Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 41

Fún adarí orin. Saamu Dafidi.

41 Ìbùkún ni fún ẹni tí ó ń ro ti aláìní:
    Olúwa yóò gbà á ní ìgbà ìpọ́njú.
Olúwa yóò dáàbò bò ó yóò sì pa ọkàn rẹ̀ mọ́:
    yóò bùkún fún un ní orí ilẹ̀
kò sì ní fi sílẹ̀ fún ìfẹ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀.
Olúwa yóò gbà á lórí àkéte àìsàn rẹ̀
    yóò sì mú un padà bọ̀ sípò kúrò nínú àìsàn rẹ̀.

Ní ti èmi, mo wí pé “Olúwa, ṣàánú fún mi;
    wò mí sàn, nítorí pé mo ti ṣẹ̀ sí ọ”.
Àwọn ọ̀tá mi ń sọ̀rọ̀ mi nínú àrankàn, pé
    “Nígbà wo ni yóò kú, ti orúkọ rẹ̀ yóò sì run?”
Nígbàkígbà tí ẹnìkan bá wá wò mí,
    wọn ń sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn, nígbà tí àyà rẹ̀ bá kó ẹ̀ṣẹ̀ jọ sí ara rẹ̀;
nígbà tí ó bá jáde lọ yóò sì máa tàn án kálẹ̀.

Àwọn ọ̀tá mi gbìmọ̀ papọ̀ nípa mi;
    èmi ni wọ́n ń gbìmọ̀ ibi sí,
wọ́n wí pé, “Ohun búburú ni ó dì mọ́ ọn ṣinṣin
    àti ní ibi tí ó dùbúlẹ̀ sí,
kì yóò dìde mọ́.”
(A)Pàápàá, ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́, ẹni tí mo gbẹ́kẹ̀lé,
    ẹni tí ó ń jẹ nínú oúnjẹ mi,
tí gbé gìgísẹ̀ rẹ̀ sókè sí mi.

10 Ṣùgbọ́n ìwọ Olúwa, ṣàánú fún mi;
    gbé mi sókè, kí ń ba lè san fún wọn.
11 Èmi mọ̀ pé inú rẹ̀ dùn sí mi,
    nítorí ọ̀tá mi kò borí mi.
12 Bí ó ṣe tèmi ni
    ìwọ dì mímú nínú ìwà òtítọ́ mi
ìwọ sì gbé mi kalẹ̀ níwájú rẹ títí láé.

13 Olùbùkún ni Olúwa, Ọlọ́run Israẹli
    láé àti láéláé.
Àmín àti Àmín.

Saamu 52

Fún adarí orin. Maskili ti Dafidi. Nígbà tí Doegi ará Edomu tọ Saulu lọ láti sọ fún pé, “Dafidi wà ní ilé Ahimeleki.”

52 Èéṣe tí ìwọ fi ń ṣe féfé nínú ìwà ìkà, ìwọ alágbára ọkùnrin?
    Èéṣe tí ìwọ fi ń gbéraga nígbà gbogbo,
    ìwọ ẹni ẹ̀gàn níwájú Ọlọ́run?
Ahọ́n rẹ̀ ń gbìmọ̀ ìparun;
    ó dàbí abẹ mímú,
    ìwọ ẹni tí ń hùwà ẹ̀tàn.
Ìwọ fẹ́ràn ibi ju ìre lọ,
    àti èké ju kí ó sọ òtítọ́ lọ.
Ìwọ fẹ́ràn ọ̀rọ̀ ìpanilára gbogbo,
    ìwọ ahọ́n ẹ̀tàn!

Ọlọ́run yóò sì lù ọ́ bolẹ̀ láéláé,
    yóò sì dì ọ́ mú,
yóò sì já ọ kúrò ni ibùjókòó rẹ,
    yóò sì fà ọ́ tu kúrò lórí ilẹ̀ alààyè. Sela.
Àwọn olódodo yóò rí, wọn yóò sì bẹ̀rù
    wọn yóò sì rẹ́rìn-ín rẹ̀, wí pé,
“Èyí ni ọkùnrin náà ti kò fi Ọlọ́run ṣe agbára rẹ̀,
    bí kò ṣe ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ rẹ̀ ni ó gbẹ́kẹ̀lé,
    ó sì mu ara rẹ̀ le nínú ìwà búburú rẹ̀.”

Ṣùgbọ́n èmi dàbí igi Olifi
    tí ó gbilẹ̀ nínú ilé Ọlọ́run;
Èmi gbẹ́kẹ̀lé ìfẹ́ Ọlọ́run tí kì í kùnà
    láé àti láéláé.
Èmi yóò yìn ọ títí fún ohun tí ó ti ṣe;
    èmi ní ìrètí nínú orúkọ rẹ,
nítorí orúkọ rẹ dára.
    Èmi yóò yìn ọ́ níwájú àwọn ènìyàn mímọ́.

