Book of Common Prayer
Fún adarí orin. Ti Dafidi ìránṣẹ́ Olúwa tí ó kọ sí Olúwa, ọ̀rọ̀ orin tí ó kọ sí Olúwa fún ìdáǹdè kúrò lọ́wọ́ Saulu ọ̀tá rẹ̀. Ó wí pé
18 (A)Mo fẹ́ ọ, Olúwa, agbára mi.
2 Olúwa ni àpáta àti odi mi, àti olùgbàlà mi;
Ọlọ́run mi ni àpáta mi, ẹni tí mo fi ṣe ibi ìsádi mi.
Òun ni àpáta ààbò àti ìwo ìgbàlà mi àti ibi ìsádi mi.
3 Mo ké pe Olúwa, ẹni tí ìyìn yẹ fún,
a ó sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá à mi.
4 Ìrora ikú yí mi kà,
àti ìṣàn omi àwọn ènìyàn búburú dẹ́rùbà mí.
5 Okùn isà òkú yí mi ká,
ìkẹ́kùn ikú dojúkọ mí.
6 Nínú ìpọ́njú mo ké pe Olúwa;
Mo sọkún sí Olúwa mi fún ìrànlọ́wọ́.
Láti inú tẹmpili rẹ̀, ó gbọ́ igbe mi;
ẹkún mi wá sí iwájú rẹ̀, sí inú etí rẹ̀.
7 Ayé wárìrì, ó sì mì tìtì,
ìpìlẹ̀ àwọn òkè gíga sì ṣídìí;
wọ́n wárìrì nítorí tí ó ń bínú.
8 Èéfín ti ihò imú rẹ̀ jáde wá;
Iná ajónirun ti ẹnu rẹ̀ jáde wá,
ẹ̀yin iná bú jáde láti inú rẹ̀.
9 Ó pín àwọn ọ̀run, Ó sì jáde wá;
àwọsánmọ̀ dúdú sì wà ní abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.
10 Ó gun orí kérúbù, ó sì fò;
ó ń rábàbà lórí ìyẹ́ apá afẹ́fẹ́.
11 Ó fi òkùnkùn ṣe ibojì rẹ̀, ó fi ṣe ìbòrí yí ara rẹ̀ ká
kurukuru òjò dúdú ní ojú ọ̀run.
12 Nípa ìmọ́lẹ̀ iwájú rẹ̀, àwọsánmọ̀ ṣíṣú dudu rẹ kọjá lọ
pẹ̀lú yìnyín àti ẹ̀yín iná
13 Olúwa sán àrá láti ọ̀run wá;
Ọ̀gá-ògo sì fọ ohun rẹ̀; yìnyín àti ẹ̀yin iná.
14 Ó ta àwọn ọfà rẹ̀, ó sì tú àwọn ọ̀tá náà ká,
ọfà mọ̀nàmọ́ná ńlá sì dà wọ́n rú.
15 A sì fi ìsàlẹ̀ àwọn Òkun hàn,
a sì rí àwọn ìpìlẹ̀ ayé
nípa ìbáwí rẹ, Olúwa,
nípa fífún èémí ihò imú rẹ.
16 Ó sọ̀kalẹ̀ láti ibi gíga, ó sì dì mímú;
Ó fà mí jáde láti inú omi jíjìn.
17 Ó gbà mí kúrò lọ́wọ́ ọ̀tá mi alágbára,
láti ọwọ́ àwọn ọ̀tá, ti ó lágbára jù fún mi.
18 Wọ́n dojúkọ mí ní ọjọ́ ìpọ́njú mi;
ṣùgbọ́n Olúwa ni alátìlẹ́yìn mi.
19 Ó mú mi jáde wá sínú ibi ńlá;
Ó gbà mí nítorí tí ó ní inú dídùn sí mi.
20 Olúwa ti hùwà sí mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi;
gẹ́gẹ́ bí mímọ́ ọwọ́ mi, ó ti fi èrè fún mi
21 Nítorí mo ti pa ọ̀nà Olúwa mọ́;
èmi kò ṣe búburú nípa yíyí padà kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run mi
22 Gbogbo òfin rẹ̀ ni ó wà níwájú mi;
èmi kò sì yípadà kúrò nínú ìlànà rẹ̀.
