Add parallel Print Page Options

Òwe afúnrúgbìn

13 (A)Ní ọjọ́ kan náà, Jesu kúrò ní ilé, ó jókòó sí etí Òkun. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn péjọ sọ́dọ̀ rẹ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi bọ́ sínú ọkọ̀ ojú omi, ó jókòó, gbogbo ènìyàn sì dúró létí Òkun. Nígbà náà ni ó fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ òwe bá wọn sọ̀rọ̀, wí pé: “Àgbẹ̀ kan jáde lọ gbin irúgbìn sínú oko rẹ̀. Bí ó sì ti gbin irúgbìn náà, díẹ̀ bọ́ sí ẹ̀bá ọ̀nà, àwọn ẹyẹ sì wá, wọ́n sì jẹ ẹ́. Díẹ̀ bọ́ sórí ilẹ̀ orí àpáta, níbi ti kò sí erùpẹ̀ púpọ̀. Àwọn irúgbìn náà sì dàgbàsókè kíákíá, nítorí erùpẹ̀ kò pọ̀ lórí wọn. Ṣùgbọ́n nígbà tí oòrùn gòkè, oòrùn gbígbóná jó wọn, gbogbo wọn sì rọ, wọ́n kú nítorí wọn kò ni gbòǹgbò. Àwọn irúgbìn mìíràn bọ́ sí àárín ẹ̀gún, ẹ̀gún sì dàgbà, ó sì fún wọn pa. Ṣùgbọ́n díẹ̀ tó bọ́ sórí ilẹ̀ rere, ó sì so èso, òmíràn ọgọ́ọ̀rún, òmíràn ọgọ́tọ̀ọ̀ta, òmíràn ọgbọọgbọ̀n, ni ìlọ́po èyí ti ó gbìn. Ẹni tí ó bá létí, kí ó gbọ́.”

Read full chapter

Òwe afúnrúgbìn

(A)Jesu sì tún bẹ̀rẹ̀ sí ń kọ́ni létí Òkun Àwọn ìjọ ènìyàn tí ó yí i ká pọ̀ jọjọ tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi bọ́ sínú ọkọ̀ ojú omi, tí ó sì jókòó nínú rẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ Òkun, nígbà tí àwọn ènìyàn sì wà ní ilẹ̀ létí Òkun. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀ nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ pé: “Ẹ fi etí sílẹ̀! Ní ọjọ́ kan, afúnrúgbìn kan jáde lọ láti lọ fúnrúgbìn rẹ̀. Bí ó ti ń fúnrúgbìn, díẹ̀ bọ́ sí ẹ̀bá ọ̀nà, àwọn ẹyẹ sì wá, wọ́n sì ṣà á jẹ. Díẹ̀ bọ́ sórí ilẹ̀ àpáta, níbi tí erùpẹ̀ ko sí púpọ̀. Láìpẹ́ ọjọ́, ó hu jáde. Ṣùgbọ́n nígbà tí oòrùn mú gangan, ó jóná, nítorí tí kò ní gbòǹgbò, ó gbẹ. Àwọn irúgbìn mìíràn sì bọ́ sáàrín ẹ̀gún, nígbà tí ẹ̀gún sì dàgbàsókè, ó fún wọn pa, tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn irúgbìn náà kò le so èso. Ṣùgbọ́n òmíràn bọ́ sí ilẹ̀ ọlọ́ràá, o sì so èso lọ́pọ̀lọpọ̀-òmíràn ọgbọọgbọ̀n, òmíràn ọgọọgọ́ta, àti òmíràn ọgọọgọ́rùn-ún.”

Jesu sì wí pé, “Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́, kí ó gbọ́.”

Read full chapter