Joshua Reviews Israel’s History

24 Then (A)Joshua gathered all the tribes of Israel at Shechem, and called for the elders of Israel, their heads, their judges, and their officers; and they presented themselves before God. Joshua said to all the people, “This is what the Lord, the God of Israel says: ‘From ancient times your fathers lived beyond the Euphrates River, namely, (B)Terah, the father of Abraham and the father of Nahor, and they served other gods. Then (C)I took your father Abraham from beyond the Euphrates River and led him through all the land of Canaan, and (D)multiplied his [a]descendants and gave him (E)Isaac. To Isaac I gave (F)Jacob and Esau, and (G)to Esau I gave Mount Seir, to possess it; but (H)Jacob and his sons went down to Egypt. Then (I)I sent Moses and Aaron, and I plagued Egypt [b]by what I did in its midst; and afterward I brought you out. So I brought your fathers out of Egypt, and (J)you came to the sea; and Egypt pursued your fathers with chariots and horsemen to the [c]Red Sea. But when they cried out to the Lord, He put darkness between you and the Egyptians, and brought the sea upon them and covered them; and your own eyes saw what I did in Egypt. And (K)you lived in the wilderness for a long time. Then (L)I brought you into the land of the Amorites, who lived beyond the Jordan, and they fought with you; but I handed them over to you, and you took possession of their land when I eliminated them before you. Then (M)Balak the son of Zippor, king of Moab, rose up and fought against Israel, and he sent messengers and summoned Balaam the son of Beor to curse you. 10 But I (N)was not willing to listen to Balaam. So he had to bless you, and I saved you from his hand. 11 (O)You crossed the Jordan and came to Jericho; and the citizens of Jericho fought against you, and (P)the Amorite, the Perizzite, the Canaanite, the Hittite, the Girgashite, the Hivite, and the Jebusite. Therefore (Q)I handed them over to you. 12 Then I (R)sent the hornet before you and it [d]drove out the two kings of the Amorites from you—(S)not by your sword nor your bow. 13 And (T)I gave you a land on which you had not labored, and cities which you had not built, and you have lived in them; you are eating of vineyards and olive groves which you did not plant.’

“We Will Serve the Lord

14 “Now, therefore, [e](U)fear the Lord and serve Him in sincerity and [f]truth; and do away with the gods which your fathers served beyond the Euphrates River and in Egypt, and serve the Lord. 15 But if it is disagreeable in your sight to serve the Lord, choose for yourselves today whom you will serve: whether the gods which your fathers served, which were beyond the Euphrates River, or (V)the gods of the Amorites in whose land you are living; but as for me and my house, we will serve the Lord.”

16 The people answered and said, “Far be it from us that we would abandon the Lord to serve other gods; 17 for the Lord our God is He who brought us and our fathers up out of the land of Egypt, from the house of slaves, and did these great signs in our sight and watched over us through all the way in which we went and among all the peoples through whose midst we passed. 18 The Lord drove out from before us all the peoples, even the Amorites who lived in the land. We also will serve the Lord, for He is our God.”

19 Then Joshua said to the people, “You will not be able to serve the Lord, (W)for He is a holy God. He is (X)a jealous God; (Y)He will not forgive your wrongdoing or your sins. 20 (Z)If you abandon the Lord and serve foreign gods, then He will turn and do you harm and destroy you after He has done good to you.” 21 And the people said to Joshua, “No, but we will serve the Lord.” 22 So Joshua said to the people, “You are witnesses against yourselves that (AA)you have chosen for yourselves the Lord, to serve Him.” And they said, “We are witnesses.” 23 “Now then, do away with the foreign gods which are in your midst, and (AB)incline your hearts to the Lord, the God of Israel.” 24 And (AC)the people said to Joshua, “We will serve the Lord our God and [g]obey His voice.” 25 (AD)So Joshua made a covenant with the people that day, and made for them a statute and an ordinance in Shechem. 26 And Joshua (AE)wrote these words in the Book of the Law of God; and he took a large stone and set it up there under the oak that was by the sanctuary of the Lord. 27 Then Joshua said to all the people, “Behold, (AF)this stone shall be a witness against us, because it has heard all the words of the Lord which He spoke [h]to us; so it shall be a witness against you, so that you do not deny your God.” 28 Then Joshua dismissed the people, each to his inheritance.

