Add parallel Print Page Options

Ẹbọ ààyè mímọ́

12 (A)Nítorí náà mo fi ìyọ́nú Ọlọ́run bẹ̀ yín ará, kí ẹ̀yin kí ó fi ara yín fún Ọlọ́run ní ẹbọ ààyè mímọ́, ìtẹ́wọ́gbà, èyí ni iṣẹ́ ìsìn yín tí ó tọ̀nà. (B)Kí ẹ má sì da ara yín pọ̀ mọ́ ayé yìí; ṣùgbọ́n kí ẹ paradà láti di tuntun ní èrò inú yín, kí ẹ̀yin kí ó lè rí ìdí ìfẹ́ Ọlọ́run, tí ó dára, tí ó sì ṣe ìtẹ́wọ́gbà, ti ó sì pé.

Ìsìn ìrẹ̀lẹ̀ nínú Kristi

Ǹjẹ́ mo wí fún olúkúlùkù ènìyàn tí ó wà nínú yín, nípa oore-ọ̀fẹ́ tí a fi fún mi, kí ó má ṣe ro ara rẹ̀ ju bí ó ti yẹ ní rírò lọ; ṣùgbọ́n kí ó le rò níwọ́ntún-wọ́nsì, bí Ọlọ́run ti fi ìwọ̀n ìgbàgbọ́ fún olúkúlùkù. (C)Nítorí gẹ́gẹ́ bí àwa ti ní ẹ̀yà púpọ̀ nínú ara kan, tí gbogbo ẹ̀yà kò sì ní iṣẹ́ kan náà: (D)Bẹ́ẹ̀ ni àwa, tí a jẹ́ púpọ̀, a jẹ́ ara kan nínú Kristi, àti olúkúlùkù ẹ̀yà ara ọmọnìkejì rẹ̀. (E)Ǹjẹ́ bí àwa sì ti ń rí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ẹ̀bùn gbà gẹ́gẹ́ bí oore-ọ̀fẹ́ tí a fi fún wa, bí ó ṣe ìsọtẹ́lẹ̀ ni, kí a máa sọtẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n ìgbàgbọ́; Tàbí iṣẹ́ ìránṣẹ́, kí a kọjú sí iṣẹ́ ìránṣẹ́ wa tàbí ẹni tí ń kọ́ni, kí ó kọjú sí kíkọ́. Tàbí ẹni tí ó ń gbani níyànjú, sí ìgbìyànjú; ẹni tí ń fi fún ni kí ó máa fi inú kan ṣe é; ẹni tí ń ṣe olórí, kí ó máa ṣe é ní ojú méjèèjì; ẹni tí ń ṣàánú, kí ó máa fi inú dídùn ṣe é.

Ẹ̀kọ́ nípa ìfẹ́

Kí ìfẹ́ kí ó wà ní àìṣẹ̀tàn. Ẹ máa takété sí ohun tí í ṣe búburú; ẹ fi ara mọ́ ohun tí í ṣe rere. 10 Ní ti ìfẹ́ ará, ẹ máa fi ìyọ́nú fẹ́ràn ara yín; ní ti ọlá, ẹ máa fi ẹnìkejì yín ṣáájú. 11 Ní ti iṣẹ́ ṣíṣe, ẹ má ṣe ọ̀lẹ; ẹ máa ní ìgbóná ọkàn; ẹ máa sìn Olúwa. 12 (F)Ẹ máa yọ̀ ni ìrètí; ẹ máa mú sùúrù nínú ìpọ́njú; ẹ máa dúró gbọingbọin nínú àdúrà. 13 Ẹ máa pèsè fún àìní àwọn ènìyàn mímọ́; ẹ fi ara yín fún àlejò ṣíṣe.

14 (G)Ẹ máa súre fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí yín; ẹ máa súre, ẹ má sì ṣépè. 15 Àwọn tí ń yọ̀, ẹ máa bá wọn yọ̀, àwọn tí ń sọkún, ẹ máa bá wọn sọkún. 16 (H)Ẹ máa wà ní inú kan náà sí ara yín. Ẹ má ṣe gbéraga, ṣùgbọ́n ẹ má tẹ̀lé àwọn onírẹ̀lẹ̀. Ẹ má ṣe jẹ́ ọlọ́gbọ́n ní ojú ara yín.

