Book of Common Prayer
Fún adarí orin. Orin. Saamu.
66 Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Ọlọ́run, ẹ̀yin ilẹ̀ gbogbo!
2 Ẹ kọrin ọlá orúkọ rẹ̀;
Ẹ kọrin ìyìnsí i,
3 Ẹ wí fún Ọlọ́run “pé,
ìwọ ti ní ẹ̀rù tó nínú iṣẹ́ rẹ!
Nípa ọ̀pọ̀ agbára rẹ ni àwọn ọ̀tá
rẹ yóò fi sìn ọ́.
4 Gbogbo ayé ń wólẹ̀ fún ọ;
wọn ń kọrin ìyìn sí ọ,
wọ́n ń kọrin ìyìn sí orúkọ rẹ.” Sela.
5 Ẹ wá wo ohun tí Ọlọ́run ṣe,
Iṣẹ́ rẹ̀ ti ní ẹ̀rù tó sí àwọn ọmọ ènìyàn!
6 Ó yí Òkun padà sí ilẹ̀ gbígbẹ,
wọ́n fi ẹsẹ̀ rin inú omi kọjá,
níbẹ̀ ni àwa yọ̀ nínú rẹ̀.
7 Ó ń jẹ ọba títí láé nípa agbára rẹ̀,
ojú rẹ̀ ń wo orílẹ̀-èdè
kí àwọn ọlọ̀tẹ̀ má ṣe gbé ara wọn ga. Sela.
8 Ẹ yin Ọlọ́run wa, ẹ̀yin ènìyàn,
jẹ́ kí a mú ni gbọ́ ohùn ìyìn rẹ̀;
9 Ó ti dá ààbò bo ẹ̀mí wa,
kò sì jẹ́ kí ẹsẹ̀ wa kí ó yẹ̀
10 Nítorí ìwọ, Ọlọ́run, dán wa wò;
ìwọ dán wa bí a tí ń dán fàdákà wò.
11 Ìwọ mú wa wá sínú ẹ̀wọ̀n
o sì di ẹrù lé ẹ̀yìn wa
12 Ìwọ mú àwọn ènìyàn gún wá ní orí
àwa la iná àti omi kọjá
ṣùgbọ́n ìwọ mú wa dé ibi ọ̀pọ̀.
13 Èmi ó wá sí tẹmpili rẹ pẹ̀lú ọrẹ ẹbọ sísun,
kí n sì mú ẹ̀jẹ́ mi ṣẹ sí ọ
14 Ẹ̀jẹ́ tí ètè mi jẹ́, tí ẹnu mi sì sọ
nígbà tí mo wà nínú ìṣòro.
15 Èmi ó rú ẹbọ sísun ọlọ́ràá sí ọ,
àti ẹbọ ọ̀rá àgbò;
èmi ó rú akọ màlúù àti ewúrẹ́. Sela.
16 Ẹ wá gbọ́ gbogbo ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run;
ẹ jẹ́ kí n sọ ohun tí ó ṣe fún mi.
17 Mo fi ẹnu mi kígbe sókè sí i:
Ìyìn rẹ̀ wà ní ẹnu mi.
18 Bí èmi bá gba ẹ̀ṣẹ̀ ní àyà mi,
Olúwa kì yóò gbọ́ ohùn mi;
19 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run gbọ́ nítòótọ́
ó ti gbọ́ ohùn mi nínú àdúrà.
20 Ìyìn ni fún Ọlọ́run
ẹni tí kò kọ àdúrà mi
tàbí mú ìfẹ́ rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ mi!
Fún adarí orin. Pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn. Saamu. Orin.
67 Kí Ọlọ́run kí ó ṣàánú fún wa kí ó sì bùkún fún wa,
kí ó sì jẹ́ kí ojú rẹ̀ tàn yí wa ká,
2 kí ọ̀nà rẹ le di mí mọ̀ ní ayé,
ìgbàlà rẹ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè.
3 Kí àwọn ènìyàn kí ó yìn ọ́, Ọlọ́run;
kí gbogbo ènìyàn kí ó yìn ọ́!
