Book of Common Prayer
ÌWÉ KÌN-ÍN-NÍ
Saamu 1–41
1 (A)Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà,
tí kò rìn ní ìmọ̀ àwọn ènìyàn búburú,
ti kò dúró ní ọ̀nà àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,
tàbí tí kò sì jókòó ní ibùjókòó àwọn ẹlẹ́gàn.
2 Ṣùgbọ́n ayọ̀ inú rẹ̀ wà nínú òfin Olúwa
àti nínú òfin rẹ̀ ni ó ń ṣe àṣàrò ní ọ̀sán àti òru.
3 Ó dàbí igi tí a gbìn sí etí odò tí ń sàn,
tí ń so èso rẹ̀ jáde ní àkókò rẹ̀
tí ewé rẹ̀ kì yóò rẹ̀.
Ohunkóhun tí ó dáwọ́lé, ni yóò máa yọrí sí rere.
4 Kò le rí bẹ́ẹ̀ fún àwọn ènìyàn búburú!
Wọn yóò dàbí ìyàngbò ọkà
tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ dànù.
5 Nítorí náà àwọn ènìyàn búburú kì yóò le è dìde dúró ní ìdájọ́,
bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ kì yóò le è dúró ní àwùjọ àwọn olódodo.
6 Nítorí Olúwa ń ṣọ́ ọ̀nà àwọn olódodo,
ṣùgbọ́n ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú ni yóò ṣègbé.
2 (B)Èéṣe tí àwọn orílẹ̀-èdè fi ń dìtẹ̀,
àti tí àwọn ènìyàn ń ṣe rìkíṣí asán?
2 Àwọn ọba ayé péjọpọ̀
àti àwọn ìjòyè gbìmọ̀ pọ̀
sí Olúwa àti sí Ẹni ààmì òróró rẹ̀.
3 Wọ́n sọ pé, “Ẹ jẹ́ kí a fa ẹ̀wọ̀n wọn já,
kí a sì ju ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ wọn nù.”
4 Ẹni tí ó gúnwà lórí ìtẹ́ lọ́run rẹ́rìn-ín;
Olúwa fi wọ́n rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà.
5 Nígbà náà ni yóò bá wọn wí ní ìbínú rẹ̀
yóò sì dẹ́rùbà wọ́n ní ìrunú rẹ̀, ó wí pé,
6 “Èmi ti fi ọba mi sí ipò
lórí Sioni, òkè mímọ́ mi.”
7 (C)Èmi yóò sì kéde ìpinnu Olúwa:
Ó sọ fún mi pé, “Ìwọ ni ọmọ mi;
lónìí, èmi ti di baba rẹ.
8 (D)Béèrè lọ́wọ́ mi,
Èmi yóò jẹ́ kí orílẹ̀-èdè di ìní rẹ,
òpin ilé ayé yóò sì jẹ́ ogún rẹ.
9 Ìwọ yóò fi ọ̀pá irin ṣe àkóso wọn
ìwọ yóò sì rún wọn wómúwómú bí ìkòkò amọ̀.”
10 Nítorí náà, ẹ̀yin ọba, ẹ jẹ́ ọlọ́gbọ́n;
ẹ gbọ́ ìkìlọ̀ ẹ̀yin alákòóso ayé.
11 Ẹ sin Olúwa pẹ̀lú ìbẹ̀rù
ẹ sì máa yọ̀ pẹ̀lú ìwárìrì.
12 Fi ẹnu ko ọmọ náà ní ẹnu, kí ó má ba à bínú,
kí ó má ba à pa yín run ní ọ̀nà yín,
nítorí ìbínú rẹ̀ lè ru sókè ní ẹ̀ẹ̀kan.
Ìbùkún ni fún gbogbo àwọn tí ó fi í ṣe ibi ìsádi wọn.
Saamu ti Dafidi. Nígbà ti ó sá fún ọmọ rẹ̀ Absalomu.
3 Olúwa, báwo ni àwọn ọ̀tá mi ṣe pọ̀ tó báyìí!
Báwo ni àwọn ti ó dìde sí mi ṣe pọ̀ tó!
2 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó ń sọ ní ti tèmi, pé
“Ọlọ́run kò nígbà á là.” Sela.
3 Ṣùgbọ́n ìwọ ni asà yí mi ká, Olúwa;
ìwọ fi ògo fún mi, ìwọ sì gbé orí mi sókè.
4 Olúwa ni mo kígbe sókè sí,
ó sì dá mi lóhùn láti orí òkè mímọ́ rẹ̀ wá. Sela.
5 Èmi dùbúlẹ̀, mo sì sùn;
mo sì tún padà jí, nítorí Olúwa ni ó ń gbé mi ró.
6 Èmi kì yóò bẹ̀rù ẹgbẹgbẹ̀rún ènìyàn
tí wọ́n rọ̀gbà yí mi ká.