17 (I)Ẹ má ṣe fi búburú san búburú fún ẹnikẹ́ni. Ẹ má pèsè ohun tí ó tọ́ níwájú gbogbo ènìyàn. 18 (J)Bí ó bá sé é ṣe, bí ó ti wà ní ipa tiyín, ẹ má wà ní àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn. 19 (K)Olùfẹ́ mi ọ̀wọ́n, ẹ má ṣe gbẹ̀san ara yín, ṣùgbọ́n ẹ fi ààyè sílẹ̀ fún ìbínú Ọlọ́run; nítorí a ti kọ ọ́ pé, Olúwa wí pé, “Tèmi ni ẹ̀san, èmi ó gbẹ̀san.” 20 (L)Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀,

“Bí ebi bá ń pa ọ̀tá rẹ, fún un ní oúnjẹ;
    bí òùngbẹ bá ń gbẹ ẹ́, fún un ní omi mu.
Ní ṣíṣe èyí, ìwọ ó kó ẹ̀yín iná lé e ní orí.”

21 Má ṣe jẹ́ kí búburú ṣẹ́gun rẹ, ṣùgbọ́n fi rere ṣẹ́gun búburú.

A Living Sacrifice

12 Therefore, I urge you,(A) brothers and sisters, in view of God’s mercy, to offer your bodies as a living sacrifice,(B) holy and pleasing to God—this is your true and proper worship. Do not conform(C) to the pattern of this world,(D) but be transformed by the renewing of your mind.(E) Then you will be able to test and approve what God’s will is(F)—his good, pleasing(G) and perfect will.

Humble Service in the Body of Christ

For by the grace given me(H) I say to every one of you: Do not think of yourself more highly than you ought, but rather think of yourself with sober judgment, in accordance with the faith God has distributed to each of you. For just as each of us has one body with many members, and these members do not all have the same function,(I) so in Christ we, though many, form one body,(J) and each member belongs to all the others. We have different gifts,(K) according to the grace given to each of us. If your gift is prophesying,(L) then prophesy in accordance with your[a] faith;(M) if it is serving, then serve; if it is teaching, then teach;(N) if it is to encourage, then give encouragement;(O) if it is giving, then give generously;(P) if it is to lead,[b] do it diligently; if it is to show mercy, do it cheerfully.

Love in Action

Love must be sincere.(Q) Hate what is evil; cling to what is good.(R) 10 Be devoted to one another in love.(S) Honor one another above yourselves.(T) 11 Never be lacking in zeal, but keep your spiritual fervor,(U) serving the Lord. 12 Be joyful in hope,(V) patient in affliction,(W) faithful in prayer.(X) 13 Share with the Lord’s people who are in need.(Y) Practice hospitality.(Z)

14 Bless those who persecute you;(AA) bless and do not curse. 15 Rejoice with those who rejoice; mourn with those who mourn.(AB) 16 Live in harmony with one another.(AC) Do not be proud, but be willing to associate with people of low position.[c] Do not be conceited.(AD)

17 Do not repay anyone evil for evil.(AE) Be careful to do what is right in the eyes of everyone.(AF) 18 If it is possible, as far as it depends on you, live at peace with everyone.(AG) 19 Do not take revenge,(AH) my dear friends, but leave room for God’s wrath, for it is written: “It is mine to avenge; I will repay,”[d](AI) says the Lord. 20 On the contrary:

“If your enemy is hungry, feed him;
    if he is thirsty, give him something to drink.
In doing this, you will heap burning coals on his head.”[e](AJ)

21 Do not be overcome by evil, but overcome evil with good.

Footnotes

  1. Romans 12:6 Or the
  2. Romans 12:8 Or to provide for others
  3. Romans 12:16 Or willing to do menial work
  4. Romans 12:19 Deut. 32:35
  5. Romans 12:20 Prov. 25:21,22