Add parallel Print Page Options

Jesu sì lọ sí orí òkè olifi.

Ó sì tún padà wá sí tẹmpili ní kùtùkùtù òwúrọ̀, gbogbo ènìyàn sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀; ó sì jókòó, ó ń kọ́ wọn. Àwọn akọ̀wé àti àwọn Farisi sì mú obìnrin kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀, tí a mú nínú ṣíṣe panṣágà; wọ́n sì mú un dúró láàrín. Wọ́n sì wí fún un pé, “Olùkọ́, a mú obìnrin yìí nínú ìṣe panṣágà, Ǹjẹ́ nínú òfin, Mose pàṣẹ fún wa láti sọ irú àwọn obìnrin bẹ́ẹ̀ ní òkúta, ṣùgbọ́n ìwọ ha ti wí?” Èyí ni wọ́n wí, láti dán án wò, kí wọn ba à lè rí ẹ̀sùn kan kà sí i lọ́rùn.

Ṣùgbọ́n Jesu bẹ̀rẹ̀ sílẹ̀, ó sì ń fi ìka rẹ̀ kọ̀wé ní ilẹ̀. Nígbà tí wọ́n ń bi í léèrè lemọ́lemọ́, ó gbe orí rẹ sókè, ó sì wí fún wọn pé, “Jẹ́ kí ẹni tí ó wà láìní ẹ̀ṣẹ̀ nínú yín kọ́kọ́ sọ òkúta lù ú.” Ó sì tún bẹ̀rẹ̀ sílẹ̀, ó ń kọ̀wé ní ilẹ̀.

Nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, (tí ẹ̀rí ọkàn wọn sì dá wọn lẹ́bi) wọ́n sì jáde lọ lọ́kọ̀ọ̀kan, bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn àgbà títí dé àwọn tí ó kẹ́yìn; a sì fi Jesu nìkan sílẹ̀, àti obìnrin náà láàrín, níbi tí ó wà. 10 Jesu sì dìde, ó sì wí fún un pé, “Obìnrin yìí, àwọn (olùfisùn rẹ) dà? Kò sí ẹnìkan tí ó dá ọ lẹ́bi?”

11 Ó wí pé, “Kò sí ẹnìkan, Olúwa.”

Jesu wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ ni èmi náà kò dá ọ lẹ́bi: máa lọ, láti ìgbà yìí lọ, má dẹ́ṣẹ̀ mọ́.”

Ẹ̀rí Jesu dájú

12 (A)Jesu sì tún sọ fún wọn pé, “Èmi ni ìmọ́lẹ̀ ayé, ẹni tí ó bá tọ̀ mí lẹ́yìn kì yóò rìn nínú òkùnkùn, ṣùgbọ́n yóò ní ìmọ́lẹ̀ ìyè.”

13 (B)Nítorí náà àwọn Farisi wí fún un pé, “Ìwọ ń jẹ́rìí ara rẹ; ẹ̀rí rẹ kì í ṣe òtítọ́.”

14 Jesu dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Bí mo tilẹ̀ ń jẹ́rìí fún ara mi, òtítọ́ ni ẹ̀rí mi: nítorí tí mo mọ ibi tí mo ti wá, mo sì mọ ibi tí mo ń lọ; ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò lè mọ ibi tí mo ti wá, àti ibi tí mo ń lọ. 15 (C)Ẹ̀yin ń ṣe ìdájọ́ nípa ti ara; èmi kò ṣe ìdájọ́ ẹnikẹ́ni. 16 (D)Ṣùgbọ́n bí èmi bá sì ṣe ìdájọ́, òtítọ́ ni: nítorí èmi nìkan kọ́, ṣùgbọ́n èmi àti Baba tí ó rán mi. 17 (E)A sì kọ ọ́ pẹ̀lú nínú òfin pé, òtítọ́ ni ẹ̀rí ènìyàn méjì. 18 Èmi ni ẹni tí ń jẹ́rìí ara mi, Baba tí ó rán mi sì ń jẹ́rìí mi.”

19 (F)Nítorí náà wọ́n wí fún un pé, “Níbo ni Baba rẹ wà?”

