Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 132

Orin fún ìgòkè.

132 Olúwa, rántí Dafidi
    nínú gbogbo ìpọ́njú rẹ̀.

Ẹni tí ó ti búra fún Olúwa,
    tí ó sì ṣe ìlérí fún Alágbára Jakọbu pé.
Nítòótọ́, èmi kì yóò wọ inú àgọ́ ilé mi lọ,
    bẹ́ẹ̀ èmi kì yóò gun orí àkéte mi:
Èmi kì yóò fi oorun fún ojú mi,
    tàbí òògbé fún ìpéǹpéjú mi,
Títí èmi ó fi rí ibi fún Olúwa,
    ibùjókòó fún Alágbára Jakọbu.

Kíyèsi i, àwa gbúròó rẹ̀ ni Efrata:
    àwa rí i nínú oko ẹgàn náà.
Àwa ó lọ sínú àgọ́ rẹ̀:
    àwa ó máa sìn níbi àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀
Olúwa, dìde sí ibi ìsinmi rẹ:
    ìwọ, àti àpótí agbára rẹ.
Kí a fi òdodo wọ àwọn àlùfáà rẹ:
    kí àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ kí ó máa hó fún ayọ̀.

10 Nítorí tí Dafidi ìránṣẹ́ rẹ̀
    Má ṣe yí ojú ẹni òróró rẹ padà.

11 (A)Olúwa ti búra nítòótọ́ fún Dafidi:
    Òun kì yóò yípadà kúrò nínú rẹ̀,
    nínú irú-ọmọ inú rẹ ni èmi ó gbé kalẹ̀ sí orí ìtẹ́ rẹ.
12 Bí àwọn ọmọ rẹ̀ yóò bá pa májẹ̀mú mi mọ́
    àti ẹ̀rí mi tí èmi yóò kọ́ wọn,
    àwọn ọmọ wọn pẹ̀lú yóò jókòó lórí ìtẹ́ rẹ láéláé.

13 Nítorí tí Olúwa ti yan Sioni:
    ó ti fẹ́ ẹ fún ibùjókòó rẹ̀.
14 Èyí ni ibi ìsinmi mi láéláé:
    níhìn-ín ni èmi yóò máa gbé:
    nítorí tí mo fẹ́ ẹ.
15 Èmi yóò bùkún oúnjẹ rẹ̀ púpọ̀púpọ̀:
    èmi yóò fi oúnjẹ tẹ́ àwọn tálákà rẹ̀ lọ́rùn.
16 Èmi yóò sì fi ìgbàlà wọ àwọn àlùfáà rẹ̀:
    àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ yóò máa hó fún ayọ̀.

17 Níbẹ̀ ni èmi yóò gbé mú ìwo Dafidi yọ̀,
    èmi ti ṣe ìlànà fìtílà kan fún ẹni òróró mi.
18 Àwọn ọ̀tá rẹ̀ ni èmi yóò fi ìtìjú wọ̀:
    ṣùgbọ́n lára òun tìkára rẹ̀ ni adé yóò máa gbilẹ̀.

Isaiah 11:1-10

Ẹ̀ka láti ọ̀dọ̀ Jese

11 (A)Èèkàn kan yóò sọ láti ibi
    kùkùté Jese,
láti ara gbòǹgbò rẹ̀ ni ẹ̀ka kan
    yóò ti so èso.
(B)Ẹ̀mí Olúwa yóò sì bà lé e
    ẹ̀mí ọgbọ́n àti ti òye
ẹ̀mí ìmọ̀ràn àti ti agbára
    ẹ̀mí ìmọ̀ àti ti ìbẹ̀rù Olúwa
Òun yóò sì ní inú dídùn nínú ìbẹ̀rù Olúwa.