23 Mo ti jẹ́ aláìlẹ́bi níwájú rẹ̀;
mo sì pa ara mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀.
24 Olúwa san ẹ̀san fún mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi;
gẹ́gẹ́ bí mímọ́ ọwọ́ mi níwájú rẹ̀.
25 Fún olóòtítọ́ ni ìwọ ó fi ara rẹ̀ hàn ní olóòtítọ́,
sí aláìlẹ́bi, ìwọ ó fi ara rẹ̀ hàn ní aláìlẹ́bi,
26 Sí ọlọ́kàn mímọ́, ìwọ ó fi ara rẹ̀ hàn ní ọlọ́kàn mímọ́,
ṣùgbọ́n sí ọlọ́kàn-wíwọ́, ìwọ ó fi ara rẹ̀ hàn ní òǹrorò.
27 O pa onírẹ̀lẹ̀ mọ́,
ṣùgbọ́n ó rẹ àwọn ti ń gbéraga sílẹ̀.
28 Ìwọ, Olúwa, jẹ́ kí fìtílà mi
kí ó máa tàn; Ọlọ́run mi, yí òkùnkùn mi padà sí ìmọ́lẹ̀.
29 Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ rẹ̀, èmi sáré tọ ogun lọ;
pẹ̀lú Ọlọ́run mi mo lè fo odi kan.
30 Bí ó ṣe ti Ọlọ́run mi, ọ̀nà rẹ̀ pé,
a ti rídìí ọ̀rọ̀ Olúwa
òun ni àpáta ààbò fún gbogbo àwọn tí ó fi ṣe ààbò.
31 Nítorí ta ni ṣe Ọlọ́run bí kò ṣe Olúwa?
Ta ní àpáta bí kò ṣe Olúwa wa?
32 Ọlọ́run ni ẹni tí ó fi agbára dì mí ní àmùrè
ó sì mú ọ̀nà mi pé.
33 Ó ṣe ẹsẹ̀ mi gẹ́gẹ́ bi ẹsẹ̀ abo àgbọ̀nrín;
ó jẹ́ ki n lè dúró lórí ibi gíga.
34 Ó kọ́ ọwọ́ mi ni ogun jíjà;
apá mi lè tẹ ọrùn idẹ
35 Ìwọ fi asà ìṣẹ́gun rẹ̀ fún mi,
ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ gbé mí dúró;
àti ìwà pẹ̀lẹ́ rẹ̀ sọ mí di ńlá.
36 Ìwọ sọ ìrìn ẹsẹ̀ mi di ńlá ní ìsàlẹ̀ mi,
kí kókó-ẹsẹ̀ mi má ṣe yẹ̀.
37 Èmi lépa àwọn ọ̀tá mi, èmi sì bá wọn
èmi kò sì padà lẹ́yìn wọn títí a fi run wọ́n.
38 Èmi sá wọn ní ọgbẹ́ tí wọn ko fi le è dìde;
Wọ́n ṣubú ní abẹ́ ẹsẹ̀ mi.
39 Nítorí ìwọ fi agbára dì mí ní àmùrè fún ogun náà;
ìwọ ti mú àwọn tí ó dìde si mí tẹríba ní abẹ́ ẹsẹ̀ mi
40 Ìwọ yí ẹ̀yìn àwọn ọ̀tá mí padà sí mi
èmi sì pa àwọn tí ó kórìíra mi run.
41 Wọ́n kígbe fún ìrànlọ́wọ́, ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan tí ó gbà wọ́n,
àní sí Olúwa, ṣùgbọ́n kò dá wọn lóhùn.
42 Mo lù wọ́n gẹ́gẹ́ bí eruku níwájú afẹ́fẹ́;
mo dà wọ́n síta gẹ́gẹ́ bí ẹrọ̀fọ̀.
43 Ìwọ ti gbà mí lọ́wọ́ ìkọlù àwọn ènìyàn;
Ìwọ ti fi mí ṣe olórí àwọn orílẹ̀-èdè.
Àwọn ènìyàn ti èmi kò mọ, yóò sì máa sìn mí,
44 ni wéré ti wọ́n gbọ́ ohùn mi, wọ́n pa àṣẹ mi mọ́;
àwọn ọmọ àjèjì yóò tẹríba fún mi.
