Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 148-150

148 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

Ẹ fi ìyìn fún Olúwa láti ọ̀run wá,
    Ẹ fi ìyìn fún un níbi gíga.
Ẹ fi ìyìn fún un,
    gbogbo ẹ̀yin angẹli rẹ̀
Ẹ fi ìyìn fún un,
    gbogbo ẹ̀yin ọmọ-ogun rẹ̀
Ẹ fi ìyìn fún un,
    oòrùn àti òṣùpá
Ẹ fi ìyìn fún un,
    gbogbo ẹ̀yin ìràwọ̀ ìmọ́lẹ̀.
Ẹ fi ìyìn fún un,
    ẹ̀yin ọ̀run àti àwọn ọ̀run gíga
    àti ẹ̀yin omi tí ń bẹ ní òkè ọ̀run.

Ẹ jẹ́ kí wọn kí ó yin orúkọ Olúwa
    nítorí ó pàṣẹ a sì dá wọn
Ó fi ìdí wọn múlẹ̀ láé àti láéláé
    ó sì ti ṣe ìlànà kan tí kì yóò já.

Ẹ yin Olúwa láti ilẹ̀ ayé wá
    ẹ̀yin ẹ̀dá inú Òkun títóbi
    àti ẹ̀yin ibú Òkun
Mọ̀nàmọ́ná àti òjò yìnyín
    ìdí omi àti àwọn ìkùùkuu,
    ìjì líle tí ń mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ;
Òkè ńlá àti gbogbo òkè kéékèèkéé,
    igi eléso àti gbogbo igi kedari,
10 Àwọn ẹranko ńlá àti ẹran ọ̀sìn
    gbogbo ohun afàyàfà àti àwọn ẹyẹ abìyẹ́:
11 Àwọn ọba ayé àti ènìyàn ayé gbogbo
    àwọn ọmọ-aládé àti gbogbo àwọn onídàájọ́ ayé,
12 Ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin
    àwọn arúgbó àti àwọn ọmọdé.

13 Ẹ jẹ́ kí wọn kí ó yin orúkọ Olúwa
    nítorí orúkọ rẹ̀ nìkan ni ó ní ọlá
    ògo rẹ̀ kọjá ayé àti ọ̀run
14 Ó sì gbé ìwo kan sókè fún àwọn ènìyàn rẹ̀,
    ìyìn fún gbogbo ènìyàn mímọ́ rẹ̀ àní fún àwọn ọmọ Israẹli,
    àwọn ènìyàn tí ó súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀.

Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
149 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

Ẹ kọrin tuntun sí Olúwa.
    Ẹ yìn ín ní àwùjọ àwọn ènìyàn mímọ́.

Jẹ́ kí Israẹli kí ó ní inú dídùn sí ẹni tí ó dá a
    jẹ́ kí àwọn ọmọ Sioni kí ó ní
    ayọ̀ nínú ọba wọn.
Jẹ́ kí wọn kí ó fi ijó yin orúkọ rẹ̀
    jẹ́ kí wọn kí ó fi ohun èlò orin kọrin ìyìn sí i.
Nítorí Olúwa ní inú dídùn sí àwọn ènìyàn rẹ̀
    ó fi ìgbàlà dé àwọn onírẹ̀lẹ̀ ládé
Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mímọ́ kí ó yọ̀ nínú ọlá rẹ̀
    kí wọn kí ó máa kọrin fún ayọ̀ ní orí ibùsùn wọn.

Kí ìyìn Ọlọ́run kí ó wà ní ẹnu wọn
    àti idà olójú méjì ní ọwọ́ wọn.
Láti gba ẹ̀san lára àwọn orílẹ̀-èdè,
    àti ìjìyà lára àwọn ènìyàn,
Láti fi ẹ̀wọ̀n de àwọn ọba wọn
    àti láti fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀
irin de àwọn ọlọ́lá wọn.
Láti ṣe ìdájọ́ tí àkọsílẹ̀ rẹ̀ sí wọn
    èyí ni ògo àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀.

Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
150 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

Ẹ fi ìyìn fún Ọlọ́run ní ibi mímọ́ rẹ̀
    Ẹ yìn ín nínú agbára ọ̀run rẹ̀.
Ẹ yìn ín fún iṣẹ́ agbára rẹ̀.
    Ẹ yìn ín fún títóbi rẹ̀ tí ó tayọ̀.
Ẹ fi ohùn ìpè yìn ín.
    Ẹ fi ohun èlò orin yìn ín.
Ẹ fi ohun èlò orin àti ijó yìn ín
    fi ohun èlò orin olókùn àti ìpè yìn ín
Ẹ yìn ín pẹ̀lú aro olóhùn òkè,
    Ẹ yìn ín lára aro olóhùn gooro.

Jẹ́ kí gbogbo ohun tí ó ní ẹ̀mí yin Olúwa.

Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

Saamu 114-115

114 Nígbà tí Israẹli jáde ní Ejibiti,
    ilé Jakọbu láti inú ènìyàn àjèjì èdè
Juda wà ní ibi mímọ́,
    Israẹli wà ní ìjọba.

(A)Òkun sì rí i, ó sì wárìrì:
    Jordani sì padà sẹ́yìn.
Àwọn òkè ńlá ń fò bí àgbò àti
    òkè kéékèèkéé bí ọ̀dọ́-àgùntàn.

Kí ni ó ṣe ọ́, ìwọ Òkun, tí ìwọ fi wárìrì?
    Ìwọ Jordani, tí ìwọ fi padà sẹ́yìn?
Ẹ̀yin òkè ńlá kí ló dé ti ẹ fi ń fò bí àgbò,
    àti ẹ̀yin òkè kéékèèkéé bí ọ̀dọ́-àgùntàn?

Wárìrì, ìwọ ilẹ̀, níwájú Olúwa;
    ní iwájú Ọlọ́run Jakọbu
tí ó sọ àpáta di adágún omi,
    àti òkúta-ìbọn di orísun omi.
115 Kì í ṣe fún wa, Olúwa kì í ṣe fún wa,
    ṣùgbọ́n fún orúkọ rẹ ni a fi ògo fún,
    fún àánú àti òtítọ́ rẹ.

Torí kí ni àwọn kèfèrí yóò ṣe sọ pé,
    níbo ni Ọlọ́run wa wà.
Ṣùgbọ́n Ọlọ́run wa wà lọ́run:
    tí ó ń ṣe èyí tí ó wù ú.
(B)Fàdákà òun wúrà ni èrè àwọn aláìkọlà,
    iṣẹ́ ọwọ́ ènìyàn ni,
Wọ́n ní ẹnu, ṣùgbọ́n wọn kò le sọ̀rọ̀,
    wọ́n ní ojú, ṣùgbọ́n wọn kò fi ríran.
Wọ́n ní etí, ṣùgbọ́n wọn kò fi gbọ́rọ̀:
    wọ́n ní imú, ṣùgbọ́n wọn kò fi gbóòórùn
Wọ́n ní ọwọ́, ṣùgbọ́n wọn kò lò ó,
    wọ́n ní ẹsẹ̀, ṣùgbọ́n wọn kò rìn;
    bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sọ̀rọ̀ nínú òfin wọn.
Àwọn tí ń ṣe wọ́n dàbí wọn;
    gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni olúkúlùkù ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé wọn.

Ìwọ Israẹli gbẹ́kẹ̀lé Olúwa:
    òun ni ìrànwọ́ àti ààbò wọn
10 Ẹ̀ yin ilé Aaroni, gbẹ́kẹ̀lé Olúwa:
    òun ni ìrànwọ́ àti ààbò wọn
11 Ẹ̀ yin tí ó bẹ̀rù Olúwa, gbẹ́kẹ̀lé Olúwa:
    òun ní ìrànwọ́ àti ààbò wọn.

12 Olúwa tí ń ṣe ìrántí wa; yóò bùkún ilé Israẹli;
    yóò bùkún ilé Aaroni.
13 (C)Ìbùkún ni fún àwọn tí ó bẹ̀rù Olúwa,
    àti kékeré àti ńlá.

