Galatia 3:1-4
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
Ìgbàgbọ́ tàbí iṣẹ́ òfin
3 Ẹ̀yin aláìnírònú ará Galatia! Ta ní ha tàn yín jẹ, kí ẹ̀yin má ṣe gba òtítọ́ gbọ́? Ní ojú ẹni tí a fi Jesu Kristi hàn gbangba láàrín yín ni ẹni tí a kàn mọ́ àgbélébùú. 2 Kìkì èyí ni mo fẹ́ béèrè lọ́wọ́ yín: Nípa iṣẹ́ òfin ni ẹ̀yin gba Ẹ̀mí bí, tàbí nípa ìgbọ́ràn pẹ̀lú ìgbàgbọ́? 3 Báyìí ni ẹ̀yin ṣe jẹ òmùgọ̀ tó bí? Ẹ̀yin tí ó ti bẹ̀rẹ̀ ìgbé ayé ìgbàgbọ́ yín nípa ti Ẹ̀mí, ṣé a ti wá sọ yín di pípé nípa ti ara ni? 4 Ẹ̀yin ha ti jìyà ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan wọ̀nyí lásán? Bí ó bá ṣe pé nítòótọ́ lásán ni.
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.