Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 68

Fún adarí orin. Ti Dafidi. Saamu. Orin.

68 Kí Ọlọ́run kí ó dìde, kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ kí ó fọ́nká;
    kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ kí ó sá níwájú rẹ̀.
Bí ìjì ti ń fẹ́ èéfín lọ,
    kí ó fẹ́ wọn lọ;
bí ìda ti í yọ́ níwájú iná,
    kí olùṣe búburú ṣègbé níwájú Ọlọ́run.
Ṣùgbọ́n kí inú olódodo kí ó dùn
    kí ó sì kún fún ayọ̀ níwájú Ọlọ́run;
    kí inú wọn kí ó dùn, kí ó sì kún fún ayọ̀.

Ẹ kọrin sí Ọlọ́run,
    ẹ kọrin ìyìn sí i,
ẹ la ọ̀nà fún ẹni tí ń rékọjá ní aginjù.
    Olúwa ni orúkọ rẹ̀, kí ẹ sì máa yọ̀ níwájú rẹ̀.
Baba àwọn aláìní baba àti onídàájọ́ àwọn opó ni Ọlọ́run ní ibùgbé
    rẹ̀ mímọ́
Ọlọ́run gbé aláìlera
    kalẹ̀ nínú ìdílé,
ó darí àwọn ẹlẹ́wọ̀n pẹ̀lú orin,
    ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́tẹ̀ ní ń gbé nínú ilẹ̀ gbígbẹ.

Nígbà tí ìwọ bá jáde lónìí níwájú àwọn ènìyàn rẹ, Ọlọ́run,
    tí ń kọjá lọ láàrín aginjù, Sela.
Ilẹ̀ mì títí,
    àwọn ọ̀run ń rọ òjò jáde,
níwájú Ọlọ́run,
    ẹni Sinai,
níwájú Ọlọ́run, Ọlọ́run Israẹli.
Ìwọ fún wa ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ òjò, Ọlọ́run;
    ìwọ tu ilẹ̀ ìní rẹ̀ lára nígbà tí ó rẹ̀ ẹ́ tan.
10 Àwọn ènìyàn rẹ tẹ̀dó síbẹ̀
    nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìní rẹ, Ọlọ́run, ìwọ pèsè fún àwọn aláìní.

11 Olúwa ti pàṣẹ ọ̀rọ̀,
    púpọ̀ ní ogun àwọn ẹni tí ó ń ròyìn rẹ̀.
12 “Àwọn ọba àti àwọn ológun yára sálọ;
    Obìnrin tí ó sì jókòó ni ilé ní ń pín ìkógun náà.
13 Nígbà tí ẹ̀yin dùbúlẹ̀ láàrín agbo ẹran,
    nígbà náà ni ẹ̀yin ó dàbí ìyẹ́ àdàbà ti a bò ní fàdákà,
    àti ìyẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú wúrà pupa.”
14 Nígbà tí Olódùmarè fọ́n àwọn ọba ká ní ilẹ̀ náà,
    ó dàbí òjò dídi ní Salmoni.

15 Òkè Baṣani jẹ́ òkè Ọlọ́run;
    òkè tí ó ní orí púpọ̀ ni òkè Baṣani.
16 Kí ló dé tí ẹ̀yin fi ń ṣe ìlara,
    ẹ̀yin òkè wúwo, òkè tí Ọlọ́run ti fẹ́ láti jẹ ọba
    níbi tí Ọlọ́run fúnrarẹ̀ yóò máa gbé títí láé?
17 Ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ni kẹ̀kẹ́ ogun Ọlọ́run
    ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀rún;
    Olúwa ń bẹ láàrín wọn, ní Sinai ni ibi mímọ́ rẹ̀.
18 Ìwọ ti gòkè sí ibi gíga
    ìwọ ti di ìgbèkùn ní ìgbèkùn lọ;
    ìwọ ti gba ẹ̀bùn fún ènìyàn:
nítòótọ́, fún àwọn ọlọ̀tẹ̀ pẹ̀lú,
    Olúwa Ọlọ́run lè máa bá wọn gbé.

