Add parallel Print Page Options

56 Ṣùgbọ́n gbogbo wọ̀nyí ń ṣẹlẹ̀ kí ọ̀rọ̀ tí a tì ẹnu àwọn wòlíì sọ, tí a kọ sínú Ìwé Mímọ́ lè ṣẹ.” Nígbà yìí gan an ni gbogbo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ti kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì sálọ.

Níwájú Sahẹndiri

57 (A)Àwọn tí ó mú Jesu fà á lọ sí ilé Kaiafa, olórí àlùfáà, níbi ti àwọn olùkọ́ òfin àti gbogbo àwọn àgbàgbà Júù péjọ sí. 58 Ṣùgbọ́n Peteru ń tẹ̀lé e lókèèrè. Òun sì wá sí àgbàlá olórí àlùfáà. Ó wọlé, ó sì jókòó pẹ̀lú àwọn olùṣọ́. Ó ń dúró láti ri ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí Jesu.

Read full chapter