Òwe 5:1-14
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
Ìkìlọ̀ láti yàgò fún àgbèrè
5 Ọmọ mi, fiyèsí ọgbọ́n mi,
kí o sì dẹtí rẹ sí òye mi,
2 Kí ìwọ sì lè ní ìṣọ́ra
kí ètè rẹ sì le pa ìmọ̀ mọ́.
3 Nítorí ètè àwọn àjèjì obìnrin a máa sun bi oyin,
ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì kúnná ju òróró lọ.
4 Ṣùgbọ́n ní ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín, ó korò ju òróǹró lọ,
ó mú bí idà olójú méjì.
5 Ẹsẹ̀ rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sí ọ̀nà ikú
ìgbésẹ̀ rẹ̀ lọ tààrà sí ibojì òkú.
6 Kí ìwọ má ba à já ipa ọ̀nà ìyè;
ọ̀nà rẹ̀ rí pálapàla, ṣùgbọ́n kò tilẹ̀ mọ́.
7 Nítorí náà, ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ dẹtí sí mi,
kí ẹ̀yin kí ó má ṣe yàgò kúrò nínú ọ̀rọ̀ tí mo sọ.
8 Rìn ní ọ̀nà tí ó jìnnà sí ti rẹ̀,
má ṣe súnmọ́ ẹnu-ọ̀nà ilé rẹ̀
9 Àìṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ yóò gbé gbogbo ọlá rẹ lé ẹlòmíràn lọ́wọ́
àti ọjọ́ ayé rẹ fún ìkà ènìyàn.
10 Kí a má ba à fi ọrọ̀ rẹ fún àjèjì ènìyàn,
kí làálàá rẹ sì sọ ilé ẹlòmíràn di ọlọ́rọ̀.
11 Ní ìgbẹ̀yìn ayé rẹ ìwọ yóò kérora,
nígbà tí agbára rẹ àti ara rẹ bá ti joro tán
12 Ìwọ yóò wí pé, “Mo ti kórìíra ẹ̀kọ́ tó!
Ọkàn mi ṣe wá kórìíra ìbáwí!
13 N kò gbọ́rọ̀ sí àwọn olùkọ́ mi lẹ́nu,
tàbí kí n fetí sí àwọn tí ń kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́.
14 Mo ti bẹ̀rẹ̀ ìparun pátápátá
ní àárín gbogbo àwùjọ ènìyàn.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.