19 Olùbùkún ni Olúwa,
    Ọlọ́run Olùgbàlà wa,
ẹni tí ó ń fi ojoojúmọ́ gba ẹrù wa rù. Sela.
20 Ọlọ́run wa jẹ́ Ọlọ́run tó ń gbàlà
    àti sí Olúwa Olódùmarè ni ó ń gbà wá lọ́wọ́ ikú.

21 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò tẹ orí àwọn ọ̀tá rẹ̀,
    àti agbárí onírun àwọn tó ń tẹ̀síwájú nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn
22 Olúwa wí pé, “Èmi ó mú wọn wá láti Baṣani;
    èmi ó mú wọn wá láti ibú omi Òkun,
23 Kí ẹsẹ̀ rẹ kí ó le pọ́n ní inú ẹ̀jẹ̀ àwọn ọ̀tá rẹ,
    àti ahọ́n àwọn ajá rẹ ní ìpín tiwọn lára àwọn ọ̀tá rẹ.”

24 Wọ́n ti rí ìrìn rẹ, Ọlọ́run,
    ìrìn Ọlọ́run mi àti ọba mi ní ibi mímọ́ rẹ̀.
25 Àwọn akọrin ní iwájú,
    tí wọn ń lu ṣaworo
26 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa ní ẹgbẹgbẹ́;
    àní fún Olúwa ẹ̀yin tí ó ti orísun Israẹli wá.
27 Níbẹ̀ ní ẹ̀yà kékeré Benjamini wà, tí ó ń darí wọn,
    níbẹ̀ ni àwọn ọmọ-aládé Juda,
    níbẹ̀ ni àwọn ọmọ-aládé Sebuluni àti tí Naftali.

28 Pàṣẹ agbára rẹ, Ọlọ́run;
    fi agbára rẹ hàn wá, Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti ṣe ní ìṣáájú.
29 Nítorí tẹmpili rẹ ni Jerusalẹmu
    àwọn ọba yóò mú ẹ̀bùn wá fún ọ.
30 Bá àwọn ẹranko búburú wí,
    tí ń gbé láàrín eèsún
ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn akọ màlúù
    pẹ̀lú àwọn ọmọ màlúù
títí olúkúlùkù yóò fi foríbalẹ̀ pẹ̀lú ìwọ̀n fàdákà:
    tú àwọn ènìyàn tí ń ṣe inú dídùn sí ogun ká
31 Àwọn ọmọ-aládé yóò wá láti Ejibiti;
    Etiopia yóò na ọwọ́ rẹ̀ sí Ọlọ́run.

32 Kọrin sí Ọlọ́run, ẹ̀yin ìjọba ayé,
    kọrin ìyìn sí Olúwa, Sela.
33 Sí ẹni tí ń gun ọ̀run dé ọ̀run àtijọ́ lókè,
    tó ń fọhùn rẹ̀, ohùn ńlá.
34 Kéde agbára Ọlọ́run,
    ọláńlá rẹ̀ wà lórí Israẹli,
    tí agbára rẹ̀ wà lójú ọ̀run.
35 Ìwọ ní ẹ̀rù, Ọlọ́run, ní ibi mímọ́ rẹ;
    Ọlọ́run Israẹli fi agbára àti okun fún àwọn ènìyàn rẹ.

Olùbùkún ní Ọlọ́run!

Saamu 72

Ti Solomoni

72 Fi ìdájọ́ fún àwọn ọba, Ọlọ́run,
    ọmọ-aládé ni ìwọ fi òdodo rẹ fún
Yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ pẹ̀lú òdodo,
    yóò sì máa fi ẹ̀tọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn tálákà rẹ̀.

