Add parallel Print Page Options

67 Wọ́n tu itọ́ sí i ní ojú. Wọ́n kàn án lẹ́ṣẹ̀ẹ́. Àwọn ẹlòmíràn sì gbá a lójú. 68 Wọ́n wí pé, “Sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún wa! Ìwọ Kristi, Ta ni ẹni tí ó ń lù Ọ́?”

Read full chapter

65 Àwọn kan sì bẹ̀rẹ̀ sí í tu itọ́ sí i lára. Wọ́n dì í lójú. Wọ́n ń kàn án lẹ́ṣẹ̀ẹ́ lójú. Wọ́n fi ṣe ẹlẹ́yà pé, “Sọtẹ́lẹ̀!” Àwọn olùṣọ́ sì ń fi àtẹ́lẹwọ́ wọn gbá a lójú.

Read full chapter

22 Bí ó sì ti wí èyí tan, ọ̀kan nínú àwọn aláṣẹ tí ó dúró tì í fi ọwọ́ rẹ̀ lu Jesu, pé, “alábojútó àlùfáà ni ìwọ ń dá lóhùn bẹ́ẹ̀?”

23 (A)Jesu dá a lóhùn pé, “Bí mo bá sọ̀rọ̀ búburú, jẹ́rìí sí búburú náà: ṣùgbọ́n bí rere bá ni, èéṣe tí ìwọ fi ń lù mí?” 24 (B)Nítorí Annasi rán an lọ ní dídè sọ́dọ̀ Kaiafa olórí àlùfáà.

Read full chapter