14 Olúwa yóò mú ọ pọ̀ sí i síwájú àti síwájú,
    ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ̀.
15 Ẹ fi ìbùkún fún Olúwa
    ẹni tí ó dá ọ̀run òun ayé.

16 Ọ̀run àní ọ̀run ni ti Olúwa:
    ṣùgbọ́n ayé ló fi fún ọmọ ènìyàn.
17 Òkú kò lè yìn Olúwa,
    tàbí ẹni tí ó ti lọ sí ìsàlẹ̀ ìdákẹ́ jẹ́ẹ́.
18 Ṣùgbọ́n àwa ó fi ìbùkún fún Olúwa
    láti ìsinsin yìí lọ àti títí láéláé.

Ẹ yin Olúwa.

Òwe 9:1-12

Ìpè ti ọgbọ́n àti àìgbọ́n

Ọgbọ́n ti kọ́ ilé rẹ̀,
    ó ti gbẹ́ òpó o rẹ̀ méjèèjì,
ó ti fi ilé pọn tí, ó ti fọ̀nà rokà.
    Ó sì ti ṣètò o tábìlì oúnjẹ rẹ̀
ó ti rán àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ jáde, ó sì ń pè,
    láti ibi tí ó ga jù láàrín ìlú.
“Jẹ́ kí gbogbo àwọn aláìgbọ́n wọ ibí wá!”
    Ó ń wí fún àwọn tí kò lọ́gbọ́n pé
“Wá, ẹ wá fẹ́ oúnjẹ mi
    sì mu wáìnì tí mo ti pò.
Fi ìwà àìmọ̀kan rẹ sílẹ̀ ìwọ yóò sì yè;
    rìn ní ọ̀nà òye.

“Ẹnikẹ́ni tí ó bá bá ẹlẹ́gàn wí, kọ lẹ́tà sí àbùkù
    ẹnikẹ́ni tí ó bá bá ẹni búburú wí kọ lẹ́tà sí èébú.
Má ṣe bá ẹlẹ́gàn wí, àìṣe bẹ́ẹ̀ yóò kórìíra rẹ.
    Bá ọlọ́gbọ́n wí yóò sì fẹ́ràn rẹ;
kọ́ ọlọ́gbọ́n ènìyàn lẹ́kọ̀ọ́, yóò sì gbọ́n sí i
    kọ́ olódodo ènìyàn lẹ́kọ̀ọ́, yóò sì fi kún ìmọ̀ rẹ̀.

10 “Ìbẹ̀rù Olúwa ni ìbẹ̀rẹ̀ ọgbọ́n,
    ìmọ̀ nípa Ẹni mímọ́ ni òye.
11 Nítorí nípasẹ̀ mi ọjọ́ rẹ yóò gùn
    ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún yóò sì kún ọjọ́ ayé rẹ.
12 Bí ìwọ bá gbọ́n, ọgbọ́n rẹ yóò fún ọ ní èrè:
    bí ìwọ bá jẹ́ ẹlẹ́gàn, ìwọ nìkan ni yóò jìyà.”

Ìṣe àwọn Aposteli 8:14-25

14 Nígbà tí àwọn aposteli tí ó wà ní Jerusalẹmu sí gbọ́ pé àwọn ara Samaria ti gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n rán Peteru àti Johanu sí wọn. 15 Nígbà tí wọ́n sì lọ, wọ́n gbàdúrà fún wọn, kí wọn bá à lè gba Ẹ̀mí Mímọ́: 16 nítorí títí ó fi di ìgbà náà Ẹ̀mí Mímọ́ kò tí ì bà lé ẹnikẹ́ni nínú wọn; kìkì pè a bamitiisi wọn lórúkọ Jesu Olúwa ni. 17 Nígbà náà ni Peteru àti Johanu gbé ọwọ́ lé wọn, wọn sí gba Ẹ̀mí Mímọ́.

