Book of Common Prayer
Orin fún ìgòkè. Ti Dafidi.
131 Olúwa àyà mi kò gbéga,
bẹ́ẹ̀ ni ojú mi kò gbé sókè:
bẹ́ẹ̀ ni èmi kò fi ọwọ́ mi lé ọ̀ràn ńlá,
tàbí lé ohun tí ó ga jù mí lọ
2 Nítòótọ́ èmi mú ọkàn mi sinmi,
mo sì mú un dákẹ́ jẹ́ẹ́,
bí ọmọ tí a ti ọwọ́ ìyá rẹ̀ gbà ní ẹnu ọmú:
ọkàn mi rí gẹ́gẹ́ bí ọmọ tí a já ní ẹnu ọmú.
3 Israẹli, ìwọ ní ìrètí ní ti Olúwa
láti ìsinsin yìí lọ àti láéláé.
Orin fún ìgòkè.
132 Olúwa, rántí Dafidi
nínú gbogbo ìpọ́njú rẹ̀.
2 Ẹni tí ó ti búra fún Olúwa,
tí ó sì ṣe ìlérí fún Alágbára Jakọbu pé.
3 Nítòótọ́, èmi kì yóò wọ inú àgọ́ ilé mi lọ,
bẹ́ẹ̀ èmi kì yóò gun orí àkéte mi:
4 Èmi kì yóò fi oorun fún ojú mi,
tàbí òògbé fún ìpéǹpéjú mi,
5 Títí èmi ó fi rí ibi fún Olúwa,
ibùjókòó fún Alágbára Jakọbu.
6 Kíyèsi i, àwa gbúròó rẹ̀ ni Efrata:
àwa rí i nínú oko ẹgàn náà.
7 Àwa ó lọ sínú àgọ́ rẹ̀:
àwa ó máa sìn níbi àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀
8 Olúwa, dìde sí ibi ìsinmi rẹ:
ìwọ, àti àpótí agbára rẹ.
9 Kí a fi òdodo wọ àwọn àlùfáà rẹ:
kí àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ kí ó máa hó fún ayọ̀.
10 Nítorí tí Dafidi ìránṣẹ́ rẹ̀
Má ṣe yí ojú ẹni òróró rẹ padà.
11 (A)Olúwa ti búra nítòótọ́ fún Dafidi:
Òun kì yóò yípadà kúrò nínú rẹ̀,
nínú irú-ọmọ inú rẹ ni èmi ó gbé kalẹ̀ sí orí ìtẹ́ rẹ.
12 Bí àwọn ọmọ rẹ̀ yóò bá pa májẹ̀mú mi mọ́
àti ẹ̀rí mi tí èmi yóò kọ́ wọn,
àwọn ọmọ wọn pẹ̀lú yóò jókòó lórí ìtẹ́ rẹ láéláé.
13 Nítorí tí Olúwa ti yan Sioni:
ó ti fẹ́ ẹ fún ibùjókòó rẹ̀.
14 Èyí ni ibi ìsinmi mi láéláé:
níhìn-ín ni èmi yóò máa gbé:
nítorí tí mo fẹ́ ẹ.
15 Èmi yóò bùkún oúnjẹ rẹ̀ púpọ̀púpọ̀:
èmi yóò fi oúnjẹ tẹ́ àwọn tálákà rẹ̀ lọ́rùn.
16 Èmi yóò sì fi ìgbàlà wọ àwọn àlùfáà rẹ̀:
àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ yóò máa hó fún ayọ̀.
17 Níbẹ̀ ni èmi yóò gbé mú ìwo Dafidi yọ̀,
èmi ti ṣe ìlànà fìtílà kan fún ẹni òróró mi.
18 Àwọn ọ̀tá rẹ̀ ni èmi yóò fi ìtìjú wọ̀:
ṣùgbọ́n lára òun tìkára rẹ̀ ni adé yóò máa gbilẹ̀.
Orin fún ìgòkè. Ti Dafidi
133 Kíyèsi, ó ti dára ó sì ti dùn tó fún
àwọn ará láti máa jùmọ̀ gbé ní ìrẹ́pọ̀.
2 Ó dàbí òróró ìkunra iyebíye ní orí,
tí ó sàn dé irùngbọ̀n, àní irùngbọ̀n Aaroni:
tí ó sì sàn sí etí aṣọ sórí rẹ̀;
3 Bí ìrì Hermoni
tí o sàn sórí òkè Sioni.
Nítorí níbẹ̀ ní Olúwa gbé pàṣẹ ìbùkún,
àní ìyè láéláé.
