Numbers 1
New King James Version
The First Census of Israel(A)
1 Now the Lord spoke to Moses (B)in the Wilderness of Sinai, (C)in the tabernacle of meeting, on the (D)first day of the second month, in the second year after they had come out of the land of Egypt, saying: 2 (E)“Take a census of all the congregation of the children of Israel, by their families, by their fathers’ houses, according to the number of names, every male (F)individually, 3 from (G)twenty years old and above—all who are able to go to war in Israel. You and Aaron shall number them by their armies. 4 And with you there shall be a man from every tribe, each one the head of his father’s house.
5 “These are the names of the men who shall stand with you: from Reuben, Elizur the son of Shedeur; 6 from Simeon, Shelumiel the son of Zurishaddai; 7 from Judah, Nahshon the son of Amminadab; 8 from Issachar, Nethanel the son of Zuar; 9 from Zebulun, Eliab the son of Helon; 10 from the sons of Joseph: from Ephraim, Elishama the son of Ammihud; from Manasseh, Gamaliel the son of Pedahzur; 11 from Benjamin, Abidan the son of Gideoni; 12 from Dan, Ahiezer the son of Ammishaddai; 13 from Asher, Pagiel the son of Ocran; 14 from Gad, Eliasaph the son of (H)Deuel;[a] 15 from Naphtali, Ahira the son of Enan.” 16 (I)These were (J)chosen[b] from the congregation, leaders of their fathers’ tribes, (K)heads of the divisions in Israel.
17 Then Moses and Aaron took these men who had been [c]mentioned (L)by name, 18 and they assembled all the congregation together on the first day of the second month; and they recited their (M)ancestry by families, by their fathers’ houses, according to the number of names, from twenty years old and above, each one individually. 19 As the Lord commanded Moses, so he numbered them in the Wilderness of Sinai.
20 Now the (N)children of Reuben, Israel’s oldest son, their genealogies by their families, by their fathers’ house, according to the number of names, every male individually, from twenty years old and above, all who were able to go to war: 21 those who were numbered of the tribe of Reuben were forty-six thousand five hundred.
22 From the (O)children of Simeon, their genealogies by their families, by their fathers’ house, of those who were numbered, according to the number of names, every male individually, from twenty years old and above, all who were able to go to war: 23 those who were numbered of the tribe of Simeon were fifty-nine thousand three hundred.
24 From the (P)children of Gad, their genealogies by their families, by their fathers’ house, according to the number of names, from twenty years old and above, all who were able to go to war: 25 those who were numbered of the tribe of Gad were forty-five thousand six hundred and fifty.
26 From the (Q)children of Judah, their genealogies by their families, by their fathers’ house, according to the number of names, from twenty years old and above, all who were able to go to war: 27 those who were numbered of the tribe of Judah were (R)seventy-four thousand six hundred.
28 From the (S)children of Issachar, their genealogies by their families, by their fathers’ house, according to the number of names, from twenty years old and above, all who were able to go to war: 29 those who were numbered of the tribe of Issachar were fifty-four thousand four hundred.
30 From the (T)children of Zebulun, their genealogies by their families, by their fathers’ house, according to the number of names, from twenty years old and above, all who were able to go to war: 31 those who were numbered of the tribe of Zebulun were fifty-seven thousand four hundred.
32 From the sons of Joseph, the (U)children of Ephraim, their genealogies by their families, by their fathers’ house, according to the number of names, from twenty years old and above, all who were able to go to war: 33 those who were numbered of the tribe of Ephraim were forty thousand five hundred.
34 From the (V)children of Manasseh, their genealogies by their families, by their fathers’ house, according to the number of names, from twenty years old and above, all who were able to go to war: 35 those who were numbered of the tribe of Manasseh were thirty-two thousand two hundred.
36 From the (W)children of Benjamin, their genealogies by their families, by their fathers’ house, according to the number of names, from twenty years old and above, all who were able to go to war: 37 those who were numbered of the tribe of Benjamin were thirty-five thousand four hundred.
38 From the (X)children of Dan, their genealogies by their families, by their fathers’ house, according to the number of names, from twenty years old and above, all who were able to go to war: 39 those who were numbered of the tribe of Dan were sixty-two thousand seven hundred.
40 From the (Y)children of Asher, their genealogies by their families, by their fathers’ house, according to the number of names, from twenty years old and above, all who were able to go to war: 41 those who were numbered of the tribe of Asher were forty-one thousand five hundred.
42 From the children of Naphtali, their genealogies by their families, by their fathers’ house, according to the number of names, from twenty years old and above, all who were able to go to war: 43 those who were numbered of the tribe of Naphtali were fifty-three thousand four hundred.