4 Kí orílẹ̀-èdè kí ó yọ̀, kí ó sì kọrin fún ayọ̀,
nítorí ìwọ fi òdodo darí àwọn ènìyàn,
ìwọ sì jẹ ọba àwọn orílẹ̀-èdè ní ayé.
5 Kí àwọn ènìyàn kí ó yìn ọ́, Ọlọ́run;
kí gbogbo ènìyàn kí ó yìn ọ́. Sela.
6 Nígbà náà ní ilẹ̀ yóò mú ìkórè rẹ̀ wá, Ọlọ́run,
Ọlọ́run wa, yóò bùkún fún wa.
7 Ọlọ́run yóò bùkún fún wa,
àti gbogbo òpin ilẹ̀ ayé yóò sì máa bẹ̀rù rẹ̀.
116 Èmi fẹ́ràn Olúwa, nítorí ó gbọ́ ohùn mi;
ó gbọ́ ẹkún mi fún àánú.
2 Nítorí ó yí etí rẹ̀ padà sí mi,
èmi yóò máa pè é ni wọ́n ìgbà tí mo wà láààyè.
3 Okùn ikú yí mi ká,
ìrora isà òkú wá sórí mi;
ìyọnu àti ìbànújẹ́ borí mi.
4 Nígbà náà ni mo ké pe orúkọ Olúwa:
“Olúwa, èmi bẹ̀ ọ́, gba ọkàn mi!”
5 Olúwa ní oore-ọ̀fẹ́, ó sì ní òdodo;
Ọlọ́run wa kún fún àánú.
6 Olúwa pa àwọn ọlọ́kàn fífúyẹ́ mọ́
nígbà tí mo wà nínú àìní ńlá, ó gbà mí.
7 Padà, ìwọ ọkàn mi, sí ibi ìsinmi rẹ,
nítorí Olúwa ṣe dáradára sí ọ.
8 Nítorí ìwọ, Olúwa, ti gba ọkàn mi
kúrò lọ́wọ́ ikú,
ojú mi kúrò lọ́wọ́ omijé,
àti ẹsẹ̀ mi kúrò lọ́wọ́ ìṣubú,
9 Nítorí èmi yóò máa rìn níwájú Olúwa
ní ilẹ̀ alààyè.
10 (A)Èmi gbàgbọ́; nítorí náà mo wí pé,
“èmi rí ìpọ́njú púpọ̀”.
11 Àti nínú ìdààmú mi mo wí pé
“Èké ni gbogbo ènìyàn”.
12 Kí ni èmi yóò san fún Olúwa
nítorí gbogbo rere rẹ̀ sí mi?
13 Èmi yóò gbé ago ìgbàlà sókè
èmi yóò sì máa ké pe orúkọ Olúwa.
14 Èmi yóò mú ìlérí mi ṣẹ sí Olúwa
ní ojú àwọn ènìyàn rẹ̀.
15 Iyebíye ní ojú Olúwa
àti ikú àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀.
16 Olúwa, nítòótọ́ ìránṣẹ́ rẹ ni mo jẹ́;
èmi ni ìránṣẹ́ rẹ, ọmọ ìránṣẹ́bìnrin rẹ;
ó ti tú mi sílẹ̀ nínú ìdè mi.
17 Èmi yóò rú ẹbọ ọpẹ́ sí ọ
èmi yóò sì ké pe orúkọ Olúwa
18 Èmi yóò mú ìlérí mi sẹ sí Olúwa
ní ojú gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀,
19 Nínú àgbàlá ilé Olúwa
ní àárín rẹ̀, ìwọ Jerusalẹmu.
Ẹ yin Olúwa.
117 (B)Ẹ yin Olúwa, gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀-èdè;
ẹ pòkìkí rẹ̀, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn.
2 Nítorí ìfẹ́ ńlá rẹ̀ tí ó ní sí wa,
àti òtítọ́ Olúwa dúró láéláé.
Ẹ yin Olúwa!
Àdúrà Hana
2 Hana sì gbàdúrà pé:
“Ọkàn mi yọ̀ sí Olúwa;
Ìwo agbára mi ni a sì gbé sókè sí Olúwa.
Ẹnu mi sì gbòòrò lórí àwọn ọ̀tá mi,
nítorí ti èmi yọ̀ ni ìgbàlà rẹ̀.
