Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 55

Fún adarí orin. Pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn. Maskili ti Dafidi.

55 Fi etí sí àdúrà mi, Ọlọ́run,
    Má ṣe fi ojú pa ẹ̀bẹ̀ mi rẹ́:
    Gbọ́ mi kí o sì dá mi lóhùn.
Èrò mi ń dà mí láàmú, èmi sì ń pariwo.
    Sí ohùn àwọn ọ̀tá ni,
    nítorí igbe àwọn ènìyàn búburú;
nítorí wọ́n mú ìjìyà wá sórí mi,
    wọ́n sì kẹ́gàn mi nínú ìbínú wọn.

Ọkàn mi wà nínú ìrora pẹ̀lú;
    ẹ̀rù ikú kọjú ìjà sí mi.
Ìbẹ̀rù àti ìwárìrì wa sí ara mi;
    ìbẹ̀rù ti bò mí mọ́lẹ̀.
Èmi sọ pé, “Èmi ìbá ní ìyẹ́ bí àdàbà!
    Èmi ìbá fò lọ kí n sì sinmi.
Èmi ìbá sálọ, jìnnà réré,
    kí ń sì dúró sí aginjù;
Èmi ìbá yára lọ́ si ibùgbé mi ní ibi ààbò,
    jìnnà kúrò nínú ìjì àti ẹ̀fúùfù líle.”

Da àwọn ẹni búburú láàmú, Olúwa, da ahọ́n wọn rú,
    nítorí èmi rí ìwà agbára àti ìjà ní ìlú náà.
10 Ọ̀sán àti òru ni wọ́n fi ń rìn gbogbo odi kiri;
    ìwà ìkà àti èébú wà láàrín rẹ̀.
11 Ìwà búburú ń bẹ ní àárín rẹ̀;
    ẹ̀tàn àti èké kò kúrò ní ìgboro rẹ̀.

12 Tí ọ̀tá bá tàbùkù mi,
    èmi yóò fi ara mọ́ ọn;
tí ọ̀tá bá gbé ara rẹ̀ ga sí mi,
    èmi ìbá sápamọ́ fún un.
13 Ṣùgbọ́n tí ó bá ṣe ìwọ, ọkùnrin bí ẹgbẹ́ mi,
    ẹlẹgbẹ́ mi, àti ọ̀rẹ́ tí ó súnmọ́ mi,
14 pẹ̀lú ẹni tí èmi ti jẹ ìgbádùn adùn ìdàpọ̀,
    bí a ṣe ń rìn pẹ̀lú àwùjọ ní ilé Ọlọ́run.

15 Kí ikú kí ó dé bá wọn,
    Kí wọn ó lọ láààyè sí isà òkú,
Jẹ́ kí wọn ó sọ̀kalẹ̀ sí ibojì pẹ̀lú ìpayà,
    nítorí tí ìwà búburú ń bẹ ní ibùjókòó wọn, àti nínú wọn.

16 Ṣùgbọ́n èmi pe Ọlọ́run;
    Olúwa yóò sì gbà mí.
17 Ní alẹ́, ní òwúrọ̀ àti ní ọ̀sán
    èmi sọkún jáde nínú ìpọ́njú,
    o sì gbọ́ ohùn mi.
18 Ó rà mí padà láìléwu
    kúrò nínú ogun tí ó dìde sí mi,
    nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó dìde sí mi.
19 Ọlọ́run yóò gbọ́, yóò sì pọ́n wọn lójú
    àní, ẹni tí ó ti jókòó láti ìgbàanì—Sela.
Nítorí tí wọn kò ní àyípadà,
    tí wọn kò sì bẹ̀rù Ọlọ́run.

20 Ọ̀rẹ́ mi yìí ti dalẹ̀ èmi ọ̀rẹ́ rẹ̀;
    ó ti ba májẹ̀mú rẹ̀ jẹ́.
21 Ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ kúnná ju òrí-àmọ́,
    ṣùgbọ́n ogun wà ni àyà rẹ̀;
ọ̀rọ̀ rẹ̀ fẹ́lẹ́ ju òróró lọ,
    ṣùgbọ́n idà fífàyọ ní wọn.

22 (A)Gbé ẹrù rẹ lọ sí ọ̀dọ̀ Olúwa
    yóò sì mú ọ dúró;
òun kò ní jẹ́ kí olódodo ṣubú.
23 Ṣùgbọ́n ìwọ, Ọlọ́run, ni yóò mu àwọn ọ̀tá mi
    wá sí ihò ìparun;
Àwọn ẹni tí òǹgbẹ ẹ̀jẹ̀ ń gbẹ àti ẹni ẹ̀tàn,
    kì yóò gbé ààbọ̀ ọjọ́ wọn.

