Add parallel Print Page Options

32 “Nísinsin yìí, ẹ kọ́ òwe lára igi ọ̀pọ̀tọ́: Nígbà tí ẹ̀ka rẹ̀ bá ti ń yọ tuntun tí ó bá sì ń ru ewé, ẹ̀yin mọ̀ pé ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn súnmọ́ tòsí. 33 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, nígbà tí ẹ̀yin bá sì rí i tí gbogbo nǹkan wọ̀nyí bá ń ṣẹlẹ̀, kí ẹ mọ̀ pé ìpadàbọ̀ mi dé tán lẹ́yìn ìlẹ̀kùn. 34 Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ìran yìí kì yóò kọjá títí tí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò fi ṣẹ. 35 Ọ̀run àti ayé yóò rékọjá, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ mi kì yóò rékọjá.

Read full chapter

28 “Nísinsin yìí, ẹ kọ́ òwe lára igi ọ̀pọ̀tọ́, nígbà tí ẹ̀ka rẹ bá ń yọ tuntun, tí ó bá sì ń rú ewé, èyí fihàn pé àkókò ẹ̀rùn ti dé. 29 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, nígbà tí ẹ ba ri àwọn ohun wọ̀nyí ti n ṣẹlẹ̀, kí ẹ mọ̀ pé ó súnmọ́ etílé tán, bi ìgbà tí ó wà lẹ́yìn ìlẹ̀kùn. 30 (A)Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín, ìran yìí kì yóò rékọjá títí a ó fi mú gbogbo nǹkan wọ̀nyí ṣẹ 31 (B)Ọ̀run àti ayé yóò kọjá lọ, ṣùgbọ́n àwọn ọ̀rọ̀ mi dúró dájú títí ayé àìnípẹ̀kun.

Read full chapter