angẹli Olúwa kan sì fi ara hàn án, ó dúró ní apá ọ̀tún pẹpẹ tùràrí. 12 Nígbà tí Sekariah sì rí i, orí rẹ̀ wú, ẹ̀rù sì bà á. 13 (D)Ṣùgbọ́n angẹli náà wí fún un pé, “Má bẹ̀rù, Sekariah: nítorí tí àdúrà rẹ gbà; Elisabeti aya rẹ yóò sì bí ọmọkùnrin kan fún ọ, ìwọ ó sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Johanu. 14 Òun yóò sì jẹ́ ayọ̀ àti ìdùnnú fún ọ: ènìyàn púpọ̀ yóò sì yọ̀ sí ìbí rẹ. 15 (E)Nítorí òun ó pọ̀ níwájú Olúwa, kì yóò sì mu ọtí wáìnì, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sì mu ọtí líle; yóò sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́ àní láti inú ìyá rẹ̀ wá. 16 Òun ó sì yí ènìyàn púpọ̀ padà nínú àwọn ọmọ Israẹli sí Olúwa Ọlọ́run wọn. 17 (F)Ẹ̀mí àti agbára Elijah ni Olúwa yóò sì fi ṣáájú rẹ̀ lọ, láti pa ọkàn àwọn baba dà sí ti àwọn ọmọ, àti ti àwọn aláìgbọ́ràn sí ọgbọ́n àwọn olóòtítọ́; kí ó le pèsè àwọn ènìyàn tí a múra sílẹ̀ de Olúwa.”
18 Sekariah sì wí fún angẹli náà pé, “Ààmì wo ni èmi ó fi mọ èyí? Èmi sá ti di àgbà, àti Elisabeti aya mi sì di arúgbó.”
19 (G)Angẹli náà sì dáhùn ó wí fún un pé, “Èmi ni Gabrieli, tí máa ń dúró níwájú Ọlọ́run; èmi ni a rán wá láti sọ fún ọ, àti láti mú ìròyìn ayọ̀ wọ̀nyí fún ọ wá. 20 Sì kíyèsi i, ìwọ ó yadi, ìwọ kì yóò sì le fọhùn, títí ọjọ́ náà tí nǹkan wọ̀nyí yóò fi ṣẹ, nítorí ìwọ kò gba ọ̀rọ̀ mi gbọ́ tí yóò ṣẹ ní àkókò wọn.”
21 Àwọn ènìyàn sì ń dúró de Sekariah, ẹnu sì yà wọ́n nítorí tí ó pẹ́ nínú tẹmpili. 22 Nígbà tí ó sì jáde wá, òun kò le bá wọn sọ̀rọ̀. Wọn sì kíyèsi wí pé ó ti rí ìran nínú tẹmpili, ó sì ń ṣe àpẹẹrẹ sí wọn, nítorí tí ó yadi.
23 Ó sì ṣe, nígbà tí ọjọ́ iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ pé, ó lọ sí ilé rẹ̀.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.