Orin ìgòkè.
134 Ẹ kíyèsi i, ẹ fi ìbùkún fún Olúwa,
gbogbo ẹ̀yin ìránṣẹ́ Olúwa,
tí ó dúró ní ilé Olúwa ní òru.
2 Ẹ gbé ọwọ́ yín sókè sí ibi mímọ́,
kí ẹ sì fi ìbùkún fún Olúwa.
3 Olúwa tí ó dá ọ̀run òun ayé,
kí ó bùsi i fún ọ láti Sioni wá.
135 Ẹ yin Olúwa.
Ẹ yin orúkọ Olúwa;
ẹ yìn ín, ẹ̀yin ìránṣẹ́ Olúwa.
2 Ẹ̀yin tí ń dúró ní ilé Olúwa,
nínú àgbàlá ilé Ọlọ́run wa.
3 Ẹ yin Olúwa: nítorí tí Olúwa ṣeun;
ẹ kọrin ìyìn sí orúkọ rẹ̀; nítorí tí ó dùn.
4 Nítorí tí Olúwa ti yan Jakọbu fún ara rẹ̀;
àní Israẹli fún ìṣúra ààyò rẹ̀.
5 Nítorí tí èmi mọ̀ pé Olúwa tóbi,
àti pé Olúwa jù gbogbo òrìṣà lọ.
6 Olúwa ṣe ohunkóhun tí ó wù ú,
ní ọ̀run àti ní ayé,
ní Òkun àti ní ọ̀gbun gbogbo.
7 Ó mú ìkùùkuu gòkè láti òpin ilẹ̀ wá:
ó dá mọ̀nàmọ́ná fún òjò:
ó ń mú afẹ́fẹ́ ti inú ilẹ̀ ìṣúra rẹ̀ wá.
8 Ẹni tí ó kọlu àwọn àkọ́bí Ejibiti,
àti ti ènìyàn àti ti ẹranko.
9 Ẹni tí ó rán iṣẹ́ ààmì àti iṣẹ́ ìyanu sí àárín rẹ̀, ìwọ Ejibiti,
sí ara Farao àti sí ara àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ gbogbo.
10 Ẹni tí ó kọlu àwọn orílẹ̀-èdè púpọ̀,
tí ó sì pa àwọn alágbára ọba.
11 Sihoni, ọba àwọn ará Amori, àti Ogu,
ọba Baṣani, àti gbogbo ìjọba Kenaani:
12 Ó sì fi ilẹ̀ wọn fún ni ní ìní,
ìní fún Israẹli, ènìyàn rẹ̀.
13 Olúwa orúkọ rẹ dúró láéláé;
ìrántí rẹ Olúwa, láti ìrandíran.
14 (B)Nítorí tí Olúwa yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀,
yóò sì ṣe ìyọ́nú sí àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀.
15 Fàdákà òun wúrà ni èrè àwọn aláìkọlà,
iṣẹ́ ọwọ́ ènìyàn ni.
16 Wọ́n ní ẹnu, ṣùgbọ́n wọn kò le sọ̀rọ̀;
wọ́n ní ojú, ṣùgbọ́n wọn kò fi ríran.
17 Wọ́n ní etí, ṣùgbọ́n wọn kò fi gbọ́rọ̀;
bẹ́ẹ̀ ni kò si èémí kan ní ẹnu wọn
18 Àwọn tí ń ṣe wọ́n dàbí wọn:
gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni olúkúlùkù ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé wọn.
19 Ẹ̀yin ara ilé Israẹli, ẹ fi ìbùkún fún Olúwa,
ẹ̀yin ará ilé Aaroni, fi ìbùkún fún Olúwa.
20 Ẹ̀yin ará ilé Lefi, fi ìbùkún fún Olúwa;
ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù Olúwa, fi ìbùkún fún Olúwa.
21 Olùbùkún ni Olúwa, láti Sioni wá,
tí ń gbé Jerusalẹmu.
Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
Ìwẹ̀nùmọ́ kúrò nínú ẹsẹ̀
13 “Ní ọjọ́ náà ìsun kan yóò ṣí sílẹ̀ fún ilé Dafidi àti fún àwọn ará Jerusalẹmu, láti wẹ̀ wọ́n mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àti àìmọ́ wọn.