Jesu dáhùn pé, “Ẹ̀yin kò mọ̀ mí, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò mọ Baba mi: ìbá ṣe pé ẹ̀yin mọ̀ mí, ẹ̀yin ìbá sì ti mọ Baba mi pẹ̀lú.” 20 (G)Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni Jesu sọ níbi ìṣúra, bí ó ti ń kọ́ni ní tẹmpili: ẹnikẹ́ni kò sì mú un; nítorí wákàtí rẹ̀ kò tí ì dé.

21 (H)Nítorí náà ó tún wí fún wọn pé, “Èmi ń lọ, ẹ̀yin yóò sì wá mi, ẹ ó sì kú nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín: ibi tí èmi gbé ń lọ, ẹ̀yin kì yóò lè wá.”

22 Nítorí náà àwọn Júù wí pé, “Òun ó ha pa ara rẹ̀ bí? Nítorí tí ó wí pé, ‘Ibi tí èmi gbé ń lọ, ẹ̀yin kì yóò lè wá’?”

23 (I)Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ti ìsàlẹ̀ wá; èmi ti òkè wá; ẹ̀yin jẹ́ ti ayé yìí; èmi kì í ṣe ti ayé yìí. 24 (J)Nítorí náà ni mo ṣe wí fún yín pé, ẹ ó kú nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín: nítorí bí kò ṣe pé ẹ bá gbàgbọ́ pé èmi ni, ẹ ó kú nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín.”

25 Nítorí náà wọ́n wí fún un pé, “Ta ni ìwọ jẹ́?”

Jesu sì wí fún un pé, “Èmi ni èyí tí mo ti wí fún yín ní àtètèkọ́ṣe. 26 Mo ní ohun púpọ̀ láti sọ, àti láti ṣe ìdájọ́ nípa yín: ṣùgbọ́n olóòtítọ́ ni ẹni tí ó rán mi, ohun tí èmi sì ti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá, wọ̀nyí ni èmi ń sọ fún aráyé.”

27 Kò yé wọn pé ti Baba ni ó ń sọ fún wọn. 28 (K)Lẹ́yìn náà Jesu wí fún wọn pé, “Nígbà tí ẹ mọ̀ pé, nígbà tí ẹ bá gbé Ọmọ ènìyàn sókè, nígbà náà ni ẹ ó mọ̀ pé èmi ni àti pé èmi kò dá ohunkóhun ṣe fún ara mi; ṣùgbọ́n bí Baba ti kọ́ mi, èmí ń sọ nǹkan wọ̀nyí. 29 Ẹni tí ó rán mí sì ń bẹ pẹ̀lú mi: kò fi mí sílẹ̀ ní èmi nìkan; nítorí tí èmi ń ṣe ohun tí ó wù ú nígbà gbogbo.” 30 (L)Bí ó ti ń sọ nǹkan wọ̀nyí, ọ̀pọ̀ ènìyàn gbà á gbọ́.

Àwọn ọmọ Abrahamu

31 (M)Nítorí náà Jesu wí fún àwọn Júù tí ó gbà á gbọ́, pé, “Bí ẹ bá tẹ̀síwájú nínú ọ̀rọ̀ mi ẹ ó jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn mi nítòótọ́. 32 (N)Ẹ ó sì mọ òtítọ́, òtítọ́ yóò sì sọ yín di òmìnira.”

33 (O)Wọ́n dá a lóhùn pé, “Irú-ọmọ Abrahamu ni àwa jẹ́, àwa kò sì ṣe ẹrú fún ẹnikẹ́ni rí láé; ìwọ ha ṣe wí pé, ‘Ẹ ó di òmìnira’?”