Àwọn òkè ńlá yóò máa mú àlàáfíà fún àwọn ènìyàn
    àti òkè kéékèèkéé nípa òdodo
Yóò dáàbò bo àwọn tí a pọ́n lójú láàrín àwọn ènìyàn
    yóò gba àwọn ọmọ aláìní;
    yóò sì fa àwọn aninilára ya.
Àwọn òtòṣì àti aláìní
    yóò máa fi ọ̀wọ̀ ńlá fún ọ nígbà gbogbo,
níwọ̀n ìgbà tí oòrùn àti òṣùpá bá ń ràn,
    yóò ti pẹ́ tó, láti ìrandíran.
Yóò dàbí òjò tí ó ń rọ̀ sórí pápá ìrẹ́mọ́lẹ̀
    Bí ọwọ́ òjò tó ń rin ilẹ̀
Àwọn olódodo yóò gbilẹ̀ ni ọjọ́ rẹ̀
    ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà yóò sì wà;
    títí tí òṣùpá kò fi ní sí mọ́.

Yóò máa jẹ ọba láti Òkun dé Òkun
    àti láti odò Eufurate títí dé òpin ayé.
Àwọn tí ó wà ní aginjù yóò tẹríba fún un
    àwọn ọ̀tá rẹ̀ yóò máa lá erùpẹ̀ ilẹ̀.
10 Àwọn ọba Tarṣiṣi àti ti erékùṣù
    wọn yóò mú ọrẹ wá fún un;
àwọn ọba Ṣeba àti Seba
    wọn ó mú ẹ̀bùn wá fún un.
11 Gbogbo ọba yóò tẹríba fún un
    àti gbogbo orílẹ̀-èdè yóò sìn ín.

12 Nítorí yóò gba àwọn aláìní
    nígbà tí ó bá ń ké,
tálákà àti ẹni tí kò ní olùrànlọ́wọ́.
13 Yóò káàánú àwọn aláìlera àti aláìní
    yóò pa aláìní mọ́ kúrò nínú ikú.
14 Yóò ra ọkàn wọn padà lọ́wọ́ ẹ̀tàn àti ipá
    nítorí ẹ̀jẹ̀ wọn ṣọ̀wọ́n níwájú rẹ̀.

15 Yóò sì pẹ́ ní ayé!
    A ó sì fún un ní wúrà Ṣeba.
Àwọn ènìyàn yóò sì máa gbàdúrà fún un nígbà gbogbo
    kí a sì bùkún fún un lójoojúmọ́.
16 Kí ìkúnwọ́ ọkà wà lórí ilẹ̀;
    ní orí òkè ni kí ó máa dàgbà
kí èso rẹ̀ kí o gbilẹ̀ bí ti Lebanoni
    yóò máa gbá yìn bí i koríko ilẹ̀.
17 Kí orúkọ rẹ̀ kí ó wà títí láé;
    orúkọ rẹ̀ yóò máa gbilẹ̀ níwọ̀n bí oòrùn yóò ti pẹ́ tó.

Wọn ó sì máa bùkún fún ara wọn nípasẹ̀ rẹ.
    Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ní yóò máa pè mí ní alábùkún fún.

18 Olùbùkún ni Olúwa Ọlọ́run, Ọlọ́run Israẹli,
    ẹnìkan ṣoṣo tí ó ń ṣe ohun ìyanu.
19 Olùbùkún ni orúkọ rẹ̀ tí ó lógo títí láé;
    kí gbogbo ayé kún fún ògo rẹ̀.
Àmín àti Àmín.

20 Èyí ni ìparí àdúrà Dafidi ọmọ Jese.