2 “Yóò sì ṣe ní ọjọ́ náà ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, ni èmi ó gé orúkọ àwọn òrìṣà kúrò ni ilẹ̀ náà, a kì yóò sì rántí wọn mọ́: àti pẹ̀lú èmi ó mú àwọn wòlíì èké àti àwọn ẹ̀mí àìmọ́ kúrò ni ilẹ̀ náà. 3 Yóò sì ṣe, nígbà tí ẹnìkan yóò sọtẹ́lẹ̀ síbẹ̀, ni baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ tí ó bí í yóò wí fún un pé, ‘Ìwọ ki yóò yè: nítorí ìwọ ń sọ ọ̀rọ̀ èké ni orúkọ Olúwa.’ Àti baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ tí o bí í yóò gun un ni àgúnpa nígbà tí ó bá sọtẹ́lẹ̀.
4 “Yóò sì ṣe ní ọjọ́ náà, ojú yóò tí àwọn wòlíì èké olúkúlùkù nítorí ìran rẹ̀, nígbà tí òun ba tí sọtẹ́lẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò sì wọ aṣọ wòlíì onírun rẹ̀ tí o fi ń tan ní jẹ. 5 Ṣùgbọ́n òun o wí pé, ‘Èmi kí í ṣe wòlíì, àgbẹ̀ ni èmi; nítorí tí a ti fi mí ṣe ìránṣẹ́ láti ìgbà èwe mi wá.’ 6 Ẹnìkan ó sì wí fún un pé, ‘Ọgbẹ́ kín ní wọ̀nyí ni ẹ̀yìn rẹ?’ Òun o sì dáhùn pé, ‘Wọ̀nyí ni ibi tí a ti sá mi ní ilé àwọn ọ̀rẹ́ mi.’
A lu olùṣọ́-àgùntàn, agbo ẹran fọ́nká
7 (A)“Dìde, ìwọ idà, sí olùṣọ́-àgùntàn mi,
àti sí ẹni tí í ṣe ẹnìkejì mi,”
ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí:
“Kọlu Olùṣọ́-àgùntàn,
àwọn àgùntàn a sì túká:
èmi o sì yí ọwọ́ mi sí àwọn kéékèèkéé.
8 Yóò sì ṣe, ni gbogbo ilẹ̀,” ni Olúwa wí,
“a ó gé apá méjì nínú rẹ̀ kúrò yóò sì kú;
ṣùgbọ́n apá kẹta yóò kù nínú rẹ̀.
9 Èmi ó sì mú apá kẹta náà la àárín iná,
èmi yóò sì yọ́ wọn bí a ti yọ́ fàdákà,
èmi yóò sì dán wọn wò, bi a tí ń dán wúrà wò:
wọn yóò sì pé orúkọ mi,
èmi yóò sì dá wọn lóhùn:
èmi yóò wí pé, ‘Àwọn ènìyàn mi ni,’
àwọn yóò sì wí pé, ‘Olúwa ni Ọlọ́run wa.’ ”
Ìdúpẹ́ àti àdúrà
15 (A)Nítorí ìdí èyí, nígbà tí mo ti gbúròó ìgbàgbọ́ ti ń bẹ láàrín yín nínú Jesu Olúwa, àti ìfẹ́ yín sí gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́. 16 (B)Èmi kò sì sinmi láti máa dúpẹ́ nítorí yín, àti láti máa rántí yín nínú àdúrà mi; 17 Mo sì ń béèrè nígbà gbogbo pé kí Ọlọ́run Jesu Kristi Olúwa wa, Baba ògo, lè fún yín ni Ẹ̀mí nípa ti ọgbọ́n àti ti ìfihàn kí ẹ̀yin kí ó tún lè mọ̀ ọ́n sí i. 18 (C)Mo tún ń gbàdúrà bákan náà wí pé kí ojú ọkàn yín lè mọ́lẹ̀; kí ẹ̀yin lè mọ ohun tí ìrètí ìpè rẹ̀ jẹ́, àti ọrọ̀ ògo rẹ̀ èyí tí í ṣe ogún àwọn ènìyàn mímọ́, 19 àti aláìlẹ́gbẹ́ títóbi agbára rẹ̀ fún àwa tí a gbàgbọ́. Gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ agbára rẹ̀, 20 (D)èyí tí ó fi sínú Kristi, nígbà tí o ti jí dìde kúrò nínú òkú, tí ó sì mú un jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún nínú àwọn ọ̀run. 21 (E)Ó gbéga ju gbogbo ìjọba, àti àṣẹ, àti agbára, àti òye àti gbogbo orúkọ tí a ń dá, kì í ṣe ni ayé yìí nìkan, ṣùgbọ́n ni èyí tí ń bọ̀ pẹ̀lú. 22 (F)Ọlọ́run sì ti fi ohun gbogbo sábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì fi í ṣe orí lórí ohun gbogbo fún ìjọ, 23 (G)èyí tí i ṣe ara rẹ̀, ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ẹni tí ó kún ohun gbogbo ní gbogbo ọ̀nà.