34 (P)Jesu dá wọn lóhùn pé, “Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń dẹ́ṣẹ̀, ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ ni. 35 (Q)Ẹrú kì í sì í gbé ilé títí láé: ọmọ ní ń gbé ilé títí láé 36 Nítorí náà, bí Ọmọ bá sọ yín di òmìnira ẹ ó di òmìnira nítòótọ́. 37 Mo mọ̀ pé irú-ọmọ Abrahamu ni ẹ̀yin jẹ́; ṣùgbọ́n ẹ ń wá ọ̀nà láti pa mí nítorí ọ̀rọ̀ mi kò rí ààyè nínú yín. Jesu sọ ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀ nípa ara rẹ̀. 38 Ohun tí èmi ti rí lọ́dọ̀ Baba ni mo sọ: ẹ̀yin pẹ̀lú sì ń ṣe èyí tí ẹ̀yin ti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ baba yín.”

39 Wọ́n dáhùn, wọ́n sì wí fún un pé, “Abrahamu ni baba wa!”

Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ìbá ṣe iṣẹ́ Abrahamu 40 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ẹ̀yin ń wá ọ̀nà láti pa mí, ẹni tí ó sọ òtítọ́ fún yín, èyí tí mo ti gbọ́ lọ́dọ̀ Ọlọ́run: Abrahamu kò ṣe èyí. 41 (R)Ẹ̀yin ń ṣe iṣẹ́ baba yín.”

Nígbà náà ni wọ́n wí fún un pé, “a kò bí wa nípa panṣágà: a ní Baba kan, èyí sì ni Ọlọ́run.”

Àwọn ọmọ èṣù

42 (S)Jesu wí fún wọn pé, “Ìbá ṣe pé Ọlọ́run ni Baba yín, ẹ̀yin ìbá fẹ́ràn mi: nítorí tí èmi ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run jáde, mo sì wá; bẹ́ẹ̀ ni èmi kò sì wá fún ara mi, ṣùgbọ́n òun ni ó rán mi. 43 Èéṣe tí èdè mi kò fi yé yín? Nítorí ẹ kò lè gbọ́ ọ̀rọ̀ mi. 44 (T)Ti èṣù baba yin ni ẹ̀yin jẹ́, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ baba yín ni ẹ sì ń fẹ́ ṣe. Apànìyàn ni òun jẹ́ láti àtètèkọ́ṣe, kò sì dúró nínú òtítọ́; nítorí tí kò sí òtítọ́ nínú rẹ̀. Nígbà tí ó bá ń ṣèké, nínú ohun tirẹ̀ ni ó ń sọ nítorí èké ni, àti baba èké. 45 Ṣùgbọ́n nítorí tí èmi ń sọ òtítọ́ fún yín, ẹ̀yin kò sì gbà mí gbọ́. 46 Ta ni nínú yín tí ó ti dá mi lẹ́bi ẹ̀ṣẹ̀? Bí mo bá ń ṣọ òtítọ́, èéṣe tí ẹ̀yin kò fi gbà mí gbọ́? 47 Ẹni tí ń ṣe ti Ọlọ́run, a máa gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: nítorí èyí ni ẹ̀yin kò ṣe gbọ́, nítorí ẹ̀yin kì í ṣe ti Ọlọ́run.”

Jesu béèrè nípa ohun tí n ṣe ti ara rẹ̀

48 (U)Àwọn Júù dáhùn wọ́n sì wí fún un pé, “Àwa kò wí nítòótọ́ pé, ará Samaria ni ìwọ jẹ́, àti pé ìwọ ní ẹ̀mí èṣù?”

49 Jesu sì dáhùn pé, “Èmi kò ní ẹ̀mí èṣù, ṣùgbọ́n èmi ń bu ọlá fún Baba mi, ẹ̀yin kò sì bu ọlá fún mi. 50 Èmi kò wá ògo ara mi: Ẹnìkan ń bẹ tí ó ń wá a tí yóò sì ṣe ìdájọ́. 51 Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, bí ẹnìkan bá pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, kì yóò rí ikú láéláé.”

52 Àwọn Júù wí fún un pé, “Nígbà yìí ni àwa mọ̀ pé ìwọ ní ẹ̀mí èṣù. Abrahamu kú, àti àwọn wòlíì; ìwọ sì wí pé, ‘Bí ẹnìkan bá pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, kì yóò tọ́ ikú wò láéláé’ 53 (V)Ìwọ ha pọ̀ ju Abrahamu Baba wa lọ, ẹni tí ó kú? Àwọn wòlíì sì kú: ta ni ìwọ ń fi ara rẹ pè?”