Ṣùgbọ́n fún èmi, èmi gbẹ́kẹ̀lé ọ.

Saamu 138:1-139:23

Ti Dafidi

138 Èmi yóò yìn ọ́ tinútinú mi gbogbo;
    níwájú àwọn òrìṣà ni èmi ó kọrin ìyìn sí ọ.
Èmi ó máa gbàdúrà sí ìhà tẹmpili mímọ́ rẹ̀
    èmi ó sì máa yin orúkọ rẹ
nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ àti òtítọ́ rẹ;
    nítorí ìwọ gbé ọ̀rọ̀ rẹ ga ju orúkọ rẹ lọ.
Ní ọjọ́ tí mo ké pè é ọ́, ìwọ dá mi lóhùn,
    ìwọ sì fi ipa mú mi lára le ní ọkàn mi.

Gbogbo àwọn ọba ayé yóò yìn ọ́,
    Olúwa, ní ìgbà tí wọn bá gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ
Nítòótọ́, wọn ó máa kọrin ní ipa ọ̀nà Olúwa;
    nítorí pé ńlá ni ògo Olúwa.

Olúwa tilẹ̀ ga, síbẹ̀ ó júbà àwọn onírẹ̀lẹ̀;
    ṣùgbọ́n agbéraga ni ó mọ̀ ní òkèrè réré.
Bí èmi tilẹ̀ ń rìn nínú ìpọ́njú ìwọ ni yóò sọ mi di ààyè;
    ìwọ ó na ọwọ́ rẹ sí àwọn ọ̀tá mi,
    ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò sì gbà mí.
Olúwa yóò ṣe ohun tí ń ṣe tèmi láṣepé;
    Olúwa, àánú rẹ dúró láéláé;
    Má ṣe kọ iṣẹ́ ọwọ́ ara rẹ sílẹ̀.

Fún adarí orin. Ti Dafidi. Saamu.

139 Olúwa, ìwọ tí wádìí mi,
    ìwọ sì ti mọ̀ mí.
Ìwọ mọ̀ ìjókòó mi àti ìdìde mi,
    ìwọ mọ̀ èrò mi ní ọ̀nà jíjìn réré.
Ìwọ yí ipa ọ̀nà mi ká àti ìdùbúlẹ̀ mi,
    gbogbo ọ̀nà mi sì di mí mọ̀ fún ọ.
Nítorí tí kò sí ọ̀rọ̀ kan ní ahọ́n mi,
    kíyèsi i, Olúwa, ìwọ mọ̀ ọ́n pátápátá.
Ìwọ sé mi mọ́ lẹ́yìn àti níwájú,
    ìwọ sì fi ọwọ́ rẹ lé mi.
Irú ìmọ̀ yìí jẹ ohun ìyanu fún mi jù;
    ó ga, èmi kò le mọ̀ ọ́n.

Níbo ní èmi yóò gbé lọ kúrò ni ọwọ́ ẹ̀mí rẹ?
    Tàbí níbo ni èmi yóò sáré kúrò níwájú rẹ?
Bí èmi bá gòkè lọ sí ọ̀run, ìwọ wà níbẹ̀;
    bí èmí ba sì tẹ́ ẹní mi ní ipò òkú,
    kíyèsi i, ìwọ wà níbẹ̀ pẹ̀lú.
Èmi ìbá mú ìyẹ́ apá òwúrọ̀,
    kí èmi sì lọ jókòó ní ìhà òpin Òkun;
10 Àní, níbẹ̀ náà ni ọwọ́ rẹ̀ yóò fà mí
    ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò sì dì mímú.
11 Bí mo bá wí pé, “Ǹjẹ́ kí òkùnkùn kí ó bò mí mọ́lẹ̀;
    kí ìmọ́lẹ̀ kí ó di òru yí mi ká.”
12 Nítòótọ́ òkùnkùn kì í ṣú lọ́dọ̀ rẹ;
    ṣùgbọ́n òru tan ìmọ́lẹ̀ bí ọ̀sán;
    àti òkùnkùn àti ọ̀sán, méjèèjì bákan náà ní fún ọ.