Òwe minas mẹ́wàá
11 (A)Nígbà tí wọ́n sì ń gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, ó sì tẹ̀síwájú láti pa òwe kan, nítorí tí ó súnmọ́ Jerusalẹmu, àti nítorí tí wọn ń rò pé, ìjọba Ọlọ́run yóò farahàn nísinsin yìí. 12 (B)(C)Ó sì wí pé, “Ọkùnrin ọlọ́lá kan lọ sí ìlú òkèrè láti gba ìjọba kí ó sì padà. 13 Ó sì pe àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ mẹ́wàá, ó fi owó mina mẹ́wàá fún wọn, ó sì wí fún wọn pé, ‘Ẹ máa ṣòwò títí èmi ó fi dé!’
14 “Ṣùgbọ́n àwọn ará ìlù rẹ̀ kórìíra rẹ̀, wọ́n sì rán ikọ̀ tẹ̀lé e, wí pé, ‘Àwa kò fẹ́ kí ọkùnrin yìí jẹ ọba lórí wa.’
15 “Nígbà tí ó gba ìjọba tan, tí ó padà dé, ó pàṣẹ pé, kí a pe àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ wọ̀nyí tí òun ti fi owó fún wá sọ́dọ̀ rẹ̀, nítorí kí ó le mọ iye èrè tí olúkúlùkù ti jẹ nínú iṣẹ́ òwò wọn.
16 “Èyí èkínní sì wá, ó wí pé, ‘Olúwa, owó mina rẹ jèrè owó mina mẹ́wàá sí i.’
17 (D)“Olúwa rẹ̀ sì wí fún un pé, ‘O ṣeun, ìwọ ọmọ ọ̀dọ̀ rere! Nítorí tí ìwọ ṣe olóòtítọ́ ní ohun kínkínní, gba àṣẹ lórí ìlú mẹ́wàá.’
18 “Èyí èkejì sì wá, ó wí pé, ‘Olúwa, owó mina rẹ jèrè owó mina márùn.’
19 “Olúwa rẹ sì wí fún un pẹ̀lú pé, ‘Ìwọ pẹ̀lú joyè ìlú márùn-ún!’
20 “Òmíràn sì wá, ó wí pé, ‘Olúwa, wò ó owó mina rẹ tí ń bẹ lọ́wọ́ mi ni mo dì sínú aṣọ pélébé kan; 21 Nítorí mo bẹ̀rù rẹ, àti nítorí tí ìwọ ṣe òǹrorò ènìyàn: ìwọ a máa mú èyí tí ìwọ kò fi lélẹ̀, ìwọ a sì máa ká èyí tí ìwọ kò gbìn!’
22 “Olúwa rẹ sì wí fún un pé, ‘Ní ẹnu ara rẹ náà ni èmi ó ṣe ìdájọ́ rẹ, ìwọ ọmọ ọ̀dọ̀ búburú, ìwọ mọ̀ pé òǹrorò ènìyàn ni mí, pé, èmi a máa mú èyí tí èmi kò fi lélẹ̀ èmi a sì máa ká èyí tí èmi kò gbìn; 23 Èéha sì ti ṣe tí ìwọ kò fi owó mi pamọ́ sí ilé ìfowópamọ́, pé nígbà tí mo bá dé, Èmi ìbá ti béèrè rẹ̀ pẹ̀lú èlé?’
24 “Ó sì wí fún àwọn tí ó dúró létí ibẹ̀ pé, ‘Ẹ gba owó mina náà lọ́wọ́ rẹ̀, kí ẹ sì fi í fún ẹni tí ó ní owó minas mẹ́wàá.’
25 “Wọ́n sì wí fún un pé, ‘Olúwa, ó ní owó mina mẹ́wàá.’
26 (E)“Mo wí fún yín pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó ní, ni a ó fi fún, àti lọ́dọ̀ ẹni tí kò ní èyí tí ó ní pàápàá a ó gbà á lọ́wọ́ rẹ̀. 27 Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀tá mi wọ̀nyí, tí kò fẹ́ kí èmi jẹ ọba lórí wọn ẹ mú wọn wá ìhín yìí, kí ẹ sì pa wọ́n níwájú mi!’ ”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.