Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 145

Saamu ìyìn. Ti Dafidi.

145 Èmi yóò gbé ọ ga, Ọlọ́run ọba mi;
    Èmi yóò yin orúkọ rẹ̀ láé àti láéláé
Ní ojoojúmọ́ èmi yóò yìn ọ́
    èmi yóò sì pòkìkí orúkọ rẹ láé àti láéláé.

Títóbi ni Olúwa. Òun sì ni ó yẹ láti fi ìyìn fún púpọ̀púpọ̀:
    kò sí ẹni tí ó lè wọn títóbi rẹ̀.
Ìran kan yóò máa yin iṣẹ́ rẹ dé ìran mìíràn;
    wọn yóò máa sọ iṣẹ́ agbára rẹ
Wọn yóò máa sọ ìyìn ọláńlá rẹ tí ó lógo,
    èmi yóò máa ṣe àṣàrò nínú iṣẹ́ ìyanu rẹ.
Wọn yóò sọ iṣẹ́ agbára rẹ tí ó ní ẹ̀rù
    èmi yóò kéde iṣẹ́ ńlá rẹ̀.
Wọn yóò ṣe ìrántí ọ̀pọ̀lọpọ̀
    ìwà rere rẹ àti orin ayọ̀ òdodo rẹ.

Olóore-ọ̀fẹ́ ni Olúwa àti aláàánú
    ó lọ́ra láti bínú ó sì ní ìfẹ́ púpọ̀.

Olúwa dára sí ẹni gbogbo;
    ó ní àánú lórí ohun gbogbo tí ó dá.
10 Gbogbo ohun tí ìwọ ti dá ni
    yóò máa yìn ọ́ Olúwa;
    àwọn ẹni mímọ́ yóò máa pòkìkí rẹ.
11 Wọn yóò sọ ògo ìjọba rẹ
    wọn yóò sì sọ̀rọ̀ agbára rẹ,
12 Kí gbogbo ènìyàn le mọ iṣẹ́ agbára rẹ̀
    àti ọláńlá ìjọba rẹ tí ó lógo.
13 Ìjọba rẹ ìjọba ayérayé ni,
    àti ìjọba rẹ wà ní gbogbo ìrandíran.
14 Olúwa mú gbogbo àwọn tí ó ṣubú ró
    ó sì gbé gbogbo àwọn tí ó tẹríba dìde.
15 Ojú gbogbo ènìyàn ń wò ọ́,
    ó sì fún wọn ní oúnjẹ wọn ní àkókò tí ó yẹ
16 Ìwọ ṣí ọwọ́ rẹ
    ìwọ sì tẹ́ ìfẹ́ gbogbo ohun alààyè lọ́rùn.

17 Olúwa jẹ́ olódodo ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀
    àti ìfẹ́ rẹ̀ sí gbogbo ohun tí o dá.
18 Olúwa wà ní tòsí gbogbo àwọn tí ń ké pè é,
    sí gbogbo ẹni tí ń ké pè é ní òtítọ́.
19 Ó mú ìfẹ́ àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ṣẹ;
    ó gbọ́ igbe wọn, ó sì gbà wọ́n.
20 Olúwa dá gbogbo àwọn tí ó ní ìfẹ́ sẹ sí
    ṣùgbọ́n gbogbo àwọn ẹni
    búburú ní yóò parun.

21 Ẹnu mi yóò sọ̀rọ̀ ìyìn Olúwa.
    Jẹ́ kí gbogbo ẹ̀dá yín orúkọ rẹ̀ mímọ́ láé àti láéláé.

Error: Book name not found: Sir for the version: Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
Ìṣe àwọn Aposteli 12:25-13:3

25 Barnaba àti Saulu sì padà wá láti Jerusalẹmu, nígbà ti wọ́n sì parí iṣẹ́ ìránṣẹ́ wọn, wọn sì mú Johanu ẹni tí àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Marku wá pẹ̀lú wọn.

A rán Barnaba àti Paulu fún iṣẹ́ ìránṣẹ́

13 Àwọn wòlíì àti àwọn olùkọ́ni sì ń bẹ nínú ìjọ ti ó wà ni Antioku; Barnaba àti Simeoni tí a ń pè ni Nigeri, àti Lukiu ará Kirene, àti Manaeni (ẹni tí a tọ́ pọ̀ pẹ̀lú Herodu tetrarki) àti Saulu. Bí wọn sì ti ń jọ́sìn fún Olúwa, tí wọ́n sì ń gbààwẹ̀, Ẹ̀mí Mímọ́ wí pé, “Ẹ ya Barnaba àti Saulu sọ́tọ̀ fún mi fún iṣẹ́ ti mo ti pè wọ́n sí!” Nígbà tí wọ́n sì ti gbààwẹ̀, tí wọn sì ti gbàdúrà, wọ́n gbé ọwọ́ lé wọn, wọ́n sì rán wọn lọ.

Saamu 67

Fún adarí orin. Pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn. Saamu. Orin.

67 Kí Ọlọ́run kí ó ṣàánú fún wa kí ó sì bùkún fún wa,
    kí ó sì jẹ́ kí ojú rẹ̀ tàn yí wa ká,
kí ọ̀nà rẹ le di mí mọ̀ ní ayé,
    ìgbàlà rẹ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè.