44 (Z)These are the ones who were numbered, whom Moses and Aaron numbered, with the leaders of Israel, twelve men, each one representing his father’s house. 45 So all who were numbered of the children of Israel, by their fathers’ houses, from twenty years old and above, all who were able to go to war in Israel— 46 all who were numbered were (AA)six hundred and three thousand five hundred and fifty.
47 But (AB)the Levites were not numbered among them by their fathers’ tribe; 48 for the Lord had spoken to Moses, saying: 49 (AC)“Only the tribe of Levi you shall not number, nor take a census of them among the children of Israel; 50 (AD)but you shall appoint the Levites over the tabernacle of the Testimony, over all its furnishings, and over all things that belong to it; they shall carry the tabernacle and all its furnishings; they shall attend to it (AE)and camp around the tabernacle. 51 (AF)And when the tabernacle is to go forward, the Levites shall take it down; and when the tabernacle is to be set up, the Levites shall set it (AG)up. (AH)The outsider who comes near shall be put to death. 52 The children of Israel shall pitch their tents, (AI)everyone by his own camp, everyone by his own standard, according to their armies; 53 (AJ)but the Levites shall camp around the tabernacle of the Testimony, that there may be no (AK)wrath on the congregation of the children of Israel; and the Levites shall (AL)keep[d] charge of the tabernacle of the Testimony.”
54 Thus the children of Israel did; according to all that the Lord commanded Moses, so they did.
Footnotes
- Numbers 1:14 Reuel, Num. 2:14
- Numbers 1:16 called
- Numbers 1:17 designated
- Numbers 1:53 have in their care
Numeri 1
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
Ìkànìyàn
1 (A)Olúwa bá Mose sọ̀rọ̀ ní aginjù Sinai nínú àgọ́ àjọ ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kejì ní ọdún kejì tí àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti, ó wí pé: 2 “Ka gbogbo àgbájọ ènìyàn Israẹli nípa ẹbí wọn, àti nípa ìdílé baba wọn, to orúkọ wọn olúkúlùkù ọkùnrin ní ọ̀kọ̀ọ̀kan. 3 Ìwọ àti Aaroni ni kí ẹ kà gbogbo ọmọkùnrin Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn láti ọmọ ogún ọdún sókè, àwọn tí ó tó lọ sójú ogun. 4 Kí ẹ mú ọkùnrin kọ̀ọ̀kan láti inú olúkúlùkù ẹ̀yà kí ó sì wá pẹ̀lú yín, kí olúkúlùkù jẹ́ olórí ilé àwọn baba rẹ̀.
5 “Orúkọ àwọn ọkùnrin tí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ nìyí:
“Láti ọ̀dọ̀ Reubeni, Elisuri ọmọ Ṣedeuri;
6 Láti ọ̀dọ̀ Simeoni, Ṣelumieli ọmọ Suriṣaddai;
7 Láti ọ̀dọ̀ Juda, Nahiṣoni ọmọ Amminadabu;
8 Láti ọ̀dọ̀ Isakari, Netaneli ọmọ Ṣuari;
9 Láti ọ̀dọ̀ Sebuluni, Eliabu ọmọ Heloni;
10 Láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Josẹfu:
láti ọ̀dọ̀ Efraimu, Eliṣama ọmọ Ammihudu;
Láti ọ̀dọ̀ Manase, Gamalieli ọmọ Pedasuri;
11 Láti ọ̀dọ̀ Benjamini, Abidani ọmọ Gideoni;
12 Láti ọ̀dọ̀ Dani, Ahieseri ọmọ Ammiṣaddai;
13 Láti ọ̀dọ̀ Aṣeri, Pagieli ọmọ Okanri;
14 Láti ọ̀dọ̀ Gadi, Eliasafu ọmọ Deueli;
15 Láti ọ̀dọ̀ Naftali, Ahira ọmọ Enani.”
16 Àwọn wọ̀nyí ni wọ́n yàn nínú àwùjọ ènìyàn, olórí àwọn ẹ̀yà baba wọn. Àwọn ni olórí àwọn ẹbí Israẹli.
17 Mose àti Aaroni mú àwọn ènìyàn tí a dárúkọ wọ̀nyí 18 wọ́n sì pe gbogbo àwùjọ ènìyàn Israẹli jọ ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kejì. Àwọn ènìyàn sì dárúkọ baba ńlá wọn nípa ẹbí àti ìdílé wọn. Wọ́n sì ṣe àkọsílẹ̀ orúkọ àwọn ọmọkùnrin ní ọ̀kọ̀ọ̀kan láti ọmọ ogún ọdún sókè, 19 gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose. Bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe kà wọ́n nínú aginjù Sinai.
20 Láti ìran Reubeni tí í ṣe àkọ́bí Israẹli:
Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn, lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn. 21 Àwọn tí a kà ní ẹ̀yà Reubeni jẹ́ ẹgbàá-mẹ́tàlélógún ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (46,500).