13 Nítorí ìwọ ni ó dá ọkàn mi;
    ìwọ ni ó bò mí mọ́lẹ̀ nínú ìyá mi.
14 Èmi yóò yìn ọ, nítorí tẹ̀rù tẹ̀rù àti tìyanu tìyanu ní a dá mi;
    ìyanu ní iṣẹ́ rẹ;
    èyí nì ni ọkàn mi sì mọ̀ dájúdájú
15 Ẹ̀dá ara mi kò pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ rẹ,
    nígbà tí a dá mi ní ìkọ̀kọ̀.
    Tí a sì ń ṣiṣẹ́ ní àràbarà ní ìhà ìsàlẹ̀ ilẹ̀ ayé,
16 ojú rẹ ti rí ohun ara mi
    nígbà tí a kò tí ì ṣe mí pé:
    àti nínú ìwé rẹ ni a ti kọ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sí,
ní ọjọ́ tí a dá wọn,
    nígbà tí wọn kò tilẹ̀ tí ì sí.
17 Ọlọ́run, èrò inú rẹ tí ṣe iyebíye tó fún mi,
    iye wọn ti pọ̀ tó!
18 Èmi ìbá kà wọ́n,
    wọ́n ju iyanrìn lọ ní iye:
nígbà tí mo bá jí,
    èmi yóò wà lọ́dọ̀ rẹ síbẹ̀.

19 Ọlọ́run ìbá jẹ́ pa àwọn ènìyàn búburú nítòótọ́;
    nítorí náà kúrò lọ́dọ̀ mi ẹ̀yin ọkùnrin ẹlẹ́jẹ̀.
20 Ẹni tí ń fi inú búburú sọ̀rọ̀ sí ọ,
    àwọn ọ̀tá rẹ ń pe orúkọ rẹ ní asán!
21 Olúwa, ǹjẹ́ èmi kò kórìíra àwọn tó kórìíra rẹ?
    Ǹjẹ́ inú mi kò a sì bàjẹ́ sí àwọn tí ó dìde sí ọ?
22 Èmi kórìíra wọn ní àkótán;
    èmi kà wọ́n sí ọ̀tá mi.
23 Ọlọ́run, wádìí mi, kí o sì mọ ọkàn mí;
    dán mi wò, kí o sì mọ ìrò inú mi

Error: Book name not found: Sir for the version: Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
Ìfihàn 13:11-18

Ẹranko jáde nínú ilẹ̀

11 Mo sì rí ẹranko mìíràn gòkè láti inú ilẹ̀ wá; ó sì ní ìwo méjì bí ọ̀dọ́-àgùntàn, ó sì ń sọ̀rọ̀ bí dragoni. 12 Ó sì ń lo gbogbo agbára ẹranko èkínní níwájú rẹ̀, ó sì mú ilẹ̀ ayé àti àwọn tí ń gbé inú rẹ̀ foríbalẹ̀ fún ẹranko èkínní tí a ti wo ọgbẹ́ àṣápa rẹ̀ sàn. 13 Ó sì ń ṣe ohun ìyanu ńlá, àní tí ó fi ń mú iná sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá sì ilẹ̀ ayé níwájú àwọn ènìyàn. 14 (A)Ó sì ń tán àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé jẹ nípa àwọn ohun ìyanu tí a fi fún un láti ṣe níwájú ẹranko náà; ó wí fún àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé láti ya àwòrán fún ẹranko náà tí o tí gbá ọgbẹ́ idà, tí ó sì yè. 15 (B)A sì fi fún un, láti fi ẹ̀mí fún àwòrán ẹranko náà kí ó máa sọ̀rọ̀ kí ó sì mu kí a pa gbogbo àwọn tí kò foríbalẹ̀ fún àwòrán ẹranko náà. 16 Ó sì mu gbogbo wọn, àti kékeré àti ńlá, ọlọ́rọ̀ àti tálákà, olómìnira àti ẹrú, láti gba ààmì kan sí ọwọ́ ọ̀tún wọn, tàbí ní iwájú orí wọn; 17 àti kí ẹnikẹ́ni má lè rà tàbí tà, bí kò ṣe ẹni tí o bá ní ààmì náà, èyí ni orúkọ ẹranko náà, tàbí ààmì orúkọ rẹ̀.

18 Níhìn-ín ni ọgbọ́n gbé wà. Ẹni tí o bá ní òye, kí o ka òǹkà tí ń bẹ̀ lára ẹranko náà: nítorí pé òǹkà ènìyàn ni, òǹkà rẹ̀ náà sì jẹ́ ẹgbẹ̀ta-ọgọ́ta-ẹẹ́fà. (666).