Joshua’s Death and Burial

29 Now it came about after these things that Joshua the son of Nun, the servant of the Lord, died, being 110 years old. 30 And they buried him in the territory of his inheritance, in (AG)Timnath-serah, which is in the hill country of Ephraim, on the north of Mount Gaash.

31 (AH)Israel served the Lord all the days of Joshua and all the days of the elders who [i]survived Joshua, and had known every deed of the Lord which He had done for Israel.

32 Now (AI)they buried the bones of Joseph, which the sons of Israel brought up from Egypt, at Shechem, in the plot of land (AJ)which Jacob had bought from the sons of Hamor the father of Shechem for a hundred [j]pieces of money; and they became the inheritance of Joseph’s sons. 33 And Eleazar the son of Aaron died; and they buried him at Gibeah, the town of his son (AK)Phinehas, which was given to him in the hill country of Ephraim.

Footnotes

  1. Joshua 24:3 Lit seed
  2. Joshua 24:5 Lit according to
  3. Joshua 24:6 Lit Sea of Reeds
  4. Joshua 24:12 Lit drove them out
  5. Joshua 24:14 Or revere
  6. Joshua 24:14 Or faithfulness
  7. Joshua 24:24 Lit listen to
  8. Joshua 24:27 Lit with
  9. Joshua 24:31 Lit prolonged days after
  10. Joshua 24:32 Heb qesitah

Májẹ̀mú di ọ̀tun ní Ṣekemu

24 Nígbà náà ni Joṣua pe gbogbo àwọn ẹ̀yà Israẹli jọ ní Ṣekemu. Ó pe àwọn àgbàgbà, àwọn olórí, onídàájọ́ àti àwọn ìjòyè Israẹli, wọ́n sì fi ara wọn hàn níwájú Ọlọ́run.

Joṣua sì sọ fun gbogbo ènìyàn pé, “Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run Israẹli, wí: ‘Nígbà kan rí àwọn baba ńlá yín Tẹra baba Abrahamu àti Nahori ń gbé ní ìkọjá odò Eufurate, wọ́n sì sin àwọn òrìṣà. Ṣùgbọ́n mo mú Abrahamu baba yín kúrò ní ìkọjá odò Eufurate, mo sì ṣe amọ̀nà rẹ̀ ni gbogbo Kenaani, mo sì fún ní àwọn ọmọ púpọ̀. Mo fún ní Isaaki, àti fún Isaaki ni mo fún ní Jakọbu àti Esau, mo sì fún Esau ní ilẹ̀ orí òkè Seiri ní ìní, ṣùgbọ́n Jakọbu àti àwọn ọmọ rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sí Ejibiti.

“ ‘Nígbà náà ni mo rán Mose àti Aaroni, mo sì yọ Ejibiti lẹ́nu ní ti nǹkan tí mo ṣe níbẹ̀, mo sì mú yín jáde. Nígbà tí mo mú àwọn baba yín jáde kúrò ní Ejibiti, ẹ wá sí Òkun, àwọn ará Ejibiti lépa wọn pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ ogun àti àwọn ẹlẹ́ṣin títí ó fi dé Òkun Pupa. Ṣùgbọ́n wọ́n ké pe Olúwa fún ìrànlọ́wọ́, ó sì fi òkùnkùn sí àárín yín àti àwọn ará Ejibiti, ó sì mú Òkun wá sí orí wọn; ó sì bò wọ́n mọ́lẹ̀. Ẹ sì fi ojú yín rí ohun tí mo ṣe sí àwọn ará Ejibiti. Lẹ́yìn náà ẹ sì gbé ní aginjù fún ọjọ́ pípẹ́.