Kí àwọn ènìyàn kí ó yìn ọ́, Ọlọ́run;
    kí gbogbo ènìyàn kí ó yìn ọ́!
Kí orílẹ̀-èdè kí ó yọ̀, kí ó sì kọrin fún ayọ̀,
    nítorí ìwọ fi òdodo darí àwọn ènìyàn,
    ìwọ sì jẹ ọba àwọn orílẹ̀-èdè ní ayé.
Kí àwọn ènìyàn kí ó yìn ọ́, Ọlọ́run;
    kí gbogbo ènìyàn kí ó yìn ọ́. Sela.

Nígbà náà ní ilẹ̀ yóò mú ìkórè rẹ̀ wá, Ọlọ́run,
    Ọlọ́run wa, yóò bùkún fún wa.
Ọlọ́run yóò bùkún fún wa,
    àti gbogbo òpin ilẹ̀ ayé yóò sì máa bẹ̀rù rẹ̀.

Saamu 96

96 (A)Ẹ kọrin tuntun sí Olúwa:
    Ẹ kọrin sí Olúwa gbogbo ayé.
Ẹ kọrin sí Olúwa, yin orúkọ rẹ̀
    ẹ sọ ti ìgbàlà rẹ̀ ní ọjọ́ dé ọjọ́
Ẹ sọ ti ògo rẹ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè
    àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ láàrín gbogbo ènìyàn.

Nítorí títóbi ní Olúwa ẹni tí ìyìn tọ́ sí;
    òun ní o yẹ kí a bẹ̀rù ju gbogbo òrìṣà lọ
Nítorí asán ni gbogbo àwọn òrìṣà orílẹ̀-èdè
    ṣùgbọ́n Olúwa dá àwọn ọ̀run
Ọlá àti ọláńlá wà ní iwájú rẹ̀
    agbára àti ògo wà ní ibi mímọ́ rẹ̀.

Ẹ fi fún Olúwa, ẹ̀yin ìbátan ènìyàn
    Ẹ fi agbára àti ògo fún Olúwa
Ẹ fi ògo tí ó tọ́ sí Olúwa fún un;
    ẹ mú ọrẹ wá, kí ẹ sì wá sí àgbàlá rẹ̀
Ẹ máa sin Olúwa nínú ẹwà ìwà mímọ́ rẹ̀;
    ẹ wárìrì níwájú rẹ̀ gbogbo ayé.
10 Sọ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, “Olúwa jẹ ọba”
    a fi ìdí ayé múlẹ̀, tí kò sì lè yí;
    ẹni tí yóò fi òtítọ́ ṣe ìdájọ́ ènìyàn.

11 Jẹ́ kí àwọn ọ̀run kí ó yọ̀, kí ayé sì pariwo
    jẹ́ kí pápá Òkun kí ó hó pẹ̀lú ohun
gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀.
12     Jẹ́ kí oko kún fún ayọ̀
àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀:
nígbà náà ni gbogbo igi igbó yóò máa yọ̀
13     Wọn yóò kọrin níwájú Olúwa,
    nítorí tí ó ń bọ̀ wá,
Ó ń bọ̀ wá ṣe ìdájọ́ ayé
yóò fi òdodo ṣe ìdájọ́ ayé
    àti ti àwọn ènìyàn ni yóò fi òtítọ́ rẹ̀ ṣe.

2 Timotiu 4:1-11

Nítorí náà mo pàṣẹ fún ọ níwájú Ọlọ́run, àti Kristi Jesu, ẹni tí yóò ṣe ìdájọ́ alààyè àti òkú, àti nítorí ìfarahàn rẹ̀ àti ìjọba rẹ̀. Wàásù ọ̀rọ̀ náà, ṣe àìsimi ní àkókò tí ó wọ̀, àti àkókò ti kò wọ̀; bá ni wí, ṣe ìtọ́ni, gbani níyànjú pẹ̀lú ìpamọ́ra àti ẹ̀kọ́ gbogbo. Nítorí pé ìgbà yóò dé, tí wọn kì yóò lè gba ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro, ṣùgbọ́n bí wọ́n ti jẹ́ ẹni tí etí ń rin, wọn ó lọ kó olùkọ́ jọ fún ara wọn nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wọn. Wọ́n ó sì yí etí wọn padà kúrò nínú òtítọ́, wọn ó sì yípadà sí ìtàn asán. Ṣùgbọ́n máa faradà ìpọ́njú, ṣe iṣẹ́ efangelisti, ṣe iṣẹ́ rẹ láṣepé.

Nítorí à ń fi mi rú ẹbọ nísinsin yìí, àtilọ mi sì súnmọ́ etílé. Èmi ti ja ìjà rere, èmi tí parí iré-ìje mi, èmi ti pa ìgbàgbọ́ mọ́; Láti ìsinsin yìí lọ a fi adé òdodo lélẹ̀ fún mi, tí Olúwa onídàájọ́ òdodo, yóò fífún mi ni ọjọ́ náà kì í sì í ṣe kìkì èmi nìkan ṣùgbọ́n pẹ̀lú fún gbogbo àwọn tí ó ti fẹ́ ìfarahàn rẹ̀.

Àwọn àkíyèsí ti ara ẹni

Sa ipá rẹ láti tètè tọ̀ mí wá. 10 (A)Nítorí Dema ti kọ̀ mí sílẹ̀, nítorí ó ń fẹ́ ayé yìí, ó sì lọ sí Tẹsalonika; Kreskeni sí Galatia, Titu sí Dalimatia. 11 Luku nìkan ni ó wà pẹ̀lú mi, mú Marku wá pẹ̀lú rẹ: nítorí ó wúlò fún mi fún iṣẹ́ ìránṣẹ́.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.