Gẹnẹsisi 28:10-22

Àlá Jakọbu ní Beteli

10 Jakọbu kúrò ní Beerṣeba, ó sì kọrí sí ìlú Harani. 11 Nígbà tí ó dé ibìkan, ó dúró ní òru náà nítorí tí ilẹ̀ ti ń ṣú, ó sì gbé òkúta kan ó fi ṣe ìrọ̀rí, ó sì sùn. 12 (A)Ó sì lá àlá pé, a gbé àkàsọ̀ kan dúró ti ó fi ìdí lélẹ̀, orí rẹ̀ sì kan ọ̀run, àwọn angẹli Ọlọ́run sì ń gòkè, wọ́n sì ń sọ̀kalẹ̀ lórí rẹ̀. 13 (B)Olúwa sì dúró lókè rẹ̀, ó sì wí pé, “Èmi ni Olúwa, Ọlọ́run baba rẹ Abrahamu àti Ọlọ́run Isaaki, ìwọ àti ìran rẹ ni èmi yóò fi ilẹ̀ tí ìwọ dùbúlẹ̀ sórí rẹ̀ yìí fún. 14 (C)Ìran rẹ yóò pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀, ìwọ yóò sì tànkálẹ̀ dé ìlà-oòrùn àti ìwọ̀-oòrùn, àti dé gúúsù àti àríwá. A ó sì bùkún gbogbo orílẹ̀-èdè ayé nípasẹ̀ ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ. 15 Èmi wà pẹ̀lú rẹ, èmi yóò sì pa ọ mọ́ ní ibikíbi tí ìwọ bá lọ, èmi yóò sì mú ọ padà wá sí ilẹ̀ yìí ní àlàáfíà. Èmi kì yóò fi ọ sílẹ̀ ní ìgbà kan, títí tí èmi yóò fi mú gbogbo ìlérí mi ṣẹ.”

16 Nígbà tí Jakọbu jí lójú oorun rẹ̀, ó rò nínú ara rẹ̀ pé, “Dájúdájú Olúwa ń bẹ ní ìhín yìí, èmi kò sì mọ̀.” 17 Ẹ̀rù sì bà á, ó sì wí pé, “Ìhín yìí ní ẹ̀rù gidigidi; ibí kì í ṣe ibòmíràn bí kò ṣe ilé Ọlọ́run, àní ẹnu ibodè ọ̀run nìyìí.”

18 Jakọbu sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀, ó sì gbé òkúta tí ó fi ṣe ìrọ̀rí lélẹ̀ bí ọ̀wọ́n, ó sì da òróró si lórí. 19 Ó sì pe orúkọ ibẹ̀ ní Beteli (Ilé Ọlọ́run) bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìlú náà ń jẹ́ Lusi tẹ́lẹ̀ rí.

20 Jakọbu sì jẹ́ ẹ̀jẹ́ níbẹ̀ pé, “Bí Ọlọ́run yóò bá wà pẹ̀lú mi, tí yóò sì pa mí mọ́ ní ìrìnàjò mi tí mo ń lọ, tí yóò sì fún mi ní oúnjẹ láti jẹ àti aṣọ láti wọ̀, 21 tí mo sì padà sílé baba mi ní àlàáfíà, nígbà náà Olúwa ni yóò jẹ́ Ọlọ́run mi, 22 Òkúta yìí tí mo gbé kalẹ̀ bí ọ̀wọ́n yóò jẹ́ ilé Ọlọ́run, nínú gbogbo ohun tí ìwọ ó fi fún mi, èmi yóò sì fi ìdámẹ́wàá rẹ̀ fún ọ.”

Heberu 11:13-22

13 (A)Gbogbo àwọn wọ̀nyí ni ó kú nínú ìgbàgbọ́, láìrí àwọn ìlérí náà gbà, ṣùgbọ́n tí wọn rí wọn ni òkèrè réré, tí wọ́n sì gbá wọn mú, tí wọ́n sì jẹ́wọ́ pé àlejò àti àjèjì ni àwọn lórí ilẹ̀ ayé. 14 Nítorí pé àwọn tí o ń sọ irú ohun bẹ́ẹ̀ fihàn gbangba pé, wọn ń ṣe àfẹ́rí ìlú kan tí i ṣe tiwọn. 15 Àti nítòótọ́, ìbá ṣe pé wọ́n fi ìlú tiwọn tí jáde wá sí ọkàn, wọn ìbá ti rí ààyè padà. 16 (B)Ṣùgbọ́n nísinsin yìí wọ́n ń fẹ́ ìlú kan tí o dára jù bẹ́ẹ̀ lọ, èyí yìí ni ti ọ̀run: nítorí náà ojú wọn kò ti Ọlọ́run, pé kí a máa pé òun ni Ọlọ́run wọn; nítorí tí o ti pèsè ìlú kan sílẹ̀ fún wọn.