“ ‘Èmi mú yín wá sí ilẹ̀ àwọn ará Amori tí ó ń gbé ìlà-oòrùn Jordani. Wọ́n bá yín jà, Ṣùgbọ́n mo fi wọ́n lé yín lọ́wọ́. Èmí pa wọ́n run kúrò níwájú u yín, ẹ sì gba ilẹ̀ ẹ wọn. Nígbà tí Balaki ọmọ Sippori, ọba Moabu, múra láti bá Israẹli jà, ó ránṣẹ́ sí Balaamu ọmọ Beori láti fi yín bú. 10 Ṣùgbọ́n èmi kò fetí sí Balaamu, bẹ́ẹ̀ ni ó súre fún un yín síwájú àti síwájú sí i, mo sì gbà yín kúrò ní ọwọ́ rẹ̀.

11 “ ‘Lẹ́yìn náà ni ẹ rékọjá Jordani, tí ẹ sì wá sí Jeriko. Àwọn ará ìlú Jeriko sì bá yín jà, gẹ́gẹ́ bí ará Amori, Peresi, Kenaani, Hiti, Girgaṣi, Hifi àti Jebusi. Ṣùgbọ́n mo fi wọ́n lé e yín lọ́wọ́. 12 Èmi sì rán oyin sí iwájú yín, tí ó lé wọn kúrò ní iwájú yín, àní ọba Amori méjì. Ẹ kò ṣe èyí pẹ̀lú idà yín àti ọrun yín. 13 Bẹ́ẹ̀ ni mo fún un yín ní ilẹ̀ tí ẹ̀yin kò ṣiṣẹ́ fún, àti àwọn ìlú tí ẹ̀ yin kò kọ́; ẹ sì ń gbé inú wọn, ẹ sì ń jẹ nínú ọgbà àjàrà àti ọgbà olifi tí ẹ kò gbìn.’

14 “Nísinsin yìí ẹ bẹ̀rù Olúwa, kí ẹ sì máa sìn ín ní òtítọ́ àti òdodo. Kí ẹ sì mú òrìṣà tí àwọn baba ńlá yín sìn ní ìkọjá odò Eufurate àti ní Ejibiti kúrò, kí ẹ sì máa sin Olúwa. 15 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá fẹ́ láti sin Olúwa, nígbà náà ẹ yàn fún ara yín ní òní ẹni tí ẹ̀yin yóò sìn bóyá òrìṣà tí àwọn baba ńlá yín sìn ní ìkọjá odò Eufurate, tàbí òrìṣà àwọn ará Amori, ní ilẹ̀ ẹni tí ẹ̀yin ń gbé. Ṣùgbọ́n ní ti èmi àti ilé mi, Olúwa ni àwa yóò máa sìn.”

16 Àwọn ènìyàn sì dáhùn pé, “Kí a má ri tí àwa yóò fi kọ Olúwa sílẹ̀ láti sin òrìṣà! 17 Nítorí Olúwa Ọlọ́run fúnrarẹ̀ ni ó gba àwọn baba ńlá wa là kúrò ní Ejibiti, ní oko ẹrú. Òun ni Ọlọ́run tí ó ṣe iṣẹ́ ìyanu ńlá níwájú àwọn ọmọ Israẹli. Ó pa wá mọ́ nínú gbogbo ìrìnàjò wa àti ní àárín gbogbo orílẹ̀-èdè tí a là kọjá. 18 Olúwa sì lé gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè jáde kúrò ní iwájú wa, pẹ̀lú àwọn Amori, tí ń gbé ilẹ̀ náà. Àwa náà yóò máa sin Olúwa, nítorí òun ni Ọlọ́run wa.”

19 Joṣua sì wí fún àwọn ènìyàn náà, pé, “Ẹ̀yin kò le sin Olúwa, nítorí Ọlọ́run mímọ́ ni òun; Ọlọ́run owú ni òun, Kì yóò dárí ìrékọjá àti ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín. 20 Bí ẹ bá kọ Olúwa tí ẹ sì sin òrìṣà orílẹ̀-èdè mìíràn òun yóò padà yóò sì mú ibi bá a yín, yóò sì pa yín run, lẹ́yìn ìgbà tí ó ti ṣe rere fún un yín tan.”

21 Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn sọ fún Joṣua pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́! A yàn láti sin Olúwa.”

22 Lẹ́yìn náà ni Joṣua wí pé, “Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí ara yín pé, ẹ ti yàn láti sin Olúwa.”

Wọ́n dáhùn wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, àwa ni ẹlẹ́rìí.”

23 Nígbà náà ni Joṣua dáhùn wí pé, “Ẹ mú òrìṣà orílẹ̀-èdè mìíràn tí ń bẹ ní àárín yín kúrò, ki ẹ sì yí ọkàn yín padà sí Olúwa, Ọlọ́run Israẹli.”

24 Àwọn ènìyàn náà sì wí fún Joṣua pé, “Olúwa Ọlọ́run nìkan ni àwa yóò máa sìn, òun nìkan ni àwa yóò máa ṣe ìgbọ́ràn sí.”

25 Ní ọjọ́ náà Joṣua dá májẹ̀mú fún àwọn ènìyàn, ó sì fi òfin àti ìlànà fún wọn ní Ṣekemu. 26 Joṣua sì kọ gbogbo ìdáhùn àwọn ènìyàn wọ̀nyí sí inú Ìwé Òfin Ọlọ́run. Lẹ́yìn náà ó gbé òkúta ńlá kan, ó gbé e kalẹ̀ ní abẹ́ igi óákù ní ẹ̀bá ibi mímọ́ Olúwa.

27 “E wò ó!” ó wí fún gbogbo ènìyàn pé, “Òkúta yìí ni yóò jẹ́ ẹlẹ́rìí fún wa, nítorí ó ti gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ tí Olúwa ti sọ fún wa. Yóò jẹ́ ẹlẹ́rìí yín tí ẹ bá ṣe àìṣòótọ́ sí Ọlọ́run yín.”

28 Lẹ́yìn náà ni Joṣua jẹ́ kí àwọn ènìyàn lọ, olúkúlùkù sí ilẹ̀ ìní rẹ̀.

Ikú Joṣua àti Eleasari

29 Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Joṣua ọmọ Nuni ìránṣẹ́ Olúwa, kú ní ẹni àádọ́fà ọdún (110) 30 Wọ́n sì sin ín sí ilẹ̀ ìní rẹ̀, ní Timnati Serah ni ilẹ̀ orí òkè Efraimu, ní ìhà àríwá Òkè Gaaṣi.

31 Israẹli sì sin Olúwa ní gbogbo ọjọ́ ayé Joṣua àti ní gbogbo ọjọ́ àwọn àgbàgbà tí ó wà lẹ́yìn ikú rẹ̀ tí wọ́n sì rí gbogbo iṣẹ́ ńlá tí Olúwa ṣe fún Israẹli.

32 (A)Egungun Josẹfu, èyí tí àwọn ọmọ Israẹli kó kúrò ní Ejibiti, ni wọ́n sin ní Ṣekemu ní ìpín ilẹ̀ tí Jakọbu rà fún ọgọ́ọ̀rún (100) fàdákà ní ọwọ́ Hamori, baba Ṣekemu. Èyí sì jẹ́ ilẹ̀ ìní àwọn ọmọ Josẹfu.

33 Eleasari ọmọ Aaroni sì kú, wọ́n sì sin ín ní Gibeah, tí a ti pín fún ọmọ rẹ̀ Finehasi ní òkè ilẹ̀ Efraimu.