7 Dìde, Olúwa!
Gbà mí, Ọlọ́run mi!
Lu gbogbo àwọn ọ̀tá mi ní àgbọ̀n;
kí o sì ká eyín àwọn ènìyàn búburú.
8 Láti ọ̀dọ̀ Olúwa ni ìgbàlà ti wá.
Kí ìbùkún rẹ wà lórí àwọn ènìyàn rẹ. Sela.
Fún adarí orin. Pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn. Saamu ti Dafidi.
4 Dá mi lóhùn nígbà tí mo bá pè ọ́,
ìwọ Ọlọ́run òdodo mi,
Fún mi ní ìdáǹdè nínú ìpọ́njú mi;
ṣàánú fún mi, kí o sì gbọ́ àdúrà mi.
2 Báwo ni yóò ṣe pẹ́ tó, ẹ̀yin ọmọ ènìyàn, tí ẹ ó ṣe sọ ògo mi di ìtìjú?
Báwo ni yóò ṣe pẹ́ tó, tí ẹ̀yin yóò ṣe fẹ́ràn ìtànjẹ àti tí ẹ̀yin yóò fi máa wá ọlọ́run èké?
3 Ṣùgbọ́n kí ẹ mọ̀ pé, Olúwa ti ya ẹni olódodo sọ́tọ̀ fún ara rẹ̀;
Olúwa yóò gbọ́ nígbà tí mo bá pè é.
4 (E)Ẹ bínú ẹ má ṣe ṣẹ̀;
Nígbà tí ẹ bá wà lórí ibùsùn yín,
ẹ bá ọkàn yín sọ̀rọ̀, kí ó sì dákẹ́ jẹ́.
5 Ẹ rú ẹbọ òdodo
kí ẹ sì gbẹ́kẹ̀lé Olúwa.
6 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló ń béèrè pé, “Ta ni yóò ṣe rere fún wa?”
Olúwa, Jẹ́ kí ojú rẹ mọ́lẹ̀ sí wa lára,
7 Ìwọ ti fi ayọ̀ púpọ̀ kún ọkàn mi
ju ìgbà tí hóró irúgbìn àti wáìnì tuntun wọ́n pọ̀ fún mi lọ.
8 Èmi yóò dùbúlẹ̀, èmi ó sì sùn ní àlàáfíà,
nítorí ìwọ nìkan, Olúwa, ni o
mú mi gbé láìléwu.
Ṣiggaioni ti Dafidi, èyí tí ó kọ sí Olúwa nípa Kuṣi, ará Benjamini.
7 Olúwa Ọlọ́run mi, ààbò mi wà nínú rẹ;
gba mí là kí o sì tú mi sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn tó ń lé mi,
2 kí wọn ó má ba à fa ọkàn mi ya gẹ́gẹ́ bí kìnnìún,
wọ́n á ya á pẹ́rẹpẹ̀rẹ láìsí ẹni tí yóò gbà mí.
3 Olúwa Ọlọ́run mi, tí èmi bá ṣe èyí
tí ẹ̀bi sì wà ní ọwọ́ mi
4 Bí èmi bá ṣe ibi sí ẹni tí ń wá àlàáfíà pẹ̀lú mi,
tí mo ja ọ̀tá mi lólè láìnídìí:
5 Nígbà náà, jẹ́ kí ọ̀tá mi lé mi kí wọn sì mú mi;
jẹ́ kí òun kí ó tẹ ọkàn mi mọ́lẹ̀
kí wọn sì mú mi sùn nínú eruku. Sela.
6 Dìde, Olúwa, nínú ìbínú rẹ;
dìde lòdì sí ìrunú àwọn ọ̀tá mi.
Jí, Ọlọ́run mi; kéde òdodo.
7 Kí ìpéjọ àwọn ènìyàn yíká.
Jọba lórí wọn láti òkè wá;
8 Jẹ́ kí Olúwa ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn.
Ṣe ìdájọ́ mi, Olúwa, gẹ́gẹ́ bí òdodo mi,
gẹ́gẹ́ bí ìwà òtítọ́, ẹni gíga jùlọ.
9 (A)Ọlọ́run Olódodo,
Ẹni tí ó ń wo inú àti ọkàn,
tí ó ń mú òpin sí ìwà ipá ẹni búburú
tí ó sì ń pa àwọn olódodo mọ́.
10 Ààbò mi ń bẹ lọ́dọ̀ Ọlọ́run,
ẹni tí ń ṣe ìgbàlà òtítọ́ ní àyà.
11 Ọlọ́run ni onídàájọ́ òtítọ́,
Ọlọ́run tí ń sọ ìrunú rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́.
12 Bí kò bá yípadà,
Òun yóò pọ́n idà rẹ̀ mú;
ó ti fa ọrun rẹ̀ le ná, ó ti múra rẹ̀ sílẹ̀.