45 Àyà yóò pá àlejò;
wọn yóò sì fi ìbẹ̀rù jáde láti ibi kọ́lọ́fín wọn.
46 Olúwa wà láààyè! Olùbùkún ni àpáta mi!
Gbígbéga ní Ọlọ́run Olùgbàlà mi.
47 Òun ni Ọlọ́run tí ó ń gbẹ̀san mi,
tí ó sì ń ṣẹ́gun àwọn orílẹ̀-èdè tí ó wà ní abẹ́ mi,
48 tí ó pa mí mọ́ kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mí.
Ìwọ gbé mi ga ju àwọn ọ̀tá tí ó dìde sí mi lọ;
lọ́wọ́ àwọn ènìyàn alágbára ni ìwọ ti gbà mí.
49 (B)Títí láéláé, èmi yóò máa yìn ọ́ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, ìwọ Olúwa;
Èmi yóò sì máa kọ orin ìyìn sí orúkọ rẹ.
50 Ó fún ọba rẹ̀ ni ìṣẹ́gun ńlá;
ó fi ìkáàánú àìṣẹ̀tàn fún ẹni ààmì òróró rẹ̀,
fún Dafidi àti ìran rẹ̀ títí láé.
Rutu àti Boasi ní ilẹ̀ ìpakà
3 Ní ọjọ́ kan, Naomi, ìyá ọkọ Rutu wí fún un pé, “Ọmọbìnrin mi, ǹjẹ́ kò yẹ kí èmi bá ọ wá ilé ọkọ mìíràn, níbi tí wọn yóò ti le è máa tọ́jú rẹ? 2 Wò ó, Boasi ọkùnrin nì tí ìwọ bá àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ ṣiṣẹ́, tí í ṣe ìbátan wa, yóò wá láti fẹ́ ọkà barle ní ilẹ̀ ìpakà rẹ̀ ní àṣálẹ́ yìí. 3 Wẹ̀, kí o sì fi ìpara olóòórùn dídùn pa ara rẹ, kí o sì wọ aṣọ rẹ tí ó dára jùlọ, kí o sì lọ sí ilẹ̀ ìpakà tí ó gbé ń pa ọkà, ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí ó mọ̀ pé o wà níbẹ̀ títí tí yóò fi jẹ tí yóò sì mu tán. 4 Rí í dájú pé o mọ ibi tí ó sùn sí, lẹ́yìn ìgbà tí ó bá ti sùn, lọ kí o ṣí aṣọ ìbora rẹ̀ níbi ẹsẹ̀ rẹ̀ sókè kí o sì sùn sí ibi ẹsẹ̀ náà. Òun yóò sì sọ ohun tí ìwọ yóò ṣe fún ọ.”
5 Rutu sì fèsì pé, “Gbogbo ohun tí ìwọ sọ fún mi ni èmi yóò ṣe.” 6 Bẹ́ẹ̀ ni Rutu lọ sí ilẹ̀ ìpakà tí ó sì ṣe gbogbo ohun tí ìyá ọkọ rẹ̀ sọ fún un, pé kí o ṣe.
7 Nígbà tí Boasi parí jíjẹ àti mímu tán, tí ọkàn rẹ̀ sì kún fún ayọ̀. Ó lọ, ó sì dùbúlẹ̀ ní ẹ̀yìn ọkà tí wọ́n kójọ. Rutu yọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ lọ sí ibẹ̀, ó ṣí aṣọ ẹsẹ̀ rẹ̀ sókè, ó sì sùn sí ibi ẹsẹ̀ rẹ̀. 8 Ó sì ṣe nígbà tí ọkùnrin náà tají ní àárín òru, ẹ̀rù bà á, ó sì yí ara padà, ó sì ṣàkíyèsí obìnrin kan tí ó sùn sí ibi ẹsẹ̀ rẹ̀.
9 Ó sì béèrè pé, “Ta ni ìwọ í ṣe?”
Rutu sì fèsì wí pé, “Èmi ni Rutu, ìránṣẹ́bìnrin rẹ. Da etí aṣọ rẹ bò mí, nítorí pé ìwọ ni ìbátan tí ó le è rà mí padà.”
