Matiu 6:4-6
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
4 kí ìfúnni rẹ má ṣe jẹ́ mí mọ̀. Nígbà náà ni Baba rẹ̀, tí ó sì mọ ohun ìkọ̀kọ̀ gbogbo, yóò san án fún ọ.
Àdúrà
5 (A)“Nígbà tí ìwọ bá ń gbàdúrà, má ṣe ṣe bí àwọn àgàbàgebè, nítorí wọn fẹ́ràn láti máa dúró gbàdúrà ní Sinagọgu àti ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà tí ènìyàn ti lè rí wọ́n. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, wọ́n ti gba èrè wọn ní kíkún. 6 Ṣùgbọ́n nígbà tí ìwọ bá ń gbàdúrà, wọ inú iyàrá rẹ lọ, sé ìlẹ̀kùn mọ́ ara rẹ, gbàdúrà sí Baba rẹ ẹni tí ìwọ kò rí. Nígbà náà ni Baba rẹ tí ó mọ gbogbo ohun ìkọ̀kọ̀ rẹ, yóò san án fún ọ.
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.