Add parallel Print Page Options

Ọgbọ́n

Orúkọ rere sàn ju ìpara olóòórùn dídùn lọ
    ọjọ́ ikú sì dára ju ọjọ́ tí a bí ènìyàn lọ
Ó dára láti lọ sí ilé ọ̀fọ̀
    ju ibi àsè
nítorí pé ikú jẹ́ àyànmọ́ gbogbo ènìyàn
    kí alààyè ní èyí ní ọkàn.
Ìbànújẹ́ dára ju ẹ̀rín lọ,
    ó le è mú kí ojú rẹ̀ dàrú,
    ṣùgbọ́n yóò jẹ́ kí àyà rẹ le.
Ọkàn ọlọ́gbọ́n wà ní ilé ọ̀fọ̀,
    ṣùgbọ́n ọkàn òmùgọ̀ ní ilé àríyá.
Ó dára láti gba ìbáwí ọlọ́gbọ́n,
    ju fífetísílẹ̀ sí orin òmùgọ̀ lọ.
Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀gún ti ń dún lábẹ́ ìkòkò
    ni ẹ̀rín òmùgọ̀,
    Asán sì ni eléyìí pẹ̀lú.
Ìrẹ́jẹ a máa sọ ọlọ́gbọ́n di òmùgọ̀,
    àbẹ̀tẹ́lẹ̀ sì máa ń ba ìwà jẹ́ ni.

Òpin ọ̀rọ̀ dára ju ìbẹ̀rẹ̀ rẹ̀ lọ,
    sùúrù sì dára ju ìgbéraga lọ.
Má ṣe yára bínú ní ọkàn rẹ
    nítorí pé orí ẹsẹ̀ òmùgọ̀ ni ìbínú ń gbé.

10 Má ṣe sọ wí pé, “Kí ni ìdí tí àtijọ́ fi dára ju èyí?”
    Nítorí pé, kò mú ọgbọ́n wá láti béèrè irú ìbéèrè bẹ́ẹ̀.

11 Ọgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí ogún ìní jẹ́ ohun tí ó dára
    ó sì ṣe àwọn tí ó rí oòrùn láǹfààní.
12 Ọgbọ́n jẹ́ ààbò
    gẹ́gẹ́ bí owó ti jẹ́ ààbò
ṣùgbọ́n àǹfààní òye ni èyí
    pé ọgbọ́n a máa tọ́jú ẹ̀mí ẹni tí ó bá ní.

13 Wo ohun tí Ọlọ́run ti ṣe:

“Ta ni ó le è to
    ohun tí ó ti ṣe ní wíwọ́?”
14 Nígbà tí àkókò bá dára, jẹ́ kí inú rẹ dùn,
    ṣùgbọ́n nígbà tí àkókò kò bá dára, rò ó
Ọlọ́run tí ó dá èkínní
    náà ni ó dá èkejì
nítorí náà, ènìyàn kò le è ṣàwárí
    ohun kankan nípa ọjọ́ iwájú rẹ̀.

15 Nínú ayé àìní ìtumọ̀ yìí ni mo ti rí gbogbo èyí:

Ènìyàn olóòtítọ́, ọkùnrin olódodo ń parun nínú òtítọ́ rẹ̀
    ìkà ènìyàn sì ń gbé ìgbé ayé pípẹ́ nínú ìkà rẹ̀.
16 Má ṣe jẹ́ olódodo jùlọ
    tàbí ọlọ́gbọ́n jùlọ
    kí ló dé tí o fi fẹ́ pa ara rẹ run?
17 Ìwọ ma ṣe búburú jùlọ kí ìwọ má sì ṣe aṣiwèrè
    Èéṣe tí ìwọ yóò fi kú kí ọjọ́ rẹ tó pé
18 Ó dára láti mú ọ̀kan
    kí o má sì ṣe fi èkejì sílẹ̀
    Ọkùnrin tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run yóò bọ́ lọ́wọ́ gbogbo àrékérekè.

19 Ọgbọ́n máa ń mú kí ọlọ́gbọ́n ènìyàn ní agbára
    ju alákòóso mẹ́wàá lọ ní ìlú.

20 Kò sí olódodo ènìyàn kan láyé
    tí ó ṣe ohun tí ó tọ́ tí kò dẹ́ṣẹ̀ rárá.

21 Má ṣe kíyèsi gbogbo ọ̀rọ̀ tí ènìyàn ń sọ
    bí bẹ́ẹ̀ kọ́, o le è gbọ́ pé ìránṣẹ́ rẹ ń ṣépè fún ọ.
22 Tí o sì mọ̀ nínú ọkàn rẹ
    pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni ìwọ fúnrarẹ̀ ti ṣépè fún àwọn ẹlòmíràn.

23 Gbogbo èyí ni mo ti dánwò nípa ọgbọ́n, tí mo sì wí pé,

“Mo pinnu láti jẹ́ ọlọ́gbọ́n”
    ṣùgbọ́n eléyìí ti jù mí lọ.
24 Ohun tí ó wù kí ọgbọ́n le è jẹ́,
    ó ti lọ jìnnà, ó sì jinlẹ̀
    ta ni ó le è ṣe àwárí rẹ̀?
25 Mo wá rò ó nínú ọkàn mi láti mọ̀,
    láti wá àti láti ṣàwárí ọgbọ́n
àti ìdí ohun gbogbo, àti láti mọ ìwà àgọ́
    búburú àti ti ìsínwín tàbí òmùgọ̀.

26 Mo rí ohun tí ó korò ju ikú lọ
    obìnrin tí ó jẹ́ ẹ̀bìtì,
tí ọkàn rẹ̀ jẹ́ tàkúté
    tí ọwọ́ rẹ̀ sì jẹ́ ẹ̀wọ̀n,
ọkùnrin tí ó bá tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn yóò le è yọ sílẹ̀
    ṣùgbọ́n ẹni dẹ́ṣẹ̀ kò le è bọ́ nínú tàkúté rẹ̀.

27 Oniwaasu wí pé, “Wò ó” eléyìí ni ohun tí mo ti ṣàwárí:

“Mímú ohun kan pọ̀ mọ́ òmíràn láti ṣàwárí ìdí ohun gbogbo.
28     Nígbà tí mo sì ń wá a kiri
ṣùgbọ́n tí n kò rí i
    mo rí ọkùnrin tí ó dúró dáradára kan láàrín ẹgbẹ̀rún
ṣùgbọ́n n kò rí obìnrin,
    kankan kí ó dúró láàrín gbogbo wọn.
29 Eléyìí nìkan ni mo tí ì rí:
    Ọlọ́run dá ìran ènìyàn dáradára,
    ṣùgbọ́n ènìyàn ti lọ láti ṣàwárí ohun púpọ̀.”