Añadir traducción en paralelo Imprimir Opciones de la página

Jesu sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ikú ara rẹ̀

21 (A)(B) Láti ìgbà yìí lọ, Jesu bẹ̀rẹ̀ sí ṣàlàyé fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kedere nípa lílọ sí Jerusalẹmu láti jẹ ọ̀pọ̀ ìyà lọ́wọ́ àwọn àgbàgbà, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé, kí a sì pa òun, àti ní ọjọ́ kẹta, kí ó sì jíǹde.

22 Peteru mú Jesu sí ẹ̀gbẹ́ kan, ó bẹ̀rẹ̀ sí í bá a wí pé, “Kí a má rí i Olúwa! Èyí kì yóò ṣẹlẹ̀ sí Ọ!”

23 (C)Jesu pa ojú dà, ó sì wí fún Peteru pé, “Kúrò lẹ́yìn mi, Satani! Ohun ìkọ̀sẹ̀ ni ìwọ jẹ́ fún mi; ìwọ kò ro ohun tí i ṣe ti Ọlọ́run, bí kò ṣe èyí ti ṣe ti ènìyàn.”

24 (D)Nígbà náà ni Jesu wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó sẹ́ ara rẹ̀, kí ó sì gbé àgbélébùú rẹ̀, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn. 25 Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ gba ẹ̀mí rẹ̀ là, yóò sọ ẹ̀mí rẹ̀ nù ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ ẹ̀mí rẹ̀ nù nítorí mi, yóò rí i. 26 Èrè kí ni ó jẹ́ fún ènìyàn bí ó bá jèrè gbogbo ayé yìí, tí ó sì sọ ẹ̀mí rẹ̀ nù? Tàbí kí ni ènìyàn yóò fi dípò ẹ̀mí rẹ̀? 27 Nítorí Ọmọ ènìyàn yóò wá nínú ògo baba rẹ pẹ̀lú àwọn angẹli rẹ̀, nígbà náà ni yóò sì san án fún olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀.

28 “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín. Ẹlòmíràn wà nínú àwọn tí ó wà níhìn-ín yìí, tí kì yóò ri ikú títí wọn ó fi rí Ọmọ ènìyàn tí yóò máa bọ̀ ní ìjọba rẹ̀.”

Read full chapter

22 (A)Ó sì wí pé, “Ọmọ ènìyàn yóò jìyà ohun púpọ̀, a ó sì kọ̀ ọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn alàgbà, olórí àlùfáà àti láti ọ̀dọ̀ àwọn akọ̀wé, a ó sì pa á, ní ọjọ́ kẹta a ó sì jí i dìde.”

23 (B)Ó sì wí fún gbogbo wọn pé, “Bí ẹnìkan bá ń fẹ́ láti máa tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó sẹ́ ara rẹ̀, kí ó sì gbé àgbélébùú rẹ̀ ní ọjọ́ gbogbo, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn. 24 (C)Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ gba ọkàn rẹ̀ là, yóò sọ ọ́ nù: ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ ọkàn rẹ̀ nù nítorí mi, òun náà ni yóò sì gbà á là. 25 Nítorí pé èrè kín ni fún ènìyàn, bí ó jèrè gbogbo ayé, tí ó sì sọ ara rẹ̀ nù tàbí kí ó fi ṣòfò. 26 (D)Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá tijú mi, àti ọ̀rọ̀ mi, òun ni ọmọ ènìyàn yóò tijú rẹ̀ nígbà tí ó bá dé inú ògo tirẹ̀, àti ti baba rẹ̀, àti ti àwọn angẹli mímọ́.

27 (E)“Ṣùgbọ́n èmi wí fún yín nítòótọ́, ẹlòmíràn dúró níhìn-ín yìí, tí kì yóò rí ikú, títí wọn ó fi rí ìjọba Ọlọ́run.”

Read full chapter