Add parallel Print Page Options

Jesu fi ara han àwọn Aposteli

19 (A)Ní ọjọ́ kan náà, lọ́jọ́ kìn-ín-ní ọ̀sẹ̀ nígbà tí alẹ́ lẹ́, tí a sì ti ìlẹ̀kùn ibi tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn gbé péjọ, nítorí ìbẹ̀rù àwọn Júù, bẹ́ẹ̀ ni Jesu dé, ó dúró láàrín, ó sì wí fún wọn pé, “Àlàáfíà fún yín.” 20 Nígbà tí ó sì ti wí bẹ́ẹ̀ tán, ó fi ọwọ́ àti ìhà rẹ̀ hàn wọ́n. Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn yọ̀, nígbà tí wọ́n rí Olúwa.

Read full chapter

27 (A)Nígbà náà ni ó wí fún Tomasi pé, “Mú ìka rẹ wá níhìn-ín yìí, kí o sì wo ọwọ́ mi; sì mú ọwọ́ rẹ wá níhìn-ín, kí o sì fi sí ìhà mi: kí ìwọ má ṣe jẹ́ aláìgbàgbọ́ mọ́, ṣùgbọ́n jẹ́ onígbàgbọ́.”

Read full chapter

(A)Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ọmọdé, ẹ ní ẹja díẹ̀ bí?”

Wọ́n dá a lóhùn pé, “Rárá o.”

Read full chapter

Nígbà tí wọ́n gúnlẹ̀, wọ́n rí ẹ̀yín iná níbẹ̀ àti ẹja lórí rẹ̀ àti àkàrà.

10 Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ mú nínú ẹja tí ẹ pa nísinsin yìí wá.” 11 Nítorí náà, Simoni Peteru gòkè, ó sì fa àwọ̀n náà wálẹ̀, ó kún fún ẹja ńlá, ó jẹ́ mẹ́tàléláádọ́jọ: bí wọ́n sì ti pọ̀ tó náà, àwọ̀n náà kò ya. 12 Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ wá jẹun òwúrọ̀.” Kò sì sí ẹnìkan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tí ó jẹ́ bí i pé, “Ta ni ìwọ ṣe?” Nítorí tí wọ́n mọ̀ pé Olúwa ni. 13 Jesu wá, ó sì mú àkàrà, ó sì fi fún wọn, bẹ́ẹ̀ sì ni ẹja.

Read full chapter

(A)Àti pé ó farahàn Peteru, lẹ́yìn èyí, àwọn méjìlá

Read full chapter

40 Òun ni Ọlọ́run jí dìde ni ọjọ́ kẹta ó sì fi i hàn gbangba. 41 Kì í ṣe fún gbogbo ènìyàn ni o ri, bí kò ṣe fún àwa ti a jẹ́ ẹlẹ́rìí ti a ti ọwọ́ Ọlọ́run yàn tẹ̀lé, ti a bá a jẹ, ti a sì bá à mu lẹ́yìn ìgbà ti ó jíǹde kúrò nínú òkú.

Read full chapter