Saamu 44

Fún adarí orin. Ti àwọn ọmọ Kora. Maskili.

44 À ti fi etí wa gbọ́, Ọlọ́run
    àwọn baba wa tí sọ fún wa
ohun tí ìwọ ṣe ní ọjọ́ wọn,
    ní ọjọ́ pípẹ́ sẹ́yìn.
Ìwọ fi ọwọ́ rẹ lé orílẹ̀-èdè jáde
    Ìwọ sì gbin àwọn baba wa;
Ìwọ run àwọn ènìyàn náà
    Ìwọ sì mú àwọn baba wa gbilẹ̀.
Kì í ṣe nípa idà wọn ni wọ́n gba ilẹ̀ náà,
    bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe apá wọn ní ó gbà wọ́n bí kò ṣe;
ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti, apá rẹ;
    àti ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ̀, nítorí ìwọ fẹ́ wọn.

Ìwọ ni ọba àti Ọlọ́run mi,
    ẹni tí ó pàṣẹ ìṣẹ́gun fún Jakọbu.
Nípasẹ̀ rẹ ni àwa ó bi àwọn ọ̀tá wa ṣubú;
    nípasẹ̀ orúkọ rẹ ni àwa ó tẹ àwọn ọ̀tá tí ó dìde sí wa mọ́lẹ̀
Èmi kì yóò gbẹ́kẹ̀lé ọrun mi
    idà mi kì yóò mú ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá wá,
Ṣùgbọ́n ìwọ fún wa ní ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá wa,
    ìwọ sì ti dójúti àwọn tí ó kórìíra wa.
Nínú Ọlọ́run àwa ń ṣògo ní gbogbo ọjọ́,
    àwa ó sì yin orúkọ rẹ títí láé. Sela.

Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ìwọ ti kọ̀ wá, ìwọ sì ti dójútì wá;
    Ìwọ kò sì bá àwọn ọmọ-ogun wa jáde mọ́.
10 Ìwọ ti bá wa jà,
    ìwọ sì ti ṣẹ́gun wa níwájú àwọn ọ̀tá wa,
àwọn ọ̀tá wa ti gba ilẹ̀ wa,
    wọ́n sì fi ipá gba oko wa.
11 Ìwọ fi wá fún jíjẹ bí ẹran àgùntàn
    Ìwọ sì ti tú wa ká sí àárín àwọn kèfèrí.
12 Ìwọ ta àwọn ènìyàn rẹ fún owó kékeré,
    Ìwọ kò sì jẹ èrè kankan lórí iye tí ìwọ tà wọ́n.

13 Ìwọ sọ wá di ẹni ẹ̀sín ní ọ̀dọ̀ àwọn aládùúgbò wa,
    ẹlẹ́yà àti ẹni àbùkù sí àwọn tí ó yí wa ká.
14 Ìwọ ti sọ wá di ẹni ìfisọ̀rọ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè;
    àwọn ènìyàn ń mi orí wọn sí wa.
15 Ìdójútì mi ń bẹ pẹ̀lú mi ní gbogbo ọjọ́,
    ìtìjú sì bojú mi mọ́lẹ̀,
16 nítorí ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn àti ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn
    ní ojú àwọn ọ̀tá àti olùgbẹ̀san.

17 Gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí ń ṣẹlẹ̀ sí wa,
    síbẹ̀ àwa kò gbàgbé rẹ
bẹ́ẹ̀ ni a kò ṣèké sí májẹ̀mú rẹ̀.
18 Ọkàn wa kò padà sẹ́yìn;
    bẹ́ẹ̀ ni ẹsẹ̀ wa kò yẹ̀ kúrò ní ọ̀nà rẹ̀.
19 Ṣùgbọ́n wọ́n kọlù wá,
    ìwọ sì sọ wá di ẹran ọdẹ fún àwọn ẹranko búburú,
tí wọn sì fi òkùnkùn biribiri bò wá mọ́lẹ̀.

20 Bí àwa bá ti gbàgbé orúkọ Ọlọ́run wa
    tàbí tí a na ọwọ́ wa sí ọlọ́run àjèjì.
21 Ǹjẹ́ Ọlọ́run kì yóò rí ìdí rẹ̀,
    níwọ̀n ìgbà tí ó mọ ohun ìkọ̀kọ̀ inú ọkàn?
22 (A)Síbẹ̀, nítorí rẹ̀ àwa da àyà kọ ikú, ní ojoojúmọ́
    a ń kà wá sí bí àgùntàn fún pípa.