18 Nígbà tí Simoni rí i pé nípa gbígbé ọwọ́ lé ni ni a ń ti ọwọ́ àwọn aposteli fi Ẹ̀mí Mímọ́ fún ni, ó fi owó lọ̀ wọ́n, 19 ó wí pé, “Ẹ fún èmi náà ni àṣẹ yìí pẹ̀lú, kí ẹnikẹ́ni tí èmi bá gbé ọwọ́ lé lè gba Ẹ̀mí Mímọ́.”

20 Ṣùgbọ́n Peteru dá a lóhùn wí pé, “Kí owó rẹ ṣègbé pẹ̀lú rẹ, nítorí tí ìwọ rò láti fi owó ra ẹ̀bùn Ọlọ́run! 21 Ìwọ kò ni ipa tàbí ìpín nínú ọ̀ràn yìí, nítorí ọkàn rẹ kò ṣe déédé níwájú Ọlọ́run. 22 Nítorí náà ronúpìwàdà ìwà búburú rẹ yìí, kí ó sì gbàdúrà sọ́dọ̀ Ọlọ́run bóyá yóò dárí ète ọkàn rẹ jì ọ́. 23 (A)Nítorí tí mo wòye pé, ìwọ wa nínú òróǹró ìkorò, àti ní ìdè ẹ̀ṣẹ̀.”

24 Nígbà náà ni Simoni dáhùn, ó sì wí pé, “Ẹ gbàdúrà sọ́dọ̀ Olúwa fún mi, kí ọ̀kan nínú ohun tí ẹ̀yin tí sọ má ṣe bá mi.”

25 Nígbà tí wọn sì ti jẹ́rìí, tiwọn ti sọ ọ̀rọ̀ Olúwa, Peteru àti Johanu padà lọ sí Jerusalẹmu, wọ́n sì wàásù ìhìnrere ni ìletò púpọ̀ ti àwọn ará Samaria.

Luku 10:25-28

Òwe aláàánú ará Samaria

25 (A)(B) Sì kíyèsi i amòfin kan dìde, ó ń dán an wò, ó ní, “Olùkọ́, kín ni èmi ó ṣe kí èmi lè jogún ìyè àìnípẹ̀kun?”

26 Ó sì bi í pé, “Kí ni a kọ sínú ìwé òfin? Báwo ni ìwọ sì ti kà á?”

27 (C)Ó sì dáhùn wí pé, “ ‘Kí ìwọ fi gbogbo àyà rẹ, àti gbogbo ọkàn rẹ, àti gbogbo agbára rẹ, àti gbogbo inú rẹ fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ’; àti, ‘ẹnìkejì rẹ bí ara rẹ.’ ”

28 (D)Ó sì wí fún un pé, “Ìwọ́ dáhùn rere. Ṣe èyí, ìwọ ó sì yè.”

Luku 10:38-42

Ní ilé Marta àti Maria

38 (A)Ó sì ṣe, bí wọ́n ti ń lọ, o wọ ìletò kan, obìnrin kan tí a ń pè ní Marta sì gbà á sí ilé rẹ̀. 39 Ó sì ní arábìnrin kan tí a ń pè ní Maria tí ó sì jókòó lẹ́bàá ẹsẹ̀ Olúwa, tí ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀. 40 Ṣùgbọ́n Marta ń ṣe ìyọnu ohun púpọ̀, ó sì tọ̀ ọ́ wá, ó wí pé, “Olúwa, ìwọ kò sì bìkítà sí ti arábìnrin mi pé ó fi mí sílẹ̀ láti máa nìkan ṣe ìránṣẹ́? Wí fún un kí ó ràn mí lọ́wọ́.”

41 (B)Ṣùgbọ́n Olúwa sì dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Marta, Marta, ìwọ ń ṣe àníyàn àti làálàá nítorí ohun púpọ̀. 42 Ṣùgbọ́n ohun kan ni a kò lè ṣe aláìní, Maria sì ti yan ipa rere náà tí a kò lè gbà lọ́wọ́ rẹ̀.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.