13 Ó ti pèsè ohun ìjà ikú sílẹ̀;
ó ti pèsè ọfà iná sílẹ̀.
14 Ẹni tí ó lóyún ohun búburú,
tí ó sì lóyún wàhálà, ó bí èké jáde.
15 Ẹni tí ó gbẹ́ ọ̀fìn, tí ó kó o jáde
jì sí kòtò tí ó gbẹ́ sílẹ̀.
16 Wàhálà tí ó fà padà sórí rẹ̀;
Ìwà ipá rẹ̀ padà sórí ara rẹ̀.
17 Èmi ó fi ọpẹ́ fún Olúwa nítorí òdodo rẹ̀,
Èmi ó kọrin ìyìn sí Olúwa Ọ̀gá-ògo jùlọ.
9 (A)Kìkì i kí ẹ kíyèsára, kí ẹ sì ṣọ́ra a yín gidigidi kí ẹ má ba à gbàgbé àwọn ohun tí ojú yín ti rí, kí wọn má sì ṣe sá kúrò lóókan àyà yín níwọ̀n ìgbà tí ẹ sì wà láààyè. Ẹ máa fi wọ́n kọ́ àwọn ọmọ yín àti àwọn ọmọ wọn tí ń bọ̀ lẹ́yìn wọn. 10 Ẹ rántí ọjọ́ tí ẹ dúró níwájú Olúwa Ọlọ́run yín ní Horebu, nígbà tí ó wí fún mi pé, “Kó àwọn ènìyàn wọ̀nyí jọ síwájú mi láti gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, kí wọ́n lè kọ́ láti máa bu ọlá náà fún mi ní gbogbo ìgbà tí wọ́n bá gbé lórí ilẹ̀ náà, kí wọ́n sì le è fi wọ́n kọ́ àwọn ọmọ wọn.” 11 Ẹ̀yin súnmọ́ tòsí, ẹ sì dúró ní ẹsẹ̀ òkè náà, òkè náà sì ń jóná dé agbede-méjì ọrun, pẹ̀lú òkùnkùn, àti àwọsánmọ̀, àti òkùnkùn biribiri. 12 Olúwa sì bá yín sọ̀rọ̀ láti àárín iná náà wá. Ẹ gbọ́ àwọn ìró ohùn, ṣùgbọ́n ẹ kò rí ẹnikẹ́ni, ohùn nìkan ni ẹ gbọ́. 13 (B)Ó sọ àwọn májẹ̀mú rẹ̀ fún un yín àní àwọn òfin mẹ́wẹ̀ẹ̀wá tí ó pàṣẹ fún un yín láti máa tẹ̀lé, ó sì kọ wọ́n sórí wàláà òkúta méjì. 14 (C)Olúwa sì pàṣẹ fún mi nígbà náà láti kọ yín ní ìlànà àti ìdájọ, kí ẹ̀yin kí ó lè máa ṣe wọ́n ní ilẹ̀ náà, ní ibi tí ẹ̀yin ń lọ láti gbà á.
Paulu gbèjà iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀
10 (A)Ṣùgbọ́n èmi Paulu fúnra mi fi inú tútù àti ìwà pẹ̀lẹ́ Kristi bẹ̀ yín, èmi ẹni ìrẹ̀lẹ̀ lójú yín nígbà tí mo wà láàrín yín, ṣùgbọ́n nígbà tí èmi kò sí, mo di ẹni ìgboyà sí yín. 2 (B)Ṣùgbọ́n èmi bẹ̀ yín pé nígbà tí mo wà láàrín yín, kí èmi ba à lè lo ìgboyà pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé náà, eléyìí tí mo ti fọkàn sí láti fi dojúkọ àwọn kan, ti ń funra sí wa bí ẹni tí ń rìn nípa ìlànà ti ayé yìí. 3 Nítorí pé, bí àwa tilẹ̀ n gbé nínú ayé, ṣùgbọ́n àwa kò jagun nípa ti ara. 4 Nítorí ohun ìjà wa kì í ṣe ti ara, ṣùgbọ́n ó lágbára nínú Ọlọ́run láti wó ibi gíga palẹ̀. 5 Àwa ń sọ gbogbo èrò àti gbogbo ohun gíga ti ń gbe ara rẹ̀ ga sí ìmọ̀ Ọlọ́run kalẹ̀, àwa sì ń di gbogbo èrò ní ìgbèkùn wá sí ìtẹríba fún Kristi. 6 (C)Àwa sì ti murá tan láti jẹ gbogbo àìgbọ́ràn ní yà, nígbà tí ìgbọ́ràn yín bá pé.
