Add parallel Print Page Options

Jobu tẹ̀síwájú nínú àròyé rẹ̀

14 “Ènìyàn tí a bí nínú obìnrin,
    ọlọ́jọ́ díẹ̀ ni, ó sì kún fún ìpọ́njú.
Ó jáde wá bí ìtànná ewéko, a sì ké e lulẹ̀;
    ó sì ń fò lọ bí òjìji, kò sì dúró pẹ́.
Ìwọ sì ń ṣíjú rẹ wò irú èyí ni?
    Ìwọ sì mú mi wá sínú ìdájọ́ pẹ̀lú rẹ?
Ta ni ó lè mú ohun mímọ́ láti inú àìmọ́ jáde wá?
    Kò sí ẹnìkan!
Ǹjẹ́ a ti pinnu ọjọ́ rẹ̀,
    iye oṣù rẹ̀ ń bẹ ní ọwọ́ rẹ;
    Ìwọ ti pààlà rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ní òun kò le kọjá rẹ̀.
Yípadà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, kí ó lè
    sinmi, títí yóò fi pé ọjọ́ rẹ̀ bí alágbàṣe.

“Nítorí pé ìrètí wà fún igi, bí a bá
    ké e lulẹ̀, pé yóò sì tún sọ,
    àti pé ẹ̀ka rẹ̀ tuntun kì yóò gbẹ.
Bí gbòǹgbò rẹ̀ tilẹ̀ di ogbó nínú ilẹ̀,
    tí kùkùté rẹ̀ si kú ni ilẹ̀;
Síbẹ̀ nígbà tí ó bá gbóòórùn omi,
    yóò sọ, yóò sì yọ ẹ̀ka jáde bí irúgbìn.
10 Ṣùgbọ́n ènìyàn kú, a sì dàánù;
    Àní ènìyàn jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀ lọ́wọ́: Òun kò sì sí mọ́.

Àgékúrú ọjọ́ ọmọ ènìyàn

11 “Bí omi ti í tán nínú ipa odò,
    àti bí odò ṣì tí í fà tí sì gbẹ,
12 bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn dùbúlẹ̀ tí kò sì dìde mọ́;
    títí ọ̀run kì yóò fi sí mọ́,
    wọ́n kì yóò jí, a kì yóò jí wọn kúrò lójú oorun wọn.

13 “Háà! ìwọ ìbá fi mí pamọ́ ní ipò òkú,
    kí ìwọ kí ó fi mí pamọ́ ní ìkọ̀kọ̀,
títí ìbínú rẹ yóò fi rékọjá,
    ìwọ ìbá lànà ìgbà kan sílẹ̀ fún mi, kí ó si rántí mi!
14 Bí ènìyàn bá kú yóò sì tún yè bí?
    Gbogbo ọjọ́ ìgbà tí a là sílẹ̀
    fún mi ni èmi dúró dè, títí àmúdọ̀tún mi yóò fi dé.
15 Ìwọ ìbá pè, èmi ìbá sì dá ọ lóhùn;
    ìwọ ó sì ní ìfẹ́ sì iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.
16 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ìwọ ń kaye ìṣísẹ̀ mi;
    ìwọ kò fa ọwọ́ rẹ kúrò nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mi?
17 A fi èdìdì di ìrékọjá mi sínú àpò,
    ìwọ sì rán àìṣedéédéé mi pọ̀.

18 “Àti nítòótọ́ òkè ńlá tí ó ṣubú, ó dasán,
    a sì ṣí àpáta kúrò ní ipò rẹ̀.
19 Omi a máa yinrin òkúta, ìwọ a sì
    mú omi sàn bo ohun tí ó hù jáde lórí ilẹ̀,
    ìwọ sì sọ ìrètí ènìyàn dí òfo.
20 Ìwọ ṣẹ́gun rẹ̀ láéláé, òun sì kọjá lọ!
    Ìwọ pa awọ ojú rẹ̀ dà, o sì rán an lọ kúrò.
21 Àwọn ọmọ rẹ̀ bọ́ sí ipò ọlá, òun kò sì mọ̀;
    wọ́n sì rẹ̀ sílẹ̀, òun kò sì kíyèsi i lára wọn.
22 Ṣùgbọ́n ẹran-ara rẹ̀ ni yóò rí
    ìrora. Ọkàn rẹ̀ ni yóò sì máa ní ìbìnújẹ́ nínú rẹ̀.”