Luku 12:32-48

32 (A)“Má bẹ̀rù, agbo kékeré; nítorí dídùn inú Baba yín ni láti fi ìjọba fún yín. 33 (B)Ẹ ta ohun tí ẹ̀yin ní, kí ẹ sì tọrẹ àánú kí ẹ sì pèsè àpò fún ara yín, tí kì í gbó, ìṣúra ní ọ̀run tí kì í tán, ní ibi tí olè kò lè súnmọ́, àti ibi tí kòkòrò kì í bà á jẹ́. 34 Nítorí ní ibi tí ìṣúra yín gbé wà, níbẹ̀ ni ọkàn yín yóò gbé wà pẹ̀lú.

Ẹ máa ṣọ́nà

35 (C)“Ẹ di àmùrè yín, kí fìtílà yín sì máa jó. 36 Kí ẹ̀yin tìkára yín dàbí ẹni tí ń retí olúwa wọn, nígbà tí òun ó padà ti ibi ìgbéyàwó dé: pé, nígbà tí ó bá dé, tí ó sì kànkùn, kí wọn lè ṣí i sílẹ̀ fún un lọ́gán. 37 (D)Ìbùkún ni fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ náà nígbà tí olúwa náà bá dé tí yóò bá wọn tí wọn ń ṣọ́nà; lóòótọ́ ni mo wí fún yín, yóò di ara rẹ̀ ní àmùrè yóò sì mú wọn jókòó láti jẹun, yóò sì jáde wá láti ṣe ìránṣẹ́ fún wọn. 38 Bí olúwa wọn bá sì dé nígbà ìṣọ́ kejì, tàbí tí ó sì dé nígbà ìṣọ́ kẹta, tí ó sì bá wọn bẹ́ẹ̀, ìbùkún ni fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ náà. 39 (E)Ṣùgbọ́n ẹ mọ èyí pé, baálé ilé ìbá mọ wákàtí tí olè yóò wá, (òun ìbá máa ṣọ́nà) kì bá tí jẹ́ kí a já wọ inú ilé òun. 40 Nítorí náà kí ẹ̀yin múra pẹ̀lú: Nítorí ọmọ ènìyàn ń bọ̀ ní wákàtí tí ẹ̀yin kò nírètí.”

41 Peteru sì wí pé, “Olúwa, ìwọ pa òwe yìí fún wa, tàbí fún gbogbo ènìyàn?”

42 (F)(G) Olúwa sì dáhùn wí pé, “Ta ni olóòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n ìríjú náà, tí olúwa rẹ̀ fi jẹ olórí agbo ilé rẹ̀, láti máa fi ìwọ̀n oúnjẹ wọ́n fún wọn ní àkókò? 43 Ìbùkún ni fún ọmọ ọ̀dọ̀ náà, nígbà tí olúwa rẹ̀ bá dé, tí yóò bá a kí ó máa ṣe bẹ́ẹ̀. 44 Lóòótọ́ ni mo wí fún yín yóò fi jẹ olórí ohun gbogbo tí ó ní. 45 Ṣùgbọ́n bí ọmọ ọ̀dọ̀ náà bá wí ní ọkàn rẹ̀, pé, ‘Olúwa mi fi ìgbà bíbọ̀ rẹ̀ falẹ̀!’ Tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í lu àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ àti sí mu àmupara: 46 Olúwa ọmọ ọ̀dọ̀ náà yóò dé ní ọjọ́ tí kò retí rẹ̀, àti ní wákàtí tí kò dábàá, yóò sì jẹ ẹ́ ní yà gidigidi, yóò sì yan ipò rẹ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́.

47 (H)“Àti ọmọ ọ̀dọ̀ náà, tí ó mọ ìfẹ́ olúwa rẹ̀, tí kò sì múra sílẹ̀, tí kò sì ṣe gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀, òun ni a ó nà púpọ̀. 48 Ṣùgbọ́n èyí tí kò mọ̀, tí ó ṣe ohun tí ó yẹ sí lílù, òun ni a ó lù níwọ̀n. Nítorí ẹnikẹ́ni tí a fún ní púpọ̀, lọ́dọ̀ rẹ̀ ni a ó gbé béèrè púpọ̀: lọ́dọ̀ ẹni tí a bá gbé fi púpọ̀ sí, lọ́dọ̀ rẹ ni a ó gbé béèrè sí i.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.