2 “Kò sí ẹni tí ó mọ́ bi Olúwa;
kò sí ẹlòmíràn bí kò ṣe ìwọ;
kò sì sí àpáta bi Ọlọ́run wa.
3 “Má ṣe halẹ̀;
má ṣe jẹ́ kí ìgbéraga ti ẹnu yín jáde
nítorí pé Ọlọ́run olùmọ̀ ni Olúwa,
láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá ni a ti ń wọn ìwà.
4 “Ọ̀run àwọn alágbára ti ṣẹ́,
àwọn tí ó ṣe aláìlera ni a fi agbára dì ní àmùrè.
5 Àwọn tí ó yọ̀ fún oúnjẹ ti fi ara wọn ṣe alágbàṣe,
àwọn tí ebi ń pa kò sì ṣe aláìní.
Tó bẹ́ẹ̀ tí àgàn fi bí méje.
Ẹni tí ó bímọ púpọ̀ sì di aláìlágbára.
6 “Olúwa pa ó sì sọ di ààyè;
ó mú sọ̀kalẹ̀ lọ sí isà òkú, ó sì gbé dìde.
7 Olúwa sọ di tálákà; ó sì sọ di ọlọ́rọ̀;
ó rẹ̀ sílẹ̀, ó sì gbé sókè.
8 Ó gbé tálákà sókè láti inú erùpẹ̀ wá,
ó gbé alágbe sókè láti orí òkìtì eérú wá,
láti mú wọn jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ-aládé,
láti mu wọn jogún ìtẹ́ ògo:
“Nítorí pé ọ̀wọ́n ayé ti Olúwa ni,
ó sì ti gbé ayé ka orí wọn
9 Yóò pa ẹsẹ̀ àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ mọ́,
àwọn ènìyàn búburú ni yóò dákẹ́ ní òkùnkùn.
“Nípa agbára kò sí ọkùnrin tí yóò borí.
10 A ó fọ́ àwọn ọ̀tá Olúwa túútúú;
láti ọ̀run wá ni yóò sán àrá sí wọn;
Olúwa yóò ṣe ìdájọ́ òpin ayé.
“Yóò fi agbára fún ọba rẹ̀,
yóò si gbé ìwo ẹni ààmì òróró rẹ̀ sókè.”
Àwọn ẹ̀kọ́ tí a gbọdọ̀ kọ́ ní onírúurú àkójọpọ̀
2 Ṣùgbọ́n ìwọ gbọdọ̀ máa kọ́ni ní ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro lórí ìgbé ayé onígbàgbọ́ tòótọ́. 2 Kọ́ àwọn àgbà ọkùnrin lẹ́kọ̀ọ́ láti ní ìrònú àti láti jẹ́ ẹni àpọ́nlé àti ẹni ìwọ̀ntúnwọ̀nsì. Wọn gbọdọ̀ jẹ́ ẹni tí ó jinlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́, nínú ìfẹ́ àti nínú ìpamọ́ra.
3 Bákan náà, ni kí ó kọ́ àwọn àgbà obìnrin lẹ́kọ̀ọ́ láti kọ́ bí à a tí gbé ìgbé ayé ẹni ọ̀wọ̀, wọn kò gbọdọ̀ jẹ́ afọ̀rọ̀-kẹ́lẹ́-ba-tẹni-jẹ́ tàbí olùfẹ́ ọtí mímu, ṣùgbọ́n wọ́n gbọdọ̀ jẹ́ olùkọ́ni ní ohun rere. 4 Nípa èyí, wọ́n yóò lè máa kọ́ àwọn ọ̀dọ́bìnrin láti nífẹ̀ẹ́ àwọn ọkọ wọn àti àwọn ọmọ wọn, 5 láti jẹ́ ẹni ìwọ̀ntúnwọ̀nsì àti ọlọ́kàn mímọ́, kí wọ́n máa ṣe ojúṣe wọn nínú ilé, wọ́n gbọdọ̀ jẹ́ onínúrere, kí wọ́n sì máa tẹríba fún àwọn ọkọ wọ́n, kí ẹnikẹ́ni máa ba à sọ̀rọ̀-òdì sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
6 Bákan náà, rọ àwọn ọ̀dọ́ ọkùnrin láti kó ara wọn ni ìjánu. 7 Nínú ohun gbogbo fi ara rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí alápẹẹrẹ ohun rere. Nínú ẹ̀kọ́ rẹ fi àpẹẹrẹ ìwà pípé hàn, ẹni tó kún ojú òṣùwọ̀n 8 ọ̀rọ̀ tí ó yè kooro, tí a kò lè dá lẹ́bi, kí ojú kí ó ti ẹni tí ó ń sòdì, ní àìní ohun búburú kan láti wí sí wa.