    Òun kì yóò ṣe ìdájọ́ pẹ̀lú ohun tí ó fi ojú u rẹ̀ rí,
    tàbí pẹ̀lú ohun tí ó fi etí i rẹ̀ gbọ́,
Ṣùgbọ́n pẹ̀lú òdodo ni yóò ṣe ìdájọ́ àwọn aláìní,
    pẹ̀lú òtítọ́ ni yóò ṣe ìpinnu
fún àwọn aláìní ayé.
    Òun yóò lu ayé pẹ̀lú ọ̀pá tí ó wà ní ẹnu rẹ̀,
    pẹ̀lú èémí ẹnu rẹ̀ ni yóò pa àwọn ìkà.
(C)Òdodo ni yóò jẹ́ ìgbànú rẹ̀
    àti òtítọ́ ni yóò ṣe ọ̀já yí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ ká.

(D)Ìkookò yóò sì máa bá ọmọ àgùntàn gbé,
    ẹkùn yóò sì sùn ti ewúrẹ́
ọmọ màlúù òun ọmọ kìnnìún
    àti ọmọ ẹran ó wà papọ̀
    ọ̀dọ́mọdé yóò sì máa dà wọ́n.
Màlúù àti beari yóò máa jẹun pọ̀,
    àwọn ọmọ wọn yóò dùbúlẹ̀ pọ̀,
kìnnìún yóò sì máa jẹ koríko
    gẹ́gẹ́ bí akọ màlúù.
Ọ̀dọ́mọdé yóò ṣeré lẹ́bàá ihò ọká,
    ọmọdé yóò ki ọwọ́ rẹ̀ bọ ìtẹ́ paramọ́lẹ̀.
Wọn kò ní ṣe ni léṣe tàbí pa ni run
    ní gbogbo òkè mímọ́ mi,
nítorí gbogbo ayé yóò kún fún ìmọ̀ Olúwa
    gẹ́gẹ́ bí omi ti bo Òkun.

10 (E)Ní ọjọ́ náà, gbòǹgbò Jese yóò dúró gẹ́gẹ́ bí àsíá fún gbogbo ènìyàn, àwọn orílẹ̀-èdè yóò pagbo yí i ká, ibùdó ìsinmi rẹ̀ yóò jẹ́ èyí tí ó lógo.

Heberu 2:11-18

11 Nítorí àti ẹni tí ń sọ ni di mímọ́ àti àwọn tí a ń sọ di mímọ́, láti ọ̀dọ̀ ẹnìkan ṣoṣo ni gbogbo wọn ti wá: Nítorí èyí ni kò ṣe tijú láti pè wọ́n ni arákùnrin. 12 (A)Àti wí pé,

“Èmi ó sọ̀rọ̀ orúkọ rẹ̀ fún àwọn ará mi,
    ni àárín ìjọ ni èmi yóò kọrin ìyìn rẹ̀.”

13 (B)Àti pẹ̀lú,

“Èmi yóò gbẹ́kẹ̀ mi lé e.”

Àti pẹ̀lú,

“Kíyèsi í, èmi rèé, èmi àti àwọn ọmọ tí Ọlọ́run fi fún mi.”

14 Ǹjẹ́ ni ìwọ̀n bí àwọn ọmọ tí ṣe alábápín ará àti ẹ̀jẹ̀, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni òun pẹ̀lú sì ṣe alábápín nínú ohun kan náà; kí ó lè ti ipa ikú rẹ̀ pa ẹni tí ó ní agbára ikú run, èyí ni èṣù. 15 Kí o sì lè gba gbogbo àwọn tí ó tìtorí ìbẹ̀rù ikú wà lábẹ́ ìdè lọ́jọ́ ayé wọn gbogbo kúrò lọ́wọ́ ìbẹ̀rù. 16 (C)Nítorí pé, nítòótọ́, kì í ṣe àwọn angẹli ni ó ṣe ìrànlọ́wọ́ fún, ṣùgbọ́n àwọn irú-ọmọ Abrahamu ni ó ṣe ìrànlọ́wọ́ fún. 17 Nítorí náà, ó yẹ pé nínú ohun gbogbo kí ó dàbí àwọn ará rẹ̀, kí ó lè jẹ́ aláàánú àti olóòtítọ́ alábojútó Àlùfáà nínú ohun tí i ṣe ti Ọlọ́run, kí o lè ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn. 18 Nítorí níwọ̀n bí òun tìkára rẹ̀ ti jìyà tí a sì ti dán an wò, òun ní agbára láti ran àwọn tí a ń dánwò lọ́wọ́.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.