10 Boasi sì wí fún un pé, “Kí Olúwa bùkún fún ọ, ọmọbìnrin mi. Ìfẹ́ tí o fihàn yí ti pọ̀ ju ti àtẹ̀yìnwá lọ, bí ó ti jẹ́ wí pé ìwọ kò lọ láti wá àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin bóyá ọlọ́rọ̀ tàbí tálákà. 11 Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ìwọ ọmọbìnrin mi, má bẹ̀rù. Èmi yóò sì ṣe ohun gbogbo tí o béèrè fún ọ. Gbogbo ènìyàn ni ó mọ̀ ọ́n ní obìnrin oníwà rere. 12 Nítòótọ́ ni mo wí pé èmi jẹ́ ìbátan tí ó súnmọ́ ọ, ṣùgbọ́n ìbátan kan wà tí ó súnmọ́ ọ ju ti tèmi lọ. 13 Dúró síbí títí ilẹ̀ yóò fi mọ́, bí ó bá sì di òwúrọ̀ tí ọkùnrin náà sì ṣe tan láti ṣe ìràpadà, ó dára kí ó ṣe bẹ́ẹ̀, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, bí Olúwa ti ń bẹ láààyè nígbà náà ni èmi yóò ṣe ìràpadà, sùn sí ìhín títí ilẹ̀ yóò fi mọ́.”
14 Ó sì sùn ní ẹsẹ̀ rẹ̀ títí di òwúrọ̀, ṣùgbọ́n ó dìde ní òwúrọ̀ kùtùkùtù kí ẹnìkínní tó le è dá ẹnìkejì mọ̀. Boasi sì sọ fún un wí pé, “Má ṣe jẹ́ kí ó di mí mọ̀ wí pé obìnrin kan wá sí ilẹ̀ ìpakà.”
15 Ó sì tún wí fún un pé, “Mú aṣọ ìborùn rẹ tí o dà bora, kí o tẹ̀ ẹ sílẹ̀.” Rutu sì ṣe bẹ́ẹ̀, Boasi sì wọn òṣùwọ̀n ọkà barle mẹ́fà sí i, ó sì gbé e rù ú. Nígbà náà ni ó padà sí ìlú.
16 Nígbà tí Rutu dé ilé Naomi ìyá ọkọ sì bí léèrè pé, “Báwo ni ó ti rí ọmọbìnrin mi?”
Nígbà náà ni ó sì sọ gbogbo ohun tí ọkùnrin náà ṣe fún un fún ìyá ọkọ rẹ̀. 17 Ó fi kún un wí pé, “Ó sọ fún mi wí pé, ‘Má ṣe padà sí ọ̀dọ̀ ìyá ọkọ rẹ ní ọwọ́ òfo, nítorí náà, ó fún mi ní ìwọ̀n ọkà barle mẹ́fà.’ ”
18 Naomi sì wí fún un pé, “Dúró, ọmọbìnrin mi títí tí ìwọ yóò fi mọ bí ohun gbogbo yóò ti rí, nítorí pé ọkùnrin náà kò ní sinmi títí tí ọ̀rọ̀ náà yóò fi yanjú lónìí.”
Àwọn ẹ̀kọ́ fun Timotiu
4 Nísinsin yìí, èmi ń tẹnumọ́ ọ́ pé ní ìgbà ìkẹyìn àwọn mìíràn yóò kúrò nínú ìgbàgbọ́, wọn yóò máa fiyèsí àwọn ẹ̀mí tí ń tannijẹ, àti ẹ̀kọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù. 2 Nípa àgàbàgebè àwọn tí ń ṣèké, àwọn tí ọkàn tìkára wọn dàbí èyí tí a fi irin gbígbóná jó. 3 Àwọn tí ń dánilẹ́kun láti gbéyàwó tiwọn si ń pàṣẹ láti ka èèwọ̀ oúnjẹ ti Ọlọ́run ti dá fún ìtẹ́wọ́gbà pẹ̀lú ọpẹ́ àwọn onígbàgbọ́ àti àwọn ti ó mọ òtítọ́. 4 Nítorí gbogbo ohun ti Ọlọ́run dá ni ó dára, kò sí ọkàn tí ó yẹ kí a kọ̀, bí a bá fi ọpẹ́ gbà á. 5 Nítorí tí a fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti àdúrà yà sí mímọ́.
