Add parallel Print Page Options

19 Nígbà tí wọ́n bá mú yín, ẹ má ṣe ṣàníyàn ohun tí ẹ ó sọ tàbí bí ẹ ó ṣe sọ ọ́. Ní ojú kan náà ni a ó fi ohun tí ẹ̀yin yóò sọ fún yín. 20 Nítorí pé kì í ṣe ẹ̀yin ni ó sọ ọ́, bí kò ṣe Ẹ̀mí Baba yín tí ń sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ yín.

Read full chapter

11 (A)Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n bá ń fà yín lọ, tí wọ́n bá sì ń fi yín lé wọn lọ́wọ́, ẹ má ṣe ṣàníyàn ṣáájú ohun tí ẹ ó sọ. Ṣùgbọ́n ohun tí bá fi fún yín ní wákàtí náà, òun ni kí ẹ̀yin kí ó wí. Nítorí kì í ṣe ẹ̀yin ni ó ń wí, bí kò ṣe Ẹ̀mí Mímọ́.

Read full chapter

14 (A)Nítorí náà ẹ pinnu rẹ̀ ní ọkàn yín pé ẹ ko ronú ṣáájú, bí ẹ ó ti dáhùn. 15 Nítorí tí èmi ó fún yín ní ẹnu àti ọgbọ́n, tí gbogbo àwọn ọ̀tá yín kì yóò lè sọ̀rọ̀-òdì sí, tí wọn kì yóò sì lè kò lójú.

Read full chapter