Add parallel Print Page Options

(A)Olúwa ti búra,
    kò sì í yí ọkàn padà pé,
“Ìwọ ni àlùfáà,
    ní ipasẹ̀ Melkisedeki.”

Read full chapter

Ní ti ìgbòòrò Ìjọba rẹ̀ àti àlàáfíà rẹ̀ ni kì yóò ní ìpẹ̀kun.
    Yóò jẹ ọba lórí ìtẹ́ Dafidi
àti lórí ẹ̀kún un rẹ̀ gbogbo,
    nípa ìfìdímúlẹ̀ àti ìgbéró rẹ̀,
pẹ̀lú òtítọ́ àti òdodo
    láti ìgbà náà lọ àti títí láéláé.
Ìtara Olúwa àwọn ọmọ-ogun
    ni yóò mú èyí ṣẹ.

Read full chapter

25 Wọn yóò gbé ní ilẹ̀ tí mo fún Jakọbu ìránṣẹ́ mi, ilẹ̀ tí àwọn baba yín ń gbé. Àwọn àti àwọn ọmọ wọn àti àwọn ọmọ ọmọ wọn ni yóò máa gbé ibẹ̀ láéláé, ìránṣẹ́ mi Dafidi ni yóò jẹ́ Ọmọ-aládé wọn láéláé.

Read full chapter

14 (A)A sì fi ìjọba, ògo àti agbára ilẹ̀ ọba fún un; gbogbo ènìyàn, orílẹ̀-èdè àti èdè gbogbo wọn wólẹ̀ fún un. Ìjọba rẹ̀, ìjọba ayérayé ni, èyí tí kò le è kọjá, ìjọba rẹ̀ kò sì le è díbàjẹ́ láéláé.

Read full chapter

Bible Gateway Sponsors