6 Bí ìwọ bá ń rán àwọn ará létí nǹkan wọ̀nyí, ìwọ ó jẹ́ ìránṣẹ́ rere ti Kristi Jesu, tí a fi ọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́ àti ẹ̀kọ́ rere bọ́, èyí ti ìwọ ti ń tẹ̀lé. 7 Ṣùgbọ́n kọ ọ̀rọ̀ asán àti ìtàn àwọn àgbà obìnrin, sì máa tọ́ ara rẹ sí ìwà-bí-Ọlọ́run. 8 Nítorí ṣíṣe eré-ìdárayá ni èrè fún ohun díẹ̀, ṣùgbọ́n ìwà-bí-Ọlọ́run ni èrè fún ohun gbogbo, ó ní ìlérí ti ìgbé ayé ìsinsin yìí àti ti èyí tí ń bọ̀. 9 Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ náà, ó sì yẹ fún ìtẹ́wọ́gbà gbogbo. 10 Nítorí fún èyí ni àwa ń ṣe làálàá tí a sì ń jìjàkadì, nítorí àwa ní ìrètí nínú Ọlọ́run alààyè, ẹni tí í ṣe Olùgbàlà gbogbo ènìyàn, pẹ̀lúpẹ̀lú ti àwọn ti ó gbàgbọ́.
11 Nǹkan wọ̀nyí ni kí ó máa paláṣẹ kí ó máa kọ́ni. 12 Má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni gan ìgbà èwe rẹ; ṣùgbọ́n kì ìwọ jẹ́ àpẹẹrẹ fún àwọn tí ó gbàgbọ́, nínú ọ̀rọ̀, nínú ìwà híhù, nínú ìfẹ́, nínú ẹ̀mí, nínú ìgbàgbọ́, nínú ìwà mímọ́, 13 Títí èmi ó fi dé, máa fiyèsí kíkàwé àti ìgbani-níyànjú àti ìkọ́ni. 14 Má ṣe àìnání ẹ̀bùn tí ń bẹ lára rẹ, èyí tí a fi fún ọ nípa ìsọtẹ́lẹ̀ pẹ̀lú ìgbọ́wọ́lé àwọn alàgbà.
15 Máa fiyèsí nǹkan wọ̀nyí; fi ara rẹ fún wọn pátápátá; kí ìlọsíwájú rẹ lè hàn gbangba fún gbogbo ènìyàn. 16 Máa ṣe ìtọ́jú ará rẹ àti ẹ̀kọ́ rẹ; máa dúró láìyẹsẹ̀ nínú nǹkan wọ̀nyí; nítorí ní ṣíṣe èyí, ìwọ ó gba ara rẹ àti tí àwọn ti ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ là.
Jesu káàánú fún Jerusalẹmu
31 Ní wákàtí kan náà, díẹ̀ nínú àwọn Farisi tọ̀ ọ́ wá, wọ́n sì wí fún un pé, “Jáde, kí ìwọ sì lọ kúrò níhìn-ín yìí: nítorí Herodu ń fẹ́ pa ọ́.”
32 (A)Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ lọ, kí ẹ̀yin sì sọ fún kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ náà pé, ‘Kíyèsi i, èmi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, èmi ń ṣe ìmúláradá lónìí àti lọ́la, àti ní ọjọ́ mẹ́ta èmi ó ṣe àṣepé.’ 33 Ṣùgbọ́n èmi kò jẹ́ má rìn lónìí, àti lọ́la, àti ní ọ̀túnla: dájúdájú wòlíì kan ki yóò ṣègbé lẹ́yìn odi Jerusalẹmu.
34 (B)“Jerusalẹmu, Jerusalẹmu, ìwọ tí o pa àwọn wòlíì, tí o sì sọ òkúta lu àwọn tí a rán sí ọ pa; nígbà mélòó ni èmi ń fẹ́ ràgà bo àwọn ọmọ rẹ, bí àgbébọ̀ adìyẹ ti í ràgà bo àwọn ọmọ rẹ̀ lábẹ́ apá rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fẹ́! 35 (C)Sá wò ó, a fi ilé yín sílẹ̀ fún yín ní ahoro. Lóòtítọ́ ni mo sì wí fún yín, ẹ̀yin kì yóò sì rí mi títí yóò fi di àkókò tí ẹ̀yin ó wí pé, ‘Olùbùkún ni ẹni tí ó ń bọ̀ wá ní orúkọ Olúwa.’ ”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.