23 Jí, Olúwa! Èéṣe tí ìwọ ń sùn?
    Dìde fúnrarẹ̀! Má ṣe kọ̀ wá sílẹ̀ láéláé.
24 Èéṣe tí ìwọ ń pa ojú rẹ mọ́
    tí ìwọ sì gbàgbé ìpọ́njú àti ìnira wa?

25 Nítorí a tẹrí ọkàn wa ba sínú eruku;
    ara wa sì dì mọ́ erùpẹ̀ ilẹ̀.
26 Dìde kí o sì ràn wá lọ́wọ́;
    rà wá padà nítorí ìfẹ́ rẹ tí ó dúró ṣinṣin.

Deuteronomi 11:13-19

13 (A)Nítorí náà, bí ẹ bá gbọ́rọ̀ sí àṣẹ tí mo fún un yín lónìí tọkàntọkàn: tí ẹ fẹ́ràn Olúwa Ọlọ́run yín, tí ẹ sì sìn ín, pẹ̀lú gbogbo àyà yín àti gbogbo ọkàn yín: 14 nígbà náà, èmi yóò rọ òjò sórí ilẹ̀ ẹ yín lákòókò rẹ̀, àti òjò àkọ́rọ̀ àti ti àrọ̀kẹ́yìn, kí ẹ ba à lè kórè oúnjẹ yín wọlé àní wáìnì tuntun àti òróró. 15 Èmi yóò mú kí koríko hù lórí ilẹ̀ yín fún àwọn ohun ọ̀sìn in yín, ẹ ó sì jẹ, ẹ ó sì yó.

16 Ẹ ṣọ́ra, kí a má ba à tàn yín jẹ láti yípadà kí ẹ sì sin ọlọ́run mìíràn àti láti máa foríbalẹ̀ fún wọn. 17 Nígbà náà ni ìbínú Olúwa yóò sì ru sí i yín, Òun yóò ti ìlẹ̀kùn ọ̀run kí òjò má ba à rọ̀, ilẹ̀ kì yóò sì so èso kankan, ẹ ó sì ṣègbé ní ilẹ̀ rere tí Olúwa fi fún un yín. 18 Ẹ fi gbogbo ọ̀rọ̀ mi wọ̀nyí sí àyà a yín, àti ọkàn an yín, ẹ so wọ́n bí ààmì sórí ọwọ́ yín, kí ẹ sì so wọ́n mọ́ iwájú orí yín. 19 Ẹ máa fi wọ́n kọ́ àwọn ọmọ yín, ẹ máa sọ̀rọ̀ nípa wọn bí ẹ bá jókòó nínú ilé, àti ní ojú ọ̀nà bí ẹ bá ń rìn lọ, bí ẹ bá sùn àti bí ẹ bá jí.

2 Kọrinti 5:11-6:2

Iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìlàjà tí a yà sọ́tọ̀

11 Nítorí náà bí àwa ti mọ ẹ̀rù Olúwa, àwa ń yí ènìyàn lọ́kàn padà; ṣùgbọ́n a ń fi wá hàn fún Ọlọ́run; mo sì gbàgbọ́ pé, a sì ti fì wá hàn ní ọkàn yín pẹ̀lú. 12 (A)Nítorí àwa kò sì ní máa tún yin ara wá sí i yín mọ́, ṣùgbọ́n àwa fi ààyè fún yín láti máa ṣògo nítorí wa, kí ẹ lè ní ohun tí ẹ̀yin yóò fi dá wọn lóhùn, àwọn ti ń ṣògo lóde ara kì í ṣe ní ọkàn. 13 Nítorí náà bí àwa bá ń sínwín, fún Ọlọ́run ni: tàbí bí iyè wá bá ṣí pépé, fún yín ni. 14 (B)Nítorí ìfẹ́ Kristi ń rọ̀ wá, nítorí àwa mọ̀ báyìí pé, bí ẹnìkan bá kú fún gbogbo ènìyàn, ǹjẹ́ nígbà náà, gbogbo wọ́n ni ó ti kú. 15 Ó sì ti kú fún gbogbo wọn, pé kí àwọn tí ó wà láààyè má sì ṣe wà láààyè fún ara wọn mọ́, bí kò ṣe fún ẹni tí ó kú nítorí wọn, tí ó sì ti jíǹde.