17 (C)Nípa ìgbàgbọ́ ni Abrahamu, nígbà tí a dán an wò láti, fi Isaaki rú ẹbọ: àní òun ẹni tí ó rí ìlérí gba múra tan láti fi ọmọ bíbí rẹ kan ṣoṣo rú ẹbọ. 18 (D)Nípa ẹni tí wí pé, “Nínú Isaaki ni a ó ti pe irú-ọmọ rẹ̀:” 19 Ó sì rò ó si pé Ọlọ́run tilẹ̀ lè gbé e dìde kúrò nínú òkú, bẹ́ẹ̀ ni, bí a bá sọ ọ́ lọ́nà àpẹẹrẹ, ó gbà á padà.

20 (E)Nípa ìgbàgbọ́ ní Isaaki súre fún Jakọbu àti Esau ní ti ohun tí ń bọ̀.

21 (F)Nípa ìgbàgbọ́ ni Jakọbu, nígbà tí o ń ku lọ, ó súre fún àwọn ọmọ Josẹfu ni ọ̀kọ̀ọ̀kan; ó sì sinmi ní ìtẹríba lé orí ọ̀pá rẹ̀.

22 (G)Nípa ìgbàgbọ́ ni Josẹfu, nígbà tí ó ń ku lọ, ó rántí ìjáde lọ àwọn ọmọ Israẹli; ó sì pàṣẹ ní ti àwọn egungun rẹ̀.

Johanu 10:7-17

Nítorí náà Jesu tún wí fún wọn pé, “Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Èmi ni ìlẹ̀kùn àwọn àgùntàn. (A)Olè àti ọlọ́ṣà ni gbogbo àwọn tí ó ti wà ṣáájú mi: ṣùgbọ́n àwọn àgùntàn kò gbọ́ tiwọn. Èmi ni ìlẹ̀kùn: bí ẹnìkan bá bá ọ̀dọ̀ mi wọlé, òun ni a ó gbàlà, yóò wọlé, yóò sì jáde, yóò sì rí koríko. 10 Olè kì í wá bí kò ṣe láti jalè, láti pa, àti láti parun: èmi wá kí wọn lè ní ìyè, àní kí wọn lè ní i lọ́pọ̀lọpọ̀.

11 (B)“Èmi ni olùṣọ́-àgùntàn rere: olùṣọ́-àgùntàn rere fi ọkàn rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn àgùntàn. 12 Ṣùgbọ́n alágbàṣe, tí kì í ṣe olùṣọ́-àgùntàn, ẹni tí àwọn àgùntàn kì í ṣe tirẹ̀, ó rí ìkookò ń bọ̀, ó sì fi àgùntàn sílẹ̀, ó sì fọ́n wọn ká kiri. 13 Òun sálọ nítorí tí ó jẹ́ alágbàṣe, kò sì náání àwọn àgùntàn.

14 “Èmi ni olùṣọ́-àgùntàn rere, mo sì mọ àwọn tèmi, àwọn tèmi sì mọ̀ mí. 15 (C)Gẹ́gẹ́ bí Baba ti mọ̀ mí, tí èmi sì mọ Baba; mo sì fi ọkàn mi lélẹ̀ nítorí àwọn àgùntàn. 16 (D)Èmi sì ní àwọn àgùntàn mìíràn, tí kì í ṣe agbo yìí: àwọn ni èmi yóò mú wá pẹ̀lú, wọn yóò sì gbọ́ ohùn mi; wọn ó sì jẹ́ agbo kan, olùṣọ́-àgùntàn kan. 17 Nítorí náà ni Baba mi ṣe fẹ́ràn mi, nítorí tí mo fi ẹ̀mí mi lélẹ̀, kí èmi lè tún gbà á.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.