Add parallel Print Page Options

Ìdánwò Jesu

(A)Nígbà náà ni Ẹ̀mí Mímọ́ darí Jesu sí ijù láti dán an wò láti ọwọ́ èṣù. (B)Lẹ́yìn tí Òun ti gbààwẹ̀ ní ogójì ọ̀sán àti ogójì òru, ebi sì ń pa á. Nígbà náà ni olùdánwò tọ̀ ọ́ wá, ó wí pé, “Bí ìwọ bá ṣe Ọmọ Ọlọ́run, pàṣẹ kí òkúta wọ̀nyí di àkàrà.”

(C)Ṣùgbọ́n Jesu dáhùn pé, “A ti kọ ìwé rẹ̀ pé: ‘Ènìyàn kì yóò wà láààyè nípa àkàrà nìkan, bí kò ṣe nípa gbogbo ọ̀rọ̀ ti ó ti ẹnu Ọlọ́run jáde wá.’ ”

(D)Lẹ́yìn èyí ni èṣù gbé e lọ sí ìlú mímọ́ náà; ó gbé e lé ibi ṣóńṣó tẹmpili. (E)Ó wí pé, “Bí ìwọ̀ bá jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run, bẹ́ sílẹ̀ fún ara rẹ. A sá à ti kọ̀wé rẹ̀ pé:

“ ‘Yóò pàṣẹ fún àwọn angẹli rẹ̀ nítorí tìrẹ
    wọn yóò sì gbé ọ sókè ni ọwọ́ wọn
kí ìwọ kí ó má ba à fi ẹsẹ̀ rẹ gbún òkúta.’ ”

(F)Jesu sì dalóhùn, “A sá à ti kọ ọ́ pé: ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ dán Olúwa Ọlọ́run rẹ wò.’ ”

Lẹ́ẹ̀kan sí i, èṣù gbé e lọ sórí òkè gíga, ó sì fi gbogbo ilẹ̀ ọba ayé àti gbogbo ògo wọn hàn án. Ó sì wí fún un pé, “Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni èmi yóò fi fún ọ, bí ìwọ bá foríbalẹ̀ tí o sì sìn mi.”

10 (G)Jesu wí fún un pé, “Padà kúrò lẹ́yìn mi, Satani! Nítorí a ti kọ ọ́ pé: ‘Olúwa Ọlọ́run rẹ ni kí ìwọ kí ó fi orí balẹ̀ fún, òun nìkan ṣoṣo ni kí ìwọ máa sìn.’ ”

11 (H)Nígbà náà ni èṣù fi í sílẹ̀ lọ, àwọn angẹli sì tọ̀ ọ́ wá, wọ́n sì ṣe ìránṣẹ́ fún un.

Read full chapter

12 (A)Lẹ́sẹ̀kan náà, Ẹ̀mí Mímọ́ sì darí Jesu sí ijù, 13 Ó sì wà ní ogójì ọjọ́ ní aginjù. A sì ti ọwọ́ Satani dán an wò, ó sì wà pẹ̀lú àwọn ẹranko ìgbẹ́. Àwọn angẹli sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún un.

Read full chapter