7 (D)Ẹ̀yin sì ń wo nǹkan gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti fihàn lóde. Bí ẹnikẹ́ni bá ní ìgboyà nínú ara rẹ̀, ti Kristi ni òun, kí ó tún rò lẹ́ẹ̀kan si pé, bí òun ti jẹ́ ti Kristi, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni àwa pẹ̀lú jẹ́ ti Kristi. 8 Nítorí bí mo tilẹ̀ ń ṣògo bí ó ti wù mi nítorí agbára, tí Olúwa ti fi fún wá fún ìdàgbàsókè, dípò fífà yín ṣubú, ojú kí yóò tì mí. 9 Kí ó má ṣe dàbí ẹni pé èmi ń fi ìwé kíkọ dẹ́rùbà yín. 10 (E)Nítorí wọ́n wí pé, “Ìwé rẹ wúwo, wọn sì lágbára; ṣùgbọ́n ní ti ara ìrísí rẹ̀ jẹ aláìlera, ọ̀rọ̀ rẹ kò níláárí.” 11 Kí irú ènìyàn bẹ́ẹ̀ mọ̀ pé, irú ẹni tí àwa jẹ́ nínú ọ̀rọ̀ nípa ìwé kíkọ nígbà tí àwa kò sí, irú ẹni bẹ́ẹ̀ ni àwa sì jẹ́ nínú iṣẹ́ pẹ̀lú nígbà ti àwa bá wà.
12 Nítorí pé àwa kò dáṣà láti ka ara wa mọ́, tàbí láti fi ara wa wé àwọn mìíràn nínú wọn tí ń yin ara wọn; ṣùgbọ́n àwọn fúnrawọn jẹ́ aláìlóye bí wọn ti ń fi ara wọn díwọ̀n ara wọ́n, tí wọ́n sì ń fi ara wọn wé ara wọn. 13 Ṣùgbọ́n àwa kò ṣògo rékọjá ààlà wa, ṣùgbọ́n nípa ààlà ìwọ̀n tí Ọlọ́run ti pín fún wa, èyí tí ó mú kí ó ṣe é ṣe láti dé ọ̀dọ̀ yín. 14 Nítorí àwa kò nawọ́ wa rékọjá rárá, bí ẹni pé àwa kò dé ọ̀dọ̀ yín: nítorí àwa tilẹ̀ dé ọ̀dọ̀ yín pẹ̀lú nínú ìhìnrere Kristi. 15 (F)Àwa kò ṣògo rékọjá ààlà wa, èyí nì, lórí iṣẹ́ ẹlòmíràn, ṣùgbọ́n àwa ní ìrètí pé, bí ìgbàgbọ́ yín ti ń dàgbà sí i, gẹ́gẹ́ bí ààlà wa, àwa ó dí gbígbéga lọ́dọ̀ yín sí i lọ́pọ̀lọpọ̀. 16 Kí a bá à lè wàásù ìhìnrere ní àwọn ìlú tí ń bẹ níwájú yín, kí a má sì ṣògo nínú ààlà ẹlòmíràn nípa ohun tí ó wà ní àrọ́wọ́tó. 17 (G)“Ṣùgbọ́n jẹ́ kí ẹni tí ó bá ń ṣògo, kí ó máa ṣògo nínú Olúwa.” 18 Nítorí kì í ṣe ẹni tí ń yin ara rẹ̀ ni ó ní ìtẹ́wọ́gbà, bí kò ṣe ẹni tí Olúwa bá yìn.
7 Ṣùgbọ́n nígbà ti ẹ̀yin bá ń gbàdúrà, ẹ má ṣe àtúnwí asán bí àwọn aláìkọlà, nítorí wọn rò pé a ó tìtorí ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ gbọ́ tiwọn. 8 Ẹ má ṣe dàbí i wọn, nítorí Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run mọ ohun tí ẹ ṣe aláìní, kí ẹ tilẹ̀ tó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.
9 (A)“Nítorí náà, báyìí ni kí ẹ ṣe máa gbàdúrà:
“ ‘Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run,
ọ̀wọ̀ fún orúkọ yín,
10 Kí ìjọba yín dé,
Ìfẹ́ tiyín ni kí a ṣe
ní ayé bí ti ọ̀run.
11 Ẹ fún wa ní oúnjẹ òòjọ́ wa lónìí
12 Ẹ dárí gbèsè wa jì wá,
Bí àwa ti ń dáríji àwọn ajigbèsè wa,
13 (B)Ẹ má ṣe fà wá sínú ìdánwò,
Ṣùgbọ́n ẹ gbà wá lọ́wọ́ ibi.
Nítorí ìjọba ni tiyín, àti agbára àti ògo, láéláé, Àmín.’
14 (C)Nítorí náà, bí ẹ̀yin bá dárí jí àwọn tó ṣẹ̀ yín, baba yín ọ̀run náà yóò dáríjì yín. 15 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá kọ̀ láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn jì wọ́n, baba yín kò ní í dárí ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.