22 Láti ìran Simeoni:
Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè, tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n kà, wọ́n sì to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn. 23 Iye àwọn tí á kà nínú ẹ̀yà Simeoni jẹ́ ẹgbàá-mọ́kàn-dínlọ́gbọ̀n ó-lé-ọ̀ọ́dúnrún (59,300).
24 Láti ìran Gadi:
Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan, gẹ́gẹ́ bí ẹbí àti ìdílé wọn. 25 Iye àwọn tí a kà nínú ẹ̀yà Gadi jẹ́ ẹgbàá-méjìlélógún ó-lé-àádọ́ta-lé-lẹ́gbẹ̀jọ (45,650).
26 Láti ìran Juda:
Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè, tí wọ́n le lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn. 27 Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Juda jẹ́ ẹgbàá-mẹ́tàdínlógójì ó-lé-ẹgbẹ̀ta (74,600).
28 Láti ìran Isakari:
Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè tí wọ́n le lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn. 29 Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Isakari jẹ́ ẹgbàá-mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n ó-lé-irínwó (54,400).
30 Láti ìran Sebuluni:
Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn. 31 Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Sebuluni jẹ́ ẹgbàá-méjì-dínlọ́gbọ̀n ó-lé-egbèje (57,400).
32 Láti inú àwọn ọmọ Josẹfu:
Láti ìran Efraimu:
Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọ́n jẹ́ ogún ọdún sókè tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn. 33 Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Efraimu jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (40,500).
34 Láti ìran Manase:
Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè, tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn. 35 Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Manase jẹ́ ẹgbàá ẹ́rìndínlógún ó-lé-igba (32,200).
36 Láti ìran Benjamini:
Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn. 37 Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Benjamini jẹ́ ẹgbàá-mẹ́tà-dínlógún ó-lé-egbèje (35,400).
38 Láti ìran Dani:
Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ọmọ ogún ọdún sókè, tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn. 39 Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Dani jẹ́ ẹgbàá-mọ́kànlélọ́gbọ̀n ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (62,700).
40 Láti ìran Aṣeri:
Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè, tí wọ́n le lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn. 41 Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Aṣeri jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ (41,500).
42 Láti ìran Naftali:
Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún ó lé, tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn. 43 Iye àwọn tí a kà nínú ẹ̀yà Naftali jẹ́ ẹgbàá-mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ó-lé-egbèje (53,400).
44 Wọ̀nyí ni àwọn ènìyàn tí Mose àti Aaroni kà, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn olórí méjìlá (12) fún Israẹli, tí ẹnìkọ̀ọ̀kan ṣojú fún ìdílé rẹ̀. 45 Gbogbo ọmọkùnrin Israẹli tó jẹ́ ọmọ ogún ọdún (20) sókè, tó sì lè lọ sójú ogun ni wọ́n kà gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn. 46 Àpapọ̀ iye wọn jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ ó-lé-egbéjì-dínlógún-dínàádọ́ta, (603,550).
47 (B)A kò ka àwọn ìdílé ẹ̀yà Lefi mọ́ àwọn ìyókù. 48 Nítorí Olúwa ti sọ fún Mose pé, 49 “Ìwọ kò gbọdọ̀ ka ẹ̀yà Lefi, tàbí kí o kà wọ́n mọ́ àwọn ọmọ Israẹli: 50 (C)Dípò èyí yan àwọn ọmọ Lefi láti jẹ́ alábojútó àgọ́ ẹ̀rí, lórí gbogbo ohun èlò àti ohun gbogbo tó jẹ́ ti àgọ́ ẹ̀rí. Àwọn ni yóò máa gbé àgọ́ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, wọn ó máa mójútó o, kí wọn ó sì máa pàgọ́ yí i ká. 51 Ìgbàkígbà tí àgọ́ yóò bá tẹ̀síwájú, àwọn ọmọ Lefi ni yóò tú palẹ̀, nígbàkígbà tí a bá sì tún pa àgọ́, àwọn ọmọ Lefi náà ni yóò ṣe é. Àlejò tó bá súnmọ́ tòsí ibẹ̀, pípa ni kí ẹ pa á 52 kí àwọn ọmọ Israẹli pa àgọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn olúkúlùkù ní ibùdó tirẹ̀ lábẹ́ ọ̀págun tirẹ̀. 53 Àwọn ọmọ Lefi yóò jẹ́ alábojútó àti olùtọ́jú àgọ́ ẹ̀rí náà, kí ìbínú má ba à sí lára ìjọ àwọn ọmọ Israẹli; kí àwọn ọmọ Lefi sì máa ṣe ìtọ́jú àgọ́ ẹ̀rí náà.”
54 Àwọn ọmọ Israẹli sì ṣe ohun gbogbo gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.
Scripture taken from the New King James Version®. Copyright © 1982 by Thomas Nelson. Used by permission. All rights reserved.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.
