Add parallel Print Page Options

Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí ti ṣeminiti. Saamu ti Dafidi.

12 Ràn wá lọ́wọ́, Olúwa, nítorí ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run kò sí mọ́;
    Olóòtítọ́ tí pòórá kúrò láàrín àwọn ènìyàn.
Olúkúlùkù ń parọ́ fún aládùúgbò rẹ̀;
    ètè èké wọn ń sọ ẹ̀tàn.

Olúwa kí ó gé ètè èké wọn
    àti gbogbo ahọ́n ìfọ́nnu
tí ó wí pé,
    “Àwa ó borí pẹ̀lú ahọ́n wa;
    àwa ní ètè wa: Ta ni ọ̀gá wa?”

“Nítorí ìnilára àwọn aláìlágbára àti ìkérora àwọn aláìní,
    Èmi yóò dìde nísinsin yìí” ni Olúwa wí.
    “Èmi yóò dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ àwọn tí ń ṣe àrankàn wọn.”
Ọ̀rọ̀ Olúwa sì jẹ aláìlábùkù,
    gẹ́gẹ́ bí fàdákà tí a yọ́ nínú ìléru amọ̀,
    tí a sọ di mímọ́ nígbà méje.

Olúwa, ìwọ yóò pa wá mọ́
    kí o sì gbà wá lọ́wọ́ àwọn ènìyàn wọ̀nyí títí láé.
Àwọn ènìyàn búburú ń rin ìrìn fáàrí kiri
    nígbà tí wọn ń bọ̀wọ̀ fún òsì láàrín àwọn ènìyàn.