Matiu 7:4-6
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
4 Tàbí ìwọ ó ti ṣe wí fún arákùnrin rẹ pé, ‘Jẹ́ kí èmi yọ ẹ̀rún igi tí ń bẹ ni ojú rẹ,’ sì wò ó ìtì igi ń bẹ ní ojú ìwọ tìkára rẹ. 5 Ìwọ àgàbàgebè, tètè kọ́ yọ ìtì igi jáde kúrò ní ojú ara rẹ ná, nígbà náà ni ìwọ yóò sì tó ríran kedere láti yọ ẹ̀rún igi tí ń bẹ ní ojú arákùnrin rẹ kúrò.
6 “Ẹ má ṣe fi ohun mímọ́ fún ajá jẹ, ẹ má sì ṣe sọ ohun ọ̀ṣọ́ olówó iyebíye yín fún ẹlẹ́dẹ̀, bí ẹ̀yin bá ṣe bẹ́ẹ̀ kí wọ́n má bà fi ẹsẹ̀ tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀, wọn a sì yí padà sí yín, wọn a sì bù yín jẹ.
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.