54 Jesu dáhùn wí pé, “Bí mo bá yin ara mi lógo, ògo mi kò jẹ́ nǹkan; Baba mi ni ẹni tí ń yìn mí lógo, ẹni tí ẹ̀yin wí pé, Ọlọ́run yín ní i ṣe: 55 Ẹ kò sì mọ̀ ọ́n: ṣùgbọ́n èmi mọ̀ ọ́n: bí mo bá sì wí pé, èmi kò mọ̀ ọ́n, èmi yóò di èké gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin: ṣùgbọ́n èmi mọ̀ ọ́n, mo sì pa ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́. 56 (W)Abrahamu baba yín yọ̀ láti rí ọjọ́ mi: ó sì rí i, ó sì yọ̀.”

57 (X)Nítorí náà, àwọn Júù wí fún un pé, “Ọdún rẹ kò ì tó àádọ́ta, ìwọ sì ti rí Abrahamu?”

58 (Y)Jesu sì wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún yín, kí Abrahamu tó wà, èmi ti wa.” 59 (Z)Nítorí náà wọ́n gbé òkúta láti sọ lù ú: ṣùgbọ́n Jesu fi ara rẹ̀ pamọ́, ó sì jáde kúrò ní tẹmpili.

but Jesus went to the Mount of Olives.(A)

At dawn he appeared again in the temple courts, where all the people gathered around him, and he sat down to teach them.(B) The teachers of the law and the Pharisees brought in a woman caught in adultery. They made her stand before the group and said to Jesus, “Teacher, this woman was caught in the act of adultery. In the Law Moses commanded us to stone such women.(C) Now what do you say?” They were using this question as a trap,(D) in order to have a basis for accusing him.(E)

But Jesus bent down and started to write on the ground with his finger. When they kept on questioning him, he straightened up and said to them, “Let any one of you who is without sin be the first to throw a stone(F) at her.”(G) Again he stooped down and wrote on the ground.

At this, those who heard began to go away one at a time, the older ones first, until only Jesus was left, with the woman still standing there. 10 Jesus straightened up and asked her, “Woman, where are they? Has no one condemned you?”

11 “No one, sir,” she said.

“Then neither do I condemn you,”(H) Jesus declared. “Go now and leave your life of sin.”(I)


Dispute Over Jesus’ Testimony

12 When Jesus spoke again to the people, he said, “I am(J) the light of the world.(K) Whoever follows me will never walk in darkness, but will have the light of life.”(L)

13 The Pharisees challenged him, “Here you are, appearing as your own witness; your testimony is not valid.”(M)

14 Jesus answered, “Even if I testify on my own behalf, my testimony is valid, for I know where I came from and where I am going.(N) But you have no idea where I come from(O) or where I am going. 15 You judge by human standards;(P) I pass judgment on no one.(Q) 16 But if I do judge, my decisions are true, because I am not alone. I stand with the Father, who sent me.(R) 17 In your own Law it is written that the testimony of two witnesses is true.(S) 18 I am one who testifies for myself; my other witness is the Father, who sent me.”(T)

19 Then they asked him, “Where is your father?”

“You do not know me or my Father,”(U) Jesus replied. “If you knew me, you would know my Father also.”(V) 20 He spoke these words while teaching(W) in the temple courts near the place where the offerings were put.(X) Yet no one seized him, because his hour had not yet come.(Y)

Dispute Over Who Jesus Is

21 Once more Jesus said to them, “I am going away, and you will look for me, and you will die(Z) in your sin. Where I go, you cannot come.”(AA)

22 This made the Jews ask, “Will he kill himself? Is that why he says, ‘Where I go, you cannot come’?”

23 But he continued, “You are from below; I am from above. You are of this world; I am not of this world.(AB) 24 I told you that you would die in your sins; if you do not believe that I am he,(AC) you will indeed die in your sins.”

25 “Who are you?” they asked.