9 Kọ́ àwọn ẹrú láti ṣe ìgbọ́ràn sí àwọn olówó wọn nínú ohun gbogbo, láti máa gbìyànjú láti tẹ́ wọn lọ́rùn, wọn kò gbọdọ̀ gbó olówó wọn lẹ́nu, 10 wọn kò gbọdọ̀ jà wọ́n lólè ohunkóhun, ṣùgbọ́n kí wọ́n jẹ́ ẹni tó ṣe é gbẹ́kẹ̀lé, kí wọn ó làkàkà ní gbogbo ọ̀nà láti jẹ́ kí ìkọ́ni nípa Ọlọ́run àti Olùgbàlà ní ìtumọ̀ rere.
Ìsọtẹ́lẹ̀ ibi Jesu
26 Ní oṣù kẹfà Ọlọ́run sì rán angẹli Gabrieli sí ìlú kan ní Galili, tí à ń pè ní Nasareti, 27 sí wúńdíá kan tí a ṣèlérí láti fẹ́ fún ọkùnrin kan, tí a ń pè ní Josẹfu, ti ìdílé Dafidi; orúkọ wúńdíá náà a sì máa jẹ́ Maria. 28 Angẹli náà sì tọ̀ ọ́ wá, ó ní, “Àlàáfíà fun ọ, ìwọ ẹni tí a kọjú sí ṣe ní oore, Olúwa ń bẹ pẹ̀lú rẹ.”
29 Ṣùgbọ́n ọkàn Maria kò lélẹ̀ nítorí ọ̀rọ̀ náà, ó sì rò nínú ara rẹ̀ pé, irú kíkí kín ni èyí. 30 (A)Ṣùgbọ́n angẹli náà wí fún un pé, “Má bẹ̀rù, Maria: nítorí ìwọ ti rí ojúrere lọ́dọ̀ Ọlọ́run. 31 (B)Ìwọ yóò lóyún nínú rẹ, ìwọ ó sì bí ọmọkùnrin kan, ìwọ ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jesu. 32 Òun ó pọ̀, Ọmọ Ọ̀gá-ògo jùlọ ni a ó sì máa pè é: Olúwa Ọlọ́run yóò sì fi ìtẹ́ Dafidi baba rẹ̀ fún: 33 (C)Yóò sì jẹ ọba lórí ilé Jakọbu títí láé; ìjọba rẹ̀ kì yóò sì ní ìpẹ̀kun.”
34 (D)Nígbà náà ni Maria béèrè lọ́wọ́ angẹli náà pé, “Èyí yóò ha ti ṣe rí bẹ́ẹ̀, nígbà tí èmi kò tí ì mọ ọkùnrin.”
35 (E)Angẹli náà sì dáhùn ó sì wí fún un pé, “Ẹ̀mí Mímọ́ yóò tọ̀ ọ́ wá, agbára Ọ̀gá-ògo jùlọ yóò ṣíji bò ọ́. Nítorí náà ohun mímọ́ tí a ó ti inú rẹ bí, Ọmọ Ọlọ́run ni a ó máa pè é. 36 Sì kíyèsi i, Elisabeti ìbátan rẹ náà yóò sì ní ọmọkùnrin kan ní ògbólógbòó rẹ̀. Èyí sì ni oṣù kẹfà fún ẹni tí à ń pè ní àgàn. 37 (F)Nítorí kò sí ohun tí Ọlọ́run kò le ṣe.”
38 Maria sì dáhùn wí pé, “Wò ó ọmọ ọ̀dọ̀ Olúwa; kí ó rí fún mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.” Angẹli náà sì fi í sílẹ̀ lọ.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.