Add parallel Print Page Options

14 Yet it was kind of you to share my trouble. 15 And you Philippians yourselves know that in the beginning of the gospel, when I left Macedo′nia, no church entered into partnership with me in giving and receiving except you only; 16 for even in Thessaloni′ca you sent me help[a] once and again. 17 Not that I seek the gift; but I seek the fruit which increases to your credit. 18 I have received full payment, and more; I am filled, having received from Epaphrodi′tus the gifts you sent, a fragrant offering, a sacrifice acceptable and pleasing to God. 19 And my God will supply every need of yours according to his riches in glory in Christ Jesus. 20 To our God and Father be glory for ever and ever. Amen.

Final Greetings and Benediction

21 Greet every saint in Christ Jesus. The brethren who are with me greet you. 22 All the saints greet you, especially those of Caesar’s household.

23 The grace of the Lord Jesus Christ be with your spirit.

Read full chapter

Footnotes

  1. Philippians 4:16 Other ancient authorities read money for my needs

14 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ṣeun gidigidi ní ti pé ẹ̀yin ṣe alábápín nínú ìpọ́njú mi. 15 Ẹ̀yin pàápàá sì mọ̀ pẹ̀lú, ẹ̀yin ará Filipi, pé ni ìbẹ̀rẹ̀ ìhìnrere, nígbà tí mo kúrò ni Makedonia, kò sí ìjọ kan ti ó bá mi ń ṣe alábápín ní ti gbígbà àti fífún ni, bí kò ṣe ẹ̀yin nìkan ṣoṣo. 16 (A)Nítorí ní Tẹsalonika ẹ̀yin fi nǹkan ránṣẹ́, lẹ́ẹ̀kan fún àìní mi. 17 Kì í ṣe nítorí ti èmi ń fẹ́ ẹ̀bùn náà: ṣùgbọ́n èmi ń fẹ́ èso ti yóò máa di púpọ̀ nítorí yín 18 Ṣùgbọ́n mo ní ohun gbogbo, mo sì ti di púpọ̀: mo sì tún ni lọ́pọ̀lọpọ̀ nígbà ti mo tí gba nǹkan wọ̀nyí lọ́wọ́ Epafiroditu tí a ti rán wá láti lọ́dọ̀ yín, ọrẹ olóòórùn dídùn, ẹbọ ìtẹ́wọ́gbà, tì í ṣe inú dídùn gidigidi sí Ọlọ́run. 19 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run mi yóò pèsè ní kíkún fún gbogbo àìní yín, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú ògo nínú Kristi Jesu.

20 Ṣùgbọ́n ògo ni fún Ọlọ́run àti Baba wa láé àti láéláé. Àmín.

Ọ̀rọ̀ ìkíni ìkẹyìn

21 Ẹ kí olúkúlùkù ènìyàn mímọ́ nínú Kristi Jesu.

Àwọn ará tí ó wà pẹ̀lú mi kí yín.

22 Gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́ kí yín, pàápàá àwọn tí ń ṣe ti agbo ilé Kesari.

23 (B)Oore-ọ̀fẹ́ Jesu Kristi Olúwa wa, kí ó wà pẹ̀lú ẹ̀mí yín. Àmín.

Read full chapter