16 Nítorí náà láti ìsinsin yìí lọ, àwa kò mọ ẹnìkan nípa ti ara mọ́; bí àwa tilẹ̀ ti mọ Kristi nípa ti ara, ṣùgbọ́n nísinsin yìí àwa kò mọ̀ ọ́n bẹ́ẹ̀ mọ́. 17 (C)Nítorí náà bí ẹnìkan bá wà nínú Kristi, ó di ẹ̀dá tuntun: ohun àtijọ́ ti kọjá lọ; kíyèsi i, ohun tuntun ti dé. 18 (D)Ohun gbogbo sì ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, ẹni tí ó sì tipasẹ̀ Jesu Kristi bá wa làjà sọ́dọ̀ ara rẹ̀, tí ó sì ti fi iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìlàjà fún wa. 19 Èyí ni pé, Ọlọ́run wà nínú Kristi, ó ń bá aráyé làjà sọ́dọ̀ ara rẹ̀, kò sí ka ìrékọjá wọn sí wọn lọ́rùn; ó sì ti fi ọ̀rọ̀ ìlàjà lé wa lọ́wọ́. 20 (E)Nítorí náà àwa ni ikọ̀ fún Kristi, bí ẹni pé Ọlọ́run ń ti ọ̀dọ̀ wa ṣìpẹ̀ fún yín: àwa ń bẹ̀ yín ní ipò Kristi, “Ẹ bá Ọlọ́run làjà,” 21 (F)Nítorí ó tí fi í ṣe ẹ̀ṣẹ̀ nítorí wa, ẹni tí kò mọ ẹ̀ṣẹ̀kẹ́ṣẹ̀ rí: kí àwa lè di òdodo Ọlọ́run nínú rẹ̀.

Gẹ́gẹ́ bí alábáṣiṣẹ́pọ̀ nínú Ọlọ́run, ǹjẹ́, àwa ń rọ̀ yín kí ẹ má ṣe gba oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run lásán. (G)Nítorí o wí pé,

“Ní àkókò ìtẹ́wọ́gbà mi, èmi tí gbọ́ ohùn rẹ,
    àti ọjọ́ ìgbàlà, èmi sì ti ràn ọ́ lọ́wọ́.”

Èmi wí fún ọ, nísinsin yìí ní àkókò ìtẹ́wọ́gbà, nísinsin yìí ni ọjọ́ ìgbàlà.

Luku 17:1-10

Ẹ̀ṣẹ̀, ìgbàgbọ́, àti iṣẹ́

17 (A)Ó sì wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Kò le ṣe kí ohun ìkọ̀sẹ̀ máa wa: ṣùgbọ́n ègbé ni fún ẹni tí ó ti ipasẹ̀ rẹ̀ dé. Ìbá sàn fún un kí a so ọlọ mọ́ ọn ní ọrùn, kí a sì gbé e jù sínú Òkun, ju kí ó mú ọ̀kan nínú àwọn kékeré wọ̀nyí kọsẹ̀. (B)Ẹ máa kíyèsára yín.

“Bí arákùnrin rẹ bá ṣẹ̀, bá a wí; bí ó bá sì ronúpìwàdà, dáríjì ín. Bí ó bá sì ṣẹ̀ ọ́ ní igba méje ní òòjọ́, tí ó padà tọ̀ ọ́ wá ní ìgbà méje ní òòjọ́ pé, ‘Mo ronúpìwàdà,’ dáríjì ín.”

(C)(D) Àwọn aposteli sì wí fún Olúwa pé, “Bù sí ìgbàgbọ́ wa.”

Olúwa sì wí pé, “Bí ẹ̀yin bá ní ìgbàgbọ́ bí hóró irúgbìn musitadi, ẹ̀yin yóò lè wí fún igi sikamine yìí pé, ‘di fi fà á tu, kí a sì gbìn ọ́ sínú Òkun,’ yóò sì gbọ́ tiyín.

“Ṣùgbọ́n ta ni nínú yín, tí ó ní ọmọ ọ̀dọ̀, tí ó ń tulẹ̀, tàbí tí ó ń bọ́ ẹran, tí yóò wí fún un lójúkan náà tí ó bá ti oko dé pé, ‘Lọ í jókòó láti jẹun’? (E)Tí kì yóò kúkú wí fún un pé, ‘Pèsè ohun tí èmi yóò jẹ, sì di àmùrè, kí ìwọ kí ó máa ṣe ìránṣẹ́ fún mi, títí èmi ó fi jẹ kí èmi ó sì mu tán; lẹ́yìn náà ni ìwọ ó sì jẹ, tí ìwọ ó sì mu’? Òun ó ha máa dá ọpẹ́ lọ́wọ́ ọmọ ọ̀dọ̀ náà, nítorí ó ṣe ohun tí a pàṣẹ fún un bí? Èmi kò rò bẹ́ẹ̀. 10 Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin pẹ̀lú, nígbà tí ẹ bá ti ṣe ohun gbogbo tí a pàṣẹ fún yín tán, ẹ wí pé, ‘Aláìlérè ọmọ ọ̀dọ̀ ni wá: èyí tí í ṣe iṣẹ́ wa láti ṣe, ní àwa ti ṣe.’ ”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.