Add parallel Print Page Options

14 Torí pé ẹ̀mí gbogbo ẹ̀dá ni ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, torí náà ni mo fi kìlọ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli pé wọn kò gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀ ohun abẹ̀mí kankan: torí pé nínú ẹ̀jẹ̀ ohun abẹ̀mí wọ̀nyí ni ẹ̀mí wọn wà: ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ẹ́ ni a ó gé kúrò.

15 “ ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ohun tí ó kú sílẹ̀ fúnrarẹ̀: tàbí èyí tí ẹranko búburú pa kálẹ̀ yálà onílé tàbí àlejò: ó ní láti fọ aṣọ rẹ̀. Kí ó sì fi omi wẹ ara rẹ̀: yóò sì wà ní ipò àìmọ́ títí di àṣálẹ́ lẹ́yìn èyí ni yóò tó di mímọ́. 16 Ṣùgbọ́n bí ó bá kọ̀ láti wẹ ara rẹ̀ tí kò sì fọ aṣọ rẹ̀ náà: ẹ̀bi rẹ̀ yóò wà lórí ara rẹ̀.’ ”

Read full chapter