“Just what I have been telling you from the beginning,” Jesus replied. 26 “I have much to say in judgment of you. But he who sent me is trustworthy,(AD) and what I have heard from him I tell the world.”(AE)

27 They did not understand that he was telling them about his Father. 28 So Jesus said, “When you have lifted up[a] the Son of Man,(AF) then you will know that I am he and that I do nothing on my own but speak just what the Father has taught me.(AG) 29 The one who sent me is with me; he has not left me alone,(AH) for I always do what pleases him.”(AI) 30 Even as he spoke, many believed in him.(AJ)

Dispute Over Whose Children Jesus’ Opponents Are

31 To the Jews who had believed him, Jesus said, “If you hold to my teaching,(AK) you are really my disciples. 32 Then you will know the truth, and the truth will set you free.”(AL)

33 They answered him, “We are Abraham’s descendants(AM) and have never been slaves of anyone. How can you say that we shall be set free?”

34 Jesus replied, “Very truly I tell you, everyone who sins is a slave to sin.(AN) 35 Now a slave has no permanent place in the family, but a son belongs to it forever.(AO) 36 So if the Son sets you free,(AP) you will be free indeed. 37 I know that you are Abraham’s descendants. Yet you are looking for a way to kill me,(AQ) because you have no room for my word. 38 I am telling you what I have seen in the Father’s presence,(AR) and you are doing what you have heard from your father.[b](AS)

39 “Abraham is our father,” they answered.

“If you were Abraham’s children,”(AT) said Jesus, “then you would[c] do what Abraham did. 40 As it is, you are looking for a way to kill me,(AU) a man who has told you the truth that I heard from God.(AV) Abraham did not do such things. 41 You are doing the works of your own father.”(AW)

“We are not illegitimate children,” they protested. “The only Father we have is God himself.”(AX)

42 Jesus said to them, “If God were your Father, you would love me,(AY) for I have come here from God.(AZ) I have not come on my own;(BA) God sent me.(BB) 43 Why is my language not clear to you? Because you are unable to hear what I say. 44 You belong to your father, the devil,(BC) and you want to carry out your father’s desires.(BD) He was a murderer from the beginning, not holding to the truth, for there is no truth in him. When he lies, he speaks his native language, for he is a liar and the father of lies.(BE) 45 Yet because I tell the truth,(BF) you do not believe me! 46 Can any of you prove me guilty of sin? If I am telling the truth, why don’t you believe me? 47 Whoever belongs to God hears what God says.(BG) The reason you do not hear is that you do not belong to God.”

Jesus’ Claims About Himself

48 The Jews answered him, “Aren’t we right in saying that you are a Samaritan(BH) and demon-possessed?”(BI)

49 “I am not possessed by a demon,” said Jesus, “but I honor my Father and you dishonor me. 50 I am not seeking glory for myself;(BJ) but there is one who seeks it, and he is the judge. 51 Very truly I tell you, whoever obeys my word will never see death.”(BK)

52 At this they exclaimed, “Now we know that you are demon-possessed!(BL) Abraham died and so did the prophets, yet you say that whoever obeys your word will never taste death. 53 Are you greater than our father Abraham?(BM) He died, and so did the prophets. Who do you think you are?”

54 Jesus replied, “If I glorify myself,(BN) my glory means nothing. My Father, whom you claim as your God, is the one who glorifies me.(BO) 55 Though you do not know him,(BP) I know him.(BQ) If I said I did not, I would be a liar like you, but I do know him and obey his word.(BR) 56 Your father Abraham(BS) rejoiced at the thought of seeing my day; he saw it(BT) and was glad.”

57 “You are not yet fifty years old,” they said to him, “and you have seen Abraham!”

58 “Very truly I tell you,” Jesus answered, “before Abraham was born,(BU) I am!”(BV) 59 At this, they picked up stones to stone him,(BW) but Jesus hid himself,(BX) slipping away from the temple grounds.

Footnotes

  1. John 8:28 The Greek for lifted up also means exalted.
  2. John 8:38 Or presence. Therefore do what you have heard from the Father.
  3. John 8:39 Some early manuscripts “If you are